-
2 Àwọn Ọba 9:25, 26Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
25 Jéhù wá sọ fún Bídíkárì tó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ rẹ̀ lójú ogun pé: “Gbé e, kí o sì jù ú sínú ilẹ̀ Nábótì ará Jésírẹ́lì.+ Rántí pé èmi pẹ̀lú rẹ jọ ń gun ẹṣin* tẹ̀ lé Áhábù bàbá rẹ̀ nígbà tí Jèhófà fúnra rẹ̀ kéde ìdájọ́ lé e lórí pé:+ 26 ‘“Bí mo ṣe rí ẹ̀jẹ̀ Nábótì+ àti ẹ̀jẹ̀ àwọn ọmọ rẹ̀ lánàá,” ni Jèhófà wí, “màá san án pa dà+ fún ọ ní ilẹ̀ yìí kan náà,” ni Jèhófà wí.’ Torí náà, gbé e, kí o sì jù ú sórí ilẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ.”+
-
-
2 Àwọn Ọba 10:7Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
7 Gbàrà tí lẹ́tà náà tẹ̀ wọ́n lọ́wọ́, wọ́n kó àwọn ọmọkùnrin ọba, wọ́n sì pa wọ́n, àwọn àádọ́rin (70) ọkùnrin,+ wọ́n kó orí wọn sínú apẹ̀rẹ̀, wọ́n sì kó wọn ránṣẹ́ sí i ní Jésírẹ́lì.
-