Ẹ̀KỌ́ 49
Ẹ̀rí tó Yè Kooro
NÍGBÀ tí o bá sọ ọ̀rọ̀ kan, ẹ̀tọ́ àwọn olùgbọ́ rẹ ni bí wọ́n bá bi ara wọn pé: “Kí nìdí tí ọ̀rọ̀ yẹn fi jóòótọ́? Ẹ̀rí wo ló fi hàn pé èèyàn lè tẹ́wọ́ gba ohun tí olùbánisọ̀rọ̀ yìí ń sọ?” Gẹ́gẹ́ bí olùkọ́, ojúṣe rẹ ni láti dáhùn irú àwọn ìbéèrè bẹ́ẹ̀ tàbí kí o darí àwọn olùgbọ́ rẹ sí ọ̀nà tí wọ́n á fi rí ìdáhùn sí wọn. Bí ọ̀rọ̀ náà bá ṣe pàtàkì nínú àlàyé tí ò ń ṣe, rí i dájú pé o jẹ́ kí àwọn olùgbọ́ rẹ rí àwọn ìdí pàtàkì tó fi yẹ kí wọ́n gbà á. Ìyẹn á túbọ̀ jẹ́ kí àlàyé tí ò ń ṣe yí wọn lọ́kàn padà.
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ lọ́nà tó ń yíni lọ́kàn padà. Ó máa ń yí àwọn tó ń bá sọ̀rọ̀ lọ́kàn padà nípa pípèsè ẹ̀rí tó yè kooro, nípa ṣíṣe àlàyé lọ́nà tó bọ́gbọ́n mu àti nípa fífi taratara rọni. Ó tipa báyìí fi àpẹẹrẹ tó dára lélẹ̀ fún wa. (Ìṣe 18:4; 19:8) Lóòótọ́, àwọn ẹlẹ́nuúdùnjuyọ̀ kan máa ń lo ọ̀nà ìyínilọ́kànpadà láti fi ṣi àwọn èèyàn lọ́nà. (Mát. 27:20; Ìṣe 14:19; Kól. 2:4) Wọ́n lè fi ìméfò lásán tí wọ́n á gbé kalẹ̀ bí òótọ́ ọ̀rọ̀ bẹ̀rẹ̀, wọ́n lè gba ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń sọ látọ̀dọ̀ àwọn ẹlẹ́tanú, àlàyé wọn lè máà lẹ́sẹ̀ nílẹ̀, wọ́n lè gbójú fo àwọn òótọ́ ọ̀rọ̀ tó tako ọ̀rọ̀ wọn, tàbí kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí rọni láti sáà gba ọ̀rọ̀ wọn láìwulẹ̀ ronú sí ọ̀rọ̀ náà rárá. Ó yẹ ká ṣọ́ra, kí á má ṣe lo irú àwọn ọ̀nà bẹ́ẹ̀ rárá.
Gbé Àlàyé Karí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Kò gbọ́dọ̀ jẹ́ èrò àpilẹ̀ṣe ti ara wa la fi ń kọ́ni. Ohun tí a kọ́ látinú Bíbélì ni ká gbìyànjú láti máa fi kọ́ni. Àwọn ìtẹ̀jáde tí ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ àti olóye ń tẹ̀ jáde sì ń ràn wá lọ́wọ́ gidigidi láti ṣe èyí. Ìtẹ̀jáde wọ̀nyí máa ń gbà wá níyànjú pé ká máa fara balẹ̀ yẹ Ìwé Mímọ́ wò. Àwa pẹ̀lú sì máa ń darí àwọn èèyàn sínú Bíbélì nítorí pé a fẹ́ fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ jẹ́ kí wọ́n fúnra wọn rí ohun tí ó sọ, kì í ṣe nítorí pé a fẹ́ fi ṣe ẹ̀rí láti fi dá ara wa láre. A gbà pẹ̀lú ohun tí Jésù Kristi sọ nígbà tó gbàdúrà sí Bàbá rẹ̀ pé: “Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ.” (Jòh. 17:17) Kò sí aláṣẹ kan tó ju Jèhófà Ọlọ́run, Ẹlẹ́dàá ọ̀run òun ayé lọ. Ká tó lè ka ẹ̀rí ọ̀rọ̀ sí èyí tó yè kooro, a ní láti gbé e karí Ọ̀rọ̀ rẹ̀.
Nígbà mìíràn, ó lè jẹ́ ẹni tí kò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ nípa Bíbélì tàbí ẹni tí kò kà á sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lò ń bá sọ̀rọ̀. O ní láti lo òye láti fi mọ ìgbà tó yẹ kó o tọ́ka sí ẹsẹ Bíbélì àti bí o ṣe máa darí ọ̀rọ̀ lọ síbẹ̀. Ṣùgbọ́n ó yẹ kí o gbìyànjú láti tètè pàfiyèsí wọn sí Bíbélì tó jẹ́ orísun ìsọfúnni tí àṣẹ rẹ̀ kò ṣeé jà níyàn.
Ǹjẹ́ ó yẹ kí o kàn gbà lọ́kàn rẹ pé bó o bá sáà ti lè ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tó wé mọ́ ọ̀rọ̀ tí ẹ̀ ń sọ, ọ̀ràn ti yanjú pátápátá nìyẹn? Bẹ́ẹ̀ kọ́ o. Ó lè béèrè pé kí o pàfiyèsí onítọ̀hún sí àlàyé tí Bíbélì ń ṣe níbi tí ẹsẹ yẹn wà láti lè fi yé e pé Bíbélì ti ọ̀rọ̀ tí o sọ lẹ́yìn lóòótọ́. Bí ó bá jẹ́ pé ìlànà kan lo kàn fẹ́ fà yọ látinú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yẹn, ṣùgbọ́n tí ọ̀rọ̀ ibẹ̀ kò dá lórí kókó ọ̀hún, ó lè nílò àlàyé púpọ̀ sí i. Ó lè jẹ́ pé àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ mìíràn tó jẹ mọ́ ọ̀ràn yẹn lo máa lò láfikún sí i láti mú un dá olùgbọ́ rẹ lójú pé orí Ìwé Mímọ́ lo gbé ọ̀rọ̀ rẹ kà.
Yẹra fún ṣíṣe àbùmọ́ ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ. Ńṣe ni kó o fara balẹ̀ kà á. Lóòótọ́, ẹsẹ Bíbélì yẹn lè jẹ mọ́ kókó tí ò ń sọ̀rọ̀ lé lórí. Síbẹ̀ kí àlàyé ọ̀rọ̀ rẹ tó lè yí olùgbọ́ rẹ lọ́kàn padà, ó yẹ kí òun náà lè rí i pé ẹ̀rí ohun tí ò ń sọ wà níbẹ̀ lóòótọ́.
Àfikún Ẹ̀rí Tó Ti Ọ̀rọ̀ Lẹ́yìn. Ní àwọn ìgbà mìíràn, ó lè dára bí èèyàn bá mú ẹ̀rí wá láti ibòmíràn tó ṣeé gbára lé yàtọ̀ sí Bíbélì, láti fi mú kí àwọn èèyàn rí bí ọ̀rọ̀ Ìwé Mímọ́ ṣe bọ́gbọ́n mu.
Bí àpẹẹrẹ, o lè tọ́ka sí ayé àti ojú ọ̀run tó ṣeé fojú rí láti fi jẹ́rìí sí i pé Ẹlẹ́dàá wà. O lè pàfiyèsí sí àwọn òfin àbáláyé, bí òfin òòfà, kí o wá ṣàlàyé pé wíwà tí irú àwọn òfin bẹ́ẹ̀ wà fi hàn pé ẹnì kan ló ṣe àwọn òfin wọ̀nyẹn. Àlàyé rẹ á yè kooro bí ó bá bá ohun tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mu. (Jóòbù 38:31-33; Sm. 19:1; 104:24; Róòmù 1:20) Irú ẹ̀rí bẹ́ẹ̀ wúlò nítorí pé ó máa ń fi hàn pé ohun tí Bíbélì wí bá ohun téèyàn lè rí pé ó ń ṣẹlẹ̀ lóòótọ́ mu.
Ṣé ò ń gbìyànjú láti mú kí ẹnì kan rí i pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì jẹ́ lóòótọ́? Ó ṣeé ṣe kí o fa ọ̀rọ̀ àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ tó sọ pé ó jẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yọ, ṣùgbọ́n ṣe ìyẹn wá ni ẹ̀rí tó fi hàn pé ó jẹ́ bẹ́ẹ̀ lóòótọ́? Kìkì àwọn tó bá bọ̀wọ̀ fún irú àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni irú àwọn ohun tó o fà yọ bẹ́ẹ̀ lè ràn lọ́wọ́. Ǹjẹ́ o wá lè gùn lé sáyẹ́ǹsì gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí tí wàá lò láti fi hàn pé Bíbélì jóòótọ́? Bó bá jẹ́ èrò inú àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tó jẹ́ ẹ̀dá aláìpé lo fẹ́ fi ṣe àfẹ̀yìntì rẹ, a jẹ́ pé orí ìpìlẹ̀ tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ lo gbára lé yẹn. Ṣùgbọ́n bó bá jẹ́ pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lo kọ́kọ́ fi bẹ̀rẹ̀ kí o tó ṣẹ̀ṣẹ̀ wá tọ́ka sí àwárí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì láti fi gbé ọ̀rọ̀ rẹ yọ pé ohun tó jóòótọ́ délẹ̀délẹ̀ ni Bíbélì sọ, ìgbà yẹn lo tó gbé ọ̀rọ̀ karí ìpìlẹ̀ tó yè kooro.
Ohun yòówù tó o bá sáà ń gbìyànjú láti fi ẹ̀rí rẹ̀ múlẹ̀, rí i pé o mú ẹ̀rí tó pọ̀ tó jáde. Irú àwùjọ tí ò ń bá sọ̀rọ̀ ló máa jẹ́ kí o mọ ìwọ̀n ẹ̀rí tó o máa mú jáde. Bí àpẹẹrẹ, ká ní ọ̀rọ̀ nípa ọjọ́ ìkẹyìn tí 2 Tímótì 3:1-5 mẹ́nu kàn lò ń sọ, o lè pe àfiyèsí olùgbọ́ rẹ sí ìròyìn kan tó délé dóko láti fi hàn pé àwọn èèyàn ti ya “aláìní ìfẹ́ni àdánidá.” Àpẹẹrẹ kan ṣoṣo yẹn lè ti tó láti fi jẹ́rìí pé apá yìí lára àmì tó fi hàn pé a wà nínú àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ti ń ṣẹ báyìí.
Lílo àfiwé, ìyẹn fífi nǹkan méjì tó jọra wéra, sábà máa ń dára. Àmọ́ ṣá o, fífi àwọn nǹkan kan wéra nìkan kò lè dá fi ìdí ẹ̀rí ohunkóhun múlẹ̀; ó dìgbà tí a bá fi ohun tí Bíbélì fúnra rẹ̀ wí wọ̀n ọ́n wò kí á tó lè mọ̀ bóyá ó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀. Ṣùgbọ́n àfiwé yẹn lè jẹ́ kí onítọ̀hún rí bí kókó kan ṣe bọ́gbọ́n mu tó. Bí àpẹẹrẹ, o lè lo irú àfiwé yẹn nígbà tí o bá ń ṣe àlàyé nípa pé ìjọba gidi kan ni Ìjọba Ọlọ́run jẹ́. O lè fi hàn pé Ìjọba Ọlọ́run ní àwọn alákòóso, ó ní àwọn tó ń ṣàkóso lé lórí, ó ní àwọn òfin, ó ní ètò ìdájọ́ àti ètò ẹ̀kọ́ lọ́nà kan náà bíi ti ìjọba àwọn èèyàn.
Lọ́pọ̀ ìgbà, o lè lo ìrírí ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ti gidi láti fi hàn pé ó bọ́gbọ́n mu láti máa fi ìmọ̀ràn Bíbélì sílò. A tún lè lo ìrírí tẹni fúnra ẹni láti fi ti ohun kan téèyàn sọ lẹ́yìn. Bí àpẹẹrẹ, bí o bá ń sọ fún ẹnì kan nípa bí ó ṣe ṣe pàtàkì tó pé kéèyàn máa ka Bíbélì dáadáa, o lè ṣàlàyé ọ̀nà tí kíka Bíbélì ti gbà tún ayé tìrẹ ṣe. Àpọ́sítélì Pétérù sọ ìran ìyípadà ológo tó ṣẹlẹ̀ sí Jésù, èyí tí òun fúnra rẹ̀ fojú rí, láti fi gba àwọn ará ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ níyànjú. (2 Pét. 1:16-18) Pọ́ọ̀lù pẹ̀lú sọ nípa ìrírí tòun fúnra rẹ̀. (2 Kọ́r. 1:8-10; 12:7-9) Àmọ́ ṣá o, ìwọ̀nba ni kí o lo ìrírí tìrẹ fúnra rẹ mọ, kó má lọ di pé o wá ń pàfiyèsí sí ara rẹ jù.
Nítorí pé ibi tí kálukú ti wá yàtọ̀, tí ọ̀nà tí kálukú gbà ń ronú sì yàtọ̀, ẹ̀rí tó yí ẹnì kan lérò padà lè máa tíì tẹ́ ẹlòmíràn lọ́rùn. Nípa bẹ́ẹ̀, ronú nípa ohun tó jẹ́ èrò àwọn olùgbọ́ rẹ nígbà tí o bá ń yan àlàyé tí o máa ṣe àti ọ̀nà tí o máa gbà ṣe é. Òwe 16:23 sọ pé: “Ọkàn-àyà ọlọ́gbọ́n ń mú kí ẹnu rẹ̀ fi ìjìnlẹ̀ òye hàn, èyí sì ń fi ìyíniléròpadà kún ètè rẹ̀.”