Ẹ̀KỌ́ 19
Fúnni Níṣìírí Láti Lo Bíbélì
OHUN tó jẹ wá lógún ni pé ká darí àfiyèsí gbogbo èèyàn sí Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ìwé Mímọ́ la gbé ohun tí à ń wàásù kà, a sì fẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ohun tí à ń sọ ti wá, kì í ṣe ìdánúṣe ti ara wa. Àwọn èèyàn gbọ́dọ̀ fọkàn tán ọ̀rọ̀ inú Bíbélì.
Ní Òde Ẹ̀rí. Nígbà tó o bá ń múra òde ẹ̀rí sílẹ̀, rí i pé o yan ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ tí wàá kà fáwọn tó bá fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ṣe ni o kàn fẹ́ fi ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ̀ wọ́n láìsọ̀rọ̀ lọ títí, ó ṣì ṣàǹfààní láti ka ẹsẹ Bíbélì kan tó ti ọ̀rọ̀ rẹ lẹ́yìn. Bíbélì ní agbára ńlá láti tọ́ àwọn ẹni bí àgùntàn sọ́nà ju ọ̀rọ̀ èyíkéyìí tí àwa fúnra wa lè sọ jáde lẹ́nu. Níbi tí kò bá ti ṣeé ṣe láti ka Bíbélì, o kàn lè sọ ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ jáde. Ní ọ̀rúndún kìíní, àwọn ẹ̀dà àkájọ Ìwé Mímọ́ kò fi bẹ́ẹ̀ wọ́pọ̀. Ṣùgbọ́n, léraléra ni Jésù àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ń fa ọ̀rọ̀ yọ látinú Ìwé Mímọ́. Ó yẹ kí àwa náà sapá láti mọ àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ sórí, ká sì máa lò wọ́n lọ́nà yíyẹ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, nígbà mìíràn kí á kàn fa ọ̀rọ̀ yọ látinú wọn.
Nígbà tó bá ṣeé ṣe fún ọ láti ka Bíbélì, ṣí i dání lọ́nà tí onílé yóò fi lè máa fojú bá a lọ bí o ti ń kà á. Bí onílé bá ń fojú bá a lọ nínú ẹ̀dà Bíbélì tirẹ̀, ìṣarasíhùwà rẹ̀ nípa ohun tó kà lè túbọ̀ dára sí i.
Ṣùgbọ́n jẹ́ kí ó yé ọ pé ńṣe ni àwọn olùtumọ̀ Bíbélì kan kàn túmọ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sí ọ̀nà tó wù wọ́n. Ohun tí wọ́n tú lè máà bá ohun tó wà nínú èdè Bíbélì ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ mu délẹ̀délẹ̀. Àwọn Bíbélì ìgbàlódé kan tiẹ̀ ti yọ orúkọ Ọlọ́run kúrò, wọ́n ti yí ohun tí Bíbélì èdè ìpilẹ̀ṣẹ̀ sọ nípa ipò àwọn òkú padà, wọ́n sì ti mú kí ohun tí Bíbélì sọ nípa ète Ọlọ́run fún ilẹ̀ ayé fara sin. Kí ẹnì kan tó lè rí itú táwọn aráabí yẹn pa, ó lè di dandan kí onítọ̀hún fi àwọn ẹsẹ tó ṣe kókó nínú oríṣiríṣi ẹ̀dà Bíbélì tàbí nínú àwọn ìtumọ̀ Bíbélì àtijọ́ ní èdè kan náà wéra. Nígbà tí ìwé Reasoning From the Scriptures ń ṣàlàyé ọ̀pọ̀ kókó ọ̀rọ̀, ó ṣe àwọn ìfiwéra tó fi hàn bí onírúurú ìtumọ̀ ṣe tú àwọn gbólóhùn pàtàkì nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì kan tá a sábà máa ń lò. Inú ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ràn òtítọ́ á dùn láti mọ òkodoro ọ̀rọ̀ yìí.
Nínú Ìpàdé Ìjọ. Kí a fún gbogbo èèyàn níṣìírí láti máa lo Bíbélì wọn nínú ìpàdé ìjọ. Èyí ṣàǹfààní lọ́pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà. Ó ń jẹ́ kí àwùjọ lè pọkàn pọ̀ sórí ọ̀rọ̀ tí à ń sọ lọ́wọ́. Ó ń jẹ́ kí wọ́n tún lè máa fojú ara wọn rí ọ̀rọ̀ ìtọ́ni tí olùbánisọ̀rọ̀ ń sọ. Ó tún ń tẹ̀ ẹ́ mọ́ àwọn olùfìfẹ́hàn lọ́kàn pé Bíbélì ni a gbé àwọn ìgbàgbọ́ wa kà ní tòótọ́.
Bí àwùjọ ṣe ń fojú bá àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí ò ń kà lọ sí nínú Bíbélì tiwọn yóò sinmi púpọ̀ lórí ìṣírí tó o bá fún wọn. Rírọ̀ wọ́n ní tààràtà pé kí wọ́n ṣí Bíbélì tiwọn ni ọ̀kan lára ọ̀nà tó dára jù lọ.
Ojúṣe ìwọ olùbánisọ̀rọ̀ ni láti mọ àwọn ẹsẹ tó o fẹ́ tẹnu mọ́ nípa rírọ àwùjọ pé kí wọ́n ṣí i. Ohun tó máa ń dára jù ni láti ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí yóò gbé àwọn kókó pàtàkì inú ọ̀rọ̀ rẹ yọ. Lẹ́yìn náà, tí àyè rẹ̀ bá yọ, o lè tún wá ka àwọn mìíràn tí ó ti ọ̀rọ̀ rẹ lẹ́yìn.
Ṣùgbọ́n o, wíwulẹ̀ pe ẹsẹ tó o fẹ́ kà, tàbí wíwulẹ̀ rọ àwùjọ pé kí wọ́n ṣí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kì í sábàá tó. Bí o bá ka ẹsẹ kan, tó o sì tún kọjá sórí òmíràn kí àwùjọ tóó rí èyí tó o kọ́kọ́ pè, kò ní pẹ́ sú wọn, wọn ò sì ní ṣí Bíbélì wọn mọ́. Nítorí náà, fojú sílẹ̀. Ìgbà tí àwọn tó pọ̀ jù lọ bá ti rí ẹsẹ Bíbélì náà ni kí o tó kà á.
Ńṣe ni kó o ti máa ronú síwájú. Tètè máa pe ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó o fẹ́ kà ṣáájú ìgbà tó o máa bẹ̀rẹ̀ sí kà á. Èyí á dín àkókò tí wàá fi máa dúró de àwùjọ kù. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé fífàyè sílẹ̀ kí àwùjọ rí ẹsẹ Bíbélì kó o tó kà á yóò dín ọ̀rọ̀ rẹ kù, àwọn àǹfààní tó ń tìdí ẹ̀ yọ tó ohun téèyàn ń tìtorí ẹ̀ ṣe bẹ́ẹ̀.