Àpótí Ìbéèrè
◼ Èé ṣe tó fi ṣàǹfààní pé kí àwùjọ máa ṣí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ nígbà tí olùbánisọ̀rọ̀ bá sọ pé kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tó bá ń sọ àsọyé?
Kókó ọ̀rọ̀ tó ń jíròrò àti bóyá àsọyé náà jẹ́ àgbéyẹ̀wò apá kan nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, níbi tó ti ń ṣàlàyé ẹsẹ kan tẹ̀ lé òmíràn ni àwọn kókó tí yóò pinnu iye ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí ó lè sọ pé kí àwùjọ ṣí.
Ó ṣe pàtàkì pé kó ní in lọ́kàn pé ọ̀kan nínú ète tó fi ń ṣàyẹ̀wò àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ jẹ́ láti mú kí ó dáni lójú pé inú Bíbélì ni ohun tó ń sọ ti wá. (Ìṣe 17:11) Ète mìíràn jẹ́ láti ṣàyẹ̀wò ẹ̀rí Ìwé Mímọ́ tó ti ohun tó ń bá wọn jíròrò lẹ́yìn, kí ó lè fún ìgbàgbọ́ àwùjọ lókun. Rírí ohun tí Bíbélì sọ gan-an nígbà tí a bá ń ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ pàtàkì kan yóò jẹ́ kó túbọ̀ wọni lọ́kàn. Ní àfikún sí wíwo àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́, ó tún ṣàǹfààní láti máa kọ nǹkan sílẹ̀, kí á sì máa fọkàn bá àlàyé tí wọ́n ń ṣe lọ.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwé àsọyé tí Society pèsè lè tọ́ka sí ọ̀pọ̀ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ní ṣíṣàlàyé kókó ẹ̀kọ́ kan, fún àǹfààní olùbánisọ̀rọ̀ la ṣe pèsè wọn, kí ó lè ràn án lọ́wọ́ nígbà tó bá ń múra àsọyé rẹ̀. Wọ́n lè jẹ́ kó mọ àlàyé ìpìlẹ̀, wọ́n sì lè jẹ́ kó mọ àwọn ìlànà pàtàkì tó jẹ́ ti Ìwé Mímọ́ dunjú, kí ó sì lóye bí kókó kan ṣe tan mọ́ ìkejì. Olùbánisọ̀rọ̀ ni yóò pinnu àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó ṣe kókó fún gbígbé àsọyé náà kalẹ̀, tí yóò sì sọ pé kí àwùjọ máa fojú bá a lọ bí ó ti ń ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wọ̀nyẹn, tó sì ń ṣàlàyé wọn. Ó lè mẹ́nu kan àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ mìíràn tó ti ọ̀rọ̀ tó ń sọ lẹ́yìn, ó sì lè mẹ́nu ba ohun tí wọ́n sọ, ṣùgbọ́n tó bá ṣe bẹ́ẹ̀, kò pọndandan pé kí àwùjọ ṣí wọn wò.
Nígbà tí olùbánisọ̀rọ̀ bá ní láti ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́, inú Bíbélì ni kó ti kà á ní tààràtà, kò gbọdọ̀ kà á látinú ìwé tó fi ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà tẹ̀. Nígbà tí olùbánisọ̀rọ̀ bá sọ pé kí àwùjọ máa fi ojú bá ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí òun yóò kà nìṣó, lọ́nà tí yóò yé àwùjọ, yóò sọ orúkọ ìwé tó fẹ́ kà nínú Bíbélì, yóò sì sọ orí àti ẹsẹ tó fẹ́ kà. Nípa dídá ẹnu dúró láti béèrè ìbéèrè kan tàbí láti ṣàlàyé ṣókí nípa ìdí tí ó fi fẹ́ ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yẹn, yóò fún àwùjọ lákòókò láti rí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà. Sísọ ibi tó fẹ́ kà lásọtúnsọ yóò jẹ́ kí àwùjọ rántí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí ó bá kà pẹ̀lú. Àmọ́ o, a kò dámọ̀ràn pé kí ó sọ nọ́ńbà ojú ìwé tí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó yàn wà, níwọ̀n bí èyí ti lè yàtọ̀ síra nítorí pé irú Bíbélì tí àwọn tó wà nínú àwùjọ ń lò lè yàtọ̀ síra wọn. Ṣíṣí Ìwé Mímọ́ nígbà tí wọ́n bá ní kí àwùjọ ṣe bẹ́ẹ̀ ń jẹ́ kí àwùjọ jàǹfààní nínú agbára Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bí olùbánisọ̀rọ̀ ti ń ṣàlàyé nígbà àsọyé.—Héb. 4:12.