Lo Àwọn Ìṣẹ̀lẹ̀ Lọ́ọ́lọ́ọ́ Láti Ru Ìfẹ́ Sókè
1 Ṣé wàá fẹ́ láti máa rí àwọn ọ̀nà tó dára láti mú kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ máa jẹ́ ọ̀tun-ọ̀tun, kí o sì mú kí àwọn èèyàn máa nífẹ̀ẹ́ sí ìhìn Bíbélì? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, máa lo àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé nísinsìnyí àti àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ní àgbègbè rẹ láti bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò. O lè sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ ní àdúgbò àti ní orílẹ̀-èdè rẹ tàbí kí o sọ̀rọ̀ lórí àwọn nǹkan tí ìròyìn sọ pé ó ń ṣẹlẹ̀ jákèjádò ayé. Gbogbo ìgbà ni àwọn nǹkan wọ̀nyí máa ń yí padà. (1 Kọ́r. 7:31) Gbé àwọn àpẹẹrẹ tó tẹ̀ lé e yìí yẹ̀ wò.
2 Àwọn ènìyàn ń ṣàníyàn gidigidi nípa ìṣòro ọrọ̀ ajé àti ọ̀ràn àtijẹ àtimu. Nítorí náà, o lè sọ pé:
◼ “Ǹjẹ́ o gbọ́ nínú ìròyìn pé owó [sọ nǹkan náà] ti tún wọ́n sí i?” Tàbí kí o sọ̀rọ̀ nípa àìríṣẹ́ṣe, bí ilé iṣẹ́ ńlá kan bá ti lé ọ̀pọ̀ òṣìṣẹ́ kúrò lẹ́nu iṣẹ́. Ó sinmi lórí bí o bá ṣe fẹ́ kí ìjíròrò náà lọ, o lè máa bá ọ̀rọ̀ nìṣó nípa bíbéèrè pé, “Ǹjẹ́ o ti ṣe kàyéfì rí nípa ìdí tí àtijẹ àtimu fi ṣòro?” tàbí “Ǹjẹ́ o ronú pé bí gbígbọ́ bùkátà yóò ṣe máa ṣòro lọ rèé?”
3 Àwọn ìròyìn nípa ìwà ipá, irú bí ọ̀ràn ìbànújẹ́ nínú ìdílé, tàbí láàárín àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́, lè pèsè ọ̀nà mìíràn láti bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò. O lè béèrè pé:
◼ “Ǹjẹ́ o rí i kà nínú ìwé ìròyìn pé [sọ ọ̀ràn ìbànújẹ́ tó ṣẹlẹ̀ ní àdúgbò náà]?” Lẹ́yìn náà, béèrè pé, “Kí lo rò pé ó ń fa ìwà ipá púpọ̀ tó bẹ́ẹ̀ láyé yìí?” tàbí “Ǹjẹ́ o rò pé àkókò ń bọ̀ tí kò ní séwu fún wa mọ́?”
4 Ìròyìn nípa ìkún omi tí ń ba nǹkan jẹ́, ìsẹ̀lẹ̀, ìjà ìgboro ní onírúurú ibi nínú ayé ni a tún lè lò láti ru ìfẹ́ sókè. Bí àpẹẹrẹ, o lè béèrè pé:
◼ “Ṣé Ọlọ́run ló ń fa [dárúkọ àjálù kan]?” Tàbí o lè sọ̀rọ̀ nípa ìjà ìgboro tó ṣẹlẹ̀ kẹ́yìn, kí o sì sọ pé: “Bó bá jẹ́ gbogbo èèyàn ló ń fẹ́ àlàáfíà, kí ló wá dé tó fi ṣòroó rí?”
5 Máa wọ́nà láti mọ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ lọ́ọ́lọ́ọ́ tí o lè lò láti fi nasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ. A lè rí àwọn àbá tí ń ranni lọ́wọ́ lábẹ́ ìsọ̀rí ọ̀rọ̀ náà, “Awọn Ìṣẹ̀lẹ̀ Lọ́ọ́lọ́ọ́,” lójú ewé 2 àti 3, nínú ìwé kékeré Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Awọn Ìjíròrò Bibeli Kí A Sì Máa Báa Nìṣó. Ṣùgbọ́n, yẹra fún gbígbè sápá kan nínú ọ̀ràn ìṣèlú tàbí ti ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣàlàyé pé Ìwé Mímọ́ àti Ìjọba Ọlọ́run ló lè yanjú ìṣòro aráyé títí láé.