ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb22 May ojú ìwé 7
  • Ṣé O Ti Múra Sílẹ̀ fún Rògbòdìyàn Tó Lè Ṣẹlẹ̀?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé O Ti Múra Sílẹ̀ fún Rògbòdìyàn Tó Lè Ṣẹlẹ̀?
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2022
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé O Ti Múra Sílẹ̀?
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2020
  • Múra Sílẹ̀ Ní Apá Ìgbẹ̀yìn “Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn” Yìí
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2021
  • Ṣé O Ti Múra Sílẹ̀ De Ìgbà Tí Ọrọ̀ Ajé Máa Dẹnu Kọlẹ̀?
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2023
  • Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I​—Kọ́ Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Rẹ Bí Wọ́n Á Ṣe Máa Múra Ìkẹ́kọ̀ọ́ Sílẹ̀
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2018
Àwọn Míì
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2022
mwb22 May ojú ìwé 7
Ìdílé kan ń wo ìròyìn nípa rògbòdìyàn tó ṣẹlẹ̀ lórí tẹlifíṣọ̀n. Báàgì pàjáwìrì wọn wà nítòsí.

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Ṣé O Ti Múra Sílẹ̀ fún Rògbòdìyàn Tó Lè Ṣẹlẹ̀?

Bí òpin ayé búburú yìí ṣe túbọ̀ ń sún mọ́, a mọ̀ pé rògbòdìyàn, ìjà àti ogun á máa pọ̀ sí i, àwọn afẹ̀míṣòfò náà á sì túbọ̀ máa ṣọṣẹ́ (Ifi 6:4) Kí la lè ṣe láti múra sílẹ̀ fáwọn nǹkan yìí?

  • Múra sílẹ̀ nípa tẹ̀mí: Mọ àwọn ìlànà àtàwọn àpẹẹrẹ inú Bíbélì táá jẹ́ kó o túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà àti ètò rẹ̀, táá sì jẹ́ kó o dúró lórí ìpinnu ẹ láti má ṣe dá sí ọ̀rọ̀ òṣẹ̀lú àti ogun. (Owe 12:5; jr 125-126 ¶23-24) Àsìkò yìí gan-an ló sì yẹ ká jẹ́ kí àárín àwa àtàwọn ará nínú ìjọ túbọ̀ gún.​—1Pe 4:7, 8

  • Múra sílẹ̀ nípa tara: Ṣètò àwọn nǹkan tó o máa nílò bí oúnjẹ àtàwọn nǹkan míì tó bá ṣẹlẹ̀ pé o ò ní lè jáde nílé fáwọn àkókò kan. Bákan náà, ṣètò ohun tó o máa nílò àti ibi tó o máa lọ tó bá pọn dandan pé kó o kúrò nílé. Yẹ àwọn ohun tó wà nínú báàgì pàjáwìrì rẹ wò, kó o sì rí i dájú pé owó àtàwọn nǹkan tó o lè fi dáàbò bo ara ẹ bí ìbòmú, apakòkòrò àtàwọn nǹkan míì wà nínú ẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, mọ bó o ṣe lè kàn sáwọn alàgbà, kó o sì fún àwọn alàgbà náà ní ìsọfúnni ẹ kí wọ́n lè mọ bí wọ́n ṣe lè kàn sí ẹ tí nǹkan kan bá ṣẹlẹ̀.​—Ais 32:2; g17.5 3-7

Tí wàhálà bá ṣẹlẹ̀, rí i dájú pé ò ń ṣe àwọn nǹkan táá jẹ́ kó o túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, ó yẹ kó o máa gbàdúrà, kó o máa kẹ́kọ̀ọ́, kó o sì máa lọ sípàdé. (Flp 1:10) Má ṣe máa rìn kiri láìnídìí àyàfi tó bá jẹ́ ibi tó ṣe pàtàkì gan-an lò ń lọ. (Mt 10:16) Máa ṣàjọpín oúnjẹ àtàwọn nǹkan tó o ní pẹ̀lú àwọn míì.​—Ro 12:13.

Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ ṢÉ O TI MÚRA SÍLẸ̀ DE ÀJÁLÙ? KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Báwo ni Jèhófà ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ lásìkò wàhálà?

  • Àwọn nǹkan wo la lè ṣe láti múra sílẹ̀?

  • Ìrànlọ́wọ́ wo la lè ṣe fáwọn tí àjálù dé bá?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́