ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb21 May ojú ìwé 9
  • Múra Sílẹ̀ Ní Apá Ìgbẹ̀yìn “Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn” Yìí

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Múra Sílẹ̀ Ní Apá Ìgbẹ̀yìn “Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn” Yìí
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2021
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé O Ti Múra Sílẹ̀?
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2020
  • Ṣé O Ti Múra Sílẹ̀ fún Rògbòdìyàn Tó Lè Ṣẹlẹ̀?
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2022
  • Ṣé O Ti Múra Sílẹ̀ De Ìgbà Tí Ọrọ̀ Ajé Máa Dẹnu Kọlẹ̀?
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2023
  • Ṣé O Ti Múra Sílẹ̀ De Àjálù?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2012
Àwọn Míì
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2021
mwb21 May ojú ìwé 9
Ìdílé kan ń múra sílẹ̀ de àjálù, wọ́n ń kó oúnjẹ, omi àtàwọn nǹkan míì pa mọ́.

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Múra Sílẹ̀ Ní Apá Ìgbẹ̀yìn “Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn” Yìí

Ó dá wa lójú pé ṣe ni nǹkan á túbọ̀ máa le sí i bá a ṣe ń sún mọ́ apá ìgbẹ̀yìn “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” yìí. (2Ti 3:1; “wàhálà tó ń fa ìrora” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 24:8, nwtsty) Tí àjálù bá ṣẹlẹ̀, ètò Ọlọ́run sábà máa ń fún wa láwọn ìtọ́ni tó bọ́ sákòókò, tó sì máa ń dáàbò bò wá. Tá a bá fẹ́ là á já lọ́jọ́ ìwájú, a gbọ́dọ̀ jẹ́ kó mọ́ wa lára ní báyìí láti máa ṣègbọràn sáwọn ìtọ́ni tí ètò Ọlọ́rùn ń fún wa nípa tẹ̀mí àti nípa tara.​—Lk 16:10.

  • Múra sílẹ̀ nípa tẹ̀mí: Jẹ́ kó mọ́ ẹ lára láti máa ka Bíbélì déédéé, kó o sì máa dá kẹ́kọ̀ọ́. Máa lo oríṣiríṣi ọ̀nà tí iṣẹ́ ìwàásù pín sí. Má bẹ̀rù tí ipò tó o bá ara ẹ ò bá jẹ́ kó o wà pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ará. (Ais 30:15) Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà àti Jésù wà pẹ̀lú rẹ.​—od 176 ¶15-17

  • Múra sílẹ̀ nípa tara: Yàtọ̀ sí báàgì pàjáwìrì, ó tún yẹ kí ìdílé kọ̀ọ̀kan ní ìwọ̀nba oúnjẹ pa mọ́, títí kan omi, oògùn àtàwọn nǹkan míì tí wọ́n máa nílò tí àjálù bá ṣẹlẹ̀, tó sì gba pé kí wọ́n wà níbì kan fún àkókò tó gùn.​—Owe 22:3; g17.5 4, 6

Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ ṢÉ O TI MÚRA SÍLẸ̀ DE ÀJÁLÙ? KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Àwòrán látinú fídíò ‘Ṣé O Ti Múra Sílẹ̀ De Àjálù?’ Arákùnrin kan ń ka Bíbélì.

    Báwo la ṣe lè múra sílẹ̀ nípa tẹ̀mí fún àjálù?

  • Àwòrán látinú fídíò ‘Ṣé O Ti Múra Sílẹ̀ De Àjálù?’ Báàgì pàjáwìrì ìdílé kan, ìsọfúnni tá ran àwọn alàgbà lọ́wọ́ láti tètè kàn sí wọn àti fọ́tò tó júwe ibi tí ìdílé náà ti máa pàdé tí àjálù bá ṣẹlẹ̀.

    Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé . . .

    • ká fún àwọn alàgbà ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìsọfúnni nípa wa?

    • ká ní báàgì pàjáwìrì?

    • ká jíròrò irú àwọn àjálù tó lè ṣẹlẹ̀ àtohun tá a máa ṣe tí èyíkéyìí nínú wọn bá ṣẹlẹ̀?

  • Àwòrán látinú fídíò ‘Ṣé O Ti Múra Sílẹ̀ De Àjálù?’ Àwòrán: Bá a ṣe lè ṣèrànwọ́ fáwọn tí àjálù ṣẹlẹ̀ sí. 1. Arákùnrin kan ń gbàdúrà fún wọn. 2. Arákùnrin kan yọ̀ǹda ara ẹ̀ láti ràn wọ́n lọ́wọ́. 3. Arákùnrin kan ń fowó ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ kárí ayé.

    Àwọn nǹkan mẹ́ta wo la lè ṣe tá a bá fẹ́ ṣèrànwọ́ fáwọn tí àjálù ṣẹlẹ̀ sí?

BI ARA RẸ PÉ, ‘Báwo ni àrùn Corona ṣe jẹ́ kí n rí ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí n múra sílẹ̀ de àjálù?’

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́