Ṣé O Ti Múra Sílẹ̀ De Àjálù?
1. Kí nìdí tó fi bọ́gbọ́n mu pé ká múra sílẹ̀ de àjálù?
1 Ọdọọdún ni àjálù máa ń dé bá ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn kárí ayé, títí kan àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa. Irú àwọn àjálù bẹ́ẹ̀ ni ìmìtìtì ilẹ̀, omíyalé, ogun abẹ́lé, rògbòdìyàn àtàwọn àjálù míì tí àwọn èèyàn ń fọwọ́ ara wọn fà. Kò sí ibi tí àwọn apániláyà kò ti lè ṣọṣẹ́, kò sì sí ibi tí rògbòdìyàn kò ti lè bẹ́ sílẹ̀.
2. Ìdánilójú wo ni àwa ìránṣẹ́ Jèhófà ní?
2 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ipò àwọn nǹkan túbọ̀ ń burú sí i nínú ayé yìí, àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run kò ní jẹ́ kí ìbẹ̀rù àti àníyàn gbà wá lọ́kàn. Torí pé a jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó dájú pé a mọ ìtúmọ̀ àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ báyìí nínú ayé, a sì mọ bí àkókò tá a wà yìí ti ṣe pàtàkì tó. (2 Tím. 3:1, 13) Jèhófà Ọlọ́run wa ti ṣèlérí pé òun á máa dáàbò bo àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ nípa tẹ̀mí. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè la ìpọ́njú ńlá já, ìyẹn sì ni àjálù tó máa le koko jù lọ tó máa dé bá gbogbo èèyàn ayé yìí. Lẹ́yìn ìyẹn la máa wá gbádùn àwọn ìbùkún tí Ìjọba Ọlọ́run máa mú wá títí ayérayé. (Aísá. 14:7) Àmọ́ kí ìgbà yẹn tó dé, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àdánidá àtàwọn àjálù táwọn èèyàn fọwọ́ ara wọn fà yóò ṣì máa bá aráyé fínra. Torí pé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àdánidá àtàwọn àjálù táwọn èèyàn ń fọwọ́ ara wọn fà lè wáyé láìròtẹ́lẹ̀, ó sì lè kan ẹnikẹ́ni nínú wa, ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé ká múra sílẹ̀ kó tó de.—Òwe 21:5.
3. Ta ló máa pinnu fún wa bóyá ká kúrò tàbí ká má ṣe kúrò níbi tí àjálù ti ń ṣẹlẹ̀?
3 Múra Sílẹ̀ Kí Àjálù Tó Wáyé: Nígbà míì tí àjálù bá fẹ́ ṣẹlẹ̀, àwọn ìjọba máa ń kìlọ̀ fún àwọn èèyàn. Ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká fetí sí àwọn ìkìlọ̀ yẹn. (Òwe 22:3) Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, àwọn alàgbà máa gbìyànjú láti kàn sí gbogbo àwọn ará tó wà nínú ìjọ kí wọ́n lè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àwọn ìmúrasílẹ̀ tó bá yẹ. Torí náà, àwọn alàgbà ní láti máa kíyè sí bí nǹkan ṣe ń lọ sí àtàwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó bá ń wáyé ní àgbègbè wọn kí wọ́n lè fún àwọn akéde ní ìmọ̀ràn tó wúlò lórí àwọn ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe. Àmọ́ ṣá o, àwọn alàgbà kọ́ ló máa pinnu ohun táwọn ẹlòmíì máa ṣe lórí ọ̀rọ̀ yìí fún wọn, wọn kò sì ní fipá mú akéde èyíkéyìí láti ṣe ohun tí àwọn fúnra wọn bá ní lọ́kàn láti ṣe. Torí náà, kí ẹnikẹ́ni má ṣe dúró de àwọn alàgbà pé kí wọ́n wá fún òun ní ìtọ́ni kí òun tó kúrò níbi tí òun wà nígbà tí wàhálà bá fẹ́ wáyé, ẹ má sì ṣe dúró de ìsọfúnni láti ẹ̀ka ọ́fíìsì kẹ́ ẹ tó pinnu ohun tẹ́ ẹ máa ṣe. Tí rògbòdìyàn bá wáyé, oníkálùkù ló máa pinnu ohun tí òun máa ṣe, bóyá kí òun kúrò níbẹ̀ àbí kí òun ṣì wà níbẹ̀. Kí ẹnikẹ́ni má ṣe fi dandan lé e pé kí àwọn ẹlòmíì má ṣe kúrò ní ibì kan pàtó, ẹnikẹ́ni kò sì gbọ́dọ̀ fipá mú ẹlòmíì pé kó lọ síbòmíì tí kò bá wù ú láti lọ.—Gál. 6:5.
4. Kí ló bọ́gbọ́n mu pé ká ṣe tí rògbòdìyàn bá wáyé tàbí tí àwọn apániláyà bá ṣọṣẹ́ ní àgbègbè wa?
4 Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń páni láyà àti rògbòdìyàn sábà máa ń wáyé lójijì. Bíbélì gbà wá níyànjú pé ká jẹ́ ọlọ́gbọ́n, ká wà lójúfò, ká sì máa ṣọ́ra nígbà gbogbo. (Òwe 27:12) Torí náà, ó yẹ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa máa kíyè sí àwọn ohun tó bá ń ṣẹlẹ̀ ní àgbègbè wa. A retí pé kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ṣe àwọn ohun tó bá yẹ ká lè dáàbò bo ẹ̀mí ara wa àti tàwọn ẹlòmíì nígbàkigbà tó bá pọn dandan. Tó bá ṣeé ṣe, èyí lè gba pé ká kúrò láwọn ibi tá a bá rí i pé rúkèrúdò ti fẹ́ wáyé, ká sì lọ sáwọn ibi tí kò fi bẹ́ẹ̀ séwu títí dìgbà tí ipò nǹkan á fi pa dà rọgbọ. A gbóríyìn fún àwọn tí wọ́n ti gbé irú ìgbésẹ̀ yìí láìka àwọn ohun ìní tí wọ́n pàdánù sí. Ẹ̀mí wa ṣe pàtàkì gan-an ju àwọn ohun ìní wa lọ. (Lúùkù 12:15) Àṣìṣe ńlá gbáà ló máa jẹ́ tí ẹnì kan bá jókòó ti àwọn ohun ìní rẹ̀, tó sì kọ̀ láti kúrò ní ibi tó ti hàn kedere pé ẹ̀mí rẹ̀ wà nínú ewu.
5. Báwo la ṣe lè fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn alàgbà tá a bá ń gbé ní àgbègbè tó ti ṣeé ṣe kí àjálù tàbí rògbòdìyàn wáyé?
5 Tí ìjọ yín bá wà níbi tó ti ṣeé ṣe kí àjálù wáyé tàbí tẹ́ ẹ bá rí i pé ó ṣeé ṣe kí rògbòdìyàn tàbí wàhálà míì ṣẹlẹ̀, àwọn alàgbà lè gba orúkọ àti nọ́ńbà tẹlifóònù mọ̀lẹ́bí àwọn akéde tàbí ti ọ̀rẹ́ wọn sílẹ̀. Kí mọ̀lẹ́bí tàbí ọ̀rẹ́ náà jẹ́ ẹni tí kò gbé lágbègbè yẹn tí wọ́n sì lè kàn sí nígbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì bá wáyé. Èyí á jẹ́ kí àwọn alàgbà lè kàn sí àwọn àkéde tó bá ti kúrò lágbègbè náà. Àwọn alàgbà tún lè ṣètò bí ìjọ ṣe lè múra sílẹ̀, kí wọ́n jẹ́ kí àwọn ará mọ àwọn nǹkan kòṣeémáàní tó yẹ kí wọ́n mú dání, bí wọ́n ṣe máa yára kúrò níbi tí wọ́n bá wà àti ibi tí wọ́n máa lọ àti bí wọ́n ṣe máa ṣèrànwọ́ fún àwọn tó nílò àkànṣe àbójútó. Ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká fọwọ́ sowọ́ pọ̀ lórí ọ̀rọ̀ yìí.—Héb. 13:17.
6. (a) Kí ló yẹ ká ṣe tí àjálù bá wáyé ní àgbègbè wa? (b) Kí nìdí tó fi yẹ ká jẹ́ kí àwọn alàgbà mọ àdírẹ́sì wa àtàwọn nọ́ńbà fóònù wa tuntun?
6 Lẹ́yìn tí Àjálù Bá Wáyé: Kí ló yẹ kó o ṣe tí àjálù tàbí rògbòdìyàn bá wáyé lágbègbè rẹ? Rí i dájú pé o pèsè àwọn nǹkan kòṣeémáàní tí ìdílé rẹ máa nílò fún wọn. Tó ba ṣeé ṣe fún ẹ, kí o ṣe gbogbo ohun tó o bá lè ṣe láti ṣèrànwọ́ fún àwọn ẹlòmíì tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà kàn. Gbìyànjú láti tètè kàn sí alábòójútó àwùjọ rẹ tàbí alàgbà míì. Kódà, bó bá tiẹ̀ jẹ́ pé kò séwu níbi tó o wà, ó ṣì yẹ kó o kàn sí àwọn alàgbà. Tó o bá nílò ìrànlọ́wọ́, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé àwọn ará yóò ṣe gbogbo ohun tí wọ́n bá lè ṣe láti ràn ẹ́ lọ́wọ́. (1 Kọ́r. 13:4, 7) Rántí pé Jèhófà mọ àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí ọ, torí náà, gbẹ́kẹ̀ lé e, yóò sì ràn ọ́ lọ́wọ́. (Sm. 37:39; 62:8) Lo gbogbo àǹfààní tó o bá ní láti ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí kí o sì gbé wọn ró. (2 Kọ́r. 1:3, 4) Ó tún yẹ kí àwọn alàgbà rí i pé àwọn kàn sí gbogbo àwọn ará tó wà nínú ìjọ láti mọ̀ bóyá kò sí ewu níbi tí wọ́n wà tàbí bóyá wọ́n nílò ìrànlọ́wọ́. Ṣe ló máa dà bí ìgbà téèyàn ń fi àkókò ṣòfò tí àwọn alàgbà kò bá ní àkọsílẹ̀ tó kún rẹ́rẹ́ nípa bí wọ́n ṣe lè kàn sí àwọn ará. Ìdí nìyẹn tó fi dáa kí àwọn akéde jẹ́ kí akọ̀wé ìjọ àti alábòójútó àwùjọ wọn mọ àdírẹ́sì àtàwọn nọ́ńbà fóònù wọn tuntun.
7. Báwo la ṣe lè fi ọwọ́ pàtàkì mú ipò tẹ̀mí wa níbi tá a bá forí pa mọ́ sí nígbà rògbòdìyàn?
7 Níbi Tá A Bá Forí Pa Mọ́ Sí: Ibi yòówù ká forí pa mọ́ sí lásìkò wàhálà, ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká fi ọwọ́ pàtàkì mú ipò tẹ̀mí wa, ká sì jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin. Bí ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba kò bá ṣeé ṣe nírú àkókò bẹ́ẹ̀ tàbí tó bá máa léwu, níbi tó bá ti ṣeé ṣe, kí àwọn akéde kóra jọ ní àwọn àwùjọ kéékèèké, bóyá ní àwùjọ tí wọ́n ti ń jáde òde ẹ̀rí, kí wọ́n sì jọ ka àwọn ohun tá a fẹ́ jíròrò ní ìpàdé lọ́sẹ̀ náà. Àmọ́ bí èyí kò bá ṣeé ṣe, ẹ lè máa ka àwọn ìwé náà nígbà Ìjọsìn Ìdílé yín títí di ìgbà tí ipò nǹkan fi máa rọgbọ, tí ẹ ó sì lè máa ṣe àwọn ìpàdé ìjọ bíi ti tẹ́lẹ̀. Láàárín àkókò náà, ó yẹ kí gbogbo wa máa rí i dájú pé à ń fìṣọ́ra sọ “ìhìn rere ohun tí ó dára jù” fún àwọn tó bá fẹ́ gbọ́ wa. (Aísá. 52:7) Bí oṣù bá sì ti parí, kí akéde kọ̀ọ̀kan wá bí òun ṣe máa fún akọ̀wé ìjọ tàbí alábòójútó àwùjọ tàbí olùrànlọ́wọ́ rẹ̀ ní ìròyìn. A ó lè tipa bẹ́ẹ̀ máa ṣe ojúṣe wa láti máa ‘wàásù ọ̀rọ̀ náà, ní àsìkò tí ó rọgbọ àti ní àsìkò tí ó kún fún ìdààmú.’—2 Tím. 4:2.
8. Ipa wo ni ọ̀rọ̀ nípa àjálù àti rògbòdìyàn máa ń ní lórí àwa Kristẹni?
8 Ọ̀rọ̀ nípa àjálù àti rògbòdìyàn máa ń kó ìbẹ̀rù àti àníyàn bá àwọn èèyàn nínú ayé, àmọ́ ọkàn tiwa balẹ̀ pé ọ̀la ṣì ń bọ́ wá dáa. Láìpẹ́, gbogbo àjálù tó ń ṣẹlẹ̀ yóò di ohun àtijọ́. (Ìṣí. 21:4) Àmọ́ ní báyìí ná, a ṣì lè máa ṣe àwọn ohun tó bá bọ́gbọ́n mu láti múra sílẹ̀ de ìgbà wàhálà bá a ti ń bá a nìṣó láti máa fi ìtara kéde ìhìn rere fáyé gbọ́.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]
Àwọn Ohun Tẹ́ Ẹ Lè Ṣe Láti Múra Sílẹ̀ De Àjálù:
• Ẹ ṣètò àwọn ìwé tó ṣe pàtàkì tẹ́ ẹ máa mú dání tó bá ṣẹlẹ̀ pé ọ̀ràn pàjáwìrì tó máa mú kẹ́ ẹ yára kúrò nílé wáyé.
• Ẹ ṣètò àwọn nǹkan kòṣeémáàní, bí oúnjẹ, oògùn àti omi tó ṣeé mu, tó lè tó yín lò fún ọjọ́ mẹ́ta sí ọjọ́ márùn-ún, tẹ́ ẹ sì lè yára gbé dání tí ọ̀ràn pàjáwìrì bá wáyé.
• Ẹ múra sílẹ̀ láti yára jáde nílé tó bá ṣẹlẹ̀ pé ọ̀ràn pàjáwìrì wáyé, kẹ́ ẹ sì mọ ibi tí ẹ máa lọ.
• Ẹ tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà tí àwọn ìjọba àtàwọn alàgbà bá fún yín.