Àpótí Ìbéèrè
◼ Kí ni ó yẹ kí a ṣe nígbà tí ìjábá tí ó kan àwọn ará wa ní tààràtà bá ṣẹlẹ̀?
Bí Ìjábá Bá Ṣẹlẹ̀ ní Àgbègbè Rẹ: Má ṣe sá kìjokìjo. Ṣe wọ̀ọ̀, kí o sì pọkàn pọ̀ sórí ohun tí ó níye lórí ní tòótọ́—ìwàláàyè ni, kì í ṣe ohun ìní. Bójú tó ohun tí ó jẹ́ àìní lọ́wọ́lọ́wọ́ ti ìdílé rẹ. Lẹ́yìn náà, fi àyíká ipò rẹ àti ibi tí o wà tó àwọn alàgbà létí. Àwọn alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ń kó ipa pàtàkì ní pípèsè ìrànwọ́ ìtura. Bí a bá fúnni ní ìkìlọ̀ ṣáájú nípa ìjábá náà, gẹ́gẹ́ bí ó ti máa ń rí ní ti àwọn ìjì líle mélòó kan, àwọn arákùnrin wọ̀nyí gbọ́dọ̀ rí i dájú pé ẹnì kọ̀ọ̀kan wà ní ibi tí ó láàbò, bí àkókò bá sì yọ̀ǹda, wọ́n gbọ́dọ̀ wá àwọn ìpèsè tí a lè nílò, kí wọ́n sì pín wọn.
Lẹ́yìn náà, àwọn olùdarí ìkẹ́kọ̀ọ́ ìwé ìjọ gbọ́dọ̀ wá ìdílé kọ̀ọ̀kan rí, kí wọ́n sì béèrè nípa àlàáfíà wọn. A gbọ́dọ̀ fi ipò tí ìdílé kọ̀ọ̀kan wà tó alábòójútó olùṣalága tàbí alàgbà míràn létí, kódà bí nǹkan kan kò bá ṣe ẹnikẹ́ni. Bí ẹnì kan bá ṣèṣe, àwọn alàgbà yóò gbìyànjú láti ṣètò fún ìtọ́jú ìṣègùn. Wọn yóò tún pèsè ohun ìní ti ara èyíkéyìí bí oúnjẹ, aṣọ, ibùgbé, tàbí àwọn ohun èlò agboolé tí a nílò. (Jòh. 13:35; Gál. 6:10) Àwọn alàgbà àdúgbò yóò fún ìjọ ní ìtìlẹ́yìn tẹ̀mí àti ti èrò ìmọ̀lára, wọn yóò sì ṣètò bí ó bá ti lè yá tó láti bẹ̀rẹ̀ àwọn ìpàdé ìjọ lẹ́ẹ̀kan sí i. Lẹ́yìn tí a bá ti ṣe ìdíyelé dáradára, alàgbà kan gbọ́dọ̀ kàn sí alábòójútó àyíká lórúkọ ẹgbẹ́ àwọn alàgbà láti fi ìpalára èyíkéyìí, ìbàjẹ́ èyíkéyìí tí ó ṣẹlẹ̀ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba, tàbí ìbàjẹ́ èyíkéyìí tí ó ṣẹlẹ̀ sí ilé àwọn ará, títí kan àìní àrà ọ̀tọ̀ èyíkéyìí tó o létí. Lẹ́yìn náà, alábòójútó àyíká yóò fóònù tàbí ránṣẹ́ sí ọ́fíìsì ẹ̀ka, yóò sì ròyìn ipò náà. Ẹ̀ka ọ́fíìsì yóò bójú tó ìgbésẹ̀ ìpèsè ìrànwọ́ ìtura ńlá èyíkéyìí tí a nílò.
Bí Ìjábá Bá Ṣẹlẹ̀ Níbòmíràn: Rántí àwọn arákùnrin àti arábìnrin nínú àdúrà rẹ. (2 Kọ́r. 1:8-11) Bí o bá fẹ́ láti pèsè ìtìlẹ́yìn owó, o lè fi ọrẹ rẹ ránṣẹ́ sí Society, níbi ti a ti ya àkànlò owó ìrànwọ́ ìtura sọ́tọ̀ fún ète yìí. Àdírẹ́sì náà ni: Watch Tower, P.M.B. 1090, Benin City, Edo State. (Ìṣe 2:44, 45; 1 Kọ́r. 16:1-3; 2 Kọ́r. 9:5-7; wo Ji!, October 8, 1986, ojú ìwé 23 sí 25.) Má ṣe fi àwọn ohun ìní ti ara tàbí ohun èlò ránṣẹ́ sí àgbègbè tí ìjábá náà ti ṣẹlẹ̀, àyàfi bí àwọn arákùnrin tí ń bójú tó o bá béèrè fún un ní pàtó. Èyí yóò mú ìsapá ìrànwọ́ ìtura tí ó wà létòlétò àti pípín àwọn ohun èlò lọ́nà yíyẹ dájú. (1 Kọ́r. 14:40) Jọ̀wọ́ má ṣe tẹ Society láago láìnídìí, níwọ̀n bí èyí ti lè di àwọn ìlà fóònù tí a nílò láti bójú tó àwọn ìkésíni tí ń wọlé wá láti àgbègbè tí ìjábá náà ti ṣẹlẹ̀.
Lẹ́yìn tí a bá ti ṣe ìdíyelé tí ó yẹ, Society yóò pinnu bí a bá ní láti gbé ìgbìmọ̀ elétò ìrànwọ́ ìtura kalẹ̀. A óò fi tó àwọn arákùnrin tí ó ṣeé fẹrù iṣẹ́ lé lọ́wọ́ létí. Gbogbo ènìyàn gbọ́dọ̀ fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn alàgbà tí ń mú ipò iwájú kí a baà lè bójú tó àìní pàtàkì tí gbogbo àwọn ará náà ní lọ́nà tí ó tẹ́rùn.—Wo ìwé náà, Jehovah’s Witnesses—Proclaimers of God’s Kingdom (Gẹ̀ẹ́sì), ojú ìwé 310 sí 315.