ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • kr orí 20 ojú ìwé 209-219
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Tá A Fi Ń Ṣe Ìrànwọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Tá A Fi Ń Ṣe Ìrànwọ́
  • Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìdí Tí Ṣíṣe Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù Fi Jẹ́ “Iṣẹ́ Ìsìn Ọlọ́wọ̀”
  • Ìdí Tá A Fi Ń Ṣe Iṣẹ́ Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù
  • Àǹfààní Pípẹ́ Títí Wà Nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Tí A Fi Ń Ṣe Ìrànwọ́
  • Ìwọ Náà Lè Kópa
  • Bá A Ṣe Lè Ṣèrànwọ́ Tí Àjálù Bá Ṣẹlẹ̀
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2023
  • Ṣé Ẹ Máa Ń Ṣèrànwọ́ Nígbà Àjálù?
    Àwọn Ìbéèrè Táwọn Èèyàn Sábà Máa Ń Béèrè Nípa Ẹlẹ́rìí Jèhófà
  • Bá A Ṣe Pèsè Ìrànwọ́ Lọ́dún 2021—A Ò Pa Àwọn Arákùnrin Àtàwọn Arábìnrin Wa Tì
    Bá A Ṣe Ń Ná Owó Tẹ́ Ẹ Fi Ń Ṣètọrẹ
  • Ṣíṣètìlẹyìn Fún Iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run—À Ń Kọ́ Ibi Ìjọsìn, A sì Ń Ṣèrànwọ́ Nígbà Àjálù
    Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!
Àwọn Míì
Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!
kr orí 20 ojú ìwé 209-219

ORÍ 20

Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Tá A Fi Ń Ṣe Ìrànwọ́

OHUN TÍ ORÍ YÌÍ DÁ LÉ

Àwọn ará fi hàn pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn nígbà àjálù

1, 2. (a) Ìṣòro wo ni àwọn Kristẹni tó ń gbé ní Jùdíà ní? (b) Kí ni ìfẹ́ sún àwọn ará ní Áńtíókù láti ṣe fún àwọn tí ìṣòro bá yìí?

NÍ NǸKAN bí ọdún 46 Sànmánì Kristẹni, ìyàn mú gan-an nílẹ̀ Jùdíà. Oúnjẹ ò tó nǹkan, ìwọ̀nba tó sì wà gbówó lórí débi pé àwọn Júù tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Kristi pàápàá ò fi bẹ́ẹ̀ rówó rà á. Ebi fẹ́rẹ̀ẹ́ lè yọ ojú wọn! Àṣé wọ́n máa tó rọ́wọ́ Jèhófà lára wọn ní irú ọ̀nà tí kò ṣẹlẹ̀ sí èyíkéyìí lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi rí. Kí ló wá ṣẹlẹ̀?

2 Nígbà tí àwọn Júù àtàwọn Kèfèrí tó di Kristẹni, tó wà nílùú Áńtíókù nílẹ̀ Síríà gbọ́ bí ìyà ṣe ń jẹ àwọn Júù tó di Kristẹni ní Jerúsálẹ́mù àti Jùdíà, ni wọ́n bá dá oríṣiríṣi nǹkan jọ tí wọ́n fẹ́ fi ràn wọ́n lọ́wọ́. Lẹ́yìn náà, wọ́n yan àwọn àgbà ọkùnrin méjì, ìyẹn Bánábà àti Sọ́ọ̀lù pé kí wọ́n gbé àwọn nǹkan wọ̀nyí lọ sọ́dọ̀ àwọn alàgbà ìjọ tó wà ní Jerúsálẹ́mù. (Ka Ìṣe 11:27-30; 12:25.) Ẹ wo bí inú àwọn ará tó wà ní Jùdíà yẹn ṣe máa dùn tó nígbà táwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn ní Áńtíókù dìde ìrànwọ́! Bóyá ni wọ́n tíì rí irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ rí!

3. (a) Báwo ni àwọn èèyàn Ọlọ́run lóde òní ṣe ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn ará Áńtíókù ìgbàanì? Sọ àpẹẹrẹ kan. (Tún wo àpótí náà, “Ètò Ìrànwọ́ Àkọ́kọ́ Tó Kárí Ayé Lóde Òní.”) (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa gbé yẹ̀ wò nínú orí yìí?

3 Ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní Sànmánì Kristẹni yìí ni àkọ́kọ́ irú rẹ̀ tí àwọn ará máa fi nǹkan ìrànwọ́ ránṣẹ́ sí àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn tí wọ́n nílò ìrànwọ́ lórílẹ̀-èdè míì. Àpẹẹrẹ àwọn Kristẹni tó wà ní Áńtíókù ìgbàanì la ṣì ń tẹ̀ lé títí di òní. Nígbàkigbà tá a bá gbọ́ pé àjálù tàbí àdánwò bá àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa, ńṣe la máa ń dìde ìrànwọ́.a Ká lè mọyì bí ṣíṣe irú ìrànwọ́ bẹ́ẹ̀ ṣe tan mọ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, ẹ jẹ́ ká gbé àwọn ìbéèrè mẹ́ta yẹ̀ wò nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí a fi ń ṣe ìrànwọ́: Kí nìdí tí a fi ka ṣíṣe ìrànwọ́ fún àwọn tí àjálù bá sí ara iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa? Kí nìdí tá a fi ń ṣe irú iṣẹ́ ìrànlọ́wọ́ bẹ́ẹ̀? Àǹfààní wo là ń rí nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ tá a fi ń ṣe ìrànwọ́?

Ìdí Tí Ṣíṣe Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù Fi Jẹ́ “Iṣẹ́ Ìsìn Ọlọ́wọ̀”

4. Kí ni Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn ará Kọ́ríńtì nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni?

4 Nínú ìwé kejì tí Pọ́ọ̀lù kọ sí àwọn Kristẹni tó wà ní Kọ́ríńtì, ó ṣàlàyé fún wọn pé ọ̀nà méjì ni iṣẹ́ òjíṣẹ́ àwa Kristẹni pín sí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹni àmì òróró ló darí ìwé náà sí, ọ̀rọ̀ tó sọ kan “àwọn àgùntàn mìíràn” tí Kristi sọ̀rọ̀ nípa wọn. (Jòh. 10:16) Apá àkọ́kọ́ tí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa pín sí ni “iṣẹ́ òjíṣẹ́ ìpadàrẹ́,” ìyẹn iṣẹ́ ìwàásù àti kíkọ́ni. (2 Kọ́r. 5:18-20; 1 Tím. 2:3-6) Apá kejì jẹ mọ́ ‘iṣẹ́ òjíṣẹ́ fún àwọn ẹni mímọ́’ tí Pọ́ọ̀lù sọ, ìyẹn iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí a fi ń ṣe ìrànwọ́ fáwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa nígbà ìṣòro. (2 Kọ́r. 8:4) Ní ti gbólóhùn méjèèjì náà “iṣẹ́ òjíṣẹ́ ìpadàrẹ́” àti ‘iṣẹ́ òjíṣẹ́ fún àwọn ẹni mímọ́,’ ọ̀rọ̀ tá a túmọ̀ sí “iṣẹ́ òjíṣẹ́” lédè Yorùbá wá látinú ọ̀rọ̀ Gíríìkì kan náà, ìyẹn di·a·ko·niʹa. Kí nìdí tí ìyẹn fi ṣe pàtàkì?

5. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé Pọ́ọ̀lù pé iṣẹ́ ṣíṣe ìrànwọ́ nígbà àjálù ní iṣẹ́ òjíṣẹ́?

5 Bí Pọ́ọ̀lù ṣe lo ọ̀rọ̀ Gíríìkì kan náà yìí, ńṣe ló fi iṣẹ́ ṣíṣe ìrànwọ́ nígbà àjálù wé irú àwọn iṣẹ́ òjíṣẹ́ míì tá à ń ṣe nínú ìjọ Kristẹni. Ó ti kọ́kọ́ sọ fún wọn pé: “Onírúurú iṣẹ́ òjíṣẹ́ sì ní ń bẹ, síbẹ̀ Olúwa kan náà ni ó wà; onírúurú ọ̀nà ìṣiṣẹ́ sì ní ń bẹ, . . . Ṣùgbọ́n gbogbo ọ̀nà ìṣiṣẹ́ wọ̀nyí ni ẹ̀mí kan ṣoṣo náà ń mú ṣe.” (1 Kọ́r. 12:4-6, 11) Kódà, Pọ́ọ̀lù jẹ́ ká mọ̀ pé oríṣiríṣi iṣẹ́ òjíṣẹ́ tá à ń ṣe nínú ìjọ Ọlọ́run jẹ́ “iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀.”b (Róòmù 12:1, 6-8) Abájọ tó fi kà á sí ohun pàtàkì láti yọ̀ǹda àkókò rẹ̀ kó lè fi “ṣe ìránṣẹ́ fún àwọn ẹni mímọ́”!—Róòmù 15:25, 26.

6. (a) Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi sọ pé iṣẹ́ ṣíṣe ìrànwọ́ nígbà àjálù jẹ́ apá kan ìjọsìn wa? (b) Ṣàlàyé bí a ṣe ń ṣe iṣẹ́ ṣíṣe ìrànwọ́ nígbà àjálù kárí ayé lónìí. (Wo àpótí náà, “Nígbà Tí Àjálù Bá Ṣẹlẹ̀!” lójú ìwé 214.)

6 Pọ́ọ̀lù jẹ́ kó yé àwọn ará tó wà ní Kọ́ríńtì pé iṣẹ́ ṣíṣe ìrànwọ́ fáwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wọn nígbà ìṣòro jẹ́ ara iṣẹ́ òjíṣẹ́ àti ìjọsìn wọn sí Jèhófà. Pọ́ọ̀lù gbà pé Kristẹni tó bá ń ṣèrànwọ́ fún onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ń fi hàn pé òun ní “ẹ̀mí ìtẹríba fún ìhìn rere nípa Kristi.” (2 Kọ́r. 9:13) Nítorí náà, Kristẹni tó bá ń fi ẹ̀kọ́ Kristi sílò kò ní ṣàì ṣèrànwọ́ fún àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀. Pọ́ọ̀lù tún sọ pé ohun tí àwọn ará ń ṣe yìí jẹ́ “inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run títayọ ré kọjá.” (2 Kọ́r. 9:14; 1 Pét. 4:10) Tó bá di ọ̀rọ̀ ṣíṣe ìrànwọ́ fáwọn ará wa tó wà nínú ìṣòro, tó fi mọ́ iṣẹ́ ṣíṣe ìrànwọ́ nígbà àjálù, Ile-Iṣọ Na June 1, 1976 sọ pé: “Àwa kò gbọ́dọ̀ ṣiyè méjì pé Jèhófà àti Jésù ka irú iṣẹ́ báyìí sí nǹkan pàtàkì.” Ó dá wa lójú ní tòótọ́ pé irú iṣẹ́ ìsìn mímọ́ kan tó ṣeyebíye ni iṣẹ́ ṣíṣe ìrànwọ́ nígbà àjálù jẹ́.—Róòmù 12:1, 7; 2 Kọ́r. 8:7; Héb. 13:16.

Ìdí Tá A Fi Ń Ṣe Iṣẹ́ Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù

7, 8. Kí nìdí àkọ́kọ́ tá a fi ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí a fi ń ṣe ìrànwọ́ nígbà ìṣòro? Ṣàlàyé.

7 Kí nìdí tá a fi ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ tá a fi ń ṣe ìrànwọ́ fáwọn tí àjálù bá? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù dáhùn ìbéèrè yìí nínú ìwé kejì tó kọ sí àwọn ará ní Kọ́ríńtì. (Ka 2 Kọ́ríńtì 9:11-15.) Nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì yẹn, Pọ́ọ̀lù sọ ìdí pàtàkì mẹ́ta tá a fi ń ṣe “iṣẹ́ òjíṣẹ́ iṣẹ́ ìsìn fún gbogbo ènìyàn yìí,” ìyẹn, iṣẹ́ ìrànwọ́ nígbà àjálù. Ní báyìí, a fẹ́ gbé ìdí mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yẹ̀ wò lọ́kọ̀ọ̀kan.

8 Àkọ́kọ́, iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí a fi ń ṣe ìrànwọ́ nígbà ìṣòro ń yin Jèhófà lógo. Ẹ kíyè sí pé nínú ẹsẹ Bíbélì márààrún tá a kà yẹn, ọ̀dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run ni Pọ́ọ̀lù darí àfiyèsí àwọn ará sí. Ó rán wọn létí nípa ‘ìfọpẹ́hàn fún Ọlọ́run’ àti “ọ̀pọ̀ ìfọpẹ́hàn fún Ọlọ́run.” (Ẹsẹ 11 àti 12) Ó tún sọ bí iṣẹ́ ṣíṣe ìrànwọ́ nígbà àjálù yìí ṣe máa ń sún àwọn Kristẹni láti “yin Ọlọ́run lógo” kí wọ́n sì tún yìn ín nítorí “inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí” rẹ̀ “títayọ ré kọjá.” (Ẹsẹ 13 àti 14) Nígbà tí Pọ́ọ̀lù parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ lórí iṣẹ́ òjíṣẹ́ fún àwọn ẹni mímọ́ náà, ìyẹn iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí a fi ń ṣe ìrànwọ́ fáwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa nígbà ìṣòro, ó sọ pé: “Ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run.”—Ẹsẹ 15; 1 Pét. 4:11.

9. Irú àyípadà wo ni iṣẹ́ ṣíṣe ìrànwọ́ nígbà àjálù tá à ń ṣe lè mú bá èrò àwọn èèyàn? Sọ àpẹẹrẹ kan.

9 Bíi ti Pọ́ọ̀lù, àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lónìí ka ṣíṣe ìrànwọ́ nígbà àjálù sí àǹfààní láti yin Jèhófà lógo àti ọ̀nà kan láti fi hàn pé àwọn ń fi ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílò. (1 Kọ́r. 10:31; Títù 2:10) Kódà, iṣẹ́ ìrànwọ́ yìí máa ń jẹ́ kí àwọn tó ti ní èrò òdì nípa Jèhófà àti àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, yí èrò wọn pa dà. Bí àpẹẹrẹ: Obìnrin kan tó ń gbé níbì tí ìjì líle ti jà so àkọlé kan mọ́ ẹnu ọ̀nà rẹ̀ pé: “Mí Ò Fẹ́ Rí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Níbí.” Nígbà tó yá, ó rí àwọn ará wa tó ń ṣèrànwọ́ fáwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn tí àjálù ba ilé wọn jẹ́. Obìnrin náà kíyè sí pé tẹ̀rín-tọ̀yàyà ni wọ́n fi ń ṣe iṣẹ́ náà. Ló bá tọ̀ wọ́n lọ, kó lè mọ bí wọ́n ṣe jẹ́. Ó yà á lẹ́nu nígbà tó rí i pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wọ́n, ó wá sọ pé “ọ̀tọ̀ ni ohun tí mo máa ń rò nípa yín tẹ́lẹ̀.” Kí ló wá ṣẹlẹ̀? Ńṣe ló gbé àkọlé tó wà lára ìlẹ̀kùn rẹ̀ kúrò.

10, 11. (a) Kí ni ìdí kejì tá a fi ń ṣe iṣẹ́ ṣíṣe ìrànwọ́ nígbà àjálù, àwọn àpẹẹrẹ wo ló fi hàn pé à ń ṣe bẹ́ẹ̀? (b) Ìwé wo ni a ti pèsè láti ran àwọn tó ń ṣèrànwọ́ nígbà àjálù lọ́wọ́? (Wo àpótí náà, “Ìwé Kan Tó Wà Fáwọn Tó Ń Ṣe Iṣẹ́ Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù.”)

10 Ìkejì, a ń “pèsè lọ́pọ̀ yanturu” fún àìní àwọn ará wa. (2 Kọ́r. 9:12a) Tí àwọn ará wa bá wà nínú ìṣòro, ńṣe ni a máa ń múra tán láti ràn wọ́n lọ́wọ́. Ìdí ni pé “ara kan ṣoṣo” ni gbogbo wá jẹ́ nínú ìjọ Ọlọ́run, “bí ẹ̀yà ara kan bá sì ń jìyà, gbogbo ẹ̀yà ara yòókù a bá a jìyà.” (1 Kọ́r. 12:20, 26) Torí náà, ìfẹ́ni ará àti àánú ló ń sún àwọn arákùnrin àti àwọn arábìnrin wa láti fi ohun tí wọ́n ń ṣe sílẹ̀, tí wọ́n á sì kọrí síbi tí àjálù ti ṣẹlẹ̀ sí àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn kí wọ́n lè lọ ràn wọ́n lọ́wọ́ níbẹ̀. (Ják. 2:15, 16) Àpẹẹrẹ kan ni ti àkúnya omi tí wọ́n ń pè ní sùnámì tó wáyé ní Japan lọ́dún 2011. Ẹ̀ka ọ́fíìsì wa lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà kọ lẹ́tà sí àwọn Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn tó wà ní Amẹ́ríkà pé àwọn fẹ́ kí “àwọn arákùnrin díẹ̀ tó mọṣẹ́” yọ̀ǹda láti bá wọn tún àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba kọ́ níbi tí àjálù náà ti wáyé. Kí ló wá ṣẹlẹ̀? Láàárín ọ̀sẹ̀ mélòó kan, nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́fà [600] èèyàn ló ti yọ̀ǹda ara wọn, wọ́n sì múra tán láti wọkọ̀ òfuurufú lọ sí Japan kí wọ́n lè ṣèrànwọ́ níbẹ̀. Èyí tó yani lẹ́nu ni pé owó ara wọn ni wọ́n fi wọkọ̀ lọ. Ẹ̀ka ọ́fíìsì wa lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Ohun tí àwọn ará ṣe yìí wú wa lórí gan-an.” Nígbà tí arákùnrin kan ní Japan tiẹ̀ bi ọ̀kan lára àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn láti ilẹ̀ òkèèrè yẹn pé kí nìdí tó fi wá ṣèrànwọ́. Ó sọ pé: “‘Ara wa’ ni àwọn ará Japan jẹ́. Ohun tó bá sì dé bá ojú ti dé bá imú náà nìyẹn.” Irú ẹ̀mí ìfara-ẹni-jìn yìí ló mú kí ọ̀pọ̀ àwọn ará fi ẹ̀mí wọn wewu kí wọ́n lè ṣèrànwọ́ fún àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn tí àjálù bá.c—1 Jòh. 3:16.

Ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń to Àwọn ohun tí àwọn ará láti orílẹ̀-èdè Switzerland kó ránṣẹ́ sí àwọn ará wa tí ajálù bá, lódún 1946

Orílẹ̀-èdè Switzerland lọ́dún 1946

ÈTÒ ÌRÀNWỌ́ ÀKỌ́KỌ́ TÓ KÁRÍ AYÉ LÓDE ÒNÍ

NÍ OṢÙ September ọdún 1945, oṣù mélòó kan lẹ́yìn tí Ogun Àgbáyé Kejì parí ní ilẹ̀ Yúróòpù, Arákùnrin Knorr ṣe ìkéde pé ètò ti bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹu láti máa fi “àwọn nǹkan ti ara ṣèrànwọ́ fáwọn ará wa tí wọ́n jẹ́ aláìní, tí wọ́n ń gbé ní àárín gbùngbùn Yúróòpù.”

Láàárín ọ̀sẹ̀ mélòó kan lẹ́yìn ìkéde yẹn, àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní orílẹ̀-èdè Kánádà, orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà àti ní àwọn ilẹ̀ míì ti ṣètò àwọn aṣọ àti oúnjẹ tí wọ́n fẹ́ fi ránṣẹ́. Nígbà tó fi máa di January 1946, wọn ti bẹ̀rẹ̀ sí kó àwọn ìpèsè yìí ránṣẹ́ sí àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn tó wà ní orílẹ̀-èdè bí Austria, Belgium, Bulgaria, Czechoslovakia, Denmark, Finland, ilẹ̀ Faransé, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, ilẹ̀ Gíríìsì, Hungary, Ítálì, Jámánì, Netherlands, Norway, Philippines, Poland, Romania àti ilẹ̀ Ṣáínà.

Kì í ṣe ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo ni wọ́n fi irú ìpèsè yìí ránṣẹ́. Jálẹ̀ ọdún méjì àtààbọ̀ ni wọ́n fi ń kó oríṣiríṣi ìpèsè ránṣẹ́! Láàárín àkókó yìí, àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí wọ́n fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà márùndínláàádọ́rùn-ún [85,000] ni wọ́n fi àwọn ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọ̀ọ́dúnrún [300,000] kìlógíráàmù oúnjẹ ránṣẹ́, aṣọ tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́ta lé nírínwó [450,000] kìlógíráàmù, àti ẹgbàá méjìlélọ́gọ́ta [124,000] onírúurú bàtà ni wọ́n fi ránṣẹ́ sí àwọn ará wa tó wà ní àwọn ilẹ̀ tí ogun ti fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ wọ̀nyí. Iṣẹ́ ṣíṣe ìrànwọ́ nígbà àjálù tó gbòòrò yìí parí lóṣù August ọdún 1948. Ilé Ìṣọ́ ọdún 1949 sọ pé: “Kò sí àní-àní pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn lẹ́nì kínní kejì, a mọ̀ pé àwọn ará ṣe gbogbo èyí láti fi buyì fún Olúwa, wọ́n sì mọ̀ pé ìrànwọ́ nípa ti ara tí wọ́n pèsè yìí á ran ọ̀pọ̀ lọ́wọ́ láti lè máa bá ìjọsìn tòótọ́ nìṣó àti pé wọ́n kà á sí àǹfààní ńlá láti ṣèrànwọ́ fún àwọn ará wọn lọ́nà yìí.” Ohun tí wọ́n ṣe yìí ń fi ìyìn fún Jèhófà, ó ń ran àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn lọ́wọ́, ó sì tún mú kí àjọṣe tó wà láàárín wa lágbára gan-an.

11 Kì í ṣe àwa nìkan ni orí wa máa ń wú tá a bá rí nǹkan bẹ́ẹ̀, àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí pàápàá ti fi ìmọrírì hàn fún iṣẹ́ ìrànwọ́ tá à ń ṣe. Àpẹẹrẹ kan ni ti àjálù tó ṣẹlẹ̀ lọ́dún 2013, ní ìpínlẹ̀ Arkansas, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ìwé ìròyìn kan níbẹ̀ gbóríyìn fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fún bí wọ́n ṣe tètè gbé ìgbésẹ̀, ó ní: “Ètò tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe láti ṣèrànwọ́ fáwọn tí àjálù bá wúni lórí gan-an.” Abájọ tí ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi bá a mu wẹ́kú pé, à ń “pèsè lọ́pọ̀ yanturu” fún àìní àwọn ará wa.

12-14. (a) Kí ni ìdí kẹta tó fi ṣe pàtàkì láti máa pèsè ìrànwọ́ fún àwọn tí àjálù bá? (b) Kí ni àwọn kan ti sọ tó fi hàn pé ó ṣe pàtàkì kí a máa bá àwọn ìgbòkègbodò tẹ̀mí wa nìṣó?

12 Ìkẹta, iṣẹ́ ìrànwọ́ tá à ń ṣe ń jẹ́ kí àwọn tí àjálù bá lè tètè pa dà sẹ́nu ìjọsìn wọn. Kí nìdí tí èyí fi ṣe pàtàkì? Ṣé ẹ rántí ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ pé tí a bá ṣèrànwọ́ fáwọn èèyàn, ó máa ń mú kí wọ́n “fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run lọ́pọ̀lọpọ̀.” (2 Kọ́r. 9:12b) Torí náà, ọ̀nà kan tó dara jù tí àwọn tí àjálù bá lè gbà fi ọpẹ́ hàn fún ìrànwọ́ tí wọ́n rí gbà ni pé kí wọ́n tètè pa dà sẹ́nu ìjọsìn wọn sí Jèhófà. (Fílí. 1:10) Lọ́dún 1945, Ilé Ìṣọ́ kan sọ pé: ‘Pọ́ọ̀lù fọwọ́ sí i . . . pé kí wọ́n gba àwọn nǹkan tí wọ́n fẹ́ fi ṣèrànwọ́ jọ torí pé ó wúlò . . . fún àwọn Kristẹni tó ṣe aláìní kí wọ́n lè túbọ̀ ráyè láti lo gbogbo agbára wọn lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù nípa Jèhófà.’ Ohun tí àwa náà ń ṣe lónìí nìyẹn. Kété tá a bá ti pa dà sẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù báyìí, àtàwa àtàwọn tí àjálù bá la jọ ń gbé ara wa ró.—Ka 2 Kọ́ríńtì 1:3, 4.

13 Lẹ́yìn tí àwọn tí àjálù bá rí ìrànwọ́ gbà, wọ́n pa dà sẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Wọn sọ díẹ̀ lára àǹfààní tí wọ́n rí nínú wíwàásù lákòókò náà. Arákùnrin kan sọ pé: “Ìbùkún ńlá ló jẹ́ fún ìdílé wa pé a lè máa bá iṣẹ́ ìwàásù wa nìṣó. Bá a ṣe ń tu àwọn ẹlòmíì nínú kì í jẹ́ ká ronú nípa àwọn àníyàn tiwa.” Arábìnrin kan ní tiẹ̀ sọ pé: “Bí mo ṣe gbájú mọ́ ìgbòkègbodò tẹ̀mí kò jẹ́ kí n bọkàn jẹ́ jù lórí àwọn nǹkan tí àjálù náà bà jẹ́. Ó fi mí lọ́kàn balẹ̀ pẹ̀sẹ̀.” Arábìnrin míì tún sọ pé: “Ọ̀pọ̀ nǹkan tó ṣẹlẹ̀ ju agbára wa lọ, àmọ́ iṣẹ́ ìwàásù jẹ́ kí ìdílé wa rí ìtọ́sọ́nà tí a nílò. Bá a ṣe ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nípa ayé tuntun tá à ń retí bẹ́ẹ̀ ni àwa náà túbọ̀ ń ní ìgbọ́kànlé pé Ọlọ́run máa sọ ohun gbogbo dọ̀tun.”

14 Ohun míì tí àwọn tó rí ìrànwọ́ gbà nígbà àjálù tún gbọ́dọ̀ ṣe ni pé kí wọ́n má ṣe jẹ́ kó pẹ́ tí wọ́n á tún fi bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí ìpàdé ìjọ. Ronú nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Arábìnrin Kiyoko tó ti sún mọ́ ẹni ọgọ́ta ọdún [60]. Nígbà tí sùnámì wáyé níbi tó ń gbé, gbogbo ohun tó ní pátá ló pàdánù. Kìkì aṣọ àti bàtà tó wọ̀ ló kù lára rẹ̀, kò tiẹ̀ mọ nǹkan tó lè ṣe mọ́. Alàgbà kan wá sọ fún un pé inú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ òun làwọn á ti máa ṣe ìpàdé táwọn máa ń ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Arábìnrin Kiyoko sọ pé: “Alàgbà kan àti ìyàwó rẹ̀ àti àwa arábìnrin méjì la wà nínú mọ́tò náà, ibẹ̀ sì la ti ń ṣe ìpàdé. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìpàdé yẹn kì í pẹ́ púpọ̀, ọkàn mi balẹ̀, ó sì yà mí lẹ́nu pé kò pẹ́ tí ìrònú àjálù náà fi kúrò lọ́kàn mi. Ìpàdé yẹn jẹ́ kí n rí bí ìpéjọpọ̀ Kristẹni ṣe lágbára tó.” Nígbà tí arábìnrin míì ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìpàdé tó lọ lẹ́yìn tí àjálù náà ṣẹlẹ̀, ó ní: “Àwọn ìpàdé náà gbé ìgbàgbọ́ mi ró.”—Róòmù 1:11, 12; 12:12.

Àǹfààní Pípẹ́ Títí Wà Nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Tí A Fi Ń Ṣe Ìrànwọ́

15, 16. (a) Àǹfààní wo ni àwọn Kristẹni tó wà ní Kọ́ríńtì àti ibòmíì máa rí tí wọ́n bá tẹra mọ́ ṣíṣe ìrànwọ́ fún àwọn tí àjálù bá? (b) Báwo làwa náà ṣe ń jàǹfààní nínú iṣẹ́ ṣíṣe ìrànwọ́ nígbà àjálù lónìí?

15 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa ‘iṣẹ́ òjíṣẹ́ fún àwọn ẹni mímọ́,’ ìyẹn iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí a fi ń ṣe ìrànwọ́ fáwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa nígbà ìṣòro, ó sọ àǹfààní tí àwọn ará Kọ́ríńtì àti àwọn Kristẹni mìíràn máa rí gbà bí wọ́n bá ń kópa nínú rẹ̀. Ó ní: “Pẹ̀lú ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ fún yín, aáyun yín ń yun wọ́n [ìyẹn àwọn Júù tó di Kristẹni ní Jerúsálẹ́mù, tí wọ́n rí ìrànwọ́ gbà], nítorí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run títayọ . . . wà lórí yín.” (2 Kọ́r. 9:14) Òótọ́ ni Pọ́ọ̀lù sọ torí pé ìwà ọ̀làwọ́ tí àwọn ará Kọ́ríńtì hù máa mú kí àwọn Júù tó di Kristẹni náà máa gbàdúrà fún àwọn ará wọn tó wà ní Kọ́ríńtì títí kan àwọn Kèfèrí, á sì tún mú kí ìfẹ́ tí wọ́n ní sí wọn túbọ̀ jinlẹ̀.

16 Nígbà tí Ilé Ìṣọ́ December 1, 1945 ń fi ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ ṣàlàyé àǹfààní tó wà nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí a fi ń ṣe ìrànwọ́ fáwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa nígbà ìṣòro lóde òní, ó ní: ‘Nígbà táwọn tí Ọlọ́run sọ di mímọ́ bá ń ran àwọn arákùnrin wọn tó wà nínú àìní lọ́wọ́, ẹ wo bí ìrẹ́pọ̀ tó wà láàárín wọn á ṣe dùn tó!’ Bọ́rọ̀ àwọn tó ń kópa nínú iṣẹ́ ìrànwọ́ ṣe máa ń rí gan-an nìyẹn. Alàgbà kan tó lọ ṣèrànwọ́ níbi ìṣẹ̀lẹ̀ omíyalé sọ pé: “Bí mo ṣe ń kópa nínú iṣẹ́ ṣíṣe ìrànwọ́ nígbà àjálù yìí ti jẹ́ kí n túbọ̀ sún mọ́ àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ mi ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.” Arábìnrin kan tó ń ṣọpẹ́ torí ìrànwọ́ tó rí gbà sọ pé: “Ńṣe ni ẹgbẹ́ ará wa yìí dà bí Párádísè.”—Ka Òwe 17:17.

17. (a) Báwo ni ọ̀rọ̀ tó wà nínú Aísáyà 41:13 ṣe kan iṣẹ́ ṣíṣe ìrànwọ́ nígbà àjálù? (b) Sọ àwọn ìrírí tó jẹ́ ká mọ̀ pé iṣẹ́ ṣíṣe ìrànwọ́ nígbà àjálù ń gbé Jèhófà ga àti pé ó ń jẹ́ kí ìfẹ́ tó so wá pọ̀ lágbára sí i. (Tún wo àpótí náà, “Àwọn Olùyọ̀ǹda Ara Ẹni Ń Pèsè Ìrànwọ́ Jákèjádò Ayé.”)

17 Nígbà tí àwọn ará bá gbéra láti lọ ṣèrànwọ́ fáwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn tí àjálù bá, àwọn èèyàn náà máa ń rí ọwọ́ Ọlọ́run lára wọn. Ó kúkú ti ṣèlérí pé: “Èmi, Jèhófà Ọlọ́run rẹ, yóò di ọwọ́ ọ̀tún rẹ mú, Ẹni tí ń wí fún ọ pé, ‘Má fòyà. Èmi fúnra mi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́.’” (Aísá. 41:13) Bí àpẹẹrẹ, lẹ́yìn tí arábìnrin kan la àjálù burúkú kan já, ó sọ pé: “Nígbà tí mo rí adúrú ohun tí àjálù náà bà jẹ́, ìdààmú ọkàn bá mi, mo rò pé gbogbo rẹ̀ ti parí fún mi, àmọ́ mo rí ọwọ́ Jèhófà lára mi torí pé ìrànlọ́wọ́ táwọn ará ṣe fún mi gadabú.” Lẹ́yìn tí ìmìtìtì ilẹ̀ ba agbègbè tí ìjọ kan wà jẹ́, àwọn alàgbà méjì tó ṣojú fún ìjọ náà sọ pé: “Àdánù ńlá gbáà ni ìmìtìtì ilẹ̀ náà fà ṣùgbọ́n Jèhófà gbé ìrànlọ́wọ́ dìde nípasẹ̀ àwọn arákùnrin wa. A ti máa ń ka ìtàn nípa bí àwọn ará ṣe ń ran àwọn tí àjálù bá lọ́wọ́, àmọ́ ní báyìí, ojú wa kòró ló ṣe.”

Arákùnrin Peter Johnson ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ará tó ń kọ́ àwọn ilé tá à ń lò fún ìjọsìn

Ó JẸ́ KÓ FI ÌGBÉSÍ AYÉ RẸ̀ ṢE OHUN TÓ DÁRA

ÀǸFÀÀNÍ wo ni lílọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ṣíṣe ìrànwọ́ nígbà àjálù lè ṣe fún àwọn ọ̀dọ́? Wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Arákùnrin Peter Johnson. Ọmọ ọdún méjìdínlógún [18] ni nígbà tó kópa nínú iṣẹ́ yìí fún ìgbà àkọ́kọ́. Ó sọ pé: “Bí àwọn ará ṣe máa ń mọrírì ohun tá à ń ṣe máa ń múnú mi dùn àti pé ayọ̀ tó wà nínú bí mo ṣe ń yọ̀ǹda ara mi máa ń mórí mi wú. Òun ló sì mú kí n pinnu láti lo ìgbésí ayé mi fún Jèhófà débi tí agbára mi bá gbé e dé.” Lẹ́yin náà, Arákùnrin Peter bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Nígbà tó yá, ó di òṣìṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì, ó sì tún sìn gẹ́gẹ́ bí ara Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn. Arákùnrin Peter sọ pé: “Ètò ìrànwọ́ tí mo kọ́kọ́ ṣe fún àwọn tí àjálù bá ní ọdún 1974 ló jẹ́ kí n fi ìgbésí ayé mi ṣe ohun tó dára.” Ẹ̀yin ọ̀dọ́, ǹjẹ́ ẹ lè ṣe bíi ti Arákùnrin Peter? Ó lè jẹ́ pé ọ̀nà tẹ́ ẹ fi lè lo ìgbésí ayé yín láti ṣe ohun tó dára nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ni kí ẹ̀yin náà kópa nínú iṣẹ́ ṣíṣe ìrànwọ́ nígbà àjálù yìí!

Ìwọ Náà Lè Kópa

18. Tó o bá fẹ́ kópa nínú iṣẹ́ ṣíṣe ìrànwọ́ nígbà àjálù, kí ló yẹ kó o ṣe? (Tún wo àpótí náà, “Ó Jẹ́ Kó Fi Ìgbésí Ayé Rẹ̀ Ṣe Ohun Tó Dára.”)

18 Ṣé wàá fẹ́ rí ayọ̀ tó wà nínú iṣẹ́ ṣíṣe ìrànwọ́ nígbà àjálù? Tó o bá fẹ bẹ́ẹ̀, jọ̀wọ́ fi sọ́kàn pé àwọn tí wọ́n sábà máa ń yàn láti ṣe ìrànwọ́ ni àwọn tó ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba. Torí náà, sọ fún àwọn alàgbà ìjọ rẹ pé o fẹ́ di ara àwọn tó ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba kí wọ́n lè fún ẹ ní fọ́ọ̀mù tí wàá fi bẹ̀rẹ̀. Alàgbà kan tó ti pẹ́ nínú iṣẹ́ ṣíṣe ìrànwọ́ nígbà àjálù yìí sọ ohun kan tó yẹ ká fi sọ́kàn, ó ní: “Tí Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù bá ké sí ọ láti wá ni kó o tó lọ sí agbègbè náà.” Nípa bẹ́ẹ̀, iṣẹ́ ṣíṣe ìrànwọ́ náà á lè lọ létòletò.

19. Báwo ni àwọn tó ń kópa nínú iṣẹ́ ṣíṣe ìrànwọ́ nígbà àjálù ṣe ń fi hàn pé ọmọ ẹ̀yìn Kristi làwọn jẹ́ lóòótọ́?

19 Iṣẹ́ ṣíṣe ìrànwọ́ nígbà àjálù jẹ́ ọ̀nà pàtàkì tá à ń gbà tẹ̀ lé àṣẹ Jésù pé kí a ‘nífẹ̀ẹ́ ara wa lẹ́nì kìíní-kejì.’ Bí a ṣe ń fìfẹ́ hàn lọ́nà yìí fi hàn pé ọmọ ẹ̀yìn Kristi la jẹ́ lóòótọ́. (Jòh. 13:34, 35) Ẹ ò rí i pé ìbùkún ló jẹ́ fún wa lónìí pé a ní àwọn tó ń fi tinútinú yọ̀ǹda ara wọn fún iṣẹ́ tó ń pèsè ìrànwọ́ fáwọn tó ń ti Ìjọba Ọlọ́run lẹ́yìn. Èyí sì ń gbé Jèhófà Ọlọ́run ga!

a Ohun tí orí yìí dá lé ni iṣẹ́ ìrànwọ́ tá à ń ṣe fún àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa tí àjálù bá. Àmọ́, lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà pàápàá máa ń jàǹfààní nínú rẹ̀.—Gál. 6:10.

b Ọ̀rọ̀ ẹlẹ́ni púpọ̀ náà di·aʹko·nos (òjíṣẹ́), ni Pọ́ọ̀lù lò nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa “àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́.”—1 Tímótì 3:12.

c Ka àpilẹ̀kọ tá a pe àkòrí rẹ̀ ní “Ṣíṣèrànwọ́ Fún Àwọn Ìdílé Onígbàgbọ́ Wa Ní Bosnia,” tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ November 1, 1994, ojú ìwé 23 sí 27.

Ṣé O Gbà Lóòótọ́ Pé Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso?

  • Báwo la ṣe mọ̀ pé iṣẹ́ ṣíṣe ìrànwọ́ nígbà àjálù jẹ́ ará iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún Jèhófà?

  • Kí ni ìdí pàtàkì mẹ́ta tá a fi ń ṣèrànwọ́ fún àwọn ará wa nígbà àjálù?

  • Àǹfààní pípẹ́ títí wo la máa ń rí lẹ́nu iṣẹ́ ṣíṣe ìrànwọ́ nígbà àjálù?

  • Báwo ni iṣẹ́ ṣíṣe ìrànwọ́ nígbà àjálù ṣe bá àṣẹ tí Jésù pa fún wa nínú Jòhánù 13:34 mu?

ÀWỌN OLÙYỌ̀ǸDA ARA ẸNI Ń PÈSÈ ÌRÀNWỌ́ JÁKÈJÁDÒ AYÉ

ÀÁRÍN GBÙNGBÙN ÀTI ÌWỌ̀ OÒRÙN ÁFÍRÍKÀ

Ní ọdún 1994, nǹkan bí ogójì ọ̀kẹ́ [800,000] èèyàn tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ni wọ́n pa nígbà ìpẹ̀yàrun tó wáyé lórílẹ̀-èdè Rùwáńdà. Lẹ́yìn ìpakúpa burúkú yẹn, rògbòdìyàn náà tàn dé àwọn ilẹ̀ míì ní Àárín Gbùngbùn Áfíríkà. Èyí ló fà á tí àwọn àgọ́ tí wọ́n ṣètò fáwọn tí ogun lé kúrò nílùú fi kún àkúnfàya. Kí àwọn ará lè ṣe ìrànwọ́ fáwọn arákùnrin tí àjálù bá yìí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti orílẹ̀-èdè Belgium, Faransé àti Switzerland fi àwọn ẹrù tó kún inú ọkọ̀ akẹ́rù ńlá mẹ́wàá ránṣẹ́ sí wọ́n. Lára ohun tí wọ́n fi ránṣẹ́ ni aṣọ, oògùn, tapólì, oúnjẹ àtàwọn nǹkan míì. Kò sì ju bí ọ̀sẹ̀ mélòó kan tí àwọn ìpèsè yìí fi dé ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin tí àjálù náà bá.

Lápá ibòmíì nílẹ̀ Áfíríkà, àwọn arákùnrin àti arábìnrin mẹ́wàá tí wọ́n jẹ́ dókítà àti nọ́ọ̀sì láti orílẹ̀-èdè Faransé ń ṣiṣẹ́ pọ̀ láti pèsè ìrànwọ́ fáwọn ará tí àjálù bá nítorí ogun abẹ́lé, ìyàn àti àjàkálẹ̀ àrùn. Ní ọdún méjì tó kọjá, àwọn mẹ́wàá yìí ṣe àyẹ̀wò ìlera fún àwọn èèyàn tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá [10,000]. Iṣẹ́ wọ́n yìí ń fi ìyìn fún Jèhófà àti ètò rẹ̀. Ọ̀kan nínú àwọn nọ́ọ̀sì náà sọ pé: “Nígbà tá a bá dé agbègbè kan láti ran àwọn ará wa lọ́wọ́, àwọn èèyàn ibẹ̀ máa ń bọ̀wọ̀ fún wa, wọ́n á ní: ‘Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìyí tí wọ́n wá ran àwọn ará wọn lọ́wọ́.’” Lẹ́yìn tí arábìnrin kan gba ìtọ́jú lọ́dọ̀ nọ́ọ̀sì kan, ó fìdùnnú sọ pé: “O ṣeun gan-an arábìnrin mi. Jèhófà, o ṣé o!”

Nígbà míì, a máa ń ṣètò ìrànwọ́ nígbà tí ìjàǹbá burúkú bá ṣẹlẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, lọ́dún 2012, ìjàǹbá ọkọ̀ kan ṣẹlẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, àwọn Ẹlẹ́rìí mẹ́tàlá láti inú ìjọ kékeré kan ló kú nínú ìjàǹbá náà, àwọn mẹ́rìnléláàádọ́ta [54] sì fara pa yánna-yànna. Kíá ni ìgbìmọ̀ tó ń bójú tó ètò ìrànwọ́ ti ṣètò bí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn tó fara pa náà á ṣe máa gba ìtọ́jú tọ̀sán-tòru. Nígbà tí obìnrin kan tó wá gba ìtọ́jú ní ilé ìwòsàn yẹn rí bí àwọn Ẹlẹ́rìí ṣe ń tọ́jú àwọn ará wọn tó fara pa, ó pe pásítọ̀ rẹ̀ lórí fóònù, ó sì sọ fún un pé: “Kò tíì sí ará ṣọ́ọ̀ṣì wa kankan tó wá bẹ̀ mí wò. Ẹ wá sí ilé ìwòsàn yìí kí ẹ wá wo bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe nífẹ̀ẹ́ ara wọn tó!”

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àdánù ńlá ló bá àwọn ará wa ọ̀wọ́n ní ìjọ kékeré yẹn, wọ́n rí ìtùnú látinú ìfẹ́ táwọn ará wọn lọ́kùnrin àti lóbìnrin fi hàn sí wọn. Bákàn náà, nígbà táwọn arákùnrin náà rí bí àwọn ará ṣe fìfẹ́ tọ́jú wọn, ó wú wọn lórí gan-an, èyí sì mú kí wọ́n fi kún iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn. Ṣáájú ìjàǹbá ọkọ̀ náà, akéde márùnlélọ́gbọ̀n [35] ló wà nínú ìjọ yẹn, àmọ́ ọdún kan lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ náà, iye yẹn di ọgọ́ta [60].

ỌSIRÉLÍÀ

Omíyalé tó ṣẹlẹ̀ ní etíkun Queensland lọ́dún 2013 sọ àádọ́rin [70] àwọn arákùnrin wa di aláìnílé. Mark, Rhonda àti ọmọbìnrin wọn wà lára irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀. Wọ́n sá nígbà tí omi ya wọ ilé wọn, wọ́n sì bá ara wọn ní àgọ́ kan tí wọ́n tí ń fi ọkọ̀ kó àwọn tí àjálù bá lọ sí ibòmíì. Èrò kún ibẹ̀ fọ́fọ́. Rhonda sọ pé: “Ibẹ̀ há débi pé kò tiẹ̀ sáyè ìjókòó rárá.” Ariwo àwọn hẹlikópítà tó ń lọ tó ń bọ̀ kò tiẹ̀ jẹ́ kí ibẹ̀ fara rọ. Nígbà tí ara Rhonda kò gbà á mọ́, ó bi ọkọ rẹ̀ pé: “Kí la máa ṣe báyìí?” Ni Mark ọkọ rẹ̀ bá gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ran àwọn lọ́wọ́. Rhonda sọ pé: “Kò ju bí ọgbọ̀n ìṣẹ́jú lẹ́yìn náà tí àwọn arákùnrin mẹ́ta kan wakọ̀ wá sí àgọ́ náà. Nígbà tí wọ́n rí wa, wọ́n sọ fún wa pé, ‘Ẹ ká lọ ká lè fi yìn wọ̀ sí ilé arákùnrin kan.’” Rhonda wá fi kún un pé: “A ò lè sọ bí inú wa ṣe dùn tó lákòókò yẹn nígbà tá a rí bí ètò Jèhófà ṣe ń fi ìfẹ́ bójú tó wa.”

Ohun tó lé ní igba ó lé àádọ́ta [250] ará ló yọ̀ǹda ara wọn láti ran àwọn arákùnrin wọn tí àjálù náà bá lọ́wọ́. Arákùnrin àgbàlagbà kan sọ pé: “Kò pẹ́ tí àwọn Ẹlẹ́rìí kan dé tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ kára láti palẹ̀ gbogbo inú ilé mi tí ó rí játijàti mọ́. Èmi àti ìyàwó mi ò lè gbàgbé bí àwọn arákùnrin yẹn ṣe ràn wá lọ́wọ́.”

BRAZIL

Ní ọdún 2008, omíyalé ṣẹlẹ̀, ẹrẹ̀ tún ya wọ̀lú. Èyí sì lé nǹkan bí ọ̀kẹ́ mẹ́rin [80,000] èèyàn kúrò nílé wọn nílùú Santa Catarina. Ọkùnrin kan tó ń gbé lágbègbè yẹn sọ pé ńṣe ni òun ń wo bí “òbítíbitì amọ̀, ẹrẹ̀ àti igi ṣe ń rọ́ wọnú ìlú.” Àwọn arákùnrin kan sáré lọ fara pa mọ́ sí Gbọ̀ngàn Àpéjọ. Márcio tó ń bójú tó gbọ̀ngàn àpéjọ náà sọ nípa àwọn arákùnrin yẹn pé: “Kìkì aṣọ tó wà lọ́rùn wọn ló bá wọn débí, ó sì ti kún fún ẹrẹ̀.” Arábìnrin kan sọ pé: “Ìṣojú mi báyìí ni ilé wa wó lulẹ̀ bẹẹrẹbẹ tí mi ò sì lè ṣe nǹkan sí i. Ọkàn mi gbọgbẹ́ bí mo ṣe ń wo ilé náà tó pa rẹ́ ní ìṣẹ́jú akàn, àmọ́ mi ò lè gbàgbé bí àwọn ará ṣe tù wá nínú. Àwọn ará fìfẹ́ hàn sí wa gan-an! Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí ti jẹ́ kí n rí i pé títọ́jú ìṣúra wa sọ́dọ̀ Ọlọ́run ni ohun tó mọ́gbọ́n dání jù lọ.”

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣètò láti kó ohun ìrànwọ́ táwọn ará kó ránṣẹ́ fún àwọn ará wa ti àjálù bá ní Brazil

Gbọ̀ngàn Àpéjọ kan nílùú Santa Catarina, lórílẹ̀-èdè Brazil, tí wọ́n lò fún ibi tí àwọn tí àjálù bá ti ń gba ìrànlọ́wọ́ àti àwọn ohun tí wọ́n nílò, ọdún 2009

Ẹrẹ̀ tó ń ya wọ̀lú ti ba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn abúlé tó wà ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè nítòsí ìlú Rio de Janeiro jẹ́. Èyí ló mú kí àwọn arákùnrin dá Ìgbìmọ̀ Tó Ń Pèsè Ìrànwọ́ sílẹ̀ kí wọ́n lè tètè máa bójú tó àjálù tó ń ṣẹlẹ̀ léraléra níbẹ̀. Kété tá a bá ti gbọ́ pé ẹrẹ̀ tún fẹ́ ya wọ̀lú, àwọn arákùnrin tí ìgbìmọ̀ yìí ti yàn, tó ń gbé lágbègbè yẹn á ti tètè kàn sí ìgbìmọ̀ náà. Kíá ni àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni á ti dé, ọkọ̀ kan báyìí ni wọ́n máa ń gbé wá tó ní àkọlé náà “Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ń Ṣèrànwọ́ Fáwọn Tó Níṣòro.” Gbogbo àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni yìí ni wọ́n ti dá lẹ́kọ̀ọ́, ó sì ti ní iṣẹ́ tí kálukú wọn máa ṣe. Àwọn òṣìṣẹ́ yìí máa ń wọ aṣọ tí wọ́n ti sàmì sí láti fi hàn pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wọ́n. Wọ́n sì máa ń ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn láti pèsè ìtọ́jú fáwọn arákùnrin àti arábìnrin tó fara pa. Àwọn tó ń ṣe ìrànwọ́ yìí máa ń gbé oúnjẹ, omi, oògùn, aṣọ àti ọṣẹ wá fáwọn tí àjálù náà bá. Pípalẹ̀ ẹrẹ̀ mọ́ nínú ilé kì í ṣe iṣẹ́ kékeré. Bí àpẹẹrẹ, lẹ́yìn tí ẹrẹ̀ ya wọ̀lú lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ọgọ́ta [60] èèyàn ló ṣiṣẹ́ náà, wọ́n sì kó ẹrẹ̀ tó kún ọkọ̀ akẹ́rù mẹ́rin kúrò nínú ilé kan ṣoṣo!

BÍ A ṢE LÈ MÚRA SÍLẸ̀ DE ÀJÁLÙ

Ìgbìmọ̀ Olùdarí ní kí gbogbo ẹ̀ka ọ́fíìsì kárí ayé fún àwọn alàgbà àti àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò ní ìtọ́ni nípa bí wọ́n ṣe lè múra sílẹ̀ de àjálù àti ohun tí wọ́n máa ṣe tí àjálù bá ṣẹlẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ó yẹ kí àwọn alàgbà ní gbogbo ìsọfúnni nípa bí wọ́n ṣe lè kàn sí ẹni kọ̀ọ̀kan nínú ìjọ wọn ṣáájú kí àjálù tó ṣẹlẹ̀ rárá.

NÍGBÀ TÍ ÀJÁLÙ BÁ ṢẸLẸ̀!

  1. Alàgbà kan lọ ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ ìdílé Kristẹni akéde kan

    Àwọn alàgbà máa wá gbogbo àwọn akéde kàn

  2. Àwọn alàgbà máa jábọ̀ fún olùṣekòkáárí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà

  3. Bí ìsọfúnni ṣe ń dé ọ̀dọ̀ àwọn olùṣekòkáárí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà, àwọn alábòójútó àyíká àti àwọn míì tó ń múpò iwájú àti ẹ̀ka ófíìsì

    Àwọn olùṣekòkáárí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà máa jábọ̀ fún alábòójútó arìnrìn-àjò àti àwọn arákùnrin míì tó lè tètè kàn sí ẹ̀ka ọ́fíìsì

  4. Oúnjẹ àti omi

    Láìjáfara, wọ́n á pèsè oúnjẹ, omi, ibi tó ṣeé gbé àti ìtọ́jú tó yẹ. Wọ́n á tù wọ́n nínú, wọ́n á sì tún bójú tó àìní tẹ̀mí wọ́n

  5. Àyẹ̀wò ìròyìn nípa àwọn ohun ìrànwọ́ tá a nílò nígbà àjálù

    Ẹ̀ka ọ́fíìsì á fi ìròyìn nípa bí ipò nǹkan ṣe rí àti àwọn ohun tí wọ́n nílò ránṣẹ́ sí Ìgbìmọ̀ Olùṣekòkáárí tó jẹ́ apá kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí

  6. Bí wọ́n ṣe ń pín àwọn ohun ìrànwọ́ nígbà àjálù

    Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù ló máa ṣètò bí wọ́n ṣe máa ran àwọn tí àjálù náà dé bá lọ́wọ́ kí wọ́n lè kọ́fẹ pa dà

  7. Ọkọ̀ òfuruufú lójú ọ̀run

    Ìgbìmọ̀ Olùṣekòkáárí máa gbé àwọn ọ̀ràn àjálù náà yẹ̀ wò, tó bá jẹ́ pé wọ́n máa nílò àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni láti orílẹ̀-èdè míì láti ṣèrànwọ́, àwọn ni wọ́n máa fọwọ́ sí i

ÌWÉ KAN TÓ WÀ FÁWỌN TÓ Ń ṢE IṢẸ́ ÌRÀNWỌ́ NÍGBÀ ÀJÁLÙ

Iwájú ìwé pẹlẹbẹ náà Jehovah’s Witnesses and Disaster  Relief

NÍ OṢÙ June ọdún 2013, ètò Ọlọ́run mú ìwé pẹlẹbẹ kan jáde, àkòrí rẹ̀ ni Jehovah’s Witnesses and Disaster Relief. Wọ́n dìídì ṣe ìwé yìí fún àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba tó ń bójú tó ọ̀ràn pàjáwìrì ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ìwé pẹlẹbẹ náà sọ nípa àwọn ètò ìrànwọ́ tá a ti ṣe bẹ̀rẹ̀ láti ọdún 1945 títí dòní. Ìwé náà tún ní àwòrán ilẹ̀ tó fi hàn pé kárí ayé la ti ń ṣètò ìrànwọ́ yìí fún àwọn tí àjálù dé bá. Alàgbà kan tó wà lára àwọn tó ń bójú tó ètò ìrànwọ́ sọ pé: “Àwọn arákùnrin tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù máa ń lo ìwé pẹlẹbẹ yìí láti kàn sí àwọn lọ́gàá-lọ́gàá lẹ́nu iṣẹ́ ìjọba tó wà láwọn agbègbè tí àjálù ti sábà máa ń ṣẹlẹ̀. Wọ́n sì máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ ṣáájú kí àjálù tó ṣẹlẹ̀.” Arákùnrin náà wá fi kún un pé: “Nígbà táwọn òṣìṣẹ́ yìí bá ti mọ̀ nípa ètò ìrànwọ́ tá a máa ń ṣe, ó máa ń mú kó rọrùn láti gbàṣẹ ká lè wọlé sí àwọn ibi tí àjálù bá ti ṣẹlẹ̀.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́