ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwfq àpilẹ̀kọ 22
  • Ṣé Ẹ Máa Ń Ṣèrànwọ́ Nígbà Àjálù?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé Ẹ Máa Ń Ṣèrànwọ́ Nígbà Àjálù?
  • Àwọn Ìbéèrè Táwọn Èèyàn Sábà Máa Ń Béèrè Nípa Ẹlẹ́rìí Jèhófà
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìṣètò
  • Ìnáwó
  • Bá A Ṣe Lè Ṣèrànwọ́ Tí Àjálù Bá Ṣẹlẹ̀
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2023
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Tá A Fi Ń Ṣe Ìrànwọ́
    Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!
  • Ọ̀nà Wo La Lè Gbà Ṣèrànwọ́?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
  • Báwo La Ṣe Ń Ṣèrànwọ́ fún Àwọn Ará Wa Tí Àjálù Bá?
    Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?
Àwọn Míì
Àwọn Ìbéèrè Táwọn Èèyàn Sábà Máa Ń Béèrè Nípa Ẹlẹ́rìí Jèhófà
ijwfq àpilẹ̀kọ 22

Ṣé Ẹ Máa Ń Ṣèrànwọ́ Nígbà Àjálù?

Bẹ́ẹ̀ ni, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣèrànwọ́ nígbà àjálù. Àti Ẹlẹ́rìí àtẹni tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí la máa ń ràn lọ́wọ́ tí àjálù bá ṣẹlẹ̀, torí ohun tí Bíbélì ní ká ṣe nìyẹn nínú Gálátíà 6:10: “Ẹ jẹ́ kí a máa ṣe ohun rere sí gbogbo ènìyàn, ṣùgbọ́n ní pàtàkì sí àwọn tí ó bá wa tan nínú ìgbàgbọ́.” A tún máa ń gbìyànjú láti tu àwọn tí àjálù bá ṣẹlẹ̀ sí nínú, a sì máa ń fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbé wọn ró torí ohun tí wọ́n nílò gan-an lásìkò yẹn nìyẹn.—2 Kọ́ríńtì 1:3, 4.

Ìṣètò

Tí àjálù bá ṣẹlẹ̀, àwọn alàgbà ìjọ tó wà lágbègbè náà máa ń kàn sí gbogbo àwọn ará ìjọ kí wọ́n lè mọ̀ bóyà àlàáfíà ni wọ́n wà, kí wọ́n sì lè mọ̀ bóyá wọ́n á nílò ohunkóhun. Àwọn alàgbà náà á wá jábọ̀ ìsọfúnni tí wọ́n bá rí gbà àti ìgbésẹ̀ tí wọ́n bá gbé láti ṣèrànwọ́ fún ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lórílẹ̀-èdè wọn.

Tí àjálù tó ṣẹlẹ̀ bá kọjá ohun táwọn ìjọ àdúgbò náà lè bójú tó, Ìgbìmọ̀ Olùdarí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣètò láti pèsè ohun tí wọ́n nílò. Báwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní náà ṣe bójú tó ara wọn nígbà kan tí ìyàn mú nìyẹn. (1 Kọ́ríńtì 16:1-4) Ẹ̀ka ọ́fíìsì orílẹ̀-èdè náà máa wá yan Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù láti ṣètò bí ìrànwọ́ ṣe máa dé ọ̀dọ̀ àwọn tí àjálù ṣẹlẹ̀ sí. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láwọn ibòmíì máa ń yọ̀ǹda àkókò wọn láti wá ràn wọ́n lọ́wọ́, wọ́n sì máa ń fi ohun ìní wọn ṣèrànwọ́.—Òwe 17:17.

Ìnáwó

Táwọn èèyàn bá fi owó ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ọ̀kan lára ohun tá a máa ń fi ṣe ni pé ká fi ṣèrànwọ́ fún àwọn tí àjálù bá dé bá. (Ìṣe 11:27-30; 2 Kọ́ríńtì 8:13-15) Torí pé ṣe làwọn tó ń ṣèrànwọ́ máa ń yọ̀ǹda ara wọn, wọn kì í gbowó iṣẹ́, orí àwọn tí àjálù dé bá la máa ń ná gbogbo owó tí wọ́n bá ṣètò pé ká ná fún wọn sí, a kì í yọ lára rẹ̀ fún àwọn tó ń ṣèrànwọ́. A máa ń fọgbọ́n lo gbogbo ọrẹ tá a bá rí gbà.—2 Kọ́ríńtì 8:20.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́