ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 11/05 ojú ìwé 7
  • Ọ̀nà Wo La Lè Gbà Ṣèrànwọ́?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọ̀nà Wo La Lè Gbà Ṣèrànwọ́?
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé Ẹ Máa Ń Ṣèrànwọ́ Nígbà Àjálù?
    Àwọn Ìbéèrè Táwọn Èèyàn Sábà Máa Ń Béèrè Nípa Ẹlẹ́rìí Jèhófà
  • “Ẹ̀bùn Tá A Mú Dání Wá fún Jèhófà”
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2018
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Tá A Fi Ń Ṣe Ìrànwọ́
    Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!
  • Bá A Ṣe Lè Ṣèrànwọ́ Tí Àjálù Bá Ṣẹlẹ̀
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2023
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
km 11/05 ojú ìwé 7

Ọ̀nà Wo La Lè Gbà Ṣèrànwọ́?

1 Báwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá ti gbọ́ pé àjálù ṣẹlẹ̀ níbikíbi lágbàáyé, ìbéèrè tó sábà máa ń wà lẹ́nu wọn ni pé, “Ọ̀nà wo la lè gbà ṣèrànwọ́?” Àkọsílẹ̀ tó wà nínú Ìṣe 11:27-30 fi hàn pé àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní fi ìpèsè a-dín-ìṣòro-kù ránṣẹ́ sáwọn ará tó ń gbé ní Jùdíà nítorí ìyàn tó mú nílùú náà.

2 Lóde òní, òfin gbà wá láyè láti ya owó sọ́tọ̀ fún pípèsè ìrànwọ́ fáwọn tí àjálù bá dé bá, ì báà jẹ́ èyí tó dédé wáyé tàbí àfọwọ́fà ẹ̀dá, àti nígbà táwọn ìṣẹ̀lẹ̀ míì bá ṣẹlẹ̀ tó kó àwọn èèyàn sínú àìní.

3 Bí àpẹẹrẹ, lọ́dún tó kọjá, ọ̀pọ̀ àwọn ará ló fi owó ránṣẹ́ pé ká fi ṣèrànwọ́ fáwọn tí àjálù bá nígbà tí ilẹ̀ abẹ́ òkun ri ní Gúúsù Éṣíà. A mọrírì ẹ̀mí ìgbatẹnirò táwọn ará fi hàn nípa ọrẹ owó tí wọ́n fi ránṣẹ́ láti fi ṣètìlẹyìn fún pípèsè ìrànwọ́. Síbẹ̀, nígbà tẹ́ni tó fi ọrẹ ránṣẹ́ bá sọ àjálù pàtó tá a gbọ́dọ̀ lo ọrẹ náà fún, òfin àwọn orílẹ̀-èdè kan fi dandan lé e pé ká lò ó fún àjálù tẹ́ni náà ní ká lò ó fún. Ó sì gbọ́dọ̀ jẹ́ láàárín àkókò náà gan-an, kódà káwọn ará tó wà nítòsí ibẹ̀ tiẹ̀ ti pèsè ohun táwọn tí àjálù dé bá náà nílò fún wọn tàbí kó jẹ́ pé ṣe ni ọrẹ náà tó, tó sì tún ṣẹ́ kù.

4 Nítorí ìdàrúdàpọ̀ tó sábà máa ń wáyé látàrí ohun táwọn tó ń fi ọrẹ ránṣẹ́ máa ń sọ pé ká fi ọrẹ náà ṣe, á dábàá pé kí ẹ kúkú máa fi gbogbo ọrẹ yín ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ kárí ayé. A máa ń lo owó tá a bá rí lórúkọ iṣẹ́ kárí ayé yìí láti fi pèsè ìrànwọ́ fáwọn tí àjálù bá ṣẹlẹ̀ sí, a sì tún ń lò ó láti fi bójú tó ohun tí ẹgbẹ́ àwọn ará kárí ayé, tá a jọ jẹ́ Kristẹni bá nílò nípa tẹ̀mí. Bí ìdí kan bá sì wà tí ẹnì kan fi fẹ́ ṣètọrẹ fún pípèsè ìrànwọ́ fáwọn tí àjálù dé bá lọ́tọ̀ yàtọ̀ sí ọrẹ fún iṣẹ́ kárí ayé, a ó gbà á, a ó sì lò ó níbikíbi táwọn ará bá ti nílò ìrànwọ́. Lọ́rọ̀ kan ṣáá, ì bá túbọ̀ dùn mọ́ wa nínú bó bá jẹ́ pé tààràtà lẹ̀ ń fi àwọn ọrẹ yín ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ kárí ayé láìsí pé ẹ̀ ń sọ ibi tẹ́ ẹ fẹ́ ká lò ó sí àti bẹ́ ẹ ṣe fẹ́ ká lò ó.

5 Bá a ṣe ń fi àwọn ọrẹ wa ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ kárí ayé ń jẹ́ ká lè ní owó tó pọ̀ tó lọ́wọ́ láti lò fún gbogbo ẹ̀ka iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba náà dípò ká kàn máa tọ́jú rẹ̀ dìgbà tí àjálù bá tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Èyí bá ohun tó wà nínú Éfésù 4:16 mu pé bá a bá ń ṣiṣẹ́ ní ìfọwọ́sowọ́pọ̀, ara á lè “dàgbà fún gbígbé ara rẹ̀ ró nínú ìfẹ́.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́