Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ August 27
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ AUGUST 27
Orin 100 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
bt orí 25 ìpínrọ̀ 14 sí 21 (25 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Ìsíkíẹ́lì 35-38 (10 min.)
Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run (20 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
10 min: Àwọn Ìfilọ̀. “Àyípadà Tó Máa Bá Ìpàdé Àárín Ọ̀sẹ̀.” Àsọyé. Lẹ́yìn àsọyé náà, lo àbá tó wà lójú ìwé 8 láti ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní Saturday àkọ́kọ́ lóṣù September.
15 min: Jẹ́ Kí Ọ̀rọ̀ Rẹ Máa Yéni Nígbà Tó O Bá Ń Wàásù. Ìjíròrò tá a gbé ka ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ojú ìwé 226 sí 229. Ṣe àṣefihàn kókó kan tàbí méjì látinú àpilẹ̀kọ náà.
10 min: Kí La Rí Kọ́? Ìjíròrò. Ẹ ka Lúùkù 10:1-4, 17, kẹ́ ẹ sì jíròrò bí ohun tó wà níbẹ̀ ṣe lè wúlò fún wa lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa.
Orin 57 àti Àdúrà