Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí la máa fi ṣe àtúnyẹ̀wò ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ní ọ̀sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní August 27, 2012. A fi déètì ọ̀sẹ̀ tá a máa jíròrò kókó kọ̀ọ̀kan sínú àwọn ìbéèrè náà.
1. Kí lohun tí ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí nípa ilẹ̀ Júdà tó ti di apẹ̀yìndà ṣàpẹẹrẹ rẹ̀, ẹ̀kọ́ pàtàkì wo lèyí sì kọ́ wa? (Ìsík. 8:15-17) [July 2, w07 7/1 ojú ìwé 13 ìpínrọ̀ 6; w93 1/15 ojú ìwé 27 àti 28 ìpínrọ̀ 7 àti 12]
2. Ọ̀nà wo ni èyí tó pọ̀ jù lára àwọn aṣáájú ẹ̀sìn òde òní fi dà bí àwọn wòlíì èké nígbà ayé Ìsíkíẹ́lì? (Ìsík. 13:3, 7) [July 9, w99 10/1 ojú ìwé 13 ìpínrọ̀ 14 àti 15]
3. Nínú àsọtẹ́lẹ̀ inú Ìsíkíẹ́lì 17:22-24, ta ni “èyí tí ó jẹ́ ọ̀jẹ̀lẹ́,” kí ni “orí òkè ńlá gíga tí ó lọ sókè fíofío” tí wọ́n gbìn ín sí, àti pé báwo ló ṣe di “kédárì ọlọ́lá ọba”? [July 16, w07 7/1 ojú ìwé 12 àti 13 ìpínrọ̀ 6]
4. Níbàámu pẹ̀lú òwe tí ìwé Ìsíkíẹ́lì 18:2 tọ́ka sí, ta ni àwọn tó wà nígbèkùn pẹ̀lú Ìsíkíẹ́lì dẹ́bi fún pé ó fa ìyà táwọn ń jẹ, ẹ̀kọ́ wo la sì lè rí kọ́ nínú àkọsílẹ̀ yìí? [July 23, w88 9/15 ojú ìwé 18 ìpínrọ̀ 10]
5. Báwo ni ìṣẹ̀lẹ̀ tó wà nínú Ìsíkíẹ́lì 21:18-22 ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé kò sí ẹ̀dá èèyàn tàbí ẹ̀mí èṣù èyíkéyìí tó lè ní kí ìfẹ́ Jèhófà má ṣẹ? [July 30, w07 7/1 ojú ìwé 14 ìpínrọ̀ 4]
6. Bó ṣe wà nínú Ìsíkíẹ́lì 24:6, 11, 12, kí ni ìpẹtà ìkòkò ìse-oúnjẹ dúró fún, ìlànà wo ló sì wà nínú ẹsẹ 14? [Aug. 6, w07 7/1 ojú ìwé 14 ìpínrọ̀ 2]
7. Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí ìlú Tírè ṣe nímùúṣẹ? [Aug. 6, w08 1/1 ojú ìwé 23 ìpínrọ̀ 1]
8. Àwọn gbólóhùn wo nínú Ìsíkíẹ́lì 28:2, 12-17 ló bá “ọba Tírè,” àti Sátánì, ọ̀dàlẹ̀ àkọ́kọ́ náà mu? [Aug. 13, w05 10/15 ojú ìwé 23 àti 24 ìpínrọ̀ 10 sí 14]
9. Ìgbà wo làwọn ọ̀tá sọ ilẹ̀ Íjíbítì dahoro fún ogójì ọdún, kí sì nìdí tá a fi lè gbà pé ìparun yẹn ṣẹlẹ̀ lóòótọ́? (Ìsík. 29:8-12) [Aug. 13, w07 8/1 ojú ìwé 8 ìpínrọ̀ 5]
10. Kí lohun tí Ìsíkíẹ́lì ṣe nígbà táwọn èèyàn dágunlá sí i, tí wọ́n pẹ̀gàn rẹ̀, tí kò sì sí ẹni tó fetí sí i, ìdánilójú wo sì ni Jèhófà fún un? (Ìsík. 33:31-33) [Aug. 20, w91 3/15 ojú ìwé 17 ìpínrọ̀ 16 àti 17]