Àyípadà Tó Máa Bá Ìpàdé Àárín Ọ̀sẹ̀
Bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀sẹ̀ September 3, ọgbọ̀n ìṣẹ́jú [30] la ó máa fi ṣe Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ dípò ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] tá à ń lò tẹ́lẹ̀. Kí ẹni tó bá fẹ́ darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ fi ìṣẹ́jú kan ṣàtúnyẹ̀wò ẹ̀kọ́ tá a kọ́ lọ́sẹ̀ tó kọjá nínú ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀. Àkókò tí à ń lò fún Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn náà máa yí pa dà láti ìṣẹ́jú márùndínlógójì [35] sí ọgbọ̀n ìṣẹ́jú [30]. Kò ní sí apá kankan tá a dìídì yà sọ́tọ̀ fún àwọn ìfilọ̀ mọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, nígbà tá a bá ń bójú tó iṣẹ́ àkọ́kọ́ ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn la ó máa sọ àwọn ìfilọ̀ tó bá wà. Lọ́pọ̀ ìgbà, ìfilọ̀ díẹ̀ péré la ó máa ṣe, ìyẹn tó bá tiẹ̀ máa wà rárá. A kò sì ní máa sọ àwọn ọ̀rọ̀ tá a máa bójú tó nínú Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn nínú ìfilọ̀ mọ́. Àwọn ìfilọ̀ nípa ètò fún iṣẹ́ ìwàásù, ìmọ́tótó àti ìkíni kò ní sí mọ́. (km 10/08 ojú ìwé 1, ìpínrọ̀ 4) Tẹ́ ẹ bá ní ìfilọ̀ tó pọ̀ tẹ́ ẹ fẹ́ ṣe, ó máa dáa kí àwọn tó máa níṣẹ́ ní ìpàdé ti mọ̀ ṣáájú àkókò, kí wọ́n lè dín àkókò tí wọ́n máa fi ṣe iṣẹ́ wọn kù.