ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 10/08 ojú ìwé 1
  • Ọ̀nà Tuntun Tí A Ó Máa Gbà Ṣèpàdé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọ̀nà Tuntun Tí A Ó Máa Gbà Ṣèpàdé
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Pápá Tó Ń Gbéni Ró, Tó Ń Múni Gbára Dì, Tó sì Ń Mú Ká Wà Létòlétò
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2015
  • Àpótí Ìbéèrè
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
  • A Fi Tọ̀yàyàtọ̀yàyà Pè Ẹ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Àwọn Ìpàdé Tó Ń Fún “Wa Níṣìírí Láti Ní Ìfẹ́ àti Láti Ṣe Àwọn Iṣẹ́ Rere”
    A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
km 10/08 ojú ìwé 1

Ọ̀nà Tuntun Tí A Ó Máa Gbà Ṣèpàdé

1, 2. Àwọn àyípadà wo ló máa wáyé nínú ọ̀nà tá à ń gbà ṣèpàdé láti oṣù January ọdún 2009?

1 Gbogbo àwọn ará jákèjádò ayé ló gbọ́ ìfilọ̀ amóríyá kan ní ọ̀sẹ̀ April 21 sí 27, 2008. “Bẹ̀rẹ̀ láti January 1, 2009, ọjọ́ kan náà tẹ́ ẹ̀ ń ṣe Ìpàdé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run àti Ìpàdé ìṣẹ́ Ìsìn lẹ ó máa ṣe Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ. Ṣùgbọ́n dípò Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ, orúkọ tá a ó máa lò báyìí ni Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ.”

2 Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀: Wákàtí kan àti ìṣẹ́jú márùndínláàádọ́ta la ó máa fi ṣe ìpàdé yìí pẹ̀lú orin àti àdúrà. A ó máa fi orin àti àdúrà tó jẹ́ ìṣẹ́jú márùn-ún bẹ̀rẹ̀, lẹ́yìn náà la ó wá ṣe Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ fún ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25 min.). Ìpàdé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run tó jẹ́ ọgbọ̀n ìṣẹ́jú (30 min.) á wá tẹ̀ lé e. Lẹ́yìn náà, a óò kọ orin ìṣẹ́jú márùn-un láti bẹ̀rẹ̀ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn tó máa jẹ́ ìṣẹ́jú márùnlélọ́gbọ̀n (35 min.). A óò sì fi orin àti àdúrà tó jẹ́ ìṣẹ́jú márùn-ún parí ìpàdé náà. Kó lè rọrùn fún wa láti máa múra àwọn ìpàdé yìí sílẹ̀, a ó máa tẹ ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìpàdé Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ, Ìpàdé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run àti Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn sínú Ìṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa lóṣooṣù.

3. Báwo la ó ṣe máa darí ìpàdé Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ?

3 Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: Ọ̀nà tá à ń gbà ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ la ó máa gbà ṣe ìpàdé yìí. Kò ní pọn dandan ká máa ṣàtúnyẹ̀wò ohun tá a kọ́ lọ́sẹ̀ tó ṣáájú. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ ṣókí la ó máa fi bẹ̀rẹ̀. Èyí á fún àwùjọ láǹfààní láti dáhùn ní ṣókí. Alága àwọn alábòójútó ni yóò máa bójú tó yíyan àwọn alàgbà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ táá máa darí ìpàdé yìí lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀.

4. Àyípadà wo ló máa bá Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn?

4 Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn: Kò sí àyípadà nínú bá a ó ṣe máa ṣe Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn, ó kàn jẹ́ pé a máa dín àkókò díẹ̀ kù nínú apá kọ̀ọ̀kan. Ìṣẹ́jú márùn-ún la ó máa fi ṣe ìfilọ̀. Àkókò yìí á tó láti fi ṣe àwọn ìfilọ̀ pàtàkì àti láti ka àwọn lẹ́tà láti ẹ̀ka ọ́fíísì. Àwọn ìfilọ̀ bí ètò fún iṣẹ́ ìwàásù, ìmọ́tótó, ìròyìn ìnáwó, àtàwọn lẹ́tà kan láti ẹ̀ka ọ́fíísì ni a kò ni máa ka láti orí pèpéle mọ́, ńṣe la ó máa lẹ̀ ẹ́ mọ́ ara pátákó ìsọfúnni káwọn ará lè lọ máa kà á níbẹ̀. Kí gbogbo àwọn tí wọ́n bá yan iṣẹ́ fún máa múra iṣẹ́ wọn sílẹ̀ dáadáa, kí wọ́n tẹ̀ lé ìtọ́ni tó ní í ṣe pẹ̀lú iṣẹ́ wọn, kí wọ́n má sì kọjá àkókò tí a yàn fún wọn.

5. Báwo la ó ṣe máa ṣe ìpàdé lọ́sẹ̀ ìbẹ̀wò alábòójútó àyíká?

5 Ìbẹ̀wò Alábòójútó Àyíká: Ko sí àyípadà kankan nínú ìgbòkègbodò tó máa ń wáyé lọ́sẹ̀ ìbẹ̀wò alábòójútó àyíká. A ó máa ṣe ìpàdé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run àti Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn lọ́jọ́ Tuesday, a ó sì kọ orin kan lẹ́yìn àwọn ìpàdé náà, alábòójútó àyíká á wá sọ àsọyé ọgbọ̀n ìṣẹ́jú. Bá a ti máa ń ṣe lọ́sẹ̀ ìbẹ̀wò báyìí, a ó ṣètò ọjọ́ mìíràn láàárín ọ̀sẹ̀ tí a ó ṣe Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ, lẹ́yìn náà a ó kọrin, alábòójútó àyíká á sì sọ ọ̀rọ̀ iṣẹ́ ìsìn kejì. A ó sì fi orin àti àdúrà parí ìpàdé náà.

6. Kí ni iṣẹ́ alábòójútó àwùjọ?

6 Ìpàdé fún Iṣẹ́ Ìsìn Pápá: Ìgbìmọ̀ Àwọn Alàgbà á yan àwọn alábòójútó àwùjọ láti máa bójú tó bí àwùjọ tó wà lábẹ́ àbójútó wọn á ṣe máa lọ sóde ẹ̀rí, tí wọ́n á sì máa ṣèbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn sọ́dọ̀ wọn. Tó bá jẹ́ pé ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ la fẹ́ lò nípò yìí, ohun tí a ó máa pè é ni “ìránṣẹ́ àwùjọ.”

7. Àwọn nǹkan wo la máa gbádùn látinú ọ̀nà tuntun tí a ó máa gbà ṣèpàdé?

7 Bá a ṣe là á lẹ́sẹẹsẹ nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa láǹfààní láti máa gbádùn àwọn oúnjẹ tẹ̀mí tó ń gbéni ró tí yóò sì jẹ́ kí àjọṣe àwa àti Jèhófà dára sí i. Èyí á jẹ́ ká já fáfá sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù àti kíkọ́ni, a ó sì túbọ̀ máa gba ẹ̀kọ́ tó máa jẹ́ kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa máa méso jáde.—Éfé. 4:13, 14; 2 Tím. 3:17.

8. Báwo ni mímúra ìpàdé sílẹ̀ ṣe máa ṣe àwa àtàwọn ẹlòmíì láǹfààní?

8 Bá a bá ń múra àwọn ìpàdé yìí sílẹ̀, a ó lè máa pọkàn pọ̀ dáadáa sórí àwọn kókó pàtàkì tá à ń jíròrò ní ìpàdé kọ̀ọ̀kan. Gbogbo wa la máa láǹfààní láti máa dáhùn, tí a ó sì máa tipa bẹ́ẹ̀ fún ara wa níṣìírí. (Róòmù 1:11, 12; Héb. 10:24) Ohun tó yẹ kó jẹ́ àfojúsùn wa ni pé ká jẹ́ ‘kí ìlọsíwájú wa fara hàn kedere’ nípa fífi “ọwọ́ títọ̀nà mú ọ̀rọ̀ òtítọ́.”—1 Tím. 4:15; 2 Tím. 2:15.

9. Kí ló yẹ kó jẹ́ ìpinnu wa, kí sì nìdí?

9 Inú wa dùn gan-an fún àyípadà tó wáyé nínú ọ̀nà tá a ó máa gbà ṣe ìpàdé ìjọ yìí. Ẹ jẹ́ kí gbogbo wa pinnu pé a ó máa jàǹfààní àwọn ohun tí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” náà ń pèsè, ká sì sún mọ́ Olùṣọ́ Àgùntàn Ńlá náà bó ti ń múra wa sílẹ̀ de “ìpọ́njú” ńlá náà tó ti wọlé dé tán yìí.—Mát. 24:21, 45; Héb. 13:20, 21; Ìṣí. 7:14.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́