ORÍ 7
Àwọn Ìpàdé Tó Ń Fún “Wa Níṣìírí Láti Ní Ìfẹ́ àti Láti Ṣe Àwọn Iṣẹ́ Rere”
ỌJỌ́ pẹ́ táwọn èèyàn Jèhófà ti ní ètò láti máa pàdé pọ̀. Ní Ísírẹ́lì ìgbàanì, gbogbo àwọn ọkùnrin máa ń rìnrìn àjò lọ sí Jerúsálẹ́mù láti lọ ṣe àjọyọ̀ ńlá mẹ́ta. (Diu. 16:16) Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, àwọn Kristẹni máa ń péjọ déédéé, ó sì sábà máa ń jẹ́ nínú ilé ẹnì kan. (Fílém. 1, 2) Lóde òní, à ń gbádùn àwọn ìpàdé, àwọn àpéjọ àyíká àtàwọn àpéjọ agbègbè. Kí nìdí tí àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run fi máa ń péjọ? Ìdí àkọ́kọ́ ni pé ó jẹ́ apá pàtàkì nínú ìjọsìn wa.—Sm. 95:6; Kól. 3:16.
2 Àwọn ìpàdé wa tún máa ń ṣe àwọn tó ń wá síbẹ̀ láǹfààní. Bí àpẹẹrẹ, wo ohun tí Ọlọ́run sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nípa gbogbo Àjọyọ̀ Àtíbàbà keje, ó ní: “Ẹ kó àwọn èèyàn náà jọ, àwọn ọkùnrin, àwọn obìnrin, àwọn ọmọdé àti àwọn àjèjì yín tó ń gbé nínú àwọn ìlú yín, kí wọ́n lè fetí sílẹ̀, kí wọ́n sì kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà Ọlọ́run yín, kí wọ́n máa bẹ̀rù rẹ̀, kí wọ́n sì lè máa rí i dájú pé àwọn ń tẹ̀ lé gbogbo ọ̀rọ̀ Òfin yìí.” (Diu. 31:12) Ó ṣe kedere pé ìdí pàtàkì táwa èèyàn Ọlọ́run fi ń péjọ ni pé kí ‘Jèhófà lè kọ́’ wa. (Àìsá. 54:13) Àwọn ìpàdé tún máa ń jẹ́ ká lè mọ ara wa, ká fún ara wa níṣìírí, ká sì jọ fún ara wa lókun bá a ṣe ń kẹ́gbẹ́ pọ̀.
ÀWỌN ÌPÀDÉ ÌJỌ
3 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn tó pé jọ lẹ́yìn àjọyọ̀ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni tẹra mọ́ ẹ̀kọ́ àwọn àpọ́sítélì, “láti ọjọ́ dé ọjọ́, wọ́n ń pésẹ̀ déédéé sí tẹ́ńpìlì pẹ̀lú èrò tó ṣọ̀kan.” (Ìṣe 2:42, 46) Nígbà tó yá, tí àwọn Kristẹni bá péjọ láti jọ́sìn, wọ́n máa ń ka àwọn ìwé tí Ọlọ́run mí sí, títí kan àwọn lẹ́tà tí àwọn àpọ́sítélì àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn míì kọ. (1 Kọ́r. 1:1, 2; Kól. 4:16; 1 Tẹs. 1:1; Jém. 1:1) Wọ́n tún máa ń gbàdúrà pa pọ̀ nínú ìjọ. (Ìṣe 4:24-29; 20:36) Nígbà míì, wọ́n máa ń sọ ìrírí táwọn míṣọ́nnárì ní lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. (Ìṣe 11:5-18; 14:27, 28) Wọ́n máa ń jíròrò àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì, wọ́n sì máa ń jíròrò àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tó ṣẹ. Wọ́n máa ń gba ìtọ́ni lórí irú ìwà tó yẹ kí Kristẹni máa hù àti bó ṣe yẹ kí wọ́n máa sin Ọlọ́run. Wọ́n máa ń gba ara wọn níyànjú láti máa fi ìtara polongo ìhìn rere.—Róòmù 10:9, 10; 1 Kọ́r. 11:23-26; 15:58; Éfé. 5:1-33.
Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn tí nǹkan le koko yìí, a nílò ìṣírí tá à ń rí gbà bá a ṣe ń péjọ déédéé
4 Ọ̀nà tí àwọn àpọ́sítélì ń gbà ṣe ìpàdé ni àwa náà ń gbà ṣe àwọn ìpàdé lóde òní. À ń tẹ̀ lé ìyànjú tí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbà wá, èyí tó wà nínú Hébérù 10:24, 25, tó sọ pé: “Ẹ sì jẹ́ ká gba ti ara wa rò . . . , ká má ṣe máa kọ ìpàdé wa sílẹ̀, bí àṣà àwọn kan, àmọ́ ká máa gba ara wa níyànjú, ní pàtàkì jù lọ bí ẹ ṣe ń rí i pé ọjọ́ náà ń sún mọ́lé.” Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn tí àwọn nǹkan le koko yìí, a nílò àfikún ìṣírí ká lè túbọ̀ lókun nípa tẹ̀mí, kí ìgbàgbọ́ wa má sì yingin, ìdí nìyẹn tá a fi ń péjọ déédéé. (Róòmù 1:11, 12) Àárín àwọn èèyàn onímàgòmágó àti oníwà ìbàjẹ́ ni àwa Kristẹni ń gbé. A ti kọ àìṣèfẹ́ Ọlọ́run àti ìfẹ́ ayé yìí sílẹ̀. (Fílí. 2:15, 16; Títù 2:12-14) Ká sòótọ́, ibo là bá tún wà tó lè dáa ju àárín àwọn èèyàn Jèhófà lọ? (Sm. 84:10) Kí ló sì lè ṣe wá láǹfààní ju ká máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ká sì máa jíròrò rẹ̀? Jẹ́ ká jíròrò onírúurú ìpàdé tá a ti ṣètò fún àǹfààní wa.
ÌPÀDÉ ÒPIN Ọ̀SẸ̀
5 Gbogbo èèyàn ni àsọyé Bíbélì tó jẹ́ apá àkọ́kọ́ lára ìpàdé òpin ọ̀sẹ̀ wà fún, títí kan àwọn tó wá sípàdé wa fúngbà àkọ́kọ́. Àsọyé fún gbogbo èèyàn máa ń kó ipa pàtàkì nínú bí àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dara pọ̀ mọ́ wa àtàwọn ará ìjọ ṣe máa lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.—Ìṣe 18:4; 19:9, 10.
6 Kristi Jésù, àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn ṣe àwọn ìpàdé fún gbogbo èèyàn, irú èyí tá à ń ṣe lónìí nínú àwọn ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó dájú pé kò tíì sí alásọyé fún gbogbo èèyàn tó dà bíi Jésù láyé yìí. Wọ́n tiẹ̀ sọ nípa rẹ̀ pé: “Èèyàn kankan ò sọ̀rọ̀ báyìí rí.” (Jòh. 7:46) Jésù sọ̀rọ̀ lọ́nà tó fi hàn pé ó láṣẹ láti kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì ya gbogbo àwọn olùgbọ́ rẹ̀ lẹ́nu. (Mát. 7:28, 29) Àwọn tó fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ́kàn jàǹfààní tó pọ̀ gan-an. (Mát. 13:16, 17) Àwọn àpọ́sítélì tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀. Nínú Ìṣe 2:14-36, a kà nípa àsọyé tó wọni lọ́kàn tí Pétérù sọ nígbà àjọyọ̀ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni. Ọ̀rọ̀ tí ẹgbẹ̀rún mélòó kan tó wà níbẹ̀ gbọ́ mú kí wọ́n ṣàtúnṣe. Lẹ́yìn ìgbà yẹn, Pọ́ọ̀lù sọ àsọyé nílùú Áténì, àwọn kan lára àwọn tó gbọ́ àsọyé náà sì di onígbàgbọ́.—Ìṣe 17:22-34.
7 Bákan náà lónìí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn ti jàǹfààní látinú àwọn àsọyé fún gbogbo èèyàn tá a máa ń sọ láwọn ìjọ wa àtàwọn èyí tá a máa ń gbọ́ láwọn àpéjọ àyíká àti àpéjọ agbègbè. Irú àwọn àsọyé bẹ́ẹ̀ ń mú ká máa fi àwọn ẹ̀kọ́ Kristẹni sọ́kàn, ká sì máa bá iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run nìṣó. Tá a bá ń pe àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sọ́rọ̀ wa àti gbogbo èèyàn wá sí àwọn ìpàdé yìí, á jẹ́ ká lè túbọ̀ ràn wọ́n lọ́wọ́ láti lóye àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì.
8 Ohun tọ́rọ̀ dá lé nínú àwọn àsọyé fún gbogbo èèyàn máa ń yàtọ̀ síra. Ó lè jẹ́ ẹ̀kọ́ Bíbélì àtàwọn àsọtẹ́lẹ̀, ó sì lè jẹ́ àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ àti ìmọ̀ràn lórí ọ̀rọ̀ ìdílé, ọ̀rọ̀ ìgbéyàwó, ìṣòro àwọn ọ̀dọ́ tàbí àwọn ìwà tó yẹ Kristẹni. Àwọn àsọyé kan dá lórí àwọn ohun àgbàyanu tí Jèhófà dá. Àwọn míì dá lórí àwọn ẹ̀kọ́ tá a rí kọ́ lára àwọn èèyàn tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa wọn, tí wọ́n ní ìgbàgbọ́, ìgboyà àti ìwà títọ́.
9 Ká lè jàǹfààní dáadáa nínú àwọn àsọyé fún gbogbo èèyàn, ó ṣe pàtàkì pé ká máa fetí sílẹ̀ dáadáa, ká máa ṣí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí olùbánisọ̀rọ̀ bá tọ́ka sí, ká sì máa fojú bá a lọ bó ṣe ń kà á, tó sì ń ṣàlàyé rẹ̀. (Lúùkù 8:18) Bá a ṣe ń lóye àwọn nǹkan tí olùbánisọ̀rọ̀ ń jíròrò, àá lè pinnu pé a máa di ẹ̀kọ́ tá a rí kọ́ mú, a ó sì máa fi í sílò.—1 Tẹs. 5:21.
10 Tí àwọn tó lè sọ àsọyé bá wà, ó dájú pé ìjọ á lè máa gbọ́ àsọyé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Lọ́pọ̀ ìgbà a máa ń pe àwọn olùbánisọ̀rọ̀ láti àwọn ìjọ tó wà nítòsí. Tí àwọn tó lè sọ àsọyé kò bá pọ̀ tó, ìjọ á ṣètò bí wọ́n á ṣe máa gbọ́ àsọyé láwọn ìgbà tó bá ṣeé ṣe.
11 Apá kejì nínú ìpàdé òpin ọ̀sẹ̀ ni Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́. Ibẹ̀ la ti máa ń jíròrò àwọn àpilẹ̀kọ tó wà nínú ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ tó wà fún ìkẹ́kọ̀ọ́, a sì máa ń ṣe é lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn. Jèhófà máa ń lo Ilé Ìṣọ́ láti pèsè oúnjẹ tẹ̀mí tó bọ́ sí àkókò fún wa.
12 Àwọn àpilẹ̀kọ náà sábà máa ń sọ nípa bá a ṣe lè máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì nínú ìgbésí ayé wa, wọ́n máa ń fún wa lókun láti sá fún “ẹ̀mí ayé” àti ìwà àìmọ́. (1 Kọ́r. 2:12) Àwọn àpilẹ̀kọ inú Ilé Ìṣọ́ ń mú kí àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì àtàwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì túbọ̀ yéni kedere, nípa bẹ́ẹ̀, gbogbo wa túbọ̀ ń lóye òtítọ́, a sì ń rìn ní ọ̀nà àwọn olódodo. (Sm. 97:11; Òwe 4:18) Tá a bá ń lọ sí ìpàdé Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ tá a sì ń kópa nínú rẹ̀, inú wa á máa dùn bá a ṣe ń retí ayé tuntun òdodo ti Jèhófà. (Róòmù 12:12; 2 Pét. 3:13) Bí àwa Kristẹni ṣe ń péjọ yìí ń ràn wá lọ́wọ́ láti máa ní èso tẹ̀mí ó sì ń mú ká túbọ̀ máa fi ìtara sin Jèhófà. (Gál. 5:22, 23) À ń fún wa lókun láti fara da àdánwò ká sì lè ní “ìpìlẹ̀ tó dáa fún ọjọ́ iwájú,” ká lè “di ìyè tòótọ́ mú gírígírí.”—1 Tím. 6:19; 1 Pét. 1:6, 7.
13 Kí la lè ṣe ká lè túbọ̀ máa jàǹfààní nínú oúnjẹ tẹ̀mí yìí? A gbọ́dọ̀ máa múra ẹ̀kọ́ náà sílẹ̀, ó lè jẹ́ láwa nìkan tàbí ká jọ múra ẹ̀ nínú ìdílé, kí a ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a tọ́ka sí, ká sì máa dáhùn ní ọ̀rọ̀ ara wa. Èyí á mú kí òtítọ́ jinlẹ̀ lọ́kàn wa, àwọn míì sì máa jàǹfààní bí wọ́n ṣe ń gbọ́ tá à ń sọ ohun tá a gbà gbọ́. Tá a bá ń fara balẹ̀ tẹ́tí sí ìdáhùn àwọn míì, àá máa jàǹfààní látinú ẹ̀kọ́ náà lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀.
ÌPÀDÉ ÀÁRÍN Ọ̀SẸ̀
14 Ìjọ tún máa ń pàdé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ ní Gbọ̀ngàn Ìjọba láti ṣe ìpàdé tá à ń pè ní Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni. Apá mẹ́ta ni ìpàdé yìí pín sí, a sì ṣètò rẹ̀ káwa ìranṣẹ́ Ọlọ́run lè “kúnjú ìwọ̀n.” (2 Kọ́r. 3:5, 6) Ìtòlẹ́sẹẹsẹ àtàwọn ohun tá a máa ṣe lóṣooṣù máa ń wà nínú ìwé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni—Ìwé Ìpàdé. Àwọn ọ̀nà tá a lè gbà bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù tún wà nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́.
15 Apá àkọ́kọ́ lára ìpàdé náà ni Àwọn Ìṣúra Inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, èyí tó máa jẹ́ ká túbọ̀ lóye kúlẹ̀kúlẹ̀ àwọn ìtàn inú Bíbélì àtàwọn ìsọfúnni tó jẹ mọ́ ọn, títí kan bá a ṣe lè fi àwọn ẹ̀kọ́ inú ìtàn náà sílò. Lára ohun tá a máa ń gbádùn nínú apá àkọ́kọ́ yìí ni àsọyé kan, Bíbélì kíkà àti ìjíròrò lórí Bíbélì tá a bá kà lọ́sẹ̀ yẹn. Àwọn àwòrán àtàwọn ibi téèyàn lè kọ nǹkan sí nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ máa ń jẹ́ ká túbọ̀ lóye àwọn ìtàn náà. Bá a ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ nínú Bíbélì lọ́nà yìí, á mú kí ayé wa dára sí i, á jẹ́ ká di olùkọ́ tó dángájíá, tó “kúnjú ìwọ̀n dáadáa,” tó sì “gbára dì pátápátá fún gbogbo iṣẹ́ rere.”—2 Tím. 3:16, 17.
16 Apá kejì ìpàdé náà la pè ní, Máa Lo Ara Rẹ Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìwàásù, èyí tá a ṣètò kí gbogbo wa lè máa ṣe ìdánrawò, ká lè túbọ̀ dáńgájíá lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù àti kíkọ́ni. Yàtọ̀ sí iṣẹ́ táwọn akẹ́kọ̀ọ́ máa ń ṣe, a tún máa ń wo àwọn fídíò nípa bá a ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò. Apá kejì yìí máa ń jẹ́ ká ní “ahọ́n àwọn tí a kọ́” ká lè ‘mọ bó ṣe yẹ ká fi ọ̀rọ̀ tó yẹ dá ẹni tó ti rẹ̀ lóhùn.’—Àìsá. 50:4.
17 Apá kẹta ìpàdé náà ni, Máa Hùwà Tó Yẹ Kristẹni. Ibẹ̀ la ti máa ń jíròrò bá a ṣe lè fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò nígbèésí ayé wa. (Sm. 119:105) Ọ̀kan pàtàkì lára ohun tá a máa ń gbádùn nínú apá yìí ni Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ. Bíi ti Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́, Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ náà jẹ́ ìjíròrò lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.
18 Lóṣooṣù, tá a bá ti gba Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́, olùṣekòkáárí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà tàbí alàgbà tó ń ràn án lọ́wọ́ máa fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò rẹ̀, á sì ṣe ìtòlẹ́sẹẹsẹ àwọn tó máa níṣẹ́. Lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, alàgbà tó mọ bá a ṣe ń kọ́ni dáadáa tí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà fọwọ́ sí máa ṣe alága ìpàdé náà. Alága yìí á rí i dájú pé ìpàdé bẹ̀rẹ̀ ó sì parí lásìkò, òun ló máa gbóríyìn fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́, á sì fún wọn nímọ̀ràn.
19 Tá a bá ń múra Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ sílẹ̀, tá à ń lọ sípàdé déédéé, tá a sì ń kópa níbẹ̀, àá máa lóye Ìwé Mímọ́, àá dojúlùmọ̀ àwọn ìlànà Bíbélì, àá túbọ̀ nígboyà láti wàásù ìhìn rere, àá sì túbọ̀ já fáfá bá a ti ń sọ àwọn èèyàn di ọmọlẹ́yìn Jésù. Àwọn tí wọn ò tíì ṣèrìbọmi náà máa ń gbádùn bí wọ́n ṣe ń dara pọ̀ mọ́ àwọn ará, wọ́n sì máa ń jàǹfààní látinú àwọn ọ̀rọ̀ tó ń gbéni ró tá a máa ń jíròrò nípàdé. Tá a bá fẹ́ múra ìpàdé yìí àtàwọn ìpàdé míì sílẹ̀, a lè lo àkójọ ìwé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ìyẹn Watchtower Library tàbí JW Library®. A tún lè lo Àká Ìwé Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìyẹn Watchtower ONLINE LIBRARY™ (tó bá wà ní èdè wa) àti àwọn ìwé tó wà níbi ìkówèésí nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba. Ohun tó máa ń wà ní ibi ìkówèésí ní Gbọ̀ngàn Ìjọba ni àwọn ìwé tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe jáde, ìwé atọ́ka Watch Tower Publications Index, Ìwé Ìwádìí fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti oríṣiríṣi Bíbélì, ìwé atọ́ka àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì, ìwé atúmọ̀ èdè àtàwọn ìwé ìwádìí míì tó wúlò. Ẹnikẹ́ni ló lè lo èyíkéyìí nínú àwọn ìwé yìí ní Gbọ̀ngàn Ìjọba ṣáájú ìpàdé tàbí lẹ́yìn ìpàdé.
ÌPÀDÉ IṢẸ́ ÌSÌN PÁPÁ
20 Láwọn àkókò tó yàtọ̀ síra láàárín ọ̀sẹ̀ àti ní ìparí ọ̀sẹ̀, àwọn akéde máa ń ṣe ìpàdé ráńpẹ́ kí wọ́n tó lọ sóde ẹ̀rí. A máa ń ṣe ìpàdé yìí nínú ilé àdáni tàbí ní àwọn ibòmíì tó bá rọrùn. A sì tún lè ṣe ìpàdé náà ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Tí àwùjọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ bá ń pàdé láwọn ibi tó yàtọ̀ síra ní ìpínlẹ̀ ìwàásù, á mú kó rọrùn fún àwọn akéde láti lọ sí ìpàdé iṣẹ́ ìsìn pápá àti ìpínlẹ̀ ìwàásù. Á jẹ́ ká lè tètè pín àwọn ará, kí wọ́n sì lọ sí ìpínlẹ̀ ìwàásù láìjáfara. Á tún mú kó rọrùn fún alábòójútó àwùjọ láti bójú tó àwọn tó wà ní àwùjọ rẹ̀ dáadáa. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àǹfààní wà nínú kí àwọn àwùjọ máa pàdé lọ́tọ̀ọ̀tọ̀, ìgbà míì wà tó máa ń gba pé kí àwùjọ mélòó kan pàdé pọ̀. Bí àpẹẹrẹ, táwọn akéde tó máa ń lọ sóde ẹ̀rí láàárín ọ̀sẹ̀ kò bá fi bẹ́ẹ̀ pọ̀, á dára kí gbogbo àwọn ará pàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí ní ibòmíì tó bójú mu. Èyí á jẹ́ káwọn akéde rẹ́ni bá ṣiṣẹ́. Ìjọ tún lè rí i pé ó rọrùn láti máa pàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba láwọn àsìkò ọlidé. Wọ́n sì lè jọ ṣe ìpàdé iṣẹ́ ìsìn pápá lẹ́yìn Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́.
21 Tí àwọn àwùjọ bá pàdé lọ́tọ̀ọ̀tọ̀, alábòójútó àwùjọ ló máa múpò iwájú láti darí ìpàdé iṣẹ́ ìsìn pápá. Látìgbàdégbà, alábòójútó àwùjọ lè ní kí olùrànlọ́wọ́ òun tàbí arákùnrin míì tó kúnjú ìwọ̀n darí ìpàdé náà. Kí olùdarí múra sílẹ̀ láti jíròrò ohun kan tó máa ran àwọn ará lọ́wọ́ tó sì máa wúlò nínú iṣẹ́ ìwàásù. Lẹ́yìn náà, á pín àwọn ará, á sì sọ ibi tí wọ́n ti máa ṣiṣẹ́, ẹnì kan láàárín àwùjọ náà sì máa gbàdúrà. Lẹ́yìn ìyẹn, àwùjọ náà á lọ sí òde ẹ̀rí láìjáfara. Ìpàdé yìí kì í gùn ju ìṣẹ́jú márùn-ún sí méje lọ, àmọ́ kò yẹ kó pẹ́ tó bẹ́ẹ̀ tó bá wáyé lẹ́yìn ìpàdé ìjọ. Ká fi ìpàdé náà fún àwọn tó ń lọ wàásù ní ìṣírí, ìtọ́sọ́nà àtàwọn ìsọfúnni míì tó wúlò. Kí àwọn ẹni tuntun tàbí àwọn tó nílò ìrànlọ́wọ́ bá àwọn akéde tó ní ìrírí ṣiṣẹ́ kí wọ́n lè gba ìdálẹ́kọ̀ọ́.
BÍ A ṢE Ń ṢE ÌPÀDÉ NÍ ÀWỌN ÌJỌ TUNTUN TÀBÍ ÌJỌ KÉKERÉ
22 Bí àwọn tó ń di ọmọ ẹ̀yìn ṣe ń pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ ni iye àwọn ìjọ ń pọ̀ sí i. Tá a bá fẹ́ dá ìjọ tuntun sílẹ̀, alábòójútó àyíká ló sábà máa ń fi ìwé ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì. Àmọ́ láwọn ìgbà míì, àwọn àwùjọ tó kéré máa ń rí i pé ó sàn kí àwọn máa bá ìjọ tó sún mọ́ wọn jù lọ ṣèpàdé.
23 Nígbà míì, kìkì àwọn arábìnrin ló máa ń wà ní àwọn ìjọ kékeré. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, arábìnrin tó bá máa gbàdúrà nínú ìjọ tàbí tó bá máa darí àwọn ìpàdé gbọ́dọ̀ bo orí rẹ̀, bí Ìwé Mímọ́ ṣe sọ. (1 Kọ́r. 11:3-16) Lọ́pọ̀ ìgbà, ó máa wà ní ìjókòó, á sì kọjú sí àwùjọ. Àwọn arábìnrin kì í sọ àsọyé láwọn ìpàdé. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n á ka ìsọfúnni tó wá láti ọ̀dọ̀ ètò Ọlọ́run, wọ́n á sì ṣàlàyé rẹ̀, tàbí kí wọ́n ṣe é lọ́nà míì, bí àpẹẹrẹ, wọ́n lè jíròrò rẹ̀ láàárín ara wọn tàbí kí wọ́n ṣe àṣefihàn rẹ̀. Ẹ̀ka ọ́fíìsì máa yan ọ̀kan lára àwọn arábìnrin náà láti máa gba lẹ́tà tó wá láti ẹ̀ka ọ́fíìsì, kó sì máa fi ti ìjọ ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì, òun náà lá sì máa bójú tó àwọn ìpàdé. Nígbà tó bá yá, tí àwọn arákùnrin bá kúnjú ìwọ̀n, àwọn lá wá máa bójú tó àwọn iṣẹ́ náà.
ÀWỌN ÀPÉJỌ ÀYÍKÁ
24 Lọ́dọọdún, a máa ń ṣètò pé kí àwọn ìjọ tó wà ní àyíká kan náà péjọ fún àpéjọ àyíká ọlọ́jọ́ kan, èyí sì máa ń wáyé lẹ́ẹ̀mejì lọ́dún. Àwọn àkókò aláyọ̀ yìí máa ń fún gbogbo àwọn tó péjọ ní àǹfààní láti “ṣí ọkàn [wọn] sílẹ̀ pátápátá,” kí wọ́n lè túbọ̀ sún mọ́ àwọn ará. (2 Kọ́r. 6:11-13) Ètò Jèhófà máa ń fi ohun táwọn ará nílò sọ́kàn tí wọ́n bá fẹ́ yan àkòrí tó bá Ìwé Mímọ́ mu, tí wọ́n sì ń ṣètò àwọn apá míì ní àpéjọ náà. Ó lè jẹ́ àsọyé, àṣefihàn, ṣíṣe àṣefihàn ìrírí tí ẹnì kan ní, ìdánìkansọ̀rọ̀ tàbí ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò. Àwọn ìtọ́ni tó bọ́ sí àkókò yẹn máa ń ṣe gbogbo àwọn tó bá wá sí àpéjọ náà láǹfààní. Ní àwọn àpéjọ yìí, àwọn ọmọ ẹ̀yìn tuntun máa ń ṣèrìbọmi láti fi hàn pé wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà.
ÀWỌN ÀPÉJỌ AGBÈGBÈ
25 Ní ẹ̀ẹ̀kan lọ́dún, a máa ń ṣe àwọn àpéjọ ńlá. Ó sábà máa ń jẹ́ àpéjọ agbègbè ọlọ́jọ́ mẹ́ta, àwọn ìjọ láti àwọn àyíká mélòó kan ló sì máa ń wà níbẹ̀. Àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì tó kéré lè rí i pé ó máa dáa kí gbogbo ìjọ tó wà lábẹ́ àbójútó wọn kóra jọ síbì kan náà láti ṣe àpéjọ yìí. Àmọ́, ní àwọn ilẹ̀ kan, bí wọ́n ṣe máa ń ṣètò àwọn àpéjọ yìí yàtọ̀ nítorí bí nǹkan ṣe rí níbẹ̀ tàbí nítorí ìtọ́ni tí ètò Ọlọ́run fún wọn. Látìgbàdégbà, a tún máa ń ṣe àpéjọ àgbáyé tàbí àkànṣe àpéjọ láwọn orílẹ̀-èdè kan, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti àwọn orílẹ̀-èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ sì máa ń wá síbẹ̀. Láti ọ̀pọ̀ ọdún wá, ọ̀pọ̀ èèyàn ti ń gbọ́ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run torí bí a ṣe ń polongo àwọn àpéjọ ńlá táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe yìí.
26 Àkókò aláyọ̀ láti jọ́sìn pa pọ̀ làwọn àpéjọ yìí máa ń jẹ́ fún àwọn tó ti ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà. Láwọn àpéjọ yìí, wọ́n máa ń jẹ́ ká túbọ̀ lóye àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́. Ní àwọn àpéjọ kan, wọ́n máa ń mú àwọn ìwé tuntun jáde èyí tá a lè fi ṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́, tá a sì lè lò nínú ìjọ tàbí nínú iṣẹ́ ìwàásù. Àwọn èèyàn máa ń ṣèrìbọmi láwọn àpéjọ náà. Àwọn àpéjọ tún ṣe pàtàkì gan-an nítorí pé wọ́n ń jẹ́ ká lè tẹ̀ síwájú nínú ìjọsìn Ọlọ́run. Wọ́n ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé ẹgbẹ́ ará kárí ayé làwa èèyàn Jèhófà, pé a ti ya ara wa sí mímọ́ àti pé ọmọ ẹ̀yìn Jésù Kristi ni wá.—Jòh. 13:35.
27 Tá a bá ń lọ sí àwọn ìpàdé ìjọ, àpéjọ àyíká àti àpéjọ agbègbè, àá túbọ̀ máa ṣe ìfẹ́ Jèhófà. Ó tún máa dáàbò bò wá lọ́wọ́ àwọn ohun búburú tó kúnnú ayé yìí tó lè ba ìgbàgbọ́ wa jẹ́. Àwọn àpéjọ yìí máa ń mú ògo àti ìyìn bá Jèhófà. (Sm. 35:18; Òwe 14:28) A dúpẹ́ pé Jèhófà ti ṣètò àwọn àpéjọ yìí kí àwa èèyàn rẹ̀ tá a ti ya ara wa sí mímọ́ fún un lè máa rí ìtura tẹ̀mí gbà ní àkókò òpin yìí.
OÚNJẸ ALẸ́ OLÚWA
28 Ní ẹ̀ẹ̀kan lọ́dún, ní àyájọ́ ikú Jésù Kristi, gbogbo ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà jákèjádò ayé máa ń ṣe Ìrántí Ikú Kristi tá a tún ń pè ní Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa. (1 Kọ́r. 11:20, 23, 24) Ìpàdé yìí làwa èèyàn Jèhófà kà sí pàtàkì jù lọ lọ́dún. Jésù dìídì pa á láṣẹ fún wa pé ká máa ṣe Ìrántí Ikú òun.—Lúùkù 22:19.
29 Ọjọ́ kan náà tí wọ́n máa ń ṣe Ìrékọjá tí Bíbélì sọ ni Ìrántí Ikú Kristi bọ́ sí, Ìwé Mímọ́ sì fi hàn bẹ́ẹ̀. (Ẹ́kís. 12:2, 6; Mát. 26:17, 20, 26) Ìrékọjá ni àjọyọ̀ ọdọọdún tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń ṣe láti fi rántí Ìjádelọ wọn kúrò ní Íjíbítì lọ́dún 1513 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Nígbà yẹn, Jèhófà yan ọjọ́ kẹrìnlá oṣù àkọ́kọ́ tí wọ́n máa ń fi òṣùpá kà, ó ní kí wọ́n fi ọjọ́ yẹn jẹ ọ̀dọ́ àgùntàn Ìrékọjá, kí wọ́n sì kúrò lóko ẹrú ní Íjíbítì. (Ẹ́kís. 12:1-51) Bí wọ́n ṣe ń mọ ọjọ́ náà ni pé wọ́n á ka ọjọ́ mẹ́tàlá (13) lẹ́yìn ọjọ́ tí wọ́n bá kọ́kọ́ kíyè sí i ní Jerúsálẹ́mù pé ọ̀sán àti òru gùn dọ́gba nígbà ìrúwé. Ìgbà tá a máa ń ṣe Ìrántí Ikú Kristi sábà máa ń bọ́ sí ọjọ́ tí òṣùpá dégbá tó sì ran àrànmọ́jú lẹ́yìn ọjọ́ tí ọ̀sán àti òru gùn dọ́gba nígbà ìrúwé.
30 Nínú Mátíù 26:26-28 Jésù sọ bó ṣe fẹ́ ká máa ṣe Ìrántí Ikú òun. Kì í ṣe ààtò ìjọsìn tó ní àwọn ohun àdììtú nínú, kàkà bẹ́ẹ̀, ohun ìṣàpẹẹrẹ ni oúnjẹ náà, àwọn tí a ti pè láti jẹ́ ajogún pẹ̀lú Jésù Kristi nínú Ìjọba rẹ̀ lọ́run ló sì máa ń jẹ ẹ́. (Lúùkù 22:28-30) A máa ń rọ gbogbo àwọn Kristẹni yòókù tó ti yara wọn sí mímọ́ àti àwọn olùfìfẹ́hàn pé kí wọ́n wá síbi Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa láti wá wo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ níbẹ̀. Bí wọ́n ṣe ń wá síbẹ̀, wọ́n ń fi hàn pé àwọn mọrírì ohun tí Jèhófà Ọlọ́run ṣe fún àǹfààní aráyé nípasẹ̀ Jésù Kristi Ọmọ rẹ̀. Ṣáájú Ìrántí Ikú Kristi, a máa ń sọ àkànṣe àsọyé fún gbogbo èèyàn láti mú káwọn èèyàn máa fojú sọ́nà fún ìpàdé yìí, kí wọ́n sì túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ sí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
31 Inú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń dùn gan-an bá a ṣe ń fojú sọ́nà fún àwọn ìpàdé wa, torí ibẹ̀ la ti ń “gba ti ara wa rò ká lè máa fún ara wa níṣìírí láti ní ìfẹ́ àti láti ṣe àwọn iṣẹ́ rere.” (Héb. 10:24) Ẹrú olóòótọ́ àti olóye máa ń rí i dájú pé ohun tá a nílò nínú ìjọsìn wa làwọn ìpàdé wa dá lé. Gbogbo àwa ìránṣẹ́ Jèhófà pátá títí kan àwọn olùfìfẹ́hàn la rọ̀ pé ká máa pésẹ̀ déédéé sí gbogbo àwọn ìpàdé wa, ká lè máa jàǹfààní wọn lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́. Tí àwa ìránṣẹ́ Jèhófà bá ń fi hàn pé a mọrírì àwọn ohun tí Jèhófà ń pèsè fún wa nípasẹ̀ ètò rẹ̀, àá túbọ̀ wà níṣọ̀kan. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, àá máa yin Jèhófà, àá sì máa fi ògo fún un.—Sm. 111:1.