Bá A Ṣe Lè Jàǹfààní Tó Kún Rẹ́rẹ́ Nínú Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Pápá
1. Ọ̀nà wo ni ìpàdé iṣẹ́ ìsìn pápá lè gbà ràn wá lọ́wọ́?
1 Tá a bá ṣe ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá bó ṣe yẹ ká ṣe é ká tó lọ sóde ẹ̀rí, ó máa fún wa ní ìṣírí tá a nílò, a sì máa rí ìtọ́ni tó máa wúlò gbà. Ó máa ń jẹ́ ká lè kópa nínú ìjẹ́rìí àjẹ́pọ̀ kó bàa lè jẹ́ pé báwa àtàwọn ẹlòmíì ṣe ń ṣiṣẹ́ pọ̀, a ò fún ara wa ní ìtìlẹ́yìn a ó sì lè kẹ́kọ̀ọ́ lára ẹnì kìíní kejì. (Òwe 27:17; Oníw. 4:9, 10) Kí la lè ṣe ká lè jàǹfààní tó kún rẹ́rẹ́ látinú àwọn ìpàdé yìí?
2. Àwọn nǹkan wo ni ẹni tó ń darí ìpàdé náà lè jíròrò?
2 Olùdarí: Kì í sí ìtòlẹ́sẹẹsẹ pàtó fáwọn kókó tá a máa jíròrò ní ìpàdé iṣẹ́ ìsìn pápá. Nítorí náà, o gba pé kó o múra sílẹ̀ dáadáa bó bá jẹ́ pé ìwọ lo máa darí ìpàdé náà. Kì í kàn-án ṣe pé kó o ṣá ti gbà pé wàá jíròrò ẹsẹ ìwé ojoojúmọ́ ọjọ́ kan, bó tilẹ̀ jẹ́ pé o lè mú un wọnú ìjíròrò náà bó bá tan mọ́ iṣẹ́ ìwàásù. Ṣe ni kó o ronú lórí ohun tó máa wúlò fáwọn tó ń lọ sóde ẹ̀rí lọ́jọ́ náà. Bí àpẹẹrẹ, o lè jíròrò ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ kan tàbí kó o fi ṣe àṣefihàn. O lè pinnu láti jíròrò kókó kan látinú ìwé Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Awọn Ìjíròrò Bibeli Kí A Sì Máa Báa Nìṣó, ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run tàbí apá kan nínú Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn tí ò tíì pẹ́ tẹ́ ẹ jíròrò rẹ̀. Láwọn ìgbà mìíràn, o lè jíròrò bẹ́ ẹ ṣe lè kojú ìṣòro tó ṣeé ṣe kó jẹ yọ ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín, tàbí kó o jíròrò bá a ṣe lè mú káwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wa àti bá a ṣe lè bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pàápàá bó bá jẹ́ pé èyí tó pọ̀ lára àwọn tó ń lọ sóde ẹ̀rí ló máa lọ ṣe ìpadàbẹ̀wò. Ohun yòówù kó o jíròrò, fi ìtara sọ̀rọ̀ kó o sì fún àwọn ará níṣìírí.
3. Báwo lo ṣe yẹ kí ìpàdé náà pẹ́ tó, àwọn nǹkan wo la gbọ́dọ̀ rí i pé a ṣe láàárín àkókò tá a fi ṣèpàdé náà?
3 Bẹ̀rẹ̀ ìpàdé náà lákòókò kódà bó o bá mọ̀ pé àwọn ará kan máa pẹ́ lẹ́yìn. Lo ìfòyemọ̀ nígbà tó o bá ń pín àwọn ará kó o sì fún àwọn tó bá nílò ibi tí wọ́n ti máa ṣiṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ ìwàásù. Kí ìpàdé náà má ṣe gùn ju ìṣẹ́jú mẹ́wàá sí mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lọ, tó bá sì jẹ́ pé lẹ́yìn ìpàdé ìjọ lẹ ṣe é, kó má ṣe gùn tó bẹ́ẹ̀. Kí gbogbo àwọn tó pésẹ̀ ti mọ ibi tí wọ́n ti máa ṣiṣẹ́ àtẹni tí wọ́n máa bá ṣiṣẹ́ kó o tó parí ìpàdé náà. Kó o wá fi àdúrà parí ìpàdé náà.
4. Kí ni yóò máa ran gbogbo wa lọ́wọ́ láti jàǹfààní tó kún rẹ́rẹ́ nínú ìpàdé iṣẹ́ ìsìn pápá?
4 Ẹ̀yin Náà Lè Ṣèrànwọ́: Bá a ṣe máa ń ṣe láwọn ìpàdé ìjọ, a tètè máa ń dé torí pé a bọ̀wọ̀ fún Jèhófà, a sì ń gba tàwọn ẹlòmíràn rò. Lóhùn sí ìjíròrò náà. O lè jẹ́ kí olùdarí yan ẹni tó o máa bá ṣiṣẹ́ fún ẹ, o sì ti lè ṣètò láti bá ẹnì kan ṣiṣẹ́ fúnra ẹ ṣáájú ìgbà tí ìpàdé náà á bẹ̀rẹ̀. Bó bá wù ẹ́, o lè bá ẹni tó o máa bá ṣiṣẹ́ ṣàdéhùn, ṣáà rí i pé o “gbòòrò síwájú” nípa bíbá akéde ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ṣiṣẹ́ dípò kó o máa bá àwọn ọ̀rẹ́ ẹ tẹ́ ẹ jọ mọwọ́ ara yín ṣiṣẹ́ ní gbogbo ìgbà. (2 Kọ́r. 6:11-13) Bí ìpàdé náà bá ti parí, má ṣe yí ìṣètò tí wọ́n ṣe nínú ìpàdé náà padà, kàkà bẹ́ẹ̀ ṣe ni kó o forí lé ìpínlẹ̀ tẹ́ ẹ ti máa wàásù láìjáfara.
5. Kí ni ìpàdé iṣẹ́ ìsìn pápá wà fún?
5 Ohun kan náà ni ìpàdé iṣẹ́ ìsìn pápá àtàwọn ìpàdé ìjọ yòókù náà wà fún. A ṣètò wọn ká bàa lè máa “gba ti ara wa rò lẹ́nì kìíní-kejì láti ru ara wa sókè sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà.” (Héb. 10:24, 25) Bá a bá sapá láti lè jàǹfààní látinú àwọn ìpàdé yìí, ó máa ràn wá lọ́wọ́ láti lè máa ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, èyí tó jẹ́ ‘iṣẹ́ àtàtà’ ní ti gidi!