Àpótí Ìbéèrè
◼ Ta ló yẹ kó máa pe orin tá a fi ń bẹ̀rẹ̀ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn, Ìpàdé fún Gbogbo Ènìyàn àti Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́?
A máa ń tẹ nọ́ńbà orin tá a máa fi bẹ̀rẹ̀ gbogbo ìpàdé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run jálẹ̀ ọdún sínú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti oṣù October. A sì máa ń to nọ́ńbà orin tá a máa ń fi bẹ̀rẹ̀ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ àtèyí tá a máa ń fi parí rẹ̀ sójú ìwé 2 nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Bákan náà, a máa ń tẹ nọ́ńbà orin tá a máa fi bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ sójú ìwé 2 ti ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ tá a máa kẹ́kọ̀ọ́ lọ́sẹ̀ kọ̀ọ̀kan. Apá pàtàkì làwọn orin tá à ń kọ jẹ́ nínú àwọn ìpàdé wa, ìyẹn ló fi jẹ́ pé arákùnrin tó máa darí ìpàdé náà ló gbọ́dọ̀ pe orin yẹn kì í ṣe alága ìpàdé àkọ́kọ́.
Bí àpẹẹrẹ, bí alábòójútó Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run bá ti kí àwùjọ káàbọ̀, kó pe orin ìbẹ̀rẹ̀, kó darí ilé ẹ̀kọ́ náà, kó sì pe olùbánisọ̀rọ̀ àkọ́kọ́ nínú Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn sórí pèpéle. Arákùnrin tó bá máa ṣí Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn ló gbọ́dọ̀ pe orin ìbẹ̀rẹ̀ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn.
Bákan náà, alága Ìpàdé fún Gbogbo Ènìyàn ló máa ṣí ìpàdé kí àsọyé tó bẹ̀rẹ̀. Kó fi tọ̀yàyàtọ̀yàyà kí gbogbo àwọn tó wà níkàlẹ̀ káàbọ̀ kó tó ké sí wọn láti jùmọ̀ kọ orin ìbẹ̀rẹ̀ tí alásọyé yàn láti lò. Òun, ìyẹn alága (tàbí arákùnrin mìíràn tó bá tóótun tó ti sọ fún ṣáájú) ni kó fi àdúrà ṣí ìpàdé náà. Lẹ́yìn náà ni kó sọ àkòrí àsọyé, kó sì pe alásọyé sórí pèpéle. Bí àsọyé bá ti parí, kí alága sọ̀rọ̀ ìmọrírì ṣókí láti dúpẹ́ fún ìtọ́ni tá a rí gbà látinú àsọyé náà, ṣùgbọ́n kó má ṣe ṣàkópọ̀ àwọn kókó inú àsọyé náà. Kó sọ àkòrí àsọyé ọ̀sẹ̀ tó ń bọ̀, kó sì rọ àwùjọ láti wà lórí ìjókòó wọn láti gbádùn Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́. Bó bá ṣẹlẹ̀ pé ìjọ míì ni alásọyé náà ti wá, kò pọn dandan kí alága béèrè lọ́wọ́ àwùjọ bóyá wọ́n á fẹ́ láti fi ìkíni ránṣẹ́ sí ìjọ tó ti wá. Lẹ́yìn náà, kó pe arákùnrin tó máa darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ sórí pèpéle.
Olùdarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ ló máa pe orin tá a máa fi bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Kó darí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà níbàámu pẹ̀lú ìtọ́ni tá a ti tẹ̀ jáde, lẹ́yìn ìkẹ́kọ̀ọ́ náà ni kó pe orin ìparí. Alásọyé ni olùdarí Ikẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ sábà máa ń pè pé kó wá gbàdúrà ìparí.
Bá a bá ń tẹ̀ lé àwọn ìtọ́sọ́nà wọ̀nyí, á ràn wá lọ́wọ́ láti rí i pé àwọn ìpàdé ìjọ wa wà létòlétò.