Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ September 3
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ SEPTEMBER 3
Orin 6 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
bt orí 26 ìpínrọ̀ 1 sí 8 àti àpótí tó wà lójú ìwé 204 (30 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Ìsíkíẹ́lì 39-41 (10 min.)
No. 1: Ìsíkíẹ́lì 40:17-31 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Àwọn Ọ̀nà Wo Ni Ojú Wa Lè Gbà Ṣì Wá Lọ́nà?—Jẹ́n. 3:2-6 (5 min.)
No. 3: Aya Kò Gbọ́dọ̀ Gba Ọkọ Láyè Láti Ya Òun Kúrò Lọ́dọ̀ Ọlọ́run?—td 6B (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
10 min: Bá A Ṣe Lè Fèrò Wérò Pẹ̀lú Àwọn Tí À Ń Wàásù Fún—Apá 2. Ìjíròrò tá a gbé ka ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 253 ìpínrọ̀ 3 sí ìparí ojú ìwé 254. Ní ṣókí, ṣe àṣefihàn kókó kan tàbí méjì látinú àpilẹ̀kọ náà.
10 min: Ẹ Máa Fún Ara Yín Ní Ìṣírí Lẹ́nì Kìíní-Kejì. (Héb. 10:25) Ìjíròrò tá a gbé ka Ilé Ìṣọ́ August 15, 2008 ojú ìwé 20 àti 21, ìpínrọ̀ 15 sí 18.
10 min: Àwọn Àbá Tá A Lè Lò Láti Fi Ìwé Ìròyìn Lọni Lóṣù September. Ìjíròrò. Fi ààbọ̀ ìṣẹ́jú sí ìṣẹ́jú kan sọ ìdí táwọn èèyàn fi máa nífẹ̀ẹ́ sí àwọn ìwé ìròyìn wa ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín. Lẹ́yìn náà, lo àwọn àpilẹ̀kọ tó dá lórí àkòrí Ilé Ìṣọ́ September, ní kí àwọn ará sọ àwọn ìbéèrè tó lè mú kí àwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wọn, kí wọ́n sì sọ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n lè fi ti ọ̀rọ̀ wọn lẹ́yìn. Ohun kan náà ni kó o ṣe nípa àwọn àpilẹ̀kọ tó dá lórí àkòrí Jí! July–September 2012, tí àkókò bá ṣì wà, ẹ tún lè jíròrò àpilẹ̀kọ mìíràn nínú ọ̀kan lára ìwé ìròyìn méjèèjì. Ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè fi ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìwé ìròyìn náà lọni.
Orin 34 àti Àdúrà