Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé tá a máa lò ní August: Ẹ lo ọ̀kan lára àwọn ìwé pẹlẹbẹ olójú-ewé 32 wọ̀nyí: Tẹ́tí sí Ọlọ́run tàbí Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé, àti Ìwọ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run! kẹ́ ẹ́ sì gbìyànjú láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nígbà tẹ́ ẹ bá ń ṣe ìpadàbẹ̀wò, ẹ lè fún onílé ní ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni tàbí kẹ́ ẹ fún un ní ìwé pẹlẹbẹ èyíkéyìí tẹ́ ẹ bá rí i pé ó máa nífẹ̀ẹ́ sí. September àti October: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Nígbà tẹ́ ẹ bá ń ṣe ìpadàbẹ̀wò, ẹ lè fún onílé ní ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni tàbí kẹ́ ẹ fún un ní èyí tẹ́ ẹ bá rí i pé ó máa nífẹ̀ẹ́ sí nínú ìwé pẹlẹbẹ Tẹ́tí sí Ọlọ́run tàbí Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé, kẹ́ ẹ sì sapá láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú rẹ̀. November àti December: Ẹ lo àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú tẹ́ ẹ bá ní lọ́wọ́. Bí onílé bá nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wa, ẹ fi bá a ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì hàn án, kí ẹ lo ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni, Tẹ́tí sí Ọlọ́run tàbí Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé.
◼ Bẹ̀rẹ̀ láti oṣù September, àkòrí àsọyé fún gbogbo ènìyàn tí àwọn alábòójútó àyíká yóò máa sọ ni, “Bíbá Ọlọ́run Rìn Ń Ṣe Wá Láǹfààní Nísinsìnyí àti Títí Ayé.”
◼ Ẹ lè ṣe àyípadà sí ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn ti ọ̀sẹ̀ tó bá ṣáájú àpéjọ àgbègbè yín kẹ́ ẹ lè fi jíròrò àwọn ìmọ̀ràn àtàwọn ìránnilétí fún àpéjọ àgbègbè. Tó bá wá di oṣù kan tàbí méjì lẹ́yìn àpéjọ àgbègbè yín, ẹ lè lo apá tó wà fún àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ láti fi jíròrò àwọn ohun táwọn ará ti rí i pé ó wúlò fún àwọn lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ lára àwọn ohun tẹ́ ẹ gbọ́ ní àpéjọ àgbègbè.