Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ August 20
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ AUGUST 20
Orin 83 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
bt orí 25 ìpínrọ̀ 8 sí 13 àti àpótí tó wà lójú ìwé 201 (25 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Ìsíkíẹ́lì 32-34 (10 min.)
No. 1: Ìsíkíẹ́lì 34:15-28 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Ìdí Tí Wọ́n Fi Ń Ṣe Inúnibíni Sí Àwọn Kristẹni Tòótọ́—td 6A (5 min.)
No. 3: Ìdí Tí Àdúrà Tó Nítumọ̀ Fi Kọjá Ọ̀rọ̀ Sísọ—Sm. 145:18; Mát. 22:37 (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Àwọn Ìfilọ̀.
10 min: Fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu ẹnì kan tàbí méjì tó jẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Kí ló mú kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ náà? Àwọn ìṣòro wo ni wọ́n ti ní tó lè mú kí wọ́n fi iṣẹ́ náà sílẹ̀, kí ló sì ràn wọ́n lọ́wọ́ tí wọ́n fi lè borí ìṣòro náà? Kí làwọn ìbùkún tí wọ́n ti rí? Fún àwọn akéde níṣìírí láti gba iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé ní ọdún iṣẹ́ ìsìn tó ń bọ̀.
20 min: “Ṣé O Ti Múra Sílẹ̀ De Àjálù?” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Fi àlàyé kún un látinú Ilé Ìṣọ́ December 1, 2011, ojú ìwé 6 àti 7.
Orin 70 àti Àdúrà