MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Ṣé O Ti Múra Sílẹ̀?
Tí àjálù èyíkéyìí bá ṣẹlẹ̀ lágbègbè rẹ, ṣé kò ní bá ẹ lábo? Ohun kan ni pé ìmìtìtì ilẹ̀, ìjì líle tàbí àkúnya omi lè ṣẹlẹ̀ lójijì, nígbà míì sì rèé iná lè ṣàdédé sọ, kó sì ba ọ̀pọ̀ nǹkan jẹ́. Yàtọ̀ síyẹn, àjàkálẹ̀ àrùn àtàwọn afẹ̀míṣòfò lè ṣọṣẹ́ nígbàkigbà, rògbòdìyàn sì lè ṣẹlẹ̀ níbikíbi láìrò tẹ́lẹ̀. (Onw 9:11) Kò yẹ ká máa ronú pé irú àjálù bẹ́ẹ̀ ò lè ṣẹlẹ̀ lágbègbè wa.
Ẹnì kọ̀ọ̀kan wa gbọ́dọ̀ gbé ìgbésẹ̀ láti múra sílẹ̀ de àjálù. (Owe 22:3) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ètò Ọlọ́run máa ń ṣèrànwọ́ fáwọn ará nígbà tí àjálù bá ṣẹlẹ̀, ó yẹ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ṣe ipa tiwa láti múra sílẹ̀.—Ga 6:5, àlàyé ìsàlẹ̀.
JẸ́ KÍ ÀWỌN ARÁ WO FÍDÍÒ NÁÀ ṢÉ O TI MÚRA SÍLẸ̀ DE ÀJÁLÙ? LẸ́YÌN NÁÀ, Ẹ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
Báwo la ṣe lè múra sílẹ̀ nípa tẹ̀mí fún àjálù?
Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé . . .
• ká máa fi bí nǹkan ṣe ń lọ tó àwọn alàgbà létí ṣáájú kí àjálù tó ṣẹlẹ̀, nígbà tó bá ṣẹlẹ̀ àti lẹ́yìn tó bá ṣẹlẹ̀?
• ká ní báàgì pàjáwìrì?—g17.5 6
• ká jíròrò irú àwọn àjálù tó lè ṣẹlẹ̀ àtohun tá a máa ṣe tí èyíkéyìí nínú wọn bá ṣẹlẹ̀?
Àwọn nǹkan mẹ́ta wo la lè ṣe tá a bá fẹ́ ṣèrànwọ́ fáwọn tí àjálù ṣẹlẹ̀ sí?