May 11-17
JẸ́NẸ́SÍSÌ 38-39
Orin 33 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Jèhófà Ò Pa Jósẹ́fù Tì”: (10 min.)
Jẹ 39:1—Jósẹ́fù di ẹrú ní Íjíbítì (w14 11/1 12 ¶4-5)
Jẹ 39:12-14, 20—Wọ́n parọ́ mọ́ Jósẹ́fù, wọ́n sì fi í sẹ́wọ̀n (w14 11/1 14-15)
Jẹ 39:21-23—Jèhófà ò fi Jósẹ́fù sílẹ̀ nígbà kankan (w14 11/1 15 ¶2)
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (10 min.)
Jẹ 38:9, 10—Kí nìdí tí Jèhófà fi pa Ónánì? (it-2 555)
Jẹ 38:15-18—Kí la lè sọ nípa ohun tí Júdà àti Támárì ṣe? (w04 1/15 30 ¶4-5)
Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí nípa Jèhófà, iṣẹ́ ìwàásù tàbí àwọn nǹkan míì?
Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Jẹ 38:1-19 (th ẹ̀kọ́ 5)
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Nígbà Àkọ́kọ́—Fídíò: (4 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò náà, lẹ́yìn náà béèrè àwọn ìbéèrè yìí: Báwo ni arábìnrin yìí ṣe jẹ́ kí onílé lóye ohun tó ń sọ? (th ẹ̀kọ́ 17) Ọ̀nà wo lo rò pé akéde yìí lè gbà fi ọ̀kan lára àwọn ìtẹ̀jáde tó wà nínú Àpótí Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ lọ onílé?
Nígbà Àkọ́kọ́: (2 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. (th ẹ̀kọ́ 1)
Nígbà Àkọ́kọ́: (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. Onílé sọ ohun táwọn èèyàn sábà máa ń sọ ní ìpínlẹ̀ yín tí wọn kò bá fẹ́ gbọ́ ìwàásù. Fèsì ní ṣókí, kó o sì máa bá ọ̀rọ̀ rẹ lọ. (th ẹ̀kọ́ 11)
Nígbà Àkọ́kọ́: (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. Lẹ́yìn náà fún onílé ní káàdì ìkànnì jw.org. (th ẹ̀kọ́ 6)
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
“Sá fún Ìṣekúṣe Bíi Ti Jósẹ́fù”: (15 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò náà Sá fún Ìṣekúṣe.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) bh orí 19 ¶1-7
Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
Orin 26 àti Àdúrà