ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JẸ́NẸ́SÍSÌ 38-39
Jèhófà Ò Pa Jósẹ́fù Tì
Nínú gbogbo wàhálà tó bá Jósẹ́fù, Jèhófà mú kí “gbogbo ohun tó ń ṣe yọrí sí rere,” ó sì mú kó rí “ojúure ọ̀gá ọgbà ẹ̀wọ̀n náà.” (Jẹ 39:2, 3, 21-23) Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ nínú ìtàn yìí?
Tá a bá wà nínú ìṣòro, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé Jèhófà ti pa wá tì.—Sm 34:19
Ó yẹ ká máa ronú nípa àwọn ọ̀nà tí Jèhófà ń gbà bù kún wa, ká sì máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀.—Flp 4:6, 7
Ó yẹ ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé ó máa ràn wá lọ́wọ́.—Sm 55:22