MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Sá fún Ìṣekúṣe Bíi Ti Jósẹ́fù
Àpẹẹrẹ tó dáa ni Jósẹ́fù jẹ́ tó bá dọ̀rọ̀ kéèyàn sá fún ìṣekúṣe. Gbogbo ìgbà tí ìyàwó ọ̀gá rẹ̀ bá fẹ́ fa ojú ẹ̀ mọ́ra ló máa ń sá. (Jẹ 39:7-10) Èsì tí Jósẹ́fù fún ìyàwó ọ̀gá rẹ̀ fi hàn pé ó ti ronú nípa ojú tí Jèhófà fi ń wo kí ọkọ àtìyàwó jẹ́ olóòótọ́ sí ara wọn. Ó sọ pé: “Ṣé ó wá yẹ kí n hùwà burúkú tó tó báyìí, kí n sì ṣẹ Ọlọ́run?” Nígbà tí ìyàwó ọ̀gá rẹ̀ fẹ́ fipá mú un, ṣe ló sá lọ, kò sì fi nǹkan falẹ̀ débi tí obìnrin náà á fi tàn án láti ṣe ohun tí kò tọ́.—Jẹ 39:12; 1Kọ 6:18.
WO FÍDÍÒ NÁÀ SÁ FÚN ÌṢEKÚṢE, LẸ́YÌN NÁÀ, DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
Ìṣòro wo ni Jin kojú?
Ìbéèrè ọlọ́gbọ́n wo ni Jin bi ara rẹ̀ nígbà tí Mee-Kyong bẹ̀ ẹ́ pé kó wá bá òun ṣe iṣẹ́ àmúrelé?
Báwo ni ohun tí Mee-Kyong béèrè ṣe rí lára Jin?
Kí ló ran Jin lọ́wọ́ láti borí ìṣòro yẹn?
Kí ni Jin ṣe kó lè sá fún ìṣekúṣe?
Àwọn nǹkan wo lo rí kọ́ nínú fídíò yìí?