ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w07 10/1 ojú ìwé 16-20
  • Fi Ayé Rẹ Ṣe Ohun Tó Dára Gan-an

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Fi Ayé Rẹ Ṣe Ohun Tó Dára Gan-an
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Lò Ń Lé Nígbèésí Ayé Rẹ?
  • Kí Ni “Ìyè Tòótọ́”?
  • Bá A Ṣe Lè Yááfì Àwọn Ohun Kan Ká Lè Ṣe Ohun Tó Tọ́
  • Má Ṣe ‘Lo Ayé Dé Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́’
  • Bó O Ṣe Lè Fi Ohun Tó Jẹ́ Ìfẹ́ Ọlọ́run Ṣáájú Nígbèésí Ayé Rẹ
  • Ìbéèrè Kìíní: Ìwọ Ọlọ́run, Kí Nìdí Tó O Fi Dá Mi Sáyé?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Dá Wa?
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
  • Bá a Ṣe Lè Máa Ṣe Ohun Tó Jẹ́ Ìfẹ́ Ọlọ́run Lónìí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ìgbésí Ayé Tó Dára—Nísinsìnyí àti Títí Láé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
w07 10/1 ojú ìwé 16-20

Fi Ayé Rẹ Ṣe Ohun Tó Dára Gan-an

“Gbogbo ohun eléèémí—kí ó yin Jáà.”—SÁÀMÙ 150:6.

1. Sọ ọ̀nà tí ọ̀dọ́kùnrin kan gbà wá bóun ṣe máa lo ayé òun lọ́nà tó dára gan-an.

ỌKÙNRIN kan tó ń jẹ́ Seung Jin tó dàgbà sílẹ̀ Kòríàa sọ pé: “Mo lọ kẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ ìṣègùn nítorí pé mo fẹ́ fi ìgbésí ayé mi ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Mo sì tún ronú pé iyì tó wà nínú kéèyàn jẹ́ dókítà àti owó tí yóò máa wọlé fún mi á jẹ́ kí n láyọ̀. Àmọ́ nígbà tí mo wá rí i pé ìwọ̀nba ni dókítà lè ṣe láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, gbogbo rẹ̀ tojú sú mi. Ni mo bá tún lọ kọ́ ẹ̀kọ́ nípa àwòrán yíyà, àmọ́ àwọn nǹkan mèremère tí mo yà kò fi bẹ́ẹ̀ ṣàǹfààní gidi kan fáwọn èèyàn, ó sì wá ń ṣe mí bíi pé mo ní ìmọtara-ẹni-nìkan. Bí mo tún ṣe lọ di olùkọ́ nìyẹn, kò sì pẹ́ tí mo tún fi rí i pé lóòótọ́ ni mo lè kọ́ àwọn èèyàn láwọn nǹkan kan, àmọ́ mi ò lè fún wọn ní ìtọ́sọ́nà tó máa jẹ́ kí wọ́n ní ojúlówó ayọ̀.” Bíi ti ọ̀pọ̀ èèyàn, ńṣe ni Seung Jin ń wá bóun ṣe máa fáyé òun ṣe ohun tó dára gan-an.

2. (a) Kí ló túmọ̀ sí pé ẹnì kan fáyé rẹ̀ ṣe ohun tó dára gan-an? (b) Báwo la ṣe mọ̀ pé ó nídìí tí Ẹlẹ́dàá fi da wa sáyé?

2 Ká tó lè sọ pé ayé ẹnì kan dára gan-an, ó gbọ́dọ̀ ní ohun gidi kan tó ń fayé rẹ̀ ṣe, kò ní máa gbélé ayé lásán, ó sì gbọ́dọ̀ ní ohun gúnmọ́ kan tó ń lé. Ǹjẹ́ ọwọ́ ẹ̀dá èèyàn lè tẹ irú ohun bẹ́ẹ̀? Bẹ́ẹ̀ ni! Níwọ̀n bí Ẹlẹ́dàá ti fún wa ní làákàyè, tó fún wa ní ẹ̀rí ọkàn, tó sì dá wa lọ́nà tá a fi lè ronú, ó fi hàn pé ó ní ìdí pàtàkì tó fi dá wa sáyé. Nípa báyìí, ó bọ́gbọ́n mu pé, gbígbé ìgbésí ayé wa lọ́nà tó bá ìfẹ́ Ẹlẹ́dàá mu nìkan la fi lè sọ pé ayé wa dára gan-an.

3. Kí làwọn ìdí tí Ọlọ́run fi dá àwa èèyàn sáyé?

3 Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ọ̀pọ̀ ìdí ló wà tí Ọlọ́run fi dá wa sáyé. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀nà àgbàyanu tó gbà dá wa jẹ́ ẹ̀rí tó fi hàn kedere pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wa gan-an. (Sáàmù 40:5; 139:14) Táwa náà bá nífẹ̀ẹ́ àwọn mìíràn tọkàntọkàn gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ṣe nífẹ̀ẹ́ wa, yóò fi hàn pé à ń gbé ìgbésí ayé wa lọ́nà tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu. (1 Jòhánù 4:7-11) A tún ní láti máa fi àwọn ìtọ́ni Ọlọ́run sílò, èyí tó ń ràn wá lọ́wọ́ láti gbé ìgbésí ayé wa lọ́nà tó bá ìfẹ́ rẹ̀ mu.—Oníwàásù 12:13; 1 Jòhánù 5:3.

4. (a) Kí la gbọ́dọ̀ ṣe ká tó lè sọ pé à ń fi ayé wa ṣe ohun tó dára gan-an? (b) Kí lohun tó dára jù lọ tó yẹ kéèyàn máa lé?

4 Ìfẹ́ Ọlọ́run tún ni pé káwa èèyàn láyọ̀ ká sì wà lálàáfíà pẹ̀lú ara wa àti pẹ̀lú àwọn ohun mìíràn tí Ọlọ́run dá. (Jẹ́nẹ́sísì 1:26; 2:15) Àmọ́ kí la gbọ́dọ̀ ṣe ká tó lè láyọ̀ kí ọkàn wa sì balẹ̀? Tí ọmọ kékeré kan bá mọ̀ pé àwọn òbí òun wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ òun, inú ẹ̀ á máa dùn, ọkàn rẹ̀ á sì balẹ̀. Kí ìgbésí ayé wa tó lè dára gan-an, àjọṣe tó dán mọ́rán gbọ́dọ̀ wà láàárín àwa àti Baba wa ọ̀run. (Hébérù 12:9) Ọlọ́run sì ti mú kí èyí ṣeé ṣe ní ti pé ó gbà wá láyè láti sún mọ́ òun ó sì ń gbọ́ àdúrà wa. (Jákọ́bù 4:8; 1 Jòhánù 5:14, 15) Tá a bá nígbàgbọ́ bá a ti ń ‘bá Ọlọ́run rìn,’ yóò ṣeé ṣe fún wa láti múnú Baba wa ọ̀run dùn a ó sì lè máa yìn ín. (Jẹ́nẹ́sísì 6:9; Òwe 23:15, 16; Jákọ́bù 2:23) Ohun tó dára jù lọ tó sì yẹ kéèyàn máa lé nìyẹn. Ọ̀kan lára àwọn tó kọ Sáàmù sọ pé: “Gbogbo ohun eléèémí—kí ó yin Jáà.”—Sáàmù 150:6.

Kí Lò Ń Lé Nígbèésí Ayé Rẹ?

5. Kí nìdí tí kò fi bọ́gbọ́n mu láti fi nǹkan tara sípò àkọ́kọ́?

5 Lára ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ká ṣe nígbèésí ayé wa ni pé ká ṣètọ́jú ara wa àti ìdílé wa dáadáa. Èyí gba pé ká máa fún ara wa ní ìtọ́jú tó nílò ká sì tún ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Ọlọ́run. Àmọ́ ó yẹ ká ṣọ́ra bá a ti ń ṣe èyí, kó má bàa di pé ọ̀rọ̀ àtijẹ-àtimu ṣèdíwọ́ fáwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ, ìyẹn ìjọsìn Ọlọ́run. (Mátíù 4:4; 6:33) Ó bani nínú jẹ́ pé kíkó nǹkan ìní jọ ni ọ̀pọ̀ èèyàn ń fi gbogbo ọjọ́ ayé wọn lé. Síbẹ̀, kò bọ́gbọ́n mu ká máa rò pé tá a bá ti ní gbogbo nǹkan tara tá a nílò, ìṣòro wa ti tán. Ìwádìí kan tí wọ́n ṣe láìpẹ́ yìí nípa àwọn kan tó lówó bíi ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ nílẹ̀ Éṣíà fi hàn pé ọ̀pọ̀ lára wọn “lọkàn wọn ò balẹ̀ tínú wọn ò sì dùn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n gbayì láwùjọ tí wọ́n sì rí towó ṣe.”—Oníwàásù 5:11.

6. Ìmọ̀ràn wo ni Jésù fún àwọn tó ń lé ọrọ̀?

6 Jésù sọ pé ‘ọrọ̀ lágbára láti tanni jẹ.’ (Máàkù 4:19) Báwo ni ọrọ̀ ṣe ń tanni jẹ? Àwọn èèyàn máa ń rò pé ọrọ̀ ń fúnni láyọ̀, àmọ́ kò rí bẹ́ẹ̀. Sólómọ́nì tó jẹ́ ọba ọlọgbọ́n sọ pé: “Olùfẹ́ ọlà kì yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú owó tí ń wọlé wá.” (Oníwàásù 5:10) Àmọ́ ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe kéèyàn máa lé àwọn nǹkan tara kéèyàn sì tún máa sin Ọlọ́run tọkàntọkàn? Rárá, kò ṣeé ṣe. Jésù ṣàlàyé pé: “Kò sí ẹnì kan tí ó lè sìnrú fún ọ̀gá méjì; nítorí yálà òun yóò kórìíra ọ̀kan, kí ó sì nífẹ̀ẹ́ èkejì, tàbí òun yóò fà mọ́ ọ̀kan, kí ó sì tẹ́ńbẹ́lú èkejì. Ẹ kò lè sìnrú fún Ọlọ́run àti fún Ọrọ̀.” Jésù kò rọ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa kó nǹkan ìní jọ lórí ilẹ̀ ayé, ó ní kí wọ́n ní ‘ìṣúra lọ́run,’ ìyẹn ni pé kí wọ́n ní orúkọ rere lọ́dọ̀ Ọlọ́run, ẹni tó “mọ àwọn ohun tí [wọ́n] ṣe aláìní kí [wọ́n] tó béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ rárá.”—Mátíù 6:8, 19-25.

7. Báwo la ṣe lè “di ìyè tòótọ́ mú gírígírí”?

7 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fúnni nímọ̀ràn kan tó lágbárá lórí kókó yìí nínú lẹ́tà tó kọ sí Tímótì tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ ìwàásù. Ó sọ fún Tímótì pé: “Fún àwọn ọlọ́rọ̀ . . . ní àṣẹ ìtọ́ni láti má ṣe . . . gbé ìrètí wọn lé ọrọ̀ àìdánilójú, bí kò ṣe lé Ọlọ́run, ẹni tí ń pèsè ohun gbogbo fún wa lọ́pọ̀ jaburata fún ìgbádùn wa . . . , láti jẹ́ aláìṣahun, kí wọ́n múra tán láti ṣe àjọpín, kí wọ́n máa fi àìséwu to ìṣúra ìpìlẹ̀ tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ jọ fún ara wọn de ẹ̀yìn ọ̀la, kí wọ́n lè di ìyè tòótọ́ mú gírígírí.”—1 Tímótì 6:17-19.

Kí Ni “Ìyè Tòótọ́”?

8. (a) Kí nìdí tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi ń lé ọrọ̀ àti ipò iyì lójú méjèèjì? (b) Kí nirú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ kò mọ̀?

8 Ohun tó máa ń wá sọ́kàn ọ̀pọ̀ èèyàn tí wọ́n bá gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, “ìyè tòótọ́” ni pé kéèyàn láwọn nǹkan mèremère kó sì máa gbé ìgbésí ayé fàájì. Ìwé ìròyìn kan tó máa ń sọ̀rọ̀ nípa ilẹ̀ Éṣíà sọ pé: “Àwọn tó máa ń wo fíìmù tàbí tẹlifíṣọ̀n máa ń nífẹ̀ẹ́ sáwọn nǹkan tí wọ́n ń rí, wọ́n sì máa ń ronú ṣáá nípa àwọn ohun tó ṣeé ṣe káwọn ní.” Ọ̀pọ̀ èèyàn ló sọ níní ọrọ̀ àti wíwà nípò iyì dohun tí wọ́n ń fi ìgbésí ayé wọn lépa. Ọ̀pọ̀ èèyàn ni kì í gbádùn àkókò tí wọ́n fi wà lọ́dọ̀ọ́, tí wọn kì í bójú tó ìlera wọn, ìdílé wọn, àtàwọn ohun tó ní í ṣe pẹ̀lú ìjọsìn Ọlọ́run nítorí àtilé àwọn nǹkan wọ̀nyẹn. Àwọn èèyàn díẹ̀ ló ń ronú pé ohun tí wọ́n ń rí lórí tẹlifíṣọ̀n yẹn wulẹ̀ ń fi “ẹ̀mí ayé” hàn ni. Ẹ̀mí ayé ni èrò tó gbilẹ̀ lọ́kàn àwọn èèyàn tó sì ń darí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tó wà lórí ilẹ̀ ayé, òun ló sì ń mú kí wọ́n máa ṣe ohun tó lòdì sí ìdí tí Ọlọ́run fi dá wa sáyé. (1 Kọ́ríńtì 2:12; Éfésù 2:2) Abájọ táwọn èèyàn tí kò láyọ̀ fi pọ̀ rẹpẹtẹ lónìí!—Òwe 18:11; 23:4, 5.

9. Kí ni ẹ̀dá èèyàn ò lè ṣe láé, kí sì nìdí?

9 Àwọn tó ń forí ṣe fọrùn ṣe torí káyé àwọn mìíràn lè dára ńkọ́, tí wọ́n tún ń sapá lójú méjèèjì láti mú ebi, àìsàn àti ìwà ìrẹ́jẹ kúrò? Iṣẹ́ dáadáa tí wọ́n ń ṣe yìí àti ìfẹ́ ọmọnìkejì tí wọ́n ní sábà máa ń ṣe ọ̀pọ̀ èèyàn láǹfààní. Síbẹ̀, kò sí bí wọ́n ṣe lè sapá tó tí wọ́n á fi lè sọ ètò àwọn nǹkan yìí di èyí tó dára tí ìrẹ́jẹ kò sì ní sí mọ́. Kí nìdí? Ìdí ni pé “gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà,” ìyẹn Sátánì, kò sì fẹ́ kí ipò tí ayé wà yí padà.—1 Jòhánù 5:19.

10. Ìgbà wo làwọn olóòótọ́ yóò ní “ìyè tòótọ́”?

10 Ẹ ò rí i pé nǹkan ìbànújẹ́ ni yóò jẹ́ tẹ́nì kan bá lọ gbé gbogbo ìrètí rẹ̀ ka ayé ìsinsìnyí! Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Bí ó bá jẹ́ pé nínú ìgbésí ayé yìí nìkan ni a ti ní ìrètí nínú Kristi, àwa ni ó yẹ láti káàánú jù lọ nínú gbogbo ènìyàn.” Ohun tó wà lọ́kàn àwọn tó gbà gbọ́ pé ìgbésí ayé yìí nìkan ló wà, ni pé: “Ẹ jẹ́ kí a máa jẹ, kí a sì máa mu, nítorí ọ̀la ni àwa yóò kú.” (1 Kọ́ríńtì 15:19, 32) Àmọ́ ọjọ́ ọ̀la tó dára ń bọ̀, ìyẹn “ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun . . . tí a ń dúró dè ní ìbámu pẹ̀lú ìlérí [Ọlọ́run], nínú ìwọ̀nyí ni òdodo yóò sì máa gbé.” (2 Pétérù 3:13) Nígbà yẹn, á ṣeé ṣe fáwọn Kristẹni láti ní “ìyè tòótọ́,” ìyẹn “ìyè àìnípẹ̀kun,” wọ́n á sì tún dẹni pípé, yálà ní ọ̀run tàbí lórí ilẹ̀ ayé lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run tó máa jẹ́ ìjọba onífẹ̀ẹ́!—1Tímótì 6:12.

11. Kí nìdí tí ṣíṣe iṣẹ́ tó ń ti Ìjọba Ọlọ́run lẹ́yìn fi jẹ́ ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ?

11 Ìjọba Ọlọ́run nìkan ṣoṣo ló máa yanjú ìṣòro aráyé pátápátá. Nítorí náà, ṣíṣe iṣẹ́ tó ń ti Ìjọba Ọlọ́run lẹ́yìn lohun tó ṣe pàtàkì jù lọ tó yẹ kéèyàn gbájú mọ́. (Jòhánù 4:34) Bá a ti ń ṣe iṣẹ́ yẹn, ó ń jẹ́ ká ní àjọṣe tó dára gan-an pẹ̀lú Baba wa ọ̀run. A tún ń láyọ̀ pé à ń sìn pẹ̀lú ẹgbàágbèje àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa tó jẹ́ pé ohun tí à ń lé nígbèésí ayé wa làwọn náà ń lé.

Bá A Ṣe Lè Yááfì Àwọn Ohun Kan Ká Lè Ṣe Ohun Tó Tọ́

12. Sọ ọ̀nà tí “ìyè tòótọ́” gbà yàtọ̀ sí ìgbésí ayé nínú ètò nǹkan ìsinsìnyí.

12 Bíbélì sọ pé ayé ìsinsìnyí “ń kọjá lọ, bẹ́ẹ̀ sì ni ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀.” Kò sí apá kankan nínú ayé Sátánì tó máa ṣẹ́ kù tí kò ní pa run, títí kan òkìkí àti ọlà táwọn èèyàn ń lé, “ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò dúró títí láé.” (1 Jòhánù 2:15-17) Àmọ́ “ìyè tòótọ́,” ìyẹn ìyè àìnípẹ̀kun lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run yàtọ̀ sí ọrọ̀ tí kò dáni lójú, ògo tí kò láyọ̀lé, àti ìgbádùn inú ètò nǹkan ìsinsìnyí tí kò fún àwọn èèyàn ní ojúlówó ayọ̀. “Ìyè tòótọ́” yóò wà títí láé, ó sì tó bẹ́ẹ̀ ó jù bẹ́ẹ̀ lọ pé ká yááfì àwọn ohun kan, tó bá ṣáà ti jẹ́ pé ohun tó tọ́ la fẹ́ ṣe.

13. Báwo ni tọkọtaya kan ṣe yááfì àwọn ohun kan kí wọ́n lè ṣe ohun tó tọ́?

13 Ìwọ wo ohun tí Henry àti Suzanne ṣe. Wọ́n nígbàgbọ́ gan-an nínú ìlérí Ọlọ́run pé gbogbo àwọn tó bá fi Ìjọba Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé wọn yóò rí ìrànwọ́ Ọlọ́run gbà. (Mátíù 6:33) Èyí mú kí wọ́n pinnu pé ilé olówó pọ́ọ́kú làwọ́n á máa gbé, kò sì ní pọn dandan fáwọn méjèèjì láti máa ṣiṣẹ́. Èyí jẹ́ kó ṣeé ṣe fún àwọn tọkọtaya yìí àtàwọn ọmọ wọn obìnrin méjèèjì láti gbájú mọ́ lílé àwọn ohun tó ní í ṣe pẹ̀lú ìjọsìn Ọlọ́run. (Hébérù 13:15, 16) Obìnrin kan tó jẹ́ ọ̀rẹ́ wọn tó sì nífẹ̀ẹ́ wọn gan-an kò lóye ìdí tí wọ́n fi ṣe irú ìpinnu bẹ́ẹ̀. Ó sọ fún Suzanne pé: “Ọ̀rẹ́, tó o bá fẹ́ gbé ilé tó dára ju èyí lọ, wàá ṣì ní láti yááfì àwọn nǹkan kan.” Àmọ́ Henry àti Suzanne mọ̀ pé fífi Jèhófà sípò àkọ́kọ́ á jẹ́ káwọn “ní ìlérí ìyè ti ìsinsìnyí àti ti èyí tí ń bọ̀.” (1 Tímótì 4:8; Títù 2:12) Nígbà táwọn ọmọ wọn dàgbà, wọ́n di oníwàásù alákòókò-kíkún. Ìdílé yìí wá rí i pé àwọn ò pàdánù ohunkóhun, kàkà bẹ́ẹ̀ wọ́n jàǹfààní tó pọ̀ nítorí pé wọ́n lépa “ìyè tòótọ́” nígbèésí ayé wọn.—Fílípì 3:8; 1 Tímótì 6:6-8.

Má Ṣe ‘Lo Ayé Dé Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́’

14. Àwọn nǹkan ìbànújẹ́ wo ló lè tẹ̀yìn ẹ̀ yọ tá a bá gbàgbé olórí ìdí tá a fi wà láàyè?

14 Àmọ́, tá a bá lọ gbàgbé olórí ìdí tá a fi wà láàyè tá ò sì di “ìyè tòótọ́” mú gírígírí, inú ewu ńlá la wà. A lè di “ẹni tí àwọn àníyàn àti ọrọ̀ àti adùn ìgbésí ayé yìí gbé lọ.” (Lúùkù 8:14) Wíwá ọrọ̀ lójú méjèèjì àti “àníyàn ìgbésí ayé” lè mú ká kara bọ ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí ju bó ṣe yẹ lọ. (Lúùkù 21:34) Ó bani nínú jẹ́ pé àwọn kan ti jẹ́ kí ìfẹ́ láti di ọlọ́rọ̀ tó gbayé kan lónìí gbà wọ́n lọ́kàn débi pé wọ́n ti “ṣáko lọ kúrò nínú ìgbàgbọ́, wọ́n sì ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrora gún ara wọn káàkiri,” kódà wọn ò ní àjọṣe ṣíṣeyebíye tí wọ́n ní tẹ́lẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà mọ́. Ẹ ò rí i pé nǹkan ńlá ni wọ́n pàdánù nítorí pé wọn ò “di ìyè àìnípẹ̀kun mú gírígírí”!—1 Tímótì 6:9, 10, 12; Òwe 28:20.

15. Èrè wo ni ìdílé kan rí gbà nítorí pé ‘wọn kò lo ayé dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́’?

15 Ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù ni pé kí “àwọn tí ń lo ayé [dà] bí àwọn tí kò lò ó dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.” (1 Kọ́ríńtì 7:31) Arákùnrin Keith àti Bonnie, ìyàwó rẹ̀, fi ìmọ̀ràn yìí sílò. Keith sọ pé: “Bí mo ti ń ṣe tán nílé ẹ̀kọ́ ìtọ́jú eyín ni mo di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó wá di dandan kí n ṣèpinnu kan. Mo lè máa tọ́jú ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn kí n sì lówó rẹpẹtẹ, àmọ́ èyí á ṣàkóbá fún ìjọsìn èmi àti ìdílé mi. Ni mo bá pinnu pé mi ò ní kara bọ iṣẹ́ náà ju bó ṣe yẹ lọ kí ìdílé mi lè ráyè gbájú mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run ká sì lè ní ìbàlẹ̀ ọkàn. A wá ní ọmọbìnrin márùn-ún nígbà tó yá. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a kì í fi bẹ́ẹ̀ ní àjẹṣẹ́kù, a kọ́ bá a ṣe lè máa ṣọ́ owó ná, gbogbo ìgbà la sì máa ń ní ohun tá a nílò. A sún mọ́ra gan-an nínú ìdílé wa, ìfẹ́ wà, bẹ́ẹ̀ la sì máa ń láyọ̀ gan-an. Nígbà tó yá, gbogbo wa di òjíṣẹ́ alákòókò-kíkún. Ní báyìí, àwọn ọmọ wa ti lọ́kọ wọ́n sì láyọ̀ lọ́ọ̀dẹ̀ ọkọ wọn, mẹ́ta lára wọn sì ti láwọn ọmọ. Ìdílé tiwọn náà láyọ̀ bí wọ́n ti ń fi ṣíṣe ìfẹ́ Jèhófà sípò àkọ́kọ́.”

Bó O Ṣe Lè Fi Ohun Tó Jẹ́ Ìfẹ́ Ọlọ́run Ṣáájú Nígbèésí Ayé Rẹ

16, 17. Àwọn èèyàn wo ni Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa wọn pé wọ́n ní ẹ̀bùn àbínibí, àmọ́ kí lohun tá a fi ń rántí wọn?

16 Bíbélì sọ nípa àwọn tó lo ìgbésí ayé wọn fún ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run àtàwọn tí kò ṣe bẹ́ẹ̀. Gbogbo èèyàn làwọn ẹ̀kọ́ tá a lè rí kọ́ látinú àwọn àpẹẹrẹ wọ̀nyí kàn, láìka ọjọ́ orí, àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀, àti ipò téèyàn wà sí. (Róòmù 15:4; 1 Kọ́ríńtì 10:6, 11) Nímírọ́dù kọ́ àwọn ìlú ńláńlá, àmọ́ ohun tó ṣe lòdì sí ìfẹ́ Ọlọ́run. (Jẹ́nẹ́sísì 10:8, 9) Ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn sì wà tí wọ́n jẹ́ àpẹẹrẹ rere. Bí àpẹẹrẹ, Mósè kò sọ jíjẹ́ tó jẹ́ èèyàn pàtàkì nílẹ̀ Íjíbítì di ohun bàbàrà nígbèésí ayé rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó mọyì àwọn iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé fún un, ó kà wọ́n sí “ọrọ̀ tí ó tóbi ju àwọn ìṣúra Íjíbítì” lọ. (Hébérù 11:26) Ó ṣeé ṣe kí Lúùkù tó jẹ́ oníṣègùn ti ṣètọ́jú Pọ́ọ̀lù àtàwọn mìíràn nígbà tí wọ́n ń ṣàìsàn. Àmọ́ jíjẹ́ tó jẹ́ oníwàásù tó sì tún wà lára àwọn tó kọ Bíbélì ni ọ̀nà tó dára jù lọ tó gbà ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Ohun táwọn èèyàn sì mọ Pọ́ọ̀lù sí ni míṣọ́nnárì, ìyẹn “àpọ́sítélì fún àwọn orílẹ̀-èdè,” wọn ò mọ̀ ọ́n sí ògbóǹkangí amòfin.—Róòmù 11:13.

17 Ohun pàtàkì tá a fi ń rántí Dáfídì ni pé ó jẹ́ “ọkùnrin kan tí ó tẹ́ ọkàn-àyà [Ọlọ́run] lọ́rùn” kì í ṣe jíjẹ́ tó jẹ́ olórí ogun tàbí kọrinkọrin. (1 Sámúẹ́lì 13:14) Ìdí tá a fi mọ Dáníẹ́lì kì í ṣe torí pé ó jẹ́ òṣìṣẹ́ nínú ìjọba ilẹ̀ Bábílónì bí kò ṣe nítorí iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí wòlíì Jèhófà. Jíjẹ́ tí Ẹ́sítérì jẹ́ ayaba nílẹ̀ Páṣíà kọ́ ló jẹ́ ká mọ̀ ọ́n bí kò ṣe nítorí pé ó jẹ́ ẹni tó nígboyà tó sì tún nígbàgbọ́. Bákan náà, kì í ṣe torí pé Pétérù, Áńdérù, Jákọ́bù àti Jòhánù mọ ẹja pa dáadáa ló jẹ́ ká mọ̀ wọ́n bí kò ṣe torí pé wọ́n jẹ́ àpọ́sítélì Jésù. Àpẹẹrẹ tó ga jù lọ ni ti Jésù fúnra rẹ̀. “Kristi” la mọ̀ ọ́n sí kì í ṣe “káfíńtà.” (Máàkù 6:3; Mátíù 16:16) Gbogbo àwọn tá a dárúkọ yìí ló mọ̀ dájú pé ẹ̀bùn àbínibí tàbí ohun ìní yòówù káwọn ní, tàbí ipò pàtàkì tó wù káwọn wà, iṣẹ́ ìsìn àwọn sí Ọlọ́run ló gbọ́dọ̀ ṣe pàtàkì sáwọn ju iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ àwọn lọ. Wọ́n mọ̀ pé ohun tó dáa jù lọ tó sì ṣàǹfààní jù lọ táwọn lè fayé àwọn ṣe ni pé káwọn bẹ̀rù Ọlọ́run.

18. Ọ̀nà wo ni ọ̀dọ́ kan tó jẹ́ Kristẹni pinnu láti gbà lo ìgbésí ayé rẹ̀, kí ló sì wá lóye rẹ̀ nígbà tó yá?

18 Seung Jin tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ wá lóye èyí nígbà tó yá. Ó ṣàlàyé pé: “Dípò kí n máa lo gbogbo okun mi nídìí ìmọ̀ ìṣègùn, àwòrán yíyà, tàbí kíkọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ ayé, mo pinnu pé ọ̀nà tó bá ìyàsímímọ́ mi sí Ọlọ́run mu ni màá gbà lò ó. Ibi tá a ti nílò àwọn tó ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì gan-an ni mo ti ń sìn báyìí mo sì ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa rìn ní ọ̀nà tó lọ síyè àìnípẹ̀kun. Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, mo máa ń rò pé jíjẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò-kíkún kò gba ìsapá kankan. Àmọ́ mo ti wá rí i pé ọ̀rọ̀ kò rí bí mo ṣe rò, nítorí pé mo ní láti máa sapá kí ìwà mi lè túbọ̀ dára sí i kí n sì lè túbọ̀ kọ́ àwọn tí wọ́n wá láti onírúurú orílẹ̀-èdè lọ́nà tó túbọ̀ dára sí i. Mo ti wá rí i pé jíjẹ́ kí ohun tó jẹ́ ìfẹ́ Jèhófà jẹ wá lọ́kàn ni ọ̀nà kan ṣoṣo táyé èèyàn fi lè dára gan-an.”

19. Báwo la ṣe lè fi ayé wa ṣe ohun tó dára gan-an?

19 Nítorí pé a jẹ́ Kristẹni, a ní ìmọ̀ tó ń gba ẹ̀mí là àti ìrètí ìgbàlà. (Jòhánù 17:3) Nítorí náà, ẹ má ṣe jẹ́ ká “tẹ́wọ́ gba inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run kí [a] sì tàsé ète rẹ̀.” (2 Kọ́ríńtì 6:1) Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká máa fi àwọn ọjọ́ wa tó ṣeyebíye àtàwọn ọdún tá a máa lò nígbèésí ayé wa yin Jèhófà. Ẹ jẹ́ ká máa wàásù ìmọ̀ tó ń fúnni ní ojúlówó ayọ̀ nísinsìnyí, tí yóò sì yọrí sí ìyè àìnípẹ̀kun lọ́jọ́ iwájú. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a ó rí i pé òótọ́ lọ̀rọ̀ tí Jésù sọ pé: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.” (Ìṣe 20:35) Èyí á sì fi hàn pé ohun tó dára gan-an la fi ayé wa ṣe.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ kan padà.

Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?

• Kí lohun tó dára jù lọ tá a lè máa fi ìgbésí ayé wa ṣe?

• Kí nìdí tí fífi gbogbo ìgbésí ayé ẹni lé nǹkan tara kò fi bọ́gbọ́n mu?

• Kí ni “ìyè tòótọ́” tí Ọlọ́run ṣèlérí?

• Báwo la ṣe lè lo ìgbésí ayé wa lọ́nà tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu?

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Ó yẹ káwọn Kristẹni máa yááfì àwọn nǹkan kan kí wọ́n lè ṣe ohun tó tọ́

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́