Bá a Ṣe Lè Máa Ṣe Ohun Tó Jẹ́ Ìfẹ́ Ọlọ́run Lónìí
“[Kristi] kú fún gbogbo wọn kí àwọn tí ó wà láàyè má ṣe tún wà láàyè fún ara wọn mọ́.”—2 KỌ́RÍŃTÌ 5:15.
1. Sọ ìrírí tí míṣọ́nnárì kan ní níbi tó ti ń sìn.
MÍṢỌ́NNÁRÌ kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Aarona sọ pé: “Lẹ́yìn tí ogun abẹ́lé parí, ọkọ̀ wa ni ọkọ̀ tí kì í ṣe tológun tó kọ́kọ́ wọ abúlé kan tó jìnnà gan-an nílẹ̀ Áfíríkà. Ṣáájú ìgbà yẹn, kò ṣeé ṣe fún wa láti bá ìjọ kékeré tó wà níbẹ̀ sọ̀rọ̀, ó sì yẹ ká pèsè ohun táwọn arákùnrin náà nílò fún wọn. Yàtọ̀ sí oúnjẹ, aṣọ, àtàwọn ìwé tá a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ohun tá a tún mú dání ni fídíò Jehovah’s Witnesses—The Organization Behind the Name [Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà—Ètò Àjọ tí Ń Jẹ́ Orúkọ Yẹn].b Ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn nínú abúlé náà ló rọ́ wá wo fídíò náà níbi tá a ti ṣàfihàn rẹ̀ nínú ahéré ńlá kan tí wọ́n fi koríko kọ́. A gbé ẹ̀rọ fídíò àti tẹlifíṣọ̀n kan síbẹ̀, ìgbà méjì la sì fi han àwọn èèyàn. Ọ̀pọ̀ lára àwọn tó wo fídíò yìí ló ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì báyìí, èyí sì fi hàn pé gbogbo ìsapá wa kò já sásán.”
2. (a) Kí nìdí táwọn Kristẹni fi pinnu láti lo ìgbésí ayé wọn fún iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa wá jíròrò báyìí?
2 Kí nìdí tí Aaron àtàwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ fi ṣe ohun tí kò rọrùn yìí? Ìmọrírì tí wọ́n ní fún ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi mú kí wọ́n ya ìgbésí ayé wọn sí mímọ́ fún Ọlọ́run, wọ́n sì fẹ́ lo ìgbésí ayé wọn yìí lọ́nà tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu. Bíi tiwọn, gbogbo Kristẹni tó ti yara wọn sí mímọ́ ló ti pinnu pé àwọn kò ní ‘wà láàyè fún ara àwọn mọ́’ bí kò ṣe kí wọ́n máa ṣe gbogbo ohun tí wọ́n bá lè ṣe “nítorí ìhìn rere.” (2 Kọ́ríńtì 5:15; 1 Kọ́ríńtì 9:23) Wọ́n mọ̀ pé nígbà tí ètò nǹkan ìsinsìnyí bá wá sópin, gbogbo owó àti gbogbo iyì inú ayé kò ní já mọ́ nǹkan kan. Nítorí náà, níwọ̀n ìgbà tí wọ́n wà láàyè tí ara wọn sì le díẹ̀, wọ́n fẹ́ lo ìwàláàyè wọn àti okun wọn lọ́nà tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu. (Oníwàásù 12:1) Ọ̀nà wo la lè gbà ṣe èyí? Báwo la ṣe lè ní ìgboyà àti okun tá a nílò? Àwọn iṣẹ́ ìsìn wo la sì lè ṣe?
Bá A Ṣe Lè Máa Ṣe Àwọn Ohun Tó Bójú Mu Ní Ṣísẹ̀-N-Tẹ̀-Lé
3. Orí àwọn nǹkan pàtàkì wo ni ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ti máa ń bẹ̀rẹ̀?
3 Ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run jẹ́ ohun táwọn Kristẹni tòótọ́ yóò máa ṣe títí ayé. Ibi tí wọ́n sì ti sábà máa ń bẹ̀rẹ̀ ni fíforúkọ sílẹ̀ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, kíka Bíbélì lójoojúmọ́, kíkópa nínú iṣẹ́ ìwàásù, títí dórí ṣíṣe ìrìbọmi. Bá a ti ń tẹ̀ síwájú, a máa ń fi ọ̀rọ̀ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ sọ́kàn pé: “Máa fẹ̀sọ̀ ronú lórí nǹkan wọ̀nyí; fi ara rẹ fún wọn pátápátá, kí ìlọsíwájú rẹ lè fara hàn kedere fún gbogbo ènìyàn.” (1 Tímótì 4:15) Irú ìtẹ̀síwájú yìí kì í ṣe ọ̀rọ̀ pé à ń gbé ara wa ga, ó jẹ́ ọ̀nà tí à gbà ń fi hàn pé a ti pinnu láti máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run pẹ̀lú gbogbo ọkàn wa. Ṣíṣe èyí sì ń fi hàn pé à ń jẹ́ kí Ọlọ́run darí wa nínú gbogbo ohun tí à ń ṣe, ó sì ń darí wa lọ́nà tó dára gan-an ju báwa fúnra wa ṣe lè darí ara wa lọ.—Sáàmù 32:8.
4. Báwo la ṣe lè borí àwọn ìbẹ̀rù tí kò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀?
4 Àmọ́ kíkọ̀ láti ṣèpinnu tàbí ríronú nípa ara wa ju bó ṣe yẹ lọ lè ṣèdíwọ́ fún wa, kò sì ní jẹ́ ká tẹ̀ síwájú nínú iṣẹ́ ìsìn wa sí Ọlọ́run. (Oníwàásù 11:4) Nítorí náà, ká tó lè ní ojúlówó ayọ̀ bá a ti ń lo ara wa fún Ọlọ́run àtàwọn ẹlòmíràn, a ní láti kọ́kọ́ borí ẹ̀rù tó lè máa bà wá. Bí àpẹẹrẹ, Erik ń gbèrò láti lọ sìn nínú ìjọ kan tí wọ́n ti ń sọ èdè ilẹ̀ òkèèrè. Àmọ́ ó bẹ̀rẹ̀ sí í bi ara rẹ̀ pé: ‘Ǹjẹ́ wọ́n á tẹ́wọ́ gbà mí? Ṣé màá nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin tó wà nínú ìjọ náà? Ṣé wọ́n á fẹ́ràn mi?’ Ó wá sọ ohun tó ṣẹlẹ̀, ó ní: “Nígbà tó yá, mo rí i pé àwọn arákùnrin yẹn ló yẹ kí n máa ronú nípa wọn, kì í ṣe nípa ara mi. Mo pinnu pé mi ò ní dààmú ara mi nípa àwọn nǹkan wọ̀nyí mọ́, pé màá lo ara mi lọ́nàkọnà tí mo bá ti wúlò fún wọn. Mo gbàdúrà pé kí Jèhófà ràn mí lọ́wọ́, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ohun tí mo pinnu láti ṣe. Mo ti wá ń gbádùn iṣẹ́ ìsìn mi gan-an níbẹ̀ báyìí.” (Róòmù 4:20) Bẹ́ẹ̀ ni, bá a bá ṣe lo ara wa fún Ọlọ́run àtàwọn ẹlòmíràn tó, bẹ́ẹ̀ layọ̀ wa àti ìbàlẹ̀ ọkàn tá a máa ní yóò ṣe pọ̀ tó.
5. Kí nìdí tó fi yẹ ká ṣètò ara wa dáadáa bá a ti ń lépa àtiṣe ìfẹ́ Ọlọ́run? Sọ ìrírí kan.
5 Ká tó lè ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run láṣeyọrí, a tún ní láti ṣètò ara wa dáadáa. A ò ní máa tọrùn bọ gbèsè, èyí tó lè sọ wá di ẹrú ètò nǹkan ìsinsìnyí tí yóò sì dín òmìnira tá a ní láti ṣiṣẹ́ Ọlọ́run kù. Bíbélì rán wa létí pé: ‘Ayá-nǹkan ni ìránṣẹ́ awínni.’ (Òwe 22:7) Gbígbọ́kàn wa lé Jèhófà àti fífi iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ sí ipò àkọ́kọ́ yóò jẹ́ ká mọ àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù. Bí àpẹẹrẹ, arákùnrin kan tó ń jẹ́ Guoming àtàwọn ọmọ ìyá rẹ̀ méjì tí wọ́n jẹ́ obìnrin jọ ń gbé pẹ̀lú màmá wọn ní àgbègbè kan tówó ilé ti wọ́n gan-an tí kò sì rọrùn láti ríṣẹ́. Àmọ́ nípa ṣíṣọ́ owó ná, tí gbogbo wọn sì ń pawọ́ pọ̀ pín bùkátà ìdílé wọn gbé, wọ́n ní àwọn ohun tó pọn dandan, kódà nígbà táwọn kan lára wọn ò níṣẹ́ lọ́wọ́ pàápàá. Guoming sọ pé: “Nígbà míì, gbogbo wa kọ́ là ń ṣiṣẹ́. Síbẹ̀, ó ṣeé ṣe fún wa láti máa bá iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà lọ bẹ́ẹ̀ la sì tún ń tọ́jú màmá wa dáadáa. Inú wa dùn gan-an pé màmá wa ò sọ pé ká fi àwọn nǹkan tẹ̀mí tá à ń lé sílẹ̀ ká bàa lè máa pèsè àwọn ohun amáyédẹrùn fóun.”—2 Kọ́ríńtì 12:14; Hébérù 13:5.
6. Àpẹẹrẹ wo ló jẹ́ ká rí i bá a ṣe lè mú ìgbésí ayé wa bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu?
6 Bọ́wọ́ rẹ bá dí gan-an nínú àwọn nǹkan tí kò ní í ṣe pẹ̀lú ìjọsìn Ọlọ́run, bóyá lẹ́nu wíwá owó tàbí àwọn nǹkan mìíràn, o lè ní láti ṣe àwọn ìyípadà ńlá kó o bàa lè fi ohun tó jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run ṣáájú. Irú àwọn ìyípadà yìí kò lè ṣẹlẹ̀ lọ́sàn-án kan òru kan. Tó o bá sì ń ṣàṣìṣe nígbà tó o bá kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àwọn ìyípadà yìí, má ṣe rò pé kò lè ṣeé ṣe. Ìwọ wo arákùnrin kan tó ń jẹ́ Koichi, tó jẹ́ pé eré ìnàjú ló máa ń lo gbogbo àkókò rẹ̀ fún tẹ́lẹ̀. Nígbà tí Koichi wà lọ́dọ̀ọ́ ló ti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àmọ́ ọ̀pọ̀ ọdún ló fi jẹ́ pé kò lóhun méjì tó ń fi ìgbésí ayé rẹ̀ ṣe ju eré orí kọ̀ǹpútà lọ. Lọ́jọ́ kan, Koichi bá ara rẹ̀ sọ̀rọ̀, ó ní: ‘Kí ni mò ń fayé mi ṣe ná? Mo ti lé lọ́mọ ọgbọ̀n ọdún àmọ́ mi ò ní nǹkan gúnmọ́ kan tí mò ń fìgbésí ayé mi ṣe!’ Bí Koichi tún ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìyẹn ó sì gbà kí ìjọ ran òun lọ́wọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn fún un láti yí padà, síbẹ̀ kò jáwọ́. Ó gbàdúrà gan-an, àwọn mìíràn sì tún fún un níṣìírí, bó ṣe bọ́ lọ́wọ́ eré orí kọ̀ǹpútà tó ti di bárakú fún un nìyẹn. (Lúùkù 11:9) Koichi ti di ìránṣẹ́ ìṣẹ́ òjíṣẹ́ báyìí, ó sì láyọ̀.
Má Ṣe Jẹ́ Kí Ọ̀kan Pa Òmíràn Lára
7. Bá a ti ń ṣiṣẹ́ Ọlọ́run, kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa ṣe ju agbára wa lọ?
7 Gbogbo ọkàn wa ló yẹ ká fi ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Kò yẹ ká máa fi ọwọ́ yọ̀bọ́kẹ́ ṣe iṣẹ́ ìsìn wa sí Ọlọ́run tàbí ká máa ṣọ̀lẹ. (Hébérù 6:11, 12) Síbẹ̀ Jèhófà kò fẹ́ ká lo ara wa yọ́, débi táá fi rẹ̀ wá tẹnutẹnu, tọ́kàn wa á pò pọ̀, tá ò sì ní lè ronú dáadáa. Tá a bá gbà tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ pé a kò lè ṣe iṣẹ́ Ọlọ́run ní agbára tiwa fúnra wa, èyí á fògo fún un, á sì tún fi hàn pé a mọ̀wọ̀n ara wa. (1 Pétérù 4:11) Jèhófà ṣèlérí pé òun á fún wa ní okun tá a nílò láti ṣe ìfẹ́ òun, àmọ́ a ò gbọ́dọ̀ máa ṣe ju agbára wa lọ, ká wá máa tiraka láti ṣe ohun tí kò retí pé ká ṣe. (2 Kọ́ríńtì 4:7) Tá a bá fẹ́ máa ṣiṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run nìṣó láìlo ara wa lálòyọ́, ó pọn dandan ká lo okun wa lọ́nà tó bójú mu.
8. Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà tí ọ̀dọ́ kan tó jẹ́ Kristẹni gbìyànjú láti lo ara rẹ̀ fún iṣẹ́ ayé àti fún Jèhófà, àyípadà wo ló sì ṣe?
8 Bí àpẹẹrẹ, odindi ọdún méjì ni arábìnrin kan tó ń jẹ́ Ji Hye, tó ń gbé ní Ìlà Oòrùn ilẹ̀ Éṣíà, fi ṣe iṣẹ́ kan tó ń gba àkókò àti okun rẹ̀ gan-an síbẹ̀ tó tún ń ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Ó sọ pé: “Mo gbìyànjú láti lo ara mi fún Jèhófà gan-an bẹ́ẹ̀ ni mo tún ń gbìyànjú láti lo ara mi fún iṣẹ́ ayé, àmọ́ oorun wákàtí márùn-ún péré ni mo máa ń sùn lóru. Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, mi ò lè kẹ́kọ̀ọ́ mọ́, mi ò sì fi bẹ́ẹ̀ láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn mi sí Jèhófà.” Kí Ji Hye lè máa ṣe iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ sí Jèhófà pẹ̀lú ‘gbogbo ọkàn-àyà rẹ̀, àti gbogbo ọkàn rẹ̀, àti gbogbo èrò-inú rẹ̀, àti gbogbo okun rẹ̀,’ ó wá iṣẹ́ mìíràn tí kò ní máa tán an lókun. (Máàkù 12:30) Ó sọ pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn tó wà nínú ìdílé mi máa ń sọ fún mi pé kí n wá iṣẹ́ tó máa jẹ́ kí n lówó rẹpẹtẹ, mo gbìyànjú láti fi ìfẹ́ Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́. Owó tó ń wọlé fún mi tó láti ra àwọn ohun tí mo nílò, irú bí aṣọ tó bójú mu. Nígbà tí mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í sùn ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, ara mi yá gágá sí i! Mo láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn mi, àjọṣe àárín èmi àti Jèhófà sì ti dára sí i báyìí. Ohun tó jẹ́ kí èyí rí bẹ́ẹ̀ ni pé mi ò lépa àwọn nǹkan ayé yìí tó ń fani mọ́ra tó sì ń pín ọkàn níyà.”—Oníwàásù 4:6; Mátíù 6:24, 28-30.
9. Báwo ni ìsapá wa ṣe lè nípa lorí àwọn èèyàn tá a lọ ń wàásù fún?
9 Kì í ṣe gbogbo ìránṣẹ́ Ọlọ́run ló lè jẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò-kíkún. Bó bá di dandan kó o máa bá ìṣòro ọjọ́ ogbó yí, tàbí àìsàn, tàbí àwọn ìṣòro mìíràn, mọ̀ dájú pé Jèhófà mọrírì ìṣòtítọ́ rẹ gan-an àti iṣẹ́ ìsìn èyíkéyìí tí ò ń fi gbogbo ọkàn ṣe fún un. (Lúùkù 21:2, 3) Nípa báyìí, kò yẹ kẹ́nì kankan nínú wa fojú kéré ipa tí iṣẹ́ ìsìn wa lè ní lórí àwọn mìíràn, kódà bó tiẹ̀ kéré. Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé a lọ sáwọn ilé kan láti lọ wàásù tí a ò sì rẹ́nì kankan tó fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ wa. Àwọn tó wà nínú ilé náà lè máa sọ̀rọ̀ nípa wíwá tá a wá síbẹ̀ lẹ́yìn tá a bá ti kúrò, fún ọ̀pọ̀ wákàtí tàbí fún ọ̀pọ̀ ọjọ́, kódà níbi tẹ́nì kankan ò ti ṣílẹ̀kùn fún wa! A ò retí pé gbogbo ẹni tó bá gbọ́ ìwàásù ìhìn rere ló máa ṣe ohun tí à ń wàásù rẹ̀, àmọ́ àwọn kan á ṣe bẹ́ẹ̀. (Mátíù 13:19-23) Àwọn mìíràn lè bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ́tí sí wa tí ipò nǹkan nínú ayé tàbí nígbèésí ayé wọn bá yí padà. Ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀, tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, iṣẹ́ Ọlọ́run là ń ṣe yẹn. “Alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run” ni wá.—1 Kọ́ríńtì 3:9.
10. Àwọn àǹfààní wo ni gbogbo àwọn tó wà nínú ìjọ ní?
10 Síwájú sí i, gbogbo wa lè ran àwọn tó wà nínú ìdílé wa lọ́wọ́, àtàwọn arákùnrin àti arábìnrin wa nínú ìjọ. (Gálátíà 6:10) Ipa rere tí à ń ní lórí àwọn mìíràn máa ń lágbára gan-an ó sì máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́ títí lọ. (Oníwàásù 11:1, 6) Táwọn alàgbà àtàwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ bá ń ṣe iṣẹ́ wọn bó ti tọ́ àti bó ti yẹ, wọ́n á túbọ̀ ran àwọn tó wà nínú ìjọ lọ́wọ́ láti ní àjọṣe tó dára tó sì dán mọ́rán pẹ̀lú Jèhófà, èyí á sì mú kí iṣẹ́ ìsìn àwọn Kristẹni máa pọ̀ sí i. Bíbélì mú un dá wa lójú pé tá a bá ń ní ‘púpọ̀ rẹpẹtẹ láti ṣe nínú iṣẹ́ Olúwa,’ òpò wa “kì í ṣe asán.”—1 Kọ́ríńtì 15:58.
Fi Ìgbésí Ayé Rẹ Ṣèfẹ́ Ọlọ́run
11. Yàtọ̀ sí bíbá ìjọ wa ṣiṣẹ́, àwọn àǹfààní mìíràn wo ló tún lè ṣí sílẹ̀?
11 Àwa Kristẹni láyọ̀ pé a wà láàyè, a sì fẹ́ máa fògo fún Ọlọ́run nínú ohun gbogbo tí à ń ṣe. (1 Kọ́ríńtì 10:31) Tá a bá gbájú mọ́ iṣẹ́ wíwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run àti iṣẹ́ kíkọ́ àwọn èèyàn kí wọ́n lè ṣe gbogbo ohun tí Jésù pa láṣẹ, a ó rí ọ̀pọ̀ ọ̀nà tá a lè gbà ṣiṣẹ́ sin Ọlọ́run, a ó sì láyọ̀. (Mátíù 24:14; 28:19, 20) Yàtọ̀ sí bíbá ìjọ wa ṣiṣẹ́, a tún lè ní àǹfààní láti lọ wàásù níbi tó ṣeé ṣe kí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù gan-an, yálà ní ìpínlẹ̀ wa, níbi tí wọ́n ti ń sọ èdè mìíràn, tàbí lórílẹ̀-èdè mìíràn. Àwọn alàgbà àtàwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó kúnjú ìwọ̀n, àmọ́ tí wọn ò tíì ṣègbéyàwó lè lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́, lẹ́yìn náà kí wọ́n lọ sìn láwọn ìjọ tí wọ́n ti nílò àwọn Kristẹni tó lóye, yálà lórílẹ̀-èdè wọn tàbí nílẹ̀ òkèèrè. Àwọn tọkọtaya tí wọ́n wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún lè kúnjú ìwọ̀n láti gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ nílé ẹ̀kọ́ Gílíádì kí wọ́n sì lọ sìn nílẹ̀ òkèèrè. Bẹ́ẹ̀ ni kò sì sígbà kan tá ò nílò àwọn tó ń yọ̀ǹda ara wọn láti ṣe oríṣiríṣi iṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì àti láti kọ́ àwọn ibi tá a ti ń pàdé fún ìjọsìn àtàwọn ẹ̀ka ilé iṣẹ́ wa, títí kan bíbójú tó wọn.
12, 13. (a) Báwo lo ṣe lè yan irú iṣẹ́ ìsìn tó yẹ kó o ṣe? (b) Sọ bí òye téèyàn ti ní lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn kan ṣe lè wúlò lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn mìíràn.
12 Irú iṣẹ́ ìsìn wo ló yẹ kó o ṣe? Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ìránṣẹ́ Jèhófà ni ọ́, tó o sì ti ya ara rẹ sí mímọ́ fún un, jẹ́ kí Jèhófà àti ètò rẹ̀ máa tọ́ ọ sọ́nà. “Ẹ̀mí rere” rẹ̀ á ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣèpinnu tó bójú mu. (Nehemáyà 9:20) Iṣẹ́ ìsìn kan sábà máa ń ṣínà òmíràn sílẹ̀, òye téèyàn sì ti ní lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn kan lè wúlò lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn mìíràn tó bá yá.
13 Bí àpẹẹrẹ, Dennis àti aya rẹ̀ tó ń jẹ́ Jenny, máa ń ṣèrànwọ́ nígbà gbogbo láti kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba. Lẹ́yìn tí ìjì líle kan tí wọ́n pè ní Ìjì Katrina jà ní gúúsù ilẹ̀ Amẹ́ríkà, wọ́n yọ̀ǹda ara wọn láti ṣèrànwọ́ fáwọn tí ìjàǹbá náà kàn. Dennis sọ pé: “A láyọ̀ gan-an nítorí pé a lè lo àwọn ohun tá a ti mọ̀ nígbà tí à ń kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba láti ṣèrànwọ́ fáwọn Kristẹni bíi tiwa. Ìmọrírì táwọn tá a ti ràn lọ́wọ́ máa ń fi hàn máa ń múnú wa dùn gan-an. Èyí tó pọ̀ jù lára àwọn àjọ mìíràn tí wọ́n ń ṣèrànwọ́ fáwọn tó wà nínú ìṣòro kì í sábà bá àwọn èèyàn tún ilé wọn kọ́. Àwọn ilé táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti tún ṣe tàbí tá a ti tún kọ́ lé ní ẹgbẹ̀rún márùn-ún àti ọ̀ọ́dúnrún [5,300], àti ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ Gbọ̀ngàn Ìjọba. Àwọn èèyàn ti kíyè sí èyí, wọ́n sì ti túbọ̀ ń tẹ́tí sí ìwàásù wa.”
14. Kí lo lè ṣe bó bá ń wù ọ́ láti ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún?
14 Ǹjẹ́ ó lè fi iṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún ṣe iṣẹ́ tí wàá máa ṣe nígbèésí ayé rẹ láti fi hàn pé ò ń ṣe ohun tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu? Bó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó dájú pé wàá rí ọ̀pọ̀ ìbùkún. Bí ipò tó o wà báyìí kò bá jẹ́ kí èyí ṣeé ṣe, bóyá o lè ṣe nǹkan kan nípa rẹ̀. Gbàdúrà gẹ́gẹ́ bí Nehemáyà ṣe gbàdúrà nígbà tó ń wù ú gan-an láti ṣe iṣẹ́ ìsìn pàtàkì kan. Ó gbàdúrà pé: “Áà, Jèhófà, jọ̀wọ́, . . . yọ̀ǹda àṣeyọrí sí rere fún ìránṣẹ́ rẹ.” (Nehemáyà 1:11) Lẹ́yìn náà, gbẹ́kẹ̀ lé “Olùgbọ́ àdúrà” kó o sì ṣe ohun tó bá àdúrà rẹ mu. (Sáàmù 65:2) Kí Jèhófà tó lè bù kún ìsapá rẹ láti ṣiṣẹ́ sìn ín dáadáa, o ní láti kọ́kọ́ sapá ná. Tó o bá ti pinnu pé o fẹ́ ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún, rí i pé o mú ìpinnu rẹ ṣẹ. Bí àkókò ti ń lọ, ìrírí rẹ á pọ̀ sí i, ayọ̀ rẹ̀ náà á sì máa pọ̀ sí i.
Ìgbésí Ayé Tó Nítumọ̀ Gan-An
15. (a) Ọ̀nà wo ni bíbá àwọn tó ti ń sin Jèhófà tipẹ́ sọ̀rọ̀ àti kíka ìtàn wọn fi lè ṣe wá láǹfààní? (b) Sọ ìtàn ìgbésí ayé ẹnì kan tó fún ọ níṣìírí gan-an.
15 Àwọn àbájáde wo lo lè máa retí bó o bá ṣe ohun tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu? Bá àwọn tó ti ń sin Jèhófà tipẹ́ sọ̀rọ̀, pàápàá àwọn tó ti lo ọ̀pọ̀ ọdún nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún. Wàá rí i pé wọ́n láyọ̀ gan-an, ìgbésí ayé wọn sì nítumọ̀ gidi! (Òwe 10:22) Wọ́n á sọ fún ọ pé kò sígbà kan rí tí Jèhófà kò ran àwọn lọ́wọ́ láti rí ohun táwọn nílò, àní nígbà tí nǹkan ò rọgbọ pàápàá, ó sì tún pèsè fáwọn kọjá ohun táwọn retí. (Fílípì 4:11-13) Láàárín ọdún 1955 sí ọdún 1961, ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ tẹ àwọn ìtàn ìgbésí ayé irú àwọn olóòótọ́ bẹ́ẹ̀ jáde tẹ̀ léra tẹ̀ léra. Àkòrí àwọn àpilẹ̀kọ náà ni, “Mimu Ete Ti Mo Ni Fun Igbesi-Aiye Mi Ṣẹ.” Látìgbà náà, ọgọ́rọ̀ọ̀rún ìtàn ìgbésí ayé ló ti jáde nínú ìwé ìròyìn yìí. Ìtàn kọ̀ọ̀kan fi hàn pé àwọn èèyàn wọ̀nyí kò fi iṣẹ́ ìwàásù ṣeré bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì láyọ̀ gan-an, èyí sì rán wa létí irú àwọn nǹkan báyìí tó wà nínú ìwé Ìṣe nínú Bíbélì. Tó o bá ń ka irú àwọn ìtàn tó ń mórí ẹni wú yìí, èyí á mú kó o sọ pé, ‘Irú ìgbésí ayé tí mo fẹ́ gbé nìyẹn!’
16. Kí ló ń mú káyé àwa Kristẹni dára gan-an tá a sì ń láyọ̀?
16 Aaron tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ sọ pé: “Nílẹ̀ Áfíríkà, mo máa ń rí àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n ń rìn gbéregbère kiri lórílẹ̀-èdè wọn, tí wọ́n ń wá báyé wọn ṣe máa dára. Ọ̀pọ̀ jù lọ wọn lọwọ́ wọn kì í tẹ ohun tí wọ́n ń wá yìí. Àmọ́ àwa dúpẹ́ ní tiwa, nítorí pé à ń fìgbésí ayé wa ṣe ohun tó jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run nípa wíwàásù ìhìn rere Ìjọba rẹ̀, ọwọ́ wa kò dilẹ̀, ìgbésí ayé wa sì dára gan-an. A ti fojú ara wa rí i pé ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju rírígbà lọ.”—Ìṣe 20:35.
17. Kí nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ fi ìgbésí ayé wa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run lákòókò tá a wà yìí?
17 Ìwọ náà ńkọ́? Kí lò ń fayé rẹ ṣe? Bí kò bá sí àwọn nǹkan gúnmọ́ tí ò ń lé nígbèésí ayé rẹ tó máa jẹ́ kó o gbórúkọ Ọlọ́run ga, kíá làwọn ohun mìíràn tó máa gba àkókò àti okun rẹ yóò rọ́pò wọn. Kí ló dé tí wàá máa fi ìgbésí ayé rẹ tó ṣeyebíye tàfàlà lórí àwọn ohun tí ayé Sátánì kà sí bàbàrà? Tí “ìpọ́njú ńlá” bá bẹ̀rẹ̀ láìpẹ́ sígbà tá a wà yìí, ọrọ̀ àtàwọn ipò pàtàkì nínú ayé kò ní wúlò rárá. Àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà lóhun tó máa ṣe pàtàkì jù lọ. Ẹ ò rí i pé ọpẹ́ la ó máa dá nígbà yẹn pé a lo ara wa fún Ọlọ́run àti fáwọn ẹlòmíràn àti pé a fi gbogbo ìgbésí ayé wa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run!—Mátíù 24:21; Ìṣípayá 7:14, 15.
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí àwọn orúkọ kan padà.
b Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é jáde.
Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?
• Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo iṣẹ́ ìsìn tí à ń ṣe fún un?
• Báwo ni ṣíṣe àwọn ohun tó yẹ ká ṣe àti ṣíṣàì ṣe ju agbára wa lọ yóò ṣe ràn wá lọ́wọ́ láti lo ara wa fún Ọlọ́run àtàwọn ẹlòmíràn?
• Àwọn iṣẹ́ ìsìn wo ló wà tá a lè ṣe?
• Báwo la ṣe lè gbé ìgbésí ayé tó dára gan-an lákòókò yìí?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ká tó lè máa fi gbogbo ọkàn sin Jèhófà títí lọ, ohun kan kò gbọ́dọ̀ pa òmíràn lára
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Onírúurú ẹ̀ka iṣẹ́ ìsìn ló wà