ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w14 9/15 ojú ìwé 28-32
  • Ẹ Máa Rántí Àwọn Tó Ń Ṣe Iṣẹ́ Ìsìn Alákòókò Kíkún

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ Máa Rántí Àwọn Tó Ń Ṣe Iṣẹ́ Ìsìn Alákòókò Kíkún
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ÀWỌN KRISTẸNI ỌGỌ́RÙN-ÚN ỌDÚN KÌÍNÍ
  • ÀWỌN ÒJÍṢẸ́ ALÁKÒÓKÒ KÍKÚN LÓDE ÒNÍ
  • Ẹ MÁA TI ÀWỌN AṢÁÁJÚ-Ọ̀NÀ LẸ́YÌN
  • ÌRÀNWỌ́ TÁ A LÈ ṢE FÁWỌN ALÁBÒÓJÚTÓ ARÌNRÌN-ÀJÒ
  • ÌTÌLẸ́YÌN TÁ A LÈ MÁA ṢE FÁWỌN TÓ Ń SÌN NÍ BẸ́TẸ́LÌ
  • ÌRÀNWỌ́ TÁ A LÈ ṢE FÚN ÀWỌN ÒJÍṢẸ́ TÓ Ń SÌN NÍ ILẸ̀ ÒKÈÈRÈ
  • Àwọn Ọ̀nà Tó O Lè Gbà Mú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Gbòòrò Sí I
    A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà
  • Àwọn Ìbùkún Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Aṣáájú Ọ̀nà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Gbígbé Àwọn Àǹfààní Iṣẹ́ Ìsìn Mímọ́ Gẹ̀gẹ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Máa Báa Lọ Nínú Iṣẹ́-Ìsìn Aṣáájú-Ọ̀nà
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
w14 9/15 ojú ìwé 28-32

Ẹ Máa Rántí Àwọn Tó Ń Ṣe Iṣẹ́ Ìsìn Alákòókò Kíkún

“Láìdabọ̀ ni a ń fi iṣẹ́ ìṣòtítọ́ yín sọ́kàn àti òpò onífẹ̀ẹ́ yín.”—1 TẸS. 1:3.

KÍ NI ÌDÁHÙN RẸ?

  • Àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn wo ló wà ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní? Báwo sì làwọn Kristẹni ṣe ń ran àwọn tó wà nínú iṣẹ́ ìsìn wọ̀nyí lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa gbọ́ bùkátà ara wọn?

  • Iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún wo lo nífẹ̀ẹ́ sí jù lọ?

  • Ìrànlọ́wọ́ wo lo lè ṣe fún ẹnì tó wà nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún?

1. Báwo lọ̀rọ̀ àwọn tó ń sin Jèhófà tọkàntọkàn ṣe rí lára Pọ́ọ̀lù?

ÀPỌ́SÍTÉLÌ PỌ́Ọ̀LÙ rántí àwọn tó ń sa gbogbo ipá wọn káwọn èèyàn lè gbọ́ ìhìn rere. Ó sọ pé: “Láìdabọ̀ ni a ń fi iṣẹ́ ìṣòtítọ́ yín sọ́kàn àti òpò onífẹ̀ẹ́ yín àti ìfaradà yín nítorí ìrètí yín nínú Olúwa wa Jésù Kristi níwájú Ọlọ́run àti Baba wa.” (1 Tẹs. 1:3) Láìsí àní-àní, Jèhófà máa ń rántí iṣẹ́ àṣekára tí gbogbo àwọn tó ń jọ́sìn rẹ̀ tọkàntọkàn ń ṣe, bóyá púpọ̀ tàbí díẹ̀ ni wọ́n lè ṣe torí ipò wọn.—Héb. 6:10.

2. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

2 Ọ̀pọ̀ àwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni, yálà nígbà àtijọ́ tàbí lóde òní ni wọ́n ti yááfì ọ̀pọ̀ nǹkan kí wọ́n lè sin Jèhófà nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ lórí báwọn kan ṣe ṣiṣẹ́ sìn ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní. A tún máa ṣàyẹ̀wò àwọn apá tí iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún pín sí lóde òní àti bá a ṣe lè máa rántí àwọn ẹni ọ̀wọ́n yìí tí wọ́n yọ̀ǹda ara wọn láti sìn láwọn ọ̀nà àkànṣe yìí.

ÀWỌN KRISTẸNI ỌGỌ́RÙN-ÚN ỌDÚN KÌÍNÍ

3, 4. (a) Báwo làwọn kan ṣe ṣiṣẹ́ sìn ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní? (b) Báwo ni wọ́n ṣe ń gbọ́ bùkátà ara wọn?

3 Kò pẹ́ púpọ̀ lẹ́yìn tí Jésù ṣèrìbọmi, ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ kan tó máa kárí ayé. (Lúùkù 3:21-23; 4:14, 15, 43) Lẹ́yìn ikú Jésù, àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ múpò iwájú lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù kí wọ́n lè mú kó gbòòrò síwájú. (Ìṣe 5:42; 6:7) Àwọn Kristẹni kan, irú bíi Fílípì ṣe iṣẹ́ ajíhìnrere àti iṣẹ́ míṣọ́nnárì ní ilẹ̀ Palẹ́sínì. (Ìṣe 8:5, 40; 21:8) Pọ́ọ̀lù àtàwọn míì rìnrìn àjò ọ̀nà tó jìn kí wọ́n lè wàásù fáwọn èèyàn. (Ìṣe 13:2-4; 14:26; 2 Kọ́r. 1:19) Bí àpẹẹrẹ, Sílífánù (tàbí Sílà), Máàkù àti Lúùkù ṣe iṣẹ́ adàwékọ tàbí akọ̀wé. (1 Pét. 5:12) Àwọn arábìnrin pẹ̀lú ti àwọn arákùnrin olóòótọ́ yìí lẹ́yìn nínú iṣẹ́ ìwàásù. (Ìṣe 18:26; Róòmù 16:1, 2) Àwọn ìrírí alárinrin wọn tó wà nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì mú kó gbádùn mọ́ni láti kà, èyí sì fi hàn pé Jèhófà máa ń rántí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sí rere.

4 Báwo làwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún nígbà àtijọ́ ṣe ń gbọ́ bùkátà ara wọn? Nígbà míì, àwọn Kristẹni bíi tiwọn máa ń gbà wọ́n lálejò tàbí kí wọ́n ràn wọ́n lọ́wọ́ láwọn ọ̀nà míì, àmọ́ àwọn òjíṣẹ́ yìí ò béèrè ohunkóhun lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni. (1 Kọ́r. 9:11-15) Ẹnì kọ̀ọ̀kan àtàwọn ìjọ máa ń fínnúfíndọ̀ ràn wọ́n lọ́wọ́. (Ka Ìṣe 16:14, 15; Fílípì 4:15-18.) Bákan náà, Pọ́ọ̀lù àtàwọn alábàáṣiṣẹ́pọ̀ rẹ̀ tí wọ́n jọ rìnrìn àjò máa ń ṣe iṣẹ́ àbọ̀ọ̀ṣẹ́ kí wọ́n lè gbọ́ bùkátà ara wọn.

ÀWỌN ÒJÍṢẸ́ ALÁKÒÓKÒ KÍKÚN LÓDE ÒNÍ

5. Kí ni tọkọtaya kan sọ nípa ìgbé ayé wọn nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún?

5 Lónìí, iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún pín sí onírúurú apá, ọ̀pọ̀ sì ń sa gbogbo ipá wọn nínú iṣẹ́ ìsìn yìí. (Wo àpótí náà, “Àwọn Apá Tí Iṣẹ́ Ìsìn Alákòókò Kíkún Pín Sí.”) Ojú wo ni wọ́n fi ń wo iṣẹ́ ìsìn tí wọ́n yàn láàyò yìí? Ọ̀kan lára ìbéèrè tó o lè bi wọ́n nìyẹn, wàá sì rí i pé ó máa ṣe ẹ́ láǹfààní tó pọ̀ tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀. Wo àpẹẹrẹ kan: Arákùnrin kan tó ti ṣe aṣáájú-ọ̀nà déédéé rí, tó ṣe aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe àti míṣọ́nnárì, tó sì ti sìn ní Bẹ́tẹ́lì nílẹ̀ òkèèrè, sọ pé: “Ọ̀kan lára ìpinnu tó dáa jù lọ tí mo ṣe láyé mi ni bí mo ṣe bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún méjìdínlógún, mi ò mọ èyí tí màá ṣe nínú kí n lọ sí yunifásítì tàbí kí n lọ gbájú mọ́ iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ tàbí kí n ṣe aṣáájú-ọ̀nà. Àwọn ohun tí mo ti rí jẹ́ kí n mọ̀ pé Jèhófà kì í gbàgbé ohun tá a yááfì ká lè ṣe iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ ní kíkún. Mo ti lo gbogbo ẹ̀bùn tí Jèhófà fún mi lónírúurú ọ̀nà, mo sì mọ̀ pé mo lè máà rí ẹ̀bùn náà lò ká ní iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ kan ni mo lọ tara bọ̀.” Ìyàwó rẹ̀ sọ pé: “Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn iṣẹ́ ìsìn náà ló jẹ́ kí n dàgbà nípa tẹ̀mí. Àìmọye ìgbà la ti rọ́wọ́ Jèhófà lára wa bó ṣe ń dáàbò bò wá tó sì ń tọ́ wa sọ́nà. Èyí ò ní rí bẹ́ẹ̀ ká sọ pé bí nǹkan ṣe máa rọ̀ wá lọ́rùn là ń lé kiri. Ojoojúmọ́ ni mò ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé a wà nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún.” Ṣé ìwọ náà fẹ́ ní irú èrò yìí nípa ìgbésí ayé rẹ?

6. Ìdánilójú wo ló yẹ kí gbogbo wa ní nípa ojú tí Jèhófà fi ń wo iṣẹ́ ìsìn wa?

6 Àmọ́ o, àwọn kan ò lè lo gbogbo àkókò wọn lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn báyìí torí ipò tó yí wọn ká. A mọ̀ dájú pé Jèhófà mọrírì gbogbo ìsapá tí wọ́n ń ṣe tọkàntọkàn láti sìn ín. Bí àpẹẹrẹ, ronú nípa àwọn tí Pọ́ọ̀lù dárúkọ wọn nínú Fílémónì 1-3, títí kan gbogbo àwọn ará ìjọ Kólósè. (Kà á.) Pọ́ọ̀lù mọrírì wọn, Jèhófà pẹ̀lú sì mọrírì wọn. Lọ́nà kan náà, Baba wa ọ̀run mọrírì iṣẹ́ ìsìn tó ò ń ṣe. Àmọ́, báwo lo ṣe lè máa ṣètìlẹ́yìn fáwọn tó wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún?

Ẹ MÁA TI ÀWỌN AṢÁÁJÚ-Ọ̀NÀ LẸ́YÌN

7, 8. Kí ni iṣẹ́ àwọn aṣáájú-ọ̀nà, báwo sì làwọn ará ìjọ ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́?

7 Bíi tàwọn ajíhìnrere ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, orísun ìṣírí gidi ni àwọn aṣáájú-ọ̀nà onítara jẹ́ fún ìjọ. Ọ̀pọ̀ ń lo àádọ́rin wákàtí lóṣooṣù lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Báwo lo ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́?

8 Arábìnrin aṣáájú-ọ̀nà kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Shari sọ pé: “Torí bí àwọn aṣáájú-ọ̀nà ṣe máa ń jáde òde ẹ̀rí lójoojúmọ́, ara wọn máa ń le. Síbẹ̀ náà, wọ́n nílò ìṣírí.” (Róòmù 1:11, 12) Arábìnrin kan tó ṣe aṣáájú-ọ̀nà fún ọdún mélòó kan sọ nípa àwọn aṣáájú-ọ̀nà tó wà ní ìjọ rẹ̀ pé: “Wọ́n máa ń ṣiṣẹ́ kára, wọ́n sì láforítì. Táwọn èèyàn bá pè wọ́n wá jẹun, tí wọ́n fún wọn lówó díẹ̀ pé kí wọ́n fi wọ mọ́tò tàbí tí wọ́n ràn wọ́n lọ́wọ́ láwọn ọ̀nà míì, wọ́n máa ń mọrírì rẹ̀ gan-an. Èyí sì máa ń jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé àwọn èèyàn bìkítà nípa wọn.”

9, 10. Kí làwọn kan ṣe kí wọ́n lè ṣèrànwọ́ fáwọn aṣáájú-ọ̀nà tó wà nínú ìjọ wọn?

9 Ṣé wàá ti àwọn aṣáájú-ọ̀nà lẹ́yìn nínú iṣẹ́ ìwàásù? Aṣáájú-ọ̀nà kan tó ń jẹ́ Bobbi pàrọwà pé: “A fẹ́ káwọn ará túbọ̀ máa bá wa jáde láàárín ọ̀sẹ̀.” Aṣáájú-ọ̀nà míì tí wọ́n jọ wà ní ìjọ fi kún un pé: “Ìṣòro ńlá ló máa ń jẹ́ fún wa láti rí àwọn tá a máa bá jáde lọ́wọ́ ọ̀sán.” Arábìnrin kan tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Brooklyn báyìí sọ nípa ìgbà tó ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà, ó sọ tayọ̀tayọ̀ pé: “Arábìnrin kan tó ní mọ́tò sọ fún mi pé, ‘Ìgbàkigbà tó ò bá ti rí ẹni bá jáde, ìwọ ṣáà ti pè mí, màá bá ẹ jáde.’ Ọpẹ́lọpẹ́ arábìnrin yẹn lára mi, ìyẹn jẹ́ kí n lè máa bá iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà nìṣó.” Arábìnrin Shari sọ pé: “Lọ́pọ̀ ìgbà, lẹ́yìn táwọn aṣáájú-ọ̀nà tí kò láya tàbí tí kò lọ́kọ bá ti òde ẹ̀rí dé wọ́n sábà máa ń dá wà. Ẹ lè máa pe àwọn àpọ́n tàbí àwọn tí kò lọ́kọ pé kí wọ́n dara pọ̀ mọ́ yín nígbà ìjọsìn ìdílé lóòrèkóòrè. Tẹ́ ẹ bá ń pè wọ́n sáwọn ìgbòkègbodò míì, èyí á jẹ́ kí ará wọn túbọ̀ máa yá gágá.”

10 Arábìnrin kan tó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ lo àádọ́ta ọdún lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún rántí ìgbà tó ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà pẹ̀lú àwọn arábìnrin míì tí wọn ò tíì lọ́kọ, ó sọ pé: “Àwọn alàgbà wa máa ń ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwa aṣáájú-ọ̀nà ní oṣù mélòó kan síra. Wọ́n máa ń béèrè àlàáfíà wa àti iṣẹ́ wa, wọ́n sì máa ń bi wá bóyá a ní ohunkóhun tó ń jẹ wá lọ́kàn. Ọ̀rọ̀ wa jẹ wọ́n lógún gan-an. Wọ́n máa ń wá sílé wa kí wọ́n lè mọ̀ bóyá ohunkóhun wà táwọn lè ṣe fún wa láti ràn wá lọ́wọ́.” Èyí lè jẹ́ kó o rántí àwọn ọ̀rọ̀ ìmọrírì tí Pọ́ọ̀lù sọ nípa olórí ìdílé kan tó tọ́jú rẹ̀ nílùú Éfésù.—2 Tím. 1:18.

11. Kí ni iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe ní nínú?

11 Àǹfààní ńlá ló jẹ́ fáwọn ìjọ kan láti ní àwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe nínú ìjọ wọn. Ọ̀pọ̀ nínú àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin yìí máa ń lo àádóje [130] wákàtí láti fi wàásù lóṣooṣù. Èyí tó pọ̀ jù nínú àkókò wọn ni wọ́n fi ń wàásù, tí wọ́n sì fi ń bójú tó àwọn nǹkan míì nínú ìjọ, àkókò tí wọ́n fi ń ṣiṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ kò tó nǹkan tàbí kí wọ́n má tiẹ̀ ṣe é rárá. Ẹ̀ka ọ́fíìsì máa ń fún wọn ní owó ìtìlẹ́yìn táṣẹ́rẹ́ tí wọ́n á máa fi gbọ́ bùkátà ara wọn kí wọ́n lè pọkàn pọ̀ sórí iṣẹ́ ìwàásù.

12. Báwo làwọn alàgbà àtàwọn míì ṣe lè ṣèrànwọ́ fáwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe?

12 Báwo la ṣe lè ṣèrànwọ́ fáwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe? Alàgbà kan ní ẹ̀ka ọ́fíìsì wa kan sábà máa ń kàn sí ọ̀pọ̀ nínú àwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe, ó sọ pé: “Ó yẹ káwọn alàgbà máa bá wọn sọ̀rọ̀, kí wọ́n mọ bí nǹkan ṣe ń lọ sí fún wọn, kí wọ́n sì pinnu bí wọ́n ṣe máa ràn wọ́n lọ́wọ́. Àwọn ará kan rò pé àwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe kò nílò ohunkóhun torí pé wọ́n ń gba owó ìtìlẹ́yìn, àmọ́ àwọn ará ìjọ lè ràn wọ́n lọ́wọ́ ní oríṣiríṣi ọ̀nà.” Bíi tàwọn aṣáájú-ọ̀nà déédéé, àwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe náà ń fẹ́ káwọn ará máa bá àwọn jáde òde ẹ̀rí. Ṣé wàá ràn wọ́n lọ́wọ́?

ÌRÀNWỌ́ TÁ A LÈ ṢE FÁWỌN ALÁBÒÓJÚTÓ ARÌNRÌN-ÀJÒ

13, 14. (a) Kí ló yẹ ká máa fi sọ́kàn nípa àwọn alábòójútó àyíká? (b) Kí lo ronú pé o lè ṣe láti fi ṣètìlẹ́yìn fáwọn alábòójútó àyíká?

13 A sábà máa ń wo àwọn alábòójútó àyíká àtàwọn ìyàwó wọn pé wọ́n ní àjọṣe tó gún régé pẹ̀lú Jèhófà àti pé wọ́n lè fàyà rán ìṣòro. Kò sírọ́ ńbẹ̀, síbẹ̀ a lè fún wọn níṣìírí, ká bá wọn jáde òde ẹ̀rí, ká sì pè wọ́n wá bá wa ṣeré ìnàjú tó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì. Kí lẹ lè ṣe tí wọ́n bá ń ṣàìsàn tàbí tí wọ́n wà nílè ìwòsàn, bóyá wọ́n tiẹ̀ fẹ́ ṣe iṣẹ́ abẹ fún wọn tàbí ìtọ́jú míì? Inú wọ́n máa dùn gan-an táwọn ará bá fi hàn pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ wọn, tí wọ́n sì ràn wọ́n lọ́wọ́. A lè fojú inú wo bí “oníṣègùn olùfẹ́ ọ̀wọ́n,” ìyẹn Lúùkù tó kọ ìwé Ìṣe ti ní láti ṣètọ́jú Pọ́ọ̀lù àtàwọn míì tí wọ́n jọ ń rìnrìn àjò.—Kól. 4:14; Ìṣe 20:5–21:18.

14 Àwọn alábòójútó àyíká àtàwọn ìyàwó wọn nílò ọ̀rẹ́ tó máa sún mọ́ wọn, wọ́n sì máa ń mọyì àwọn ọ̀rẹ́ yìí. Alábòójútó àyíká kan sọ pé: “Àfi bíi pé àwọn ọ̀rẹ́ mi máa ń mọ̀ pé mo nílò ìṣírí. Wọ́n máa ń bi mí láwọn ìbéèrè tó fi hàn pé ọ̀rọ̀ mi jẹ wọ́n lógún, èyí sì máa ń jẹ́ kí n sọ ohun tó ń jẹ mí lọ́kàn fún wọn. Pé wọ́n tiẹ̀ máa ń fara balẹ̀ tẹ́tí gbọ́ mi lásán, nǹkan ńlá ni wọ́n ń ṣe fún mi.” Àwọn alábòójútó àyíká àtàwọn ìyàwó wọn máa ń mọrírì báwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin ṣe máa ń fi hàn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ wọn.

ÌTÌLẸ́YÌN TÁ A LÈ MÁA ṢE FÁWỌN TÓ Ń SÌN NÍ BẸ́TẸ́LÌ

15, 16. Iṣẹ́ wo làwọn ìdílé Bẹ́tẹ́lì àtàwọn tó ń sìn ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ ń ṣe, báwo la sì ṣe lè tì wọ́n lẹ́yìn?

15 Àwọn tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì àtàwọn tó ń sìn láwọn Gbọ̀ngàn Àpéjọ kárí ayé ń ṣètìlẹ́yìn pàtàkì fún iṣẹ́ Ìjọba náà láwọn orílẹ̀-èdè tó wà lábẹ́ àbójútó ẹ̀ka ọ́fíìsì wọn. Tí àwọn tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì bá wà ní ìjọ rẹ tàbí ní àyíká rẹ, báwo lo ṣe lè fi hàn pé ò ń rántí wọn?

16 Nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ dé Bẹ́tẹ́lì, àárò ilé lè máa sọ wọ́n torí pé ọ̀nà wọn ti jìn sáwọn ìdílé wọn àtàwọn ọ̀rẹ́ wọn. Ẹ wo bínú wọn ṣe máa dùn tó táwọn tí wọ́n jọ wà ní Bẹ́tẹ́lì àtàwọn ará ìjọ wọn tuntun bá mú wọn lọ́rẹ̀ẹ́! (Máàkù 10:29, 30) Iṣẹ́ tí àwọn ìdílé Bẹ́tẹ́lì ń ṣe máa ń fún wọn láyè láti lọ sí ìpàdé, kí wọ́n sì máa lọ sí òde ẹ̀rí lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Àmọ́ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àwọn tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì máa ń ṣe àwọn àfikún iṣẹ́. Tọ̀túntòsì ló máa ṣe láǹfààní táwọn ará ìjọ bá lóye èyí, tí wọ́n sì fi hàn pé wọ́n mọyì àwọn tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì àti iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe.—Ka 1 Tẹsalóníkà 2:9.

ÌRÀNWỌ́ TÁ A LÈ ṢE FÚN ÀWỌN ÒJÍṢẸ́ TÓ Ń SÌN NÍ ILẸ̀ ÒKÈÈRÈ

17, 18. Àwọn apá wo ni iṣẹ́ àwọn tó ń sìn nílẹ̀ òkèèrè pín sí?

17 Àwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún kan máa ń gbà láti lọ sìn ní orílẹ̀-èdè míì. Wọ́n lè bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ oúnjẹ tó yàtọ̀ sí èyí tí wọ́n ń jẹ tẹ́lẹ̀, wọ́n lè kọ́ èdè àti àṣà tuntun àtàwọn ipò míì tó yàtọ̀ sáwọn èyí tó ti mọ́ wọn lára tẹ́lẹ̀. Kí nìdí tí wọ́n fi gbà láti ṣe àwọn àyípadà yìí bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn?

18 Àwọn kan lára wọ́n jẹ́ míṣọ́nnárì tí ètò Ọlọ́run rán lọ sí pápá láti máa wàásù láwọn ibi tí ọ̀pọ̀ á ti jàǹfààní nínú ìdálẹ́kọ̀ọ́ àkànṣe tí wọ́n ti gbà. Ẹ̀ka ọ́fíìsì pèsè ilé tó mọ níwọ̀n àti owó táṣẹ́rẹ́ tí wọ́n á fi gbọ́ bùkátà ara wọn. Àwọn míì nínú wọn ń sìn ní ẹ̀ka ọ́fíìsì ní ilẹ̀ òkèèrè tàbí kí wọ́n ṣèrànwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìkọ́lé, irú bí àwọn ilé tá à ń lò fún ẹ̀ka ọ́fíìsì, ọ́fíìsì àwọn atúmọ̀ èdè, Gbọ̀ngàn Àpéjọ títí kan Gbọ̀ngàn Ìjọba. Ètò Ọlọ́run ń pèsè oúnjẹ fún wọn, ilé tó mọ níwọ̀n àtàwọn nǹkan míì tí wọ́n nílò. Bíi táwọn tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì, wọ́n máa ń lọ sípàdé déédéé, wọ́n sì máa ń wàásù. Ìbùkún ni wọ́n jẹ́ fáwọn ará.

19. Kí ló yẹ ká fi sọ́kàn nípa àwọn tó ń sín ní ilẹ̀ òkèèrè?

19 Báwo lo ṣe lè máa rántí irú àwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún yìí? Lákọ̀ọ́kọ́ ná, rántí pé oúnjẹ tí wọ́n á máa jẹ ní ilẹ̀ tí wọ́n bá ti ń sìn lè máà kọ́kọ́ mọ́ wọn lára. Torí náà, fi èyí sọ́kàn tó o bá pè wọ́n kí wọ́n wá jẹun nílé rẹ. O lè béèrè irú oúnjẹ tí wọ́n máa jẹ tàbí oúnjẹ ilẹ̀ yín tí wọ́n á fẹ́ tọ́ wò. Ó lè gbà wọ́n lákòókò díẹ̀ kí wọ́n tó kọ́ èdè àti àṣà ìbílẹ̀ yín. Torí náà, máa ṣe sùúrù fún wọn, kó o sì máa kọ́ wọn bí wọ́n á ṣe máa pe àwọn gbólóhùn èdè yín. Wọ́n fẹ́ kọ́ ọ̀pọ̀ nǹkan!

20. Ọ̀nà pàtàkì wo la lè gbà rántí àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún àtàwọn òbí wọn?

20 Bí ọdún ti ń gorí ọdún, àwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún yìí ń dàgbà sí i lọ́jọ́ òrí, bẹ́ẹ̀ làwọn òbí wọn ń dàgbà sí i. Táwọn òbí wọn bá jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó ṣeé ṣe kínú àwọn òbí náà dùn bí ọmọ wọn ṣe wà nínú iṣẹ́ ìsìn. (3 Jòh. 4) Òótọ́ ni pé àwọn tó wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn máa sa gbogbo ipá wọn láti tọ́jú àwọn òbí wọn, wọ́n á sì lọ máa wò wọ́n déédéé. Síbẹ̀, táwọn ọmọ tó wà nílé bá wà lárọ̀ọ́wọ́tó láti tọ́jú àwọn òbí wọn, wọ́n á mú nǹkan rọrùn fáwọn tó wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Ẹ má gbàgbé pé àwọn tó wà nínú iṣẹ́ ìsìn ní iṣẹ́ pàtàkì tí wọ́n ń ṣe. Wọ́n ń kọ́wọ́ ti iṣẹ́ ìwàásù tó jẹ́ iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ láyé lónìí. (Mát. 28:19, 20) Ǹjẹ́ ìwọ tàbí ìjọ rẹ lè ṣèrànwọ́ tí àwọn òbí àwọn tó wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn bá nílò ìrànlọ́wọ́?

21. Báwo ni ìrànlọ́wọ́ àti ìṣírí táwọn tó ń ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún ń rí gbà ṣe máa ń rí lára wọn?

21 Àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún kò ṣe é torí kí wọ́n lè dolówó, àmọ́ torí pé wọ́n fẹ́ sin Jèhófà, wọ́n sì fẹ́ ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Wọ́n mọrírì ìrànlọ́wọ́ èyíkéyìí tó o bá ṣe fún wọn. Arábìnrin kan tó ń sìn ní ilẹ̀ òkèèrè sọ bí nǹkan ṣe rí lára rẹ̀ àti lára àwọn míì tó wà nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún, ó sọ pé: “Kódà ọ̀rọ̀ ìdúpẹ́ táwọn èèyàn kọ láti fi mọrírì iṣẹ́ wa máa ń jẹ́ ká mọ̀ pé wọn ò gbàgbé wa àti pé inú wọn dùn sí iṣẹ́ tá à ń ṣe.”

22. Kí lèrò rẹ nípa iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún?

22 Iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún ni ọ̀nà tó ṣàǹfààní jù lọ téèyàn lè fi lo ìgbésí ayé rẹ̀. Iṣẹ́ tó gba kéèyàn ṣiṣẹ́ kára ni, èèyàn á kọ́ ọ̀pọ̀ nǹkan, ó sì ń fúnni láyọ̀. Bákan náà, ó ń múra wa sílẹ̀ de iṣẹ́ ìsìn aláyọ̀ tí gbogbo àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà á máa ṣe títí láé nínú Ìjọba Ọlọ́run. Ǹjẹ́ kí gbogbo wa máa ‘fi iṣẹ́ ìṣòtítọ́ àti òpò onífẹ̀ẹ́’ àwọn tó wà nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún sọ́kàn nígbà gbogbo.—1 Tẹs. 1:3.

Àwọn Apá Tí Iṣẹ́ Ìsìn Alákòókò Kíkún Pín Sí

  • Àwọn aṣáájú-ọ̀nà déédéé sábà máa ń lo àádọ́rin [70] wákátì lóṣooṣù nínu iṣẹ́ ìwàásù. Wọ́n máa ń sìn ní ìjọ wọn tàbí láwọn ìjọ tí àìní pọ̀ sí ní orílẹ̀-èdè wọn.

  • Àwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe sábà máa ń fi àádóje [130] wákàtí wàásù lóṣooṣù. Wọ́n sábà máa ń sìn láwọn ìjọ tí àìní ibẹ̀ pọ̀ gan-an.

  • Àwọn alábòójútó àyíká máa ń bẹ àwọn ìjọ wo. Wọ́n ń múpò iwájú nínú iṣẹ́ ìwàásù, wọ́n sì máa ń ṣèrànwọ́ fún ìjọ lóríṣiríṣi ọ̀nà.

  • Àwọn ìdílé Bẹ́tẹ́lì máa ń sìn ní ẹ̀ka ọ́fíìsì tàbí ọ́fíìsì àwọn atúmọ̀ èdè. Wọ́n ń tẹ àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́, wọ́n sì ń fún àwọn ará ní ìtọ́sọ́nà láwọn orílẹ̀-èdè tí ẹ̀ka ọ́fíìsì wọn ń bojú tó.

  • Àwọn míṣọ́nárì sábà máa ń lọ sìn ní ilẹ̀ òkèèrè. Ọ̀pọ̀ míṣọ́nárì máa ń fi àádóje [130] wákàtí wàásù lóṣooṣù.

  • Àwọn òṣìṣẹ́ káyé máa ń lọ sí onírúurú orílẹ̀-èdè láti kọ́ àwọn ilé tá à ń lò fún ẹ̀ka ọ́fíìsì, ọ́fíìsì àwọn atúmọ̀ èdè, Gbọ̀ngàn Àpéjọ àti Gbọ̀ngàn Ìjọba.

  • Àwọn òṣìṣẹ́ tó ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba ti gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ lórí iṣẹ́ ìkọ́lé. Wọ́n máa ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba àtàwọn ilé míì tá à ń lò fún ìjọsìn ní orílẹ̀-èdè wọn àti láwọn orílẹ̀-èdè tí ẹ̀ka ọ́fíìsì wọn ń bojú tó.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́