Máa Báa Lọ Nínú Iṣẹ́-Ìsìn Aṣáájú-Ọ̀nà
NǸKAN bíi okòólérúgba ọ̀kẹ́ ó lé márùn-ún àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni wọ́n ń kéde ìhìnrere náà jákèjádò ayé. Lára wọn ni iye tí ó ju ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, tàbí àwọn olùpòkìkí Ìjọba alákòókò kíkún wà. Àwọn wọnnì tí wọ́n wà nínú ọmọ-ogun ti aṣáájú-ọ̀nà yìí ní ọjọ́ orí wọn yàtọ̀síra láti orí àwọn tí wọn kò tíì di ọ̀dọ́langba dé orí àwọn tí wọ́n ti fẹ̀yìntì lẹ́nu iṣẹ́ tí wọ́n jẹ́ ẹni àádọ́rùn-ún ọdún ó lé. Wọ́n wá láti apá ibi gbogbo nínú ayé pẹ̀lú onírúurú ipò àtilẹ̀wá.
Láìsí àníàní, gbogbo àwọn oníwàásù alákòókò kíkún wọ̀nyí fẹ́ láti kẹ́sẹjárí nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Púpọ̀ dàníyànfẹ́ láti fi í ṣe iṣẹ́ ìgbésí-ayé wọn. Àwọn kan kò lè ṣe bẹ́ẹ̀ fún àwọn ìdí kan pàtó. Síbẹ̀, ó ti ṣeéṣe fún àwọn mìíràn láti máa bá ṣíṣe aṣáájú-ọ̀nà lọ lójú àwọn ìṣòro ìnáwó, àìlera, ìrẹ̀wẹ̀sì, àti àwọn ìṣòro mìíràn. Nítorí náà báwo ni àwọn oníwàásù alákòókò kíkún ṣe lè kojú irú àwọn ìṣòro bẹ́ẹ̀ kí wọ́n sì máa báa lọ nínú iṣẹ́-ìsìn aṣáájú-ọ̀nà?
Kíkájú Àwọn Àìní ti Ìnáwó
Lákòópọ̀, àwọn aṣáájú-ọ̀nà ń ṣiṣẹ́ oúnjẹ-òòjọ́ láti kájú àwọn ìnáwó wọn, gẹ́gẹ́ bí aposteli Paulu ti ṣe. (1 Tessalonika 2:9) Ní apá ibi púpọ̀ jùlọ ní ayé, wọ́n dojukọ iye-owó ọjà tí ń gasókè fíofío lórí oúnjẹ, aṣọ, ibùgbé, ati ọkọ̀ wíwọ̀. Ó sábà máa ń ṣòro láti rí iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ aláàbọ̀ọ̀ṣẹ́ tí wọ́n nílò. Bí ó bá wà, irú àwọn iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ sábà máa ń mú ìwọ̀nba owó kéréje wá, láìsí àwọn àǹfààní ìbánigbófò ìlera.
Bí a bá ‘ń báa lọ ní kíkọ́kọ́ wá Ìjọba Ọlọrun ati òdodo rẹ̀,’ a lè ní ìgbàgbọ́ pé Jehofa yóò pèsè fún àwọn àìní wa nípa ti ara. Nítorí náà, nígbà tí wọ́n bá wà lábẹ́ ìkìmọ́lẹ̀ níti ìnáwó, àwọn aṣáájú-ọ̀nà kò níláti ‘ṣe àníyàn nítorí ọ̀la.’ (Matteu 6:25-34) Bí wọ́n ti ń sapá kíkankíkan láti yanjú irú àwọn ìṣòro bẹ́ẹ̀, ìgbàgbọ́ alágbára nínú Jehofa yóò gbà wọ́n lọ́wọ́ àníyàn tí kò yẹ.
Nígbà tí àwọn ìṣòro ìnáwó bá dojúkọ ẹnìkan, bóyá ó lè dín ohun tí ó ń rà kù. Pẹ̀lú àwọn ìyípadà díẹ̀ nínú ètò-ìnáwó, ó lè ṣeéṣe láti kájú àwọn àìní, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kìí ṣe kìkì àwọn ohun ti ara tí a fẹ́ nìkan. Láti dín ìnáwó kù, àwọn aṣáájú-ọ̀nà kan ṣàjọpín ilé gbígbé kan pẹ̀lú àwọn Kristian mìíràn. Láti ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti ṣe aṣáájú-ọ̀nà, àwọn òbí nígbà mìíràn a máa pèsè ilé lọ́fẹ̀ẹ́ tàbí ní iye owó tí ó kéré. Àwọn mìíràn ń ṣèrànlọ́wọ́ fún àwọn aṣáájú-ọnà pẹ̀lú owó oúnjẹ ati ọkọ̀ wíwọ̀. Ṣùgbọ́n àwọn aṣáájú-ọ̀nà kì yóò fẹ́ láti jẹ́ ẹrù-ìnira fún àwọn ẹlòmíràn, nítorí pé wọ́n ní ẹrù-iṣẹ́ tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu náà láti bójútó araawọn.—2 Tessalonika 3:10-12.
Owó ọkọ̀ wíwọ̀ ni a lè dínkù nípa ṣíṣàjọpín ìnáwó pẹ̀lú àwọn aṣáájú-ọ̀nà mìíràn. Bí àwọn aṣáájú-ọ̀nà méjì bá ní ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́, wọ́n lè ṣàjọpín papọ̀ nínú iṣẹ́ ìwàásù ní àgbègbè kan-náà, ní lílo ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kan kí wọ́n sì mú ìnáwó lílo ọkọ̀ méjì kúrò. Àwọn aṣáájú-ọ̀nà tí wọn kò ní àwọn ohun ìrìnnà ni ó lè ṣeéṣe fún láti darapọ̀ mọ́ àwọn tí wọ́n ní kí wọ́n sì jọ máa pín owó ọkọ̀ wíwọ̀ san. Owó ìrìn-àjò ni a lè dínkù síwájú síi nipa kíkárí àwọn ìpínlẹ̀ tí ó súnmọ́tòsí ní pàtàkì nípa fifi ẹsẹ̀ rìn. Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè àwọn aṣáájú-ọ̀nà ń lo ìpèsè ọkọ̀ wíwọ̀ ti gbogbogbòò tí ń dín ìnáwó kù.
Lára àwọn tí wọ́n borí ìṣòro ìnáwó tí wọ́n sì wà pẹ́ títí nínú iṣẹ́-ìsìn alákòókò kíkún ni Newton Cantwell àti aya rẹ̀. Wọ́n ta oko wọn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà pẹ̀lú mẹ́fà lára àwọn ọmọ wọn méje ní 1932, lákòókò Ìlọsílẹ̀ Ètò Ọrọ̀ Ajé Ńlá náà. “Kò pẹ́ tí a fi ná gbogbo ohun tí a rí gbà nínu àwọn ohun tí a rí láti inú oko tán—a ná èyí tí ó pọ̀ jùlọ sórí ìtọ́jú láti ọ̀dọ̀ dókítà,” ni Arákùnrin Cantwell sọ. “A rántí pé nígbà tí a ṣí lọ sí ibi iṣẹ́ àyànfúnni wa èkejì, a wulẹ̀ ní èyí tí ó pọ̀ tó láti san àsansílẹ̀ owó-ilé fún ọ̀sẹ̀ méjì, tí ó sì sẹ́ku owó dollar márùn-ún. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, a mọ̀ pé Jehofa yóò pèsè níwọ̀n bí a bá ti fi taápọntaápọn ṣe iṣẹ́-ìsìn wa. . . . A kọ́ láti ṣọ́ nǹkan lò ní onírúurú ọ̀nà. Nígbà tí a bá ṣí lọ sí àgbègbè ìpínlẹ̀ titun kan, fún àpẹẹrẹ, èmi yóò bá díẹ̀ lára àwọn tí wọ́n ni ilé-epo mọ́tò sọ̀rọ̀ èmi yóò sì ṣàlàyé pé a ń lo ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ mẹ́ta lójoojúmọ́ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú iṣẹ́ Kristian wa. Èyí sábà máa ń yọrísí gbígba epo mọ́tò ní ẹ̀dínwó. Kò sì pẹ́ náà tí àwọn ọmọ wa fi mọ bí a tií ṣàtúnṣe àwọn ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ wa, èyí sì ń dín wa lówó ìtọ́kọ̀ṣe púpọ̀ kù.” Ìdílé Cantwell tipa báyìí kẹ́sẹjárí nínú kíkojú àwọn ìpèníjà ìṣúnná-owó pẹ̀lú àṣeyọrísírere wọ́n sì wà pẹ́ títí nínú iṣẹ́-ìsìn alákòókò kíkún. Arákùnrin Cantwell ṣì wà nínú àkọsílẹ̀ àwọn aṣáájú-ọ̀nà nígbà tí ó kú ní ẹni ọdún 103.
Rírí Iṣẹ́ Ààbọ̀ọ̀ṣẹ́ Gbà
Púpọ̀ àwọn aṣáájú-ọ̀nà ń ṣètìlẹ́yìn fún araawọn níti ọ̀ràn ìnáwó nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ ààbọ̀ọ̀ṣẹ́. Láti bọ́ araarẹ̀ nínu iṣẹ́-òjíṣẹ́ náà ní Korinti, Paulu ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olùpàgọ́ kan papọ̀ pẹ̀lú àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ Akuila àti Priskilla. (Iṣe 18:1-11) Lónìí, àwọn arákùnrin nípa tẹ̀mí sábà máa ń láyọ̀ láti fún àwọn aṣáájú-ọ̀nà ní iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ aláàbọ̀ àkókò. Àwọn aṣáájú-ọ̀nà mìíràn gba irú àwọn iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ nípasẹ̀ àwọn ilé-iṣẹ́ aṣojú fún ìgbanisísẹ́ tí ń fúnni ní àwọn iṣẹ́ alákòókò kúkúrú. Ìgbàgbọ́ nínú Ọlọrun ṣekókó, bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú sì ni àdúrà onífọkànsí fún ìtọ́sọ́nà rẹ̀ ní ṣíṣe àwọn ìpinnu iṣẹ́.—Owe 15:29.
“Lẹ́yìn gbígba okun púpọ̀ láti inú ìgbéyẹ̀wò tí a ṣe tàdúràtàdúrà,” ni aṣáájú-ọ̀nà kan sọ, “mo fi tó alábòójútó iṣẹ́ mi létí pé iṣẹ́-òjíṣẹ́ mi jẹ́ ẹrù-iṣẹ́ ara-ẹni ṣíṣepàtàkì kan àti pé èmi kì yóò lè gba ipò-iṣẹ́ alákòókò kíkún náà. Ní ọjọ́ Wednesday tí ó tẹ̀lé e, wọ́n bi mí léèrè bí èmi yóò bá tún ronú wò lórí iṣẹ́ náà ṣùgbọ́n láti máa fi apákan àkókò ṣe é. Mo gbà pẹ̀lú ìdùnnú.” Máṣe fojú bu agbára àdúrà kù, kí o sì gbe àdúrà rẹ lẹ́yìn pẹ̀lú iṣẹ́.
Àwọn aṣáájú-ọ̀nà lè ri pé ó yẹ ní ṣíṣe láti sọ fún àwọn tí wọn yóò wá jẹ́ agbanisíṣẹ́ wọn pé ète wọn ní wíwá iṣẹ́ ààbọ̀ọ̀ṣẹ́ ni láti lè bọ́ araawọn nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ náà. Wọ́n lè mẹ́nukan àwọn ọjọ́ tí wọn yóò wà lárọ̀ọ́wọ́tó àti iye wákàtí tí wọ́n lè fi sílẹ̀ fún iṣẹ́ kan lọ́sẹ̀. Ó ṣeéṣe fún àwọn arábìnrin tẹ̀gbọ́ntàbúrò méjì kan láti pín iṣẹ́ alákòókò kíkún láàárín araawọn ní ilé iṣẹ́ kan tí ń gbaninímọ̀ràn nípa òfin, èyí tí ó mú kí ó ṣeéṣe fún ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn láti ṣiṣẹ́ fún ọjọ́ méjì àti ààbọ̀ ní ọ̀sẹ̀ kan. Èyí ń bọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà títí fi di ìgbà tí wọ́n lọ sí Watchtower Bible School of Gilead tí wọ́n sì gba àwọn iṣẹ́ àyànfúnni miṣọ́nnárì.
Onírúurú àwọn iṣẹ́ tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu ni a lè rí nípa bíbá àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa àti àwọn mìíràn sọ̀rọ̀ tàbí nípa wíwo àwọn ìkéde ìwé ìròyìn. Ìrẹ̀lẹ̀ ń ṣèrànwọ́, nítorí pé ó lè mú kí àwọn aṣáájú-ọ̀nà yẹra fún jíjẹ́ ẹni tí ń yangàn jù nípa irú iṣẹ́ tí wọn yóò ṣe. (Fiwé Jakọbu 4:10.) Láti máa bá ṣíṣe aṣáájú-ọ̀nà lọ wọ́n lè ní láti ṣe iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ tí àwọn ènìyàn kan kà sí èyí tí ó rẹlẹ̀ tàbí tí kò níláárí. Bí a bá gba irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ ṣùgbọ́n tí ó jẹ́ pé ohun kan tí ó yàtọ̀ ni a ní ìfẹ́-ọkàn fún, ìyípadà nínú iṣẹ́ lè ṣeéṣe ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀.
Àìlera àti Ìrẹ̀wẹ̀sì
Àwọn kan gbọ́dọ̀ dá iṣẹ́-ìsìn aṣáájú-ọ̀nà wọn dúró nítorí àwọn ìṣòro ìlera lílekoko. Bí ó ti wù kí ó rí, bí àwọn aṣáájú-ọ̀nà kò bá kánjú jù nípa èyí, wọ́n lè ríi pé òkùnrùn kan lè lọ tàbí kí ìlera wọn túbọ̀ sàn dáradára tó fún wọn láti máa bá ṣíṣe aṣáájú-ọ̀nà lọ. Ọ̀pọ̀ lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà láìka àwọn ìṣòro ìlera sí nítorí pé wọ́n rí ìtọ́jú ìṣègùn gbà, daradé irú oúnjẹ kan tí ó dára fún wọn, tí wọ́n sì ní ìsinmi àti ìdárayá tí wọ́n nílò. Alábòójútó arìnrìn-àjò kan ṣàkíyèsí arábìnrin aṣáájú-ọ̀nà kan tí àrùn oríkèé-ríroni ń yọlẹ́nu débi pé ó nílò ìrànlọ́wọ́ láti rìn láti ilé dé ilé nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ náà. (Iṣe 20:20) Síbẹ̀, òun àti ọkọ rẹ̀ ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli mẹ́tàlélọ́gbọ̀n wọ́n sì ti ran ènìyàn mẹ́tàlélọ́gọ́rin lọ́wọ́ láti gba òtítọ́ Ọlọrun. Ìlera rẹ̀ sunwọ̀n síi bí àkókò ti ń lọ, ó sì lọ sí Ilé-Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́-Ìsìn Aṣáájú-Ọ̀nà ní ọdún mọ́kànlá lẹ́yìn náà.
Ìrẹ̀wẹ̀sì lè mú kí àwọn kan fi iṣẹ́-òjíṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà sílẹ̀. (Owe 24:10) Aṣáájú-ọ̀nà kan sọ fún alábòójútó arìnrìn-àjò kan pé: “Èmi yóò dáwọ́ ṣíṣe aṣáájú-ọ̀nà dúró. . . . Mo ní àwọn gbèsè láti san.” Ó nílò awò-ojú tí iye-owó rẹ̀ jẹ́ ogún owó dollar. “Ìwọ yóò ha jáwọ́ nínú ṣíṣe aṣáájú-ọ̀nà nítorí pé o nílò ogún owó dollar bí?” ni alábòójútó náà béèrè. A dámọ̀ràn pé kí aṣáájú-ọ̀nà náà ṣiṣẹ́ ní oko kọfí àdúgbò náà fún ọjọ́ kan, kí ó rí ogún owó dollar náà gbà, kí ó ra awò-ojú náà, kí ó sì máa tẹ̀síwájú nínú ṣíṣe aṣáájú-ọ̀nà. Ìjíròrò síwájú síi fihàn pé ìṣòro náà níti gidi jẹ́ ìrẹ̀wẹ̀sì lórí àtúnṣe ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tí ó gbówólórí. A dámọ̀ràn pé kí aṣáájú-ọ̀nà náà dín ìnáwó kù nípa wíwakọ̀ lójoojúmọ́ láyìíká ìwọ̀nba kìlómítà dípò lílọ sí ọ̀nà jíjìn. A tún gbà á nímọ̀ràn láti di ipò tẹ̀mí rẹ̀ mú. Aṣáájú-ọ̀nà náà fi ìmọ̀ràn náà sílò àti oṣù mẹ́fà lẹ́yìn náà ó rí ìkésíni rẹ̀ gbà láti wá sí Ilé-Ẹ̀kọ́ Gileadi. Lẹ́yìn ìkẹ́kọ̀ọ́yege a yan iṣẹ́ fún un ní orílẹ̀-èdè òkèèrè ó sì ṣiṣẹ́sìn níbẹ̀ pẹ̀lú ìṣòtítọ́ fún ọ̀pọ̀ ọdún títí fi di ìgbà ikú rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ni, àwọn ìbùkún ńláǹlà sábà máa ń jẹyọ bí a kò bá juwọ́sílẹ̀ fún ìrẹ̀wẹ̀sì ṣùgbọ́n tí a fi sọ́kàn pé Jehofa wà pẹ̀lú wa.
Ka Àǹfààní Iṣẹ́-Ìsìn Rẹ sí Ìṣúra
Láìka àwọn àdánwò sí, irú bí àwọn ọ̀ràn àìní àti àwọn àkókò láìsí oúnjẹ, Paulu ka iṣẹ́-òjíṣẹ́ rẹ̀ sí ìṣúra. (2 Korinti 4:7; 6:3-6) Lójú ìnira àti ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ lónìí, púpọ̀ lára àwọn ìránṣẹ́ Jehofa ní Africa, Asia, Ìlà-Oòrùn Europe, àti ní àwọn apá ibòmíràn ti di àǹfààní ṣíṣe aṣáájú-ọ̀nà wọn mú. Nítorí náà, nígbà tí o bá dojúkọ àdánwò, sa gbogbo ipá láti máa báa lọ nínú àǹfààní iṣẹ́-ìsìn yìí, sí ìyìn Jehofa.
Ó ṣeéṣe fún ọ̀pọ̀ àwọn aṣáájú-ọ̀nà láti wọnú iṣẹ́ ìwàásù alákòókò kíkún kìkì nítorí pé wọ́n mú ọ̀nà ìgbésí-ayé wọn dẹrùn. Bíi ti Paulu, wọ́n kọjú ìjà sí àwọn ẹ̀tàn ọrọ̀ àlùmọ́nì wọ́n sì mú ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú “oúnjẹ àti aṣọ” dàgbà. Láti máa báa lọ nínù iṣẹ́-ìsìn aṣáájú-ọ̀nà, wọ́n níláti ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú àwọn ohun ṣíṣepàtàkì. (1 Timoteu 6:8) Ayọ̀ ń wá láti inú kíka àwọn àǹfààní tí Ọlọrun fifún wá sí ìṣúra, àti gbígbé wọn ga ju àwọn ohun-ìní ti ara lọ.
Láti ṣàpèjúwe: Anton Koerber ní àǹfààní láti ṣojú àwọn ire Ìjọba fún àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba ní Washington, D.C. Ó ṣiṣẹ́sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà fún àkókò díẹ̀ ó sì jẹ́ alábòójútó àyíká ní àwọn ọdún 1950. Díẹ̀ lára àwọn alábàáṣiṣẹ́ rẹ̀ tẹ́lẹ̀rí kò ó lójú pẹ̀lú ìdámọ̀ràn kan tí yóò mú kí ó lè jèrè million kan owó dollar sápò araarẹ̀. Bí ó ti wù ki ó rí, láti ṣe bẹ́ẹ̀, yóò ti pọndandan fún un láti fi àkókò rẹ̀ sílẹ̀ fún àwọn àlámọ̀rí òwò fún nǹkan bí ọdún kan. Lẹ́yìn gbígbàdúrà fún ìtọ́sọ́nà àti ẹ̀mí èrò-inú yíyèkooro, ó wí pé: “Kò ṣeéṣe fún mi láti fi àwọn àǹfààní àgbàyanu mi ti ṣíṣiṣẹ́sin Jehofa níhìn-ín sílẹ̀ fún àní ọdún kan péré, rárá, kìí ṣe fún gbogbo owó tí ó wà ní ayé. Ṣíṣiṣẹ́sin àwọn arákùnrin mi níhìn-ín ní Washington ṣe iyebíye fún mi jù, àti níhìn-ín mo mọ̀ pé mo ní ìbùkún Jehofa. Láìṣe àníàní èmi yóò jèrè million kan owó dollar, ṣùgbọ́n ní òpin ọdún irú ìgbésí-ayé yẹn, báwo ni èmi yóò ti rí nípa tẹ̀mí, tàbí pàápàá nípa ti ara?” Nítorí náà ó kọ ìpèsè náà. Kíka àwọn àǹfààní wọn sí ìṣúra ní ọ̀nà kan-náà ń ran ọ̀pọ̀lọpọ̀ lọ́wọ́ láti máa báa lọ nínú iṣẹ́-ìsìn aṣáájú-ọ̀nà.
Ẹ wo irú ìbùkún ńláǹlà tí àwọn aṣáájú-ọ̀nà ń gbádùn! Ó jẹ́ ìbùkún láti lo ọ̀pọ̀ wákàtí ní sísọ̀rọ̀ nípa ipò ọba ológo ti Jehofa. (Orin Dafidi 145:11-13) Nítorí yíyọ̀ǹda àkókò tí ó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ fún iṣẹ́-òjíṣẹ́ náà, àwọn aṣáájú-ọ̀nà ní ìbùkún mímú ìtùnú nípa tẹ̀mí wá fún àwọn aláìní ati àwọn tí a ń pọ́n lójú, àwọn aláìsàn tàbí àwọn tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀, àti àwọn mìíràn tí wọ́n ní ìdààmú gidigidi tí wọ́n sì nílò ìrètí tí ó dájú. Nípa bẹ́ẹ̀, bí ipò àyíká bá gbà wá láàyè láti lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù alákòókò kíkún, àwa nítòótọ́ yóò gbádùn ọ̀pọ̀ ìbùkún. “Ìbùkún Oluwa ní í mú ni í là.” (Owe 10:22) Àti pé pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àti ìbùkún rẹ̀ ni ọ̀pọ̀ àwọn olùpòkìkí Ìjọba ṣe ń fi tayọ̀tayọ̀ bá a nìṣó nínú iṣẹ́-ìsìn aṣáájú-ọ̀nà.