Àwọn Ìbùkún Tó Wà Nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Aṣáájú Ọ̀nà
1, 2. Àwọn ìbùkún wo là ń rí gbà nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà, kí sì nìdí tí èyí fi rí bẹ́ẹ̀?
1 Aṣáájú ọ̀nà kan sọ pé: “Mo mọ̀ pé kò sí iṣẹ́ mìíràn tí ó lè mú irú ìtẹ́lọ́rùn tí mo ti rí nínú ṣíṣàjọpín òtítọ́ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn wá fún mi.” Òmíràn sọ pé: “Ní òpin ọjọ́ kọ̀ọ̀kan, oorun mi máa ń dùn, ọkàn mi sì máa ń kún fún ayọ̀.” Àwọn aṣáájú ọ̀nà yìí gbẹnu sọ fún àwọn tí wọ́n ti rí ìbùkún tó wà nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà gbà.—Òwe 10:22.
2 Ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀ tí ń gbẹ̀mí là tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa ń fúnni ní ojúlówó ìtẹ́lọ́rùn. (Ìṣe 20:35; 1 Tẹs. 2:19, 20) Ẹnì kan tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà sọ pé: “Ó ń wúni lórí, ó sì ń fún ìgbàgbọ́ ẹni lókun láti rí bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti lágbára tó ní sísún àwọn ènìyàn láti ṣe ìyípadà nínú ìgbésí ayé wọn.” Ó dájú pé, bí àwọn aṣáájú ọ̀nà bá ń yọ̀ǹda ara wọn láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, tí wọ́n sì ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, yóò ṣeé ṣe fún wọn láti rí àwọn ìbùkún bí èyí gbà.
3, 4. Báwo ní iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà ṣe lè kọ́ni láti gbára lé Jèhófà, báwo lèyí sì ṣe lè ranni lọ́wọ́ láti dàgbà nípa tẹ̀mí?
3 Gbígbára Lé Jèhófà: Bí àwọn aṣáájú ọ̀nà ṣe ń gbára lé ẹ̀mí Ọlọ́run lójoojúmọ́ bí wọ́n ti ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ní “èso ti ẹ̀mí,” ó sì tún jẹ́ ààbò fún wọn. (Gál. 5:16, 22, 23) Láfikún sí i, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ìgbà gbogbo làwọn aṣáájú ọ̀nà ń lo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n sábà máa ń jáfáfá nínú lílo Ìwé Mímọ́ láti gbèjà òtítọ́, wọ́n sì tún ń lò ó láti fún àwọn ẹlòmíràn lókun. (2 Tím. 2:15) Arákùnrin kan tó ti ń ṣe aṣáájú ọ̀nà fún ọ̀pọ̀ ọdún sọ pé: “Iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà ti ràn mí lọ́wọ́ láti jèrè ìmọ̀ jíjinlẹ̀ nínú Bíbélì, [mo sì ti lo ìmọ̀ yìí láti] ran ọ̀pọ̀ ènìyàn lọ́wọ́ láti wá mọ Jèhófà àti àwọn ète rẹ̀.” Àǹfààní ńlá gbáà mà lèyí o!
4 Ó tún yẹ kí àwọn aṣáájú ọ̀nà déédéé gbára lé Jèhófà láwọn ọ̀nà púpọ̀ mìíràn. Bíbùkún tí Jèhófà ń bù kún ìsapá wọn láti gbọ́ bùkátà ara wọn ń fún ìgbàgbọ́ wọn lókun. Ẹni ọdún méjìléláàádọ́rin kan tó ti lo ọdún márùnléláàádọ́ta lẹ́nu iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà sọ pé: “Jèhófà kò já mi kulẹ̀ rí.” Síwájú sí i, bí àwọn aṣáájú ọ̀nà bá lẹ́mìí ohun-moní-tómi, èyí á jẹ́ kí wọ́n bọ́ lọ́wọ́ ọ̀pọ̀ àníyàn ìgbésí ayé. Ǹjẹ́ èyí ò wù ọ́?—Mát. 6:22; Héb. 13:5, 6.
5. Báwo ni iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà ṣe lè ranni lọ́wọ́ láti sún mọ́ Jèhófà?
5 Sísúnmọ́ Ọlọ́run: Àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà ni ohun tó ṣeyebíye jù lọ fún wa. (Sm. 63:3) Nígbà tá a bá ń kópa ní kíkún nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà nítorí ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà, èyí á mú ká túbọ̀ sún mọ́ ọn. (Ják. 4:8) Ẹnì kan tó ti lò ju ọdún méjìdínlógún lẹ́nu iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà sọ pé: “Iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà fún wa láǹfààní láti ‘tọ́ ọ wò, kí a sì rí i pé rere ni Olúwa,’ ní mímú kí a mú ipò ìbátan lílágbára dàgbà pẹ̀lú Ẹlẹ́dàá wa lójoojúmọ́.”— Sm. 34:8.
6. Kí ni àwọn aṣáájú ọ̀nà gbọ́dọ̀ ní, àwọn wo ló sì tún ń jàǹfààní yàtọ̀ sí àwọn aṣáájú ọ̀nà fúnra wọn?
6 Yàtọ̀ sí pé kí ipò tí àwọn aṣáájú ọ̀nà wà yọ̀ǹda fún wọn láti máa bá a nìṣó, wọ́n gbọ́dọ̀ ní ìgbàgbọ́ tó lágbára, kí wọ́n ní ojúlówó ìfẹ́ fún Ọlọ́run àti aládùúgbò, kí wọ́n sì ṣe tán láti fi àwọn nǹkan kan du ara wọn. (Mát. 16:24; 17:20; 22:37-39) Àmọ́ ṣá o, bó ti ń hàn lójú àwọn aṣáájú ọ̀nà níbi gbogbo pé wọ́n ń láyọ̀, ó dájú pé ìbùkún tó wà nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà pọ̀ gan-an ní ìfiwéra. (Mál. 3:10) Àwọn aṣáájú ọ̀nà nìkan kọ́ ló ń rí ìbùkún yìí gbà o, ìdílé wọn àti ìjọ pàápàá ń jàǹfààní lọ́pọ̀lọpọ̀ látinú ẹ̀mí rere tí wọ́n ń fi hàn.—Fílí. 4:23.