Iṣẹ́ Aṣáájú Ọ̀nà Jẹ́ Fífọgbọ́n Lo Àkókò Wa!
1 ‘Ọwọ́ mi ti dí jù o jàre! Ṣé àkókò yìí ni yóò wá bọ́gbọ́n mu fún mi láti sọ pé mo fẹ́ ṣaṣáájú ọ̀nà?’ Èrò arábìnrin kan nìyẹn bó ti ń tẹ́tí sí ẹṣin ọ̀rọ̀ tí alàgbà kan tó jẹ́ aṣáájú ọ̀nà sọ ní àpéjọ àyíká, ẹṣin ọ̀rọ̀ ọ̀hún ni “Títẹ̀síwájú Nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Aṣáájú Ọ̀nà.” Arákùnrin ọ̀dọ́ kan tóun náà wà níjokòó ronú pé, ‘Ọ̀nà wo ló gbé e gbà tó fi lè máa ṣaṣáájú ọ̀nà? N kì í ṣalàgbà, ṣùgbọ́n ọwọ́ mi ti dí jù!’
2 Bí alàgbà náà ti ń bá a nìṣó láti máa jíròrò àwọn ìbùkún tí ń jẹ yọ nínú ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà, ó fọ̀rọ̀ wá àwọn aṣáájú ọ̀nà mélòó kan láti àyíká náà lẹ́nu wò, àwọn wọ̀nyí sọ nípa àyípadà tí wọ́n ti ṣe láti lè máa bá iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà lọ, wọ́n tún sọ bí Jèhófà ti ṣe bù kún ìsapá wọn. Ọ̀kan lára wọn jẹ́ aláàbọ̀ ara, ọkàn ní tirẹ̀ aláìgbàgbọ́ ni ẹnì kejì rẹ̀ nínú ìgbéyàwó, ọ̀kan ti fi iṣẹ́ ayé sílẹ̀, síbẹ̀ owó tó ń wọlé fún un tó o láti gbọ́ bùkátà ara rẹ̀. Bí arákùnrin àti arábìnrin tí wọ́n wà níjokòó yìí ti ń gbọ́ bí àwọn aṣáájú ọ̀nà wọ̀nyí ṣe ṣàṣeyọrí pẹ̀lú ìrànwọ́ Jèhófà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ṣàyẹ̀wò ìrònú àti ipò wọn. A rọ ìwọ náà láti ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú, pàápàá níwọ̀n ìgbà tí wákàtí táà ń béèrè lọ́wọ́ àwọn aṣáájú ọ̀nà nísinsìnyí ti jẹ́ ohun tí kò fi bẹ́ẹ̀ nira fún ọ̀pọ̀ àwọn akéde ìhìn rere náà láti lé bá.
3 Àwa mọ̀ pé Jèhófà ni Ẹlẹ́dàá àti Ọba Aláṣẹ Àgbáyé àti pé òun ni a jẹ ní gbèsè fún ìwàláàyè wa. (Dan. 4:17; Ìṣe 17:28) Ó yé wa yékéyéké pé ètò àjọ kan ṣoṣo ni Jèhófà ń lò. Àǹfààní ńlá ló jẹ́ fún wa láti fi ìdúróṣinṣin sìn pẹ̀lú ètò àjọ náà, láti kọ́wọ́ ti “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” náà lẹ́yìn, nípa jíjẹ́rìí nípa Ìjọba náà kí òpin tó dé. (Mát. 24:45; 25:40; 1 Pét. 2:9) Níwọ̀n bí a ti rìn jìnnà wọnú “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn,” a mọ̀ pé àkókò táa ní láti fi wàásù ń tán lọ. (2 Tím. 3:1) Ní àkókò táa ṣì wà yìí, a ní láti gbọ́ bùkátà ìdílé wa. (1 Tím. 5:8) Owó tí ń wọlé fúnni kò sì tóo ná mọ́ bí tàtẹ̀yìnwá. Ara wa pàápàá lè máà dá ṣáṣá bíi ti tẹ́lẹ̀. Táà bá sì ní tanra wa jẹ, a fẹ́ ní àkókò díẹ̀ táa lè fi gbọ́ tara wa, táa tún lè lò láti fi wá owó díẹ̀ táa lè ná sórí ara wa. (Oníw. 3:12, 13) Nítorí náà, a lè bẹ̀rẹ̀ sí kọminú lórí bóyá dídáhùn sí ìpè náà láti ṣe aṣáájú ọ̀nà bọ́gbọ́n mu.
4 Ó kù sọ́wọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan wa láti yẹ ipò wa wò dáadáa, ká sì wá pinnu bóyá a lè ṣe aṣáájú ọ̀nà. (Róòmù 14:12; Gál. 6:5) Ó wúni lórí púpọ̀ láti kíyè sí bí àwọn tí ń dáhùn padà sí ìpè náà láti di aṣáájú ọ̀nà ṣe ń pọ̀ sí i. Láìka pákáǹleke àti ìṣòro àwọn ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí sí, ìròyìn iṣẹ́ ìsìn tí a tẹ̀ jáde nínú ìwé 1999 Yearbook fi hàn pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin [700,000] àwọn ènìyàn Jèhófà jákèjádò ayé tí wọ́n ń bá a nìṣó nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà. Yálà wọ́n ń sìn lábẹ́ ipò ọrọ̀ ajé tó le koko ni o, tàbí níbi tí kò ti sí ohun ìrìnnà, bóyá ìlera wọn ni kò jí pépé tó, tàbí wọ́n dojú kọ ìṣòro àti ìnira mìíràn, àwọn arákùnrin àti arábìnrin wọ̀nyí kò ṣàárẹ̀ nínú ṣíṣe ohun tó dára, ó sì yẹ ká gbóríyìn fún wọn nítorí èyí. (Gál. 6:9) Wọ́n ti gba ohun tí Jèhófà sọ wí pé, kí wọ́n dán òun wò. (Mál. 3:10) Wọ́n gbà pé ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà jẹ́ ọ̀nà tí wọ́n lè gbà fi ọgbọ́n lo àkókò ìgbésí ayé tó kúrú yìí àti ohun ìní tí wọ́n ní àti pé Jèhófà ti bù kún wọn ní tòótọ́ nítorí tí wọ́n ṣe àyípadà tó yẹ kí wọ́n bàa lè wọnú iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà, kí wọ́n sì máa bá a lọ.
5 Àwọn Aṣáájú Ọ̀nà Ń Rí Ìbùkún Gbà: Arábìnrin kan ní Cameroon tó ní ọmọdébìnrin kan ṣàlàyé pé: “Láti ìgbà tí mo ti bí ọmọ mi, ló ti máa ń bá mi jáde nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Kó tiẹ̀ tó mọ̀-ọ́n rìn pàápàá, ni mo ti máa ń pọ̀n ọ́n sẹ́yìn mi, tí máa fi ọ̀já gbà á dáadáa. Lówùúrọ̀ ọjọ́ kan nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, mo dúró níbi tẹ́nì kan ti ń tajà lẹ́bàá ọ̀nà. Ni ọmọ mi bá fi mí sílẹ̀, ló bá kó àwọn ìwé ìròyìn mélòó kan nínú àpò mi. Ló bá rìn tàgétàgé lọ sítòsí níbi tẹ́lòmìn-ín ti ń tajà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò lè sọ̀rọ̀ púpọ̀, ó kọjú sí obìnrin kan, ó sì fi ìwé ìròyìn lọ̀ ọ́. Ìyàlẹ́nu ńlá ló jẹ́ fún obìnrin náà láti rí irú ọmọdébìnrin bẹ́ẹ̀ tí ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ yìí. Kíá ló gba ìwé ìròyìn náà, tó sì gbà láti máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì!”
6 Ní ìdáhùnpadà sí ìpè fún ọ̀pọ̀ aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́, alàgbà kan, tó sì tún jẹ́ olórí ìdílé kan ní Zambia, tó tún ń ṣiṣẹ́ láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀ pinnu láti ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ láìka bí ọwọ́ rẹ̀ ti máa ń dí tó sí. Ó fẹ́ fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ nínú ìjọ rẹ̀ àti fún ìdílé rẹ̀. Ní àwọn àkókò kan, ó máa ń gbé ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ rẹ̀ sí ẹ̀bá ọ̀nà tí yóò sì máa tẹ́tí sí kásẹ́ẹ̀tì ìwé Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé, yóò wá ké sí àwọn tí ń kọjá lọ láti wá tẹ́tí sí ohun tí a ń kà jáde ketekete. Lọ́nà yẹn, ó ṣeé ṣe fún un láti fi ìwé Ayọ̀ Ìdílé mẹ́rìndínlógún àti ìwé Ìmọ̀ mẹ́tàlá síta, ó sì bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì méjì.
7 Nílẹ̀ Zimbabwe tí kò jìnnà síbi táa mẹ́nu kàn tán, a kíyè sí ẹ̀mí rere tí àwọn èèyàn ní nípa aṣáájú ọ̀nà pẹ̀lú. Lóṣù April 1998, ìjọ kan tó ní akéde mẹ́tàdínlọ́gọ́fà ròyìn àádọ́rin aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ àti aṣáájú ọ̀nà déédéé mẹ́sàn-án. Nínú ìjọ mìíràn tó ní akéde mẹ́rìnléláàádọ́rùn-ún, aṣáájú ọ̀nà méjìdínlọ́gọ́ta ló ròyìn níbẹ̀. Ìjọ mìíràn tó ní akéde mẹ́rìndínláàádóje ròyìn pé àwọn méjìdínlọ́gọ́ta pinnu láti ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ pẹ̀lú àwọn aṣáájú ọ̀nà déédéé mẹ́rin tí wọ́n ní. Ọdún àrà ọ̀tọ̀ gbáà lọdún iṣẹ́ ìsìn tó kọjá jẹ́ ní Zimbabwe. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọwọ́ àwọn ará di fún ọ̀ràn ìdílé, ìgbòkègbodò ìjọ, àti kíkọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì, wọ́n pọkàn pọ̀ sórí fífi ọgbọ́n lo àkókò wọn nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́.
8 Àwọn aṣáájú ọ̀nà mọ̀ pé bíbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà àti bíbá a nìṣó kò sinmi lórí agbára tiwọn fúnra wọn. Àwọn lẹni tó kọ́kọ́ gbà pé ohunkóhun tí wọ́n bá ṣe, ṣeé ṣe, nítorí pé wọ́n “gbára lé okun tí Ọlọ́run ń pèsè.” (1 Pét. 4:11) Ìgbàgbọ́ wọn ràn wọ́n lọ́wọ́ láti máa bá iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn lọ láti ọjọ́ dé ọjọ́. Kàkà tí wọn yóò fi máa wá ìgbésí ayé gbẹ̀fẹ́, àwọn aṣáájú ọ̀nà aláṣeyọrí mọ̀ pé báwọn bá fẹ́ tẹ̀ síwájú, ó ń béèrè “ọ̀pọ̀ ìjàkadì” ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ìbùkún ni wọ́n ti rí gbà nítorí rẹ̀.—1 Tẹ́s. 2:2.
9 Àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù Ṣeé Fara Wé: Àkọsílẹ̀ àṣeyọrí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ àti ìrànwọ́ rere tó ṣe fún ọ̀pọ̀ èèyàn ń bẹ nínú Bíbélì. Síbẹ̀, báa bá ń sọ̀rọ̀ nípa ẹni tójú ẹ rí nǹkan láyé yìí, ọ̀kan ni Pọ́ọ̀lù jẹ́. Ó fara da inúnibíni àti ìnira kó bàa lè wàásù ìhìn rere náà, kó sì lè fún àwọn ìjọ lókun. Bẹ́ẹ̀ sì ló ní ìṣòro àìlera tó lágbára tí ń bá a fínra. (2 Kọ́r. 11:21-29; 12:7-10) Ó pinnu láti fi ọgbọ́n lo àkókò rẹ̀. Ó jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ló ran òun lọ́wọ́ tí òun fi ṣe gbogbo ohun tóun ṣe. (Fílí. 4:13) Kò síkan lára àwọn tí Pọ́ọ̀lù ràn lọ́wọ́ tí yóò ní ìdí láti dé ìparí èrò náà pé, ńṣe ni Pọ́ọ̀lù wulẹ̀ fi ìsapá rẹ̀ nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ṣòfò tàbí kí onítọ̀hún sọ pé ì bá sàn kí Pọ́ọ̀lù ti lo àkókò rẹ̀ fún nǹkan mìíràn. Họ́wù, lónìí pàápàá a ṣì ń jàǹfààní láti inú ọ̀nà tí Pọ́ọ̀lù gbà fi ọgbọ́n lo àkókò rẹ̀! Ẹ wo bí a ṣe mọrírì ìmọ̀ràn onímìísí rẹ̀ tó, ìmọ̀ràn tí ń ràn wá lọ́wọ́ láti mọ àwọn ohun tó yẹ ká kọ́kọ́ ṣe, kí a sì rọ̀ mọ́ òtítọ́ ní àwọn àkókò ìṣòro yìí!
10 Nísinsìnyí ju ti ìgbàkigbà rí lọ, ‘àkókò tí ó ṣẹ́ kù láti wàásù ìhìn rere náà ti dín kù.’ (1 Kọ́r. 7:29; Mát. 24:14) Nítorí náà, béèrè lọ́wọ́ ara rẹ pé, ‘Ká ní mo tiẹ̀ kú lọ́la òde yìí, ǹjẹ́ mo lè sọ fún Jèhófà pé mo ti fọgbọ́n lo àkókò mi?’ (Ják. 4:14) Èé ṣe tí o kò fi gbàdúrà sí Jèhófà báyìí, kí o sì mú un dá a lójú pé ó wù ẹ́ láti fi ọgbọ́n lo àkókò rẹ gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀? (Sm. 90:12) Gbàdúrà fún ìrànlọ́wọ́ Jèhófà láti mú kí ìgbésí ayé rẹ rọrùn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé o ti lè rò pé o kò lè ṣe aṣáájú ọ̀nà tẹ́lẹ̀, o kò ha rí i nísinsìnyí pé ó bá ìgbésí ayé rẹ mu?
11 Lo Àǹfààní Tóo Bá Ní Dáadáa: Ó yéni yéké pé, nítorí bí ipò nǹkan ti rí, kì í ṣe gbogbo ẹni tó fẹ́ láti lo àádọ́rin wákàtí lóṣù kan gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà déédéé ló lè ṣe bẹ́ẹ̀. Bó ti wù kó rí, ọ̀pọ̀ akéde ló ń ṣètò láti lo àádọ́ta wákàtí lóṣù nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ní gbogbo ìgbà tó bá ṣe é ṣe, àwọn mìíràn tilẹ̀ ń ṣe é láìdáwọ́ dúró. Bí ipò rẹ kò bá yọ̀ǹda fún ẹ láti ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ tàbí aṣáájú ọ̀nà déédéé báyìí, má rẹ̀wẹ̀sì. Ṣáà máa gbàdúrà pé kí ipò rẹ yí padà. Ní báyìí ná, bí o kò bá lè ṣe ìyípadà kankan, rí ìtùnú nínú mímọ̀ pé inú Jèhófà ń dún sí ohunkóhun tí o bá lè fi tọkàntọkàn ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. (Mát. 13:23) Ó mọ̀ pé ọ̀dọ̀ òun ló dúró sí gbágbáágbá, ó sì mọ̀ pé ò ń làkàkà gidigidi láti jẹ́ akéde tí kì í fiṣẹ́ ṣeré, ẹni tí kò ní jẹ́ kí oṣù kan lọ láìjẹ́ pé ó lo àǹfààní tó ní láti jẹ́rìí. Ó ṣeé ṣe kí o lè tẹ̀ síwájú nípa títúbọ̀ mú kí òye rẹ̀ nípa ìjẹ́rìí múná sí i, nípa ṣíṣiṣẹ́ láti di oníwàásù àti olùkọ́ ìhìn rere tó dáńgájíá.—1 Tím. 4:16.
12 Pẹ̀lú “ọjọ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù ti Jèhófà” tó ń sún mọ́lé, ó ṣe pàtàkì pé kí a fi ọgbọ́n lo àkókò tó ṣẹ́ kù bí a bá fẹ́ parí iṣẹ́ tí a ti yàn fún wa. (Jóẹ́lì 2:31) Sátánì mọ̀ pé àkókò òun kúrú, ju ti ìgbàkigbà rí lọ, ó ń sa gbogbo agbára rẹ̀ láti mú kí ìgbésí ayé wa dojú rú, kí ó sì mú kí nǹkan nira fún wa, kí a má baà lè pọkàn pọ̀ sórí àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ. (Fílí. 1:10; Ìṣí. 12:12) Má ṣe fojú kéré ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí ẹ. Jèhófà lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti mú kí ìgbésí ayé ẹ rọrùn, kí o sì lè ṣe gbogbo ohun tó wà lórí ẹ̀mí ẹ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà. (Sm. 145:16) Ó dùn mọ́ni pé, ọ̀pọ̀ ń rí i pé, nígbà táwọn yẹ ipò àwọn wò, àwọn lè dara pọ̀ mọ́ agbo àwọn aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ tàbí àwọn aṣáájú ọ̀nà déédéé. Ní tòótọ́, àwọn aṣáájú ọ̀nà ń rí ìtẹ́lọ́rùn tó jinlẹ̀ nínú fífi ọgbọ́n lo àkókò wọn. Ṣé wàá jẹ́ ọ̀kan lára wọn?