ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w98 8/1 ojú ìwé 25-29
  • Gbígbé Àwọn Àǹfààní Iṣẹ́ Ìsìn Mímọ́ Gẹ̀gẹ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Gbígbé Àwọn Àǹfààní Iṣẹ́ Ìsìn Mímọ́ Gẹ̀gẹ̀
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Nígbà Tí Àìní Kánjúkánjú Bá Dìde Nínú Ìdílé
  • Títẹ́wọ́gba Ẹrù Iṣẹ́ Wọn
  • Pẹ̀lú Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ Ìdílé
  • Àwọn Òbí Tó Fi Tọkàntọkàn Yọ̀ǹda fún Jèhófà
  • Àwọn Ìjọ Tí Ń Ṣètìlẹyìn
  • Ẹ Máa Rántí Àwọn Tó Ń Ṣe Iṣẹ́ Ìsìn Alákòókò Kíkún
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • Ẹ Máa Bọlá fún Àwọn Àgbàlagbà Tó Wà Láàárín Yín
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • Bí A Ṣe Lè Máa Bá a Lọ Ní Jíjẹ́ Aláyọ̀ Nínú Iṣẹ́ Ìsìn Alákòókò Kíkún
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ǹjẹ́ O Lè Yọ̀ǹda Ara Rẹ?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
w98 8/1 ojú ìwé 25-29

Gbígbé Àwọn Àǹfààní Iṣẹ́ Ìsìn Mímọ́ Gẹ̀gẹ̀

ÀWỌN iṣẹ́ tí a bá yàn fún wa nínú iṣẹ́ ìsìn mímọ́ kì í ṣe nǹkan tí a ó fọwọ́ dẹngbẹrẹ mú. Nígbà tí àwọn àlùfáà ní Júdà ìgbàanì fojú yẹpẹrẹ wo àǹfààní tí a fún wọn nínú tẹ́ńpìlì Jèhófà, ó bá wọn wí kíkankíkan. (Málákì 1:6-14) Nígbà tí àwọn kan ní Ísírẹ́lì rọ àwọn Násírì láti fọwọ́ yọ̀bọ́kẹ́ mú àwọn ẹrù iṣẹ́ tí wọ́n tẹ́wọ́ gbà nínú iṣẹ́ ìsìn mímọ́, Jèhófà bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ẹlẹ́ṣẹ̀ wọnnì wí gidigidi. (Ámósì 2:11-16) Àwọn Kristẹni tòótọ́ pẹ̀lú ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn mímọ́, wọ́n sì fi ọwọ́ pàtàkì mú un. (Róòmù 12:1) Iṣẹ́ ìsìn mímọ́ yìí ní onírúurú ẹ̀ka, gbogbo wọ́n sì ṣe pàtàkì.

Nígbà tí Jésù ṣì wà lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, ó fún wọn ní ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tó sọ wọ́n di olùpòkìkí Ìjọba Ọlọ́run. Nígbà tó bá yá, ìhìn iṣẹ́ wọn yóò dé òpin ilẹ̀ ayé. (Mátíù 28:19, 20; Ìṣe 1:8) Iṣẹ́ ìwàásù yìí ti túbọ̀ di kánjúkánjú ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí.

Gbogbo Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ yìí. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún ń rí ayọ̀ nínú àǹfààní ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà. Láti lè kúnjú àwọn àìní pàtàkì nínú iṣẹ́ kárí ayé yìí, ẹgbẹẹgbẹ̀rún ti yọ̀ǹda ara wọn fún àkànṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún ní Bẹ́tẹ́lì, nínú iṣẹ́ arìnrìn-àjò gẹ́gẹ́ bí alábòójútó àyíká àti ti àgbègbè, tàbí nínú iṣẹ́ ìsìn míṣọ́nnárì. Fún àwọn tó fẹ́ máa bá irú àkànṣe iṣẹ́ ìsìn bẹ́ẹ̀ nìṣó, kí ni èyí lè wé mọ́?

Nígbà Tí Àìní Kánjúkánjú Bá Dìde Nínú Ìdílé

Kí ẹnì kan tó kó wọnú àkànṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún, ó sábà máa ń pọndandan kí ó ṣe àwọn àtúnṣe kan nínú ipò rẹ̀. Kì í ṣe gbogbo ènìyàn ló lè ṣe èyí. Àwọn ojúṣe tí Ìwé Mímọ́ là sílẹ̀, èyí tó wà lọ́rùn ẹnì kan, lè máà jẹ́ kí ó ṣeé ṣe. Ṣùgbọ́n, bí ó bá wá ṣẹlẹ̀ ńkọ́ o, pé àìní kánjúkánjú dìde nínú ìdílé ẹnì kan tó ti wà nínú iṣẹ́ ìsìn àkànṣe, bóyá àìní tó kan àwọn òbí àgbàlagbà? Àwọn ìlànà àti ìmọ̀ràn Bíbélì tó tẹ̀ lé e yìí yóò pèsè ìtọ́sọ́nà tí a nílò.

Gbogbo ìgbésí ayé wa pátá gbọ́dọ̀ wé mọ́ ìbátan wa pẹ̀lú Jèhófà. (Oníwàásù 12:13; Máàkù 12:28-30) Àwọn nǹkan mímọ́ tí a fi síkàáwọ́ wa ní a ní láti gbé gẹ̀gẹ̀. (Lúùkù 1:74, 75; Hébérù 12:16) Ní àkókò kan, Jésù sọ fún ọkùnrin kan tó yẹ kí ó yí àwọn ohun àkọ́múṣe rẹ̀ padà pé, ṣe ni ó yẹ kí ọwọ́ rẹ̀ dí fọ́fọ́ ní pípolongo Ìjọba Ọlọ́run. Ní kedere, ọkùnrin náà ń gbèrò àtisún irú ìgbòkègbodò bẹ́ẹ̀ síwájú títí di ẹ̀yìn ikú baba rẹ̀. (Lúùkù 9:59, 60) Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, Jésù fi hàn pé èrò òdì gbáà ni ó jẹ́, bí ẹnikẹ́ni bá sọ pé torí pé òun ti ya ohun gbogbo sí mímọ́ fún Ọlọ́run, òun kò ní “ṣe ẹyọ ohun kan mọ́ fún baba [òun] tàbí ìyá [òun].” (Máàkù 7:9-13) Bákan náà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi hàn pé ẹrù iṣẹ́ pàtàkì ni ó jẹ́ láti pèsè fún ‘àwọn tí í ṣe tẹni,’ títí kan àwọn òbí àti òbí àgbà.—1 Tímótì 5:3-8.

Èyí ha túmọ̀ sí pé nígbà tí àìní kánjúkánjú bá dìde, ó yẹ kí àwọn tó wà nínú iṣẹ́ ìsìn àkànṣe fi iṣẹ́ àyànfúnni wọn sílẹ̀ láti lọ di olùṣètọ́jú? A óò gbé ọ̀pọ̀ nǹkan yẹ̀ wò kí a tó lè dáhùn. Ìpinnu ti ara ẹni ni èyí jẹ́. (Gálátíà 6:5) Ọ̀pọ̀ ló ti ronú pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun ìgbégẹ̀gẹ̀ ni iṣẹ́ àyànfúnni wọn, síbẹ̀síbẹ̀ yóò bọ́gbọ́n mu láti lọ jókòó ti àwọn òbí wọn láti lè fún wọn ní ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n nílò. Èé ṣe? Ó lè jẹ́ pé níbi tí ọ̀ràn àìní náà dé, iná ti jó dórí kókó wàyí, ó lè máà sí mẹ́ńbà ìdílé mìíràn tó lè ṣèrànwọ́, tàbí kẹ̀, kí ó jẹ́ pé ìjọ àdúgbò kò ní lè kájú àìní náà. Ó ti ṣeé ṣe fún àwọn kan láti máa ṣe aṣáájú ọ̀nà bí wọ́n ti ń pèsè irú ìrànlọ́wọ́ bẹ́ẹ̀. Ó ti ṣeé ṣe fún àwọn mìíràn láti tún padà sẹ́nu àkànṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún lẹ́yìn tí a ti yanjú ipò ìṣòro inú ìdílé. Ṣùgbọ́n o, lọ́pọ̀ ìgbà, ó ti ṣeé ṣe láti gbé nǹkan gba ọ̀nà mìíràn.

Títẹ́wọ́gba Ẹrù Iṣẹ́ Wọn

Nígbà tí àìní kánjúkánjú bá dìde, ó ti ṣeé ṣe fún àwọn kan tí wọ́n wà nínú àkànṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún láti bójú tó irú àìní bẹ́ẹ̀ láìfi iṣẹ́ àyànfúnni wọn sílẹ̀. Gbé ìwọ̀nba àpẹẹrẹ díẹ̀ yẹ̀ wò.

Tọkọtaya kan tí ń sìn ní orílé iṣẹ́ àgbáyé ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wọnú iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì ní ọdún 1978, lẹ́yìn tí wọ́n ti ṣe iṣẹ́ alábòójútó àyíká àti ti àgbègbè. Iṣẹ́ arákùnrin náà wé mọ́ ẹrù iṣẹ́ bàǹtà banta nínú ètò àjọ Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n àwọn òbí rẹ̀ pẹ̀lú nílò ìrànlọ́wọ́. Tọkọtaya yìí tí ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì ń ṣèbẹ̀wò ẹ̀ẹ̀mẹ́ta tàbí ẹ̀ẹ̀mẹ́rin lọ́dọọdún—nǹkan bí 3,500 kìlómítà ní tàlọ-tàbọ̀—láti tọ́jú àwọn òbí wọn. Wọ́n fúnra wọn kọ́ ilé kan nítorí àìní àwọn òbí wọn. Wọ́n ti rìnrìn àjò láti bójú tó àwọn ìṣòro ìlera tó dìde ní pàjáwìrì. Fún nǹkan bí 20 ọdún báyìí, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo àkókò ìsinmi wọn ni wọ́n ti lò láti bójú tó ẹrù iṣẹ́ yìí. Wọ́n nífẹ̀ẹ́ àwọn òbí wọn, wọ́n sì ń bọlá fún wọn, ṣùgbọ́n wọ́n tún fojú ribiribi wo àǹfààní iṣẹ́ ìsìn mímọ́ tí wọ́n ní.

Arákùnrin mìíràn ti wà nínú iṣẹ́ arìnrìn-àjò fún ọdún 36 nígbà tí ohun tó pè ní ìpèníjà tó le jù lọ nínú ìgbésí ayé dojú kọ ọ́. Ó di dandan kí ìyá ìyàwó rẹ̀ tó jẹ́ ẹni ọdún 85, tí í ṣe olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà, máa gbé pẹ̀lú ẹnì kan tí yóò lè máa ràn án lọ́wọ́. Nígbà yẹn, ọ̀pọ̀ jù lọ nínú àwọn ọmọ rẹ̀ sọ pé kò ní rọ àwọn lọ́rùn láti mú un tira. Ọ̀kan lára àwọn ẹ̀bi alábòójútó arìnrìn-àjò náà sọ fún un pé ṣe ni ó yẹ kí òun àti ìyàwó rẹ̀ fi iṣẹ́ ìsìn sílẹ̀, kí wọ́n sì wá tọ́jú ìyá rẹ̀, lórúkọ ìdílé. Ṣùgbọ́n tọkọtaya náà kò fi iṣẹ́ ìsìn ṣíṣeyebíye náà sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kò fojú tín-ín-rín àìní ìyá wọn. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo ọdún mẹ́sàn-án tó tẹ̀ lé e ló fi wà pẹ̀lú wọn. Wọ́n kọ́kọ́ ń gbé nínú ilé alágbèérìn, nígbà tó yá, wọ́n wá ń gbé nínú oríṣiríṣi ibùgbé tí àwọn àyíká pèsè. Fún àkókò gígùn, arákùnrin náà, tó jẹ́ alábòójútó àgbègbè nígbà yẹn, ń rìnrìn àjò láti lọ bójú tó iṣẹ́ àyànfúnni rẹ̀, nígbà tí ìyàwó rẹ̀ dúró ti ìyá rẹ̀ láti máa pèsè ìtọ́jú onífẹ̀ẹ́ látòwúrọ̀ ṣúlẹ̀. Lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, lẹ́yìn ìpàdé ní ọjọ́ Sunday, ọkọ rẹ̀ yóò rin ìrìn àjò ọ̀nà jíjìn padà láti wá ràn wọ́n lọ́wọ́. Ọ̀pọ̀ tó mọ̀ nípa ipò náà mọrírì ohun tí tọkọtaya yìí ṣe gan-an. Nígbà tó yá, èyí ta àwọn mẹ́ńbà ìdílé yòókù jí láti pèsè ìrànlọ́wọ́ díẹ̀. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ènìyàn Jèhófà ń jàǹfààní láti inú iṣẹ́ ìsìn tọkọtaya olùfara-ẹni-rúbọ náà, nítorí tí wọ́n rọ̀ mọ́ àǹfààní àkànṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún wọn.

Pẹ̀lú Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ Ìdílé

Nígbà tí àwọn mẹ́ńbà ìdílé bá mọyì àkànṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún, wọ́n lè fọwọ́ sowọ́ pọ̀ kí àwọn díẹ̀ lára wọn, ó kéré tán, lè kópa nínú rẹ̀.

Irú ẹ̀mí ìfọwọ́sowọ́pọ̀ ìdílé bẹ́ẹ̀ ti ṣèrànwọ́ fún tọkọtaya ará Kánádà kan tí ń sìn gẹ́gẹ́ bí míṣọ́nnárì ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà. Wọn kò dúró di ìgbà tó di ọ̀ràn pàjáwìrì, kí wọ́n wulẹ̀ máa retí pé kò sí nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀. Kí wọ́n tó lọ sí Watch Tower Bible School of Gilead, tí yóò múra wọn sílẹ̀ fún iṣẹ́ ìsìn ní ilẹ̀ òkèèrè, ọkọ náà bá àbúrò rẹ̀ ọkùnrin jíròrò nípa bí àwọn yóò ṣe tọ́jú ìyá àwọn, bó bá ṣẹlẹ̀ pé àìsàn kọlù ú tàbí tó bá di abirùn. Láti fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ ìyá àwọn, àti pé òun tún mọrírì iṣẹ́ míṣọ́nnárì, àbúrò rẹ̀ sọ pé: “Mo ti ní ìdílé, mo sì ti lọ́mọ. N kò lè lọ sí ọ̀nà jíjìn, kí n sì ṣe bí tìrẹ. Nítorí náà, bí nǹkan kan bá ṣe Màmá, n óò tọ́jú rẹ̀.”

Tọkọtaya kan tí ń sìn ní Gúúsù Amẹ́ríkà rí ìfọwọ́sowọ́pọ̀ púpọ̀ láti ọ̀dọ̀ ìdílé ìyàwó ní títọ́jú ìyá rẹ̀ tó ti darúgbó. Ọkàn lára ẹ̀gbọ́n rẹ̀ obìnrin àti ọkọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ tọ́jú ìyá wọn títí àrùn burúkú kan fi kọlu ẹ̀gbọ́n rẹ̀ yẹn. Kí wá ni ṣíṣe? Láti paná ìdààmú èyíkéyìí, àna rẹ̀ kọ̀wé pé: “Níwọ̀n ìgbà tí èmi àti àwọn ọmọ bá ṣì wà, kì yóò sí ìdí kankan fún yín láti fi iṣẹ́ ìsìn míṣọ́nnárì sílẹ̀.” Àfikún ìrànwọ́ láti inú ìdílé dé nígbà tí àbúrò rẹ̀ mìíràn àti ọkọ rẹ̀ fi ilé wọn sílẹ̀, tí wọ́n sì ṣí lọ síbi tí ìyá wọn ń gbé kí wọ́n lè ráyè máa tọ́jú rẹ̀, wọ́n sì tọ́jú rẹ̀ títí ó fi kú. Ẹ̀mí ìfọwọ́sowọ́pọ̀ yìí mà dára o! Gbogbo wọn ló kọ́wọ́ ti iṣẹ́ ìsìn míṣọ́nnárì.

Àwọn Òbí Tó Fi Tọkàntọkàn Yọ̀ǹda fún Jèhófà

Àwọn òbí sábà máa ń fi ìmọrírì àrà ọ̀tọ̀ hàn fún iṣẹ́ ìsìn mímọ́. Lára ohun níníyelórí jù lọ tí wọ́n fi lè bọlá fún Jèhófà ni ọmọ tiwọn. (Òwe 3:9) Ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni òbí ń fún àwọn ọmọ wọn ní ìṣírí láti kó wọnú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Àwọn kan nínú wọn sì ń ronú bí Hánà, ẹni tó fi Sámúẹ́lì ọmọkùnrin rẹ̀ fún Jèhófà nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ “fún àkókò tí ó lọ kánrin,” èyíinì ni, “ní gbogbo ọjọ́ tí ó bá wà.”—1 Sámúẹ́lì 1:22, 28.

Ọ̀kan lára irú òbí bẹ́ẹ̀ kọ̀wé sí ọmọbìnrin rẹ̀ ní Áfíríkà pé: “A dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún àǹfààní àgbàyanu tí o ní. A kò lè retí kí o tún ṣe jù báyìí lọ.” Nígbà mìíràn, ó sọ pé: “Òtítọ́ ni pé a gbọ́dọ̀ máa fara da jíjìnnà síra, ṣùgbọ́n wo bí ayọ̀ wa ti pọ̀ tó láti rí bí Jèhófà ti ń tọ́jú rẹ!”

Lẹ́yìn tí míṣọ́nnárì kan ní Ecuador ṣàtúnyẹ̀wò onírúurú ipò tó ti dìde lẹ́nu pípèsè ìtọ́jú tó yẹ fún àwọn òbí rẹ̀ àgbàlagbà, ó kọ̀wé pé: “Mo lérò pé ìrànlọ́wọ́ gíga jù lọ tí èmi àti ìyàwó mi ti rí gbà ni àdúrà baba mi. Lẹ́yìn ikú rẹ̀, ìyá mi sọ fún wa pé: ‘Ọjọ́ kan kò lè kọjá rí, kí baba rẹ má gbàdúrà pé kí Jèhófà jẹ́ kí ó ṣeé ṣe fún ẹ̀yin méjèèjì láti máa bá iṣẹ́ yín nìṣó.’”

Tọkọtaya àgbàlagbà kan ní California, U.S.A., láyọ̀ pé ọ̀kan lára àwọn ọmọkùnrin wọn wọnú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Ọmọkùnrin yẹn àti ìyàwó rẹ̀ wà ní Sípéènì nígbà tí ìyá wọn kú. Àwọn mẹ́ńbà yòókù nínú ìdílé ronú pé ó yẹ kí àwọn ṣètò bí àwọn yóò ṣe máa tọ́jú baba wọn. Nítorí pé iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ àti ọmọ títọ́ ń dí wọn lọ́wọ́, wọn kò rò pé àwọn lè gbé ẹrù iṣẹ́ yẹn. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n rọ tọkọtaya tó wà nínú àkànṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún pé kí wọ́n padà wálé wá tọ́jú baba wọn. Àmọ́ ṣá o, ara baba ṣì le, bó tilẹ̀ jẹ́ ẹni ọdún 79, ó sì ní ojú ìwòye tó mọ́lẹ̀ rekete nípa tẹ̀mí. Nígbà ìpàdé ìdílé kan tí wọ́n ṣe, lẹ́yìn tí ọ̀pọ̀ ti sọ tẹnu wọn, baba dìde, ó sojú abẹ níkòó, ó ní: “Mo fẹ́ kí wọ́n padà sí Sípéènì, kí wọ́n sì máa bá iṣẹ́ wọn nìṣó.” Wọ́n padà, ṣùgbọ́n àwọn náà ràn án lọ́wọ́ lọ́nà tó ṣe gúnmọ́. Ẹnu iṣẹ́ alábòójútó àyíká ni wọ́n wà báyìí ní Sípéènì. Láti ìgbà tí wọ́n ti ṣe ìpàdé ìdílé yẹn, àwọn mẹ́ńbà yòókù nínú ìdílé ti wá mọyì ohun tí tọkọtaya tó wà nínú iṣẹ́ ìsìn ní ilẹ̀ òkèèrè ń ṣe. Lẹ́yìn ọdún mélòó kan, ọ̀kan lára àwọn ọmọkùnrin yòókù mú baba wọn tira, ó sì tọ́jú rẹ̀ títí ó fi kú.

Ní Pennsylvania, U.S.A., arákùnrin kan tó jẹ́ ẹni àmì òróró, tó ti ṣe aṣáájú ọ̀nà fún nǹkan bí 40 ọdún, ti lé ní ẹni 90 ọdún nígbà tí ara ìyàwó rẹ̀ kò yá gan-an, tí obìnrin náà sì kú. Nígbà yẹn, ó ní ọmọkùnrin kan àti ọmọbìnrin mẹ́ta, àti ọ̀pọ̀ ọmọ nípa tẹ̀mí. Ọ̀kan lára àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ ti wà nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún fún ohun tó ju 40 ọdún, òun àti ọkọ rẹ̀ ti sìn gẹ́gẹ́ bí míṣọ́nnárì, wọ́n ti sin nínú iṣẹ́ arìnrìn-àjò, wọ́n sì ti sìn ní Bẹ́tẹ́lì. Ó ṣèrànwọ́ láti ṣètò ìtọ́jú tí baba rẹ̀ yóò nílò. Àwọn ará tí ń bẹ ládùúgbò pẹ̀lú ṣèrànwọ́ láti máa gbé e lọ sí ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, nígbà tí ọkọ rẹ̀ kú, ó béèrè lọ́wọ́ baba rẹ̀ bóyá ó fẹ́ kí òun kúrò ní Bẹ́tẹ́lì, kí òun lè ráyè wá tọ́jú rẹ̀. Ojú ribiribi ni arákùnrin yìí fi ń wo nǹkan mímọ́, ó sì gbà pé a lè bójú tó àwọn àìní òun lọ́nà mìíràn. Fún ìdí yìí, ó fèsì pé: “Bí o bá torí tèmi kúrò nínú iṣẹ́ ìsìn, nǹkan búburú gbáà ni yóò jẹ́, yóò sì tún burú ju ìyẹn lọ bí mo bá jẹ́ kí o ṣe bẹ́ẹ̀.”

Àwọn Ìjọ Tí Ń Ṣètìlẹyìn

Àwọn ìjọ kan ti ṣèrànwọ́ gan-an ní bíbá àwọn tó wà nínú àkànṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún tọ́jú àwọn òbí wọn àgbàlagbà. Ní pàtàkì, wọ́n mọyì àwọn tó ti wà lẹ́nu irú iṣẹ́ ìsìn bẹ́ẹ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò lè gba ẹrù iṣẹ́ tí Ìwé Mímọ́ gbé kà wọ́n léjìká ṣe, ìjọ wọ̀nyí ń ṣe púpọ̀ láti sọ ẹrù náà di fífúyẹ́ gẹgẹ, kí ó má bàa pọndandan fún àwọn ọmọ náà láti fi àkànṣe iṣẹ́ ìsìn wọn sílẹ̀.

Tọkọtaya kan láti Germany ti wà nínú iṣẹ́ ìsìn ilẹ̀ òkèèrè fún nǹkan bí ọdún 17, wọ́n ti lo èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àkókò yẹn nínú iṣẹ́ arìnrìn-àjò, kí ó tó di pé àwọn àìní ìyá arúgbó arákùnrin náà búrẹ́kẹ. Ọdọọdún ni wọ́n ń lo àkókò ìsinmi wọn láti ràn án lọ́wọ́. Àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ládùúgbò tún ń ṣe ìrànwọ́ onífẹ̀ẹ́. Nígbà kan tí tọkọtaya náà tó wà nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún wà pẹ̀lú ìyá náà lásìkò kan tó jọ pé iná fẹ́ jó dórí kókó, àwọn alàgbà ìjọ àdúgbò ṣètò láti bá wọn sọ̀rọ̀. Wọ́n mọ gbogbo ohun tí tọkọtaya náà ń ṣe déédéé fún ìyá náà. Wọ́n tún mọrírì ìjẹ́pàtàkì iṣẹ́ ìsìn àkànṣe tí tọkọtaya náà ń ṣe. Nítorí náà, àwọn alàgbà gbé ìtòlẹ́sẹẹsẹ kan kalẹ̀ fún títọ́jú ìyá náà, wọ́n sì sọ pé: “Ẹ kò lè ṣe ju ohun tí ẹ ń ṣe fún un; a ó ràn yín lọ́wọ́ kí ẹ lè máa bá iṣẹ́ yín nìṣó ní Sípéènì.” Àwọn alàgbà wọ̀nyí ti ń ṣe èyí fún ọdún méje gbáko báyìí.

Bákan náà, arákùnrin kan tó ti ń sìn ní Senegal láti ọdún 1967 rí ọ̀pọ̀ ìtìlẹyìn onífẹ̀ẹ́ gbà láti ọ̀dọ̀ ìjọ tí baba rẹ̀ wà. Nígbà tí ìṣòro dé, pẹ̀lú ìfọwọ́sowọ́pọ̀ aya rẹ̀ onífẹ̀ẹ́, ọkọ dá lọ sí United States láti lọ ran àwọn òbí rẹ̀ lọ́wọ́. Ó rí i pé ó pọndandan láti dúró níbẹ̀ fún oṣù mélòó kan. Ipò nǹkan kò rọrùn rárá, ṣùgbọ́n lẹ́yìn tó ti ṣe èyí tó lè ṣe, ìjọ pèsè ìrànlọ́wọ́ kí ó lè ṣeé ṣe fún un láti máa bá iṣẹ́ ìsìn míṣọ́nnárì rẹ̀ nìṣó. Ọdún 18 gbáko ni ìjọ fi pèsè ìrànlọ́wọ́ onífẹ̀ẹ́ ní àìmọye ọ̀nà, lákọ̀ọ́kọ́ fún baba náà (bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò dá púpọ̀ nínú wọn mọ̀ mọ́) àti lẹ́yìn náà fún ìyá. Ìyẹn ha túmọ̀ sí pé wọ́n ti gba ojúṣe ọmọkùnrin yẹn ṣe bí? Ó tì o; léraléra ló máa ń rìnrìn àjò lọ láti Senegal, ó sì máa ń lo àkókò ìsinmi rẹ̀ láti ṣe gbogbo ohun tó bá lè ṣe. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ nínú ìjọ yẹn láyọ̀ pé àwọn náà ń kópa nínú mímú kí ó ṣeé ṣe fún tọkọtaya òṣìṣẹ́ kára yìí láti máa bá àkànṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún nìṣó ní Senegal.

Jésù sọ pé àwọn tó fi ohun gbogbo sílẹ̀ nítorí ìhìn rere yóò wá ní àwọn arákùnrin, arábìnrin, ìyá, àti àwọn ọmọ ní ìlọ́po ọgọ́rùn-ún. (Máàkù 10:29, 30) Báyìí ni ọ̀ràn rí gẹ́lẹ́ láàárín àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà. Tọkọtaya kan tí ń sìn ní Benin, Ìwọ Oòrùn Áfíríkà báyìí, ní ìrírí èyí lákànṣe nígbà tí Àwọn Ẹlẹ́rìí méjì nínú ìjọ àwọn òbí wọn sọ fún wọn pé kí wọ́n má dààmú nípa àwọn òbí wọn. Wọ́n fi kún un pé: “Òbí tiyín jẹ́ òbí tàwa náà.”

Bẹ́ẹ̀ ni, ọ̀nà púpọ̀ wà tí a lè gbà fi hàn pé a ń gbé àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn mímọ́ gẹ̀gẹ̀. Ọ̀nà mìíràn ha wà tí o fi lè túbọ̀ ṣe èyí bí?

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Wọ́n ti yọ̀ǹda ara wọn fún àkànṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́