ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 4/03 ojú ìwé 3-5
  • Ǹjẹ́ O Lè Yọ̀ǹda Ara Rẹ?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ O Lè Yọ̀ǹda Ara Rẹ?
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Èyí Ha Lè Jẹ́ Iṣẹ́ Tó Dára Jù Lọ fún Ọ Bí?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Fífi Ìmọrírì Wo “Ilé Ọlọrun”
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Àwọn Iṣẹ́ Rere Tá Ò Ní Gbàgbé
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2019
  • Gbogbo Èèyàn La Pè!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
km 4/03 ojú ìwé 3-5

Ǹjẹ́ O Lè Yọ̀ǹda Ara Rẹ?

1 Ìṣẹ̀lẹ̀ àgbàyanu kan wáyé ní ọdún 778 ṣáájú Sànmánì Tiwa. Nínú ìran, wòlíì Aísáyà rí “Jèhófà, tí ó jókòó lórí ìtẹ́ tí ó ga fíofío, tí a sì gbé sókè.” Aísáyà wá gbọ́ tí àwọn séráfù ń pe àfiyèsí sí ògo Jèhófà, tí wọ́n ń sọ pé: “Mímọ́, mímọ́, mímọ́ ni Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun.” Kò sí àní-àní pé àrà mérìíyìírí gbáà ni ìran yẹn máa jẹ́! Nínú ìran yẹn, Jèhófà béèrè ìbéèrè amúnironújinlẹ̀ kan, ó ní: “Ta ni èmi yóò rán, ta sì ni yóò lọ fún wa?” Jèhófà ò ṣe àlàyé kankan nípa irú iṣẹ́ tó fẹ́ yàn fúnni tàbí bóyá ẹni tó bá yọ̀ǹda ara rẹ̀ yóò jàǹfààní látinú iṣẹ́ náà. Síbẹ̀, láìfọ̀rọ̀ falẹ̀, Aísáyà dáhùn pé: “Èmi nìyí! Rán mi.” (Aís. 6:1, 3, 8) Ǹjẹ́ o múra tán láti yọ̀ǹda ara rẹ tinútinú bíi ti Aísáyà?

2 À ń fẹ́ àwọn ará tó máa wá sìn ní Bẹ́tẹ́lì. Èyí ń béèrè pé kí wọ́n ní ìfẹ́ àtọkànwá láti fi ire Ìjọba Ọlọ́run sí ipò àkọ́kọ́, kí wọ́n sì múra tán láti ṣe iṣẹ́ èyíkéyìí tí a bá yàn fún wọn láti ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe kárí ayé. (Mát. 6:33) Ní tòótọ́, sísìn gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára ìdílé Bẹ́tẹ́lì yóò jẹ́ kéèyàn ní àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ láti sin Jèhófà tọkàntọkàn. Báwo lèyí ṣe rí bẹ́ẹ̀?

3 Ọ̀kan-Kò-Jọ̀kan Iṣẹ́: Iṣẹ́ oríṣiríṣi la máa ń yàn fún àwọn tó jẹ́ ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì. Ní orílé-iṣẹ́ tó wà ní Brooklyn àti ní àwọn ẹ̀ka iléeṣẹ́ bíi mélòó kan, àwọn kan ń lo ẹ̀rọ ìtẹ̀wé tó ń tẹ Bíbélì, ìwé ńlá, ìwé ìròyìn, ìwé pẹlẹbẹ, àtàwọn ìwé àṣàrò kúkúrú, èyí tá a máa pín kiri jákèjádò ayé. Àwọn mìíràn ń ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka ìdìwépọ̀, níbi tí wọ́n ti ń di Bíbélì àtàwọn ìwé mìíràn, nígbà tí iṣẹ́ àwọn mìíràn jẹ́ ṣíṣètò bí wọ́n á ṣe kó àwọn ìtẹ̀jáde wọ̀nyí ránṣẹ́ sí àwọn ìjọ kárí ayé. A yan àwọn kan láti máa bójú tó àwọn ohun èlò tí a fi ń ṣiṣẹ́ àtàwọn ilé tí a kọ́ sí Bẹ́tẹ́lì. Ní Bẹ́tẹ́lì, iṣẹ́ kékeré kọ́ ni à ń ṣe láti bójú tó ìdílé wa. Bí àpẹẹrẹ, ní ẹ̀ka iléeṣẹ́ ti Nàìjíríà, láàárín ogún ìṣẹ́jú, àwọn kan máa ń gbé oúnjẹ òwúrọ̀ sórí tábìlì fún nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] èèyàn. Láfikún sí i, àwọn tó jẹ́ olùtọ́jú ilé kì í fi ọ̀ràn ìmọ́tótó ṣeré rárá láwọn ilé gbígbé, wọ́n sì tún ń bójú tó àwọn iṣẹ́ pàtàkì mìíràn.

4 Kò rọrùn láti ṣe gbogbo iṣẹ́ bàǹtà-banta wọ̀nyí, àmọ́ iṣẹ́ tó ń mérè wá nípa tẹ̀mí ni wọ́n. Mímọ̀ pé gbogbo okun àti agbára wa là ń lò láti ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ ìwàásù àti iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ náà máa ń fúnni láyọ̀ gan-an. Iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì ń ṣèrànwọ́ láti jẹ́ ká túbọ̀ mọ̀ nípa ètò àjọ Jèhófà dáadáa. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé onísáàmù náà rọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n sapá láti mọ ibùjókòó ìṣàkóso àtọ̀runwá lórí ilẹ̀ ayé ní àkókò wọn lámọ̀dunjú.—Sm. 48:12, 13.

5 Àwọn Ìbùkún Iṣẹ́ Ìsìn Bẹ́tẹ́lì: Ojú wo làwọn tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì fi ń wo àǹfààní iṣẹ́ ìsìn wọn? Kíyè sí àwọn gbólóhùn tó tẹ̀ lé e wọ̀nyí látẹnu àwọn ọ̀dọ́ àtàwọn àgbàlagbà tó jẹ́ ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì. Arábìnrin kan tó ti sìn ní Bẹ́tẹ́lì fún ọdún mẹ́ta sọ pé: “Iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì ti mú kí àjọṣe mi pẹ̀lú Jèhófà dán mọ́rán sí i. Bí àkókò tí mò ń lò níbí ṣe ń gùn sí i tí mo sì túbọ̀ ń kọ́ nípa ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ṣe àwọn nǹkan ní Bẹ́tẹ́lì, bẹ́ẹ̀ ni mo túbọ̀ ń mọ̀ nípa irú ẹni tí Jèhófà jẹ́. Iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì tún ti là mí lóye pé kò sẹ́ni tí Jèhófà ò lè lò fún iṣẹ́ rẹ̀. Kò sì dìgbà téèyàn bá di ẹni pípé kó tó lè ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.”

6 Arákùnrin ọ̀dọ́ kan sọ pé: “Ohun tó sábà máa ń wá sí mi lọ́kàn ni pé, ‘Áá mà dára o kí n dénú ayé tuntun kí n sì máa sọ fún àwọn ọkùnrin olóòótọ́ ìgbàanì tí wọ́n ti jíǹde pé Bẹ́tẹ́lì ni mo ti lo ọdún tó pọ̀ jù lọ nínú ìgbésí ayé mi, kì í ṣe pé mò ń lé owó kiri nínú ayé.’”

7 Nígbà tí arábìnrin kan ronú nípa àwọn ìbùkún tó ti gbà títí di àkókò yìí, ó ní: “Àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ tẹ̀mí tí wọ́n ṣètò ní Bẹ́tẹ́lì ti kọ́ mi ní ohun púpọ̀ nípa Jèhófà, àti nípa bí mo ṣe lè túbọ̀ fara wé e nínú èrò, ìmọ̀lára àti ìṣe mi. Níwọ̀n bó sì ti jẹ́ pé ẹ̀kọ́ tí mò ń gbà kò dáwọ́ dúró, ńṣe ni ìbùkún tí mò ń rí gbà ń pọ̀ sí i.”

8 Arákùnrin kan tó ti lo àpapọ̀ ọdún mọ́kàndínlọ́gọ́ta nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún, tí mẹ́tàlélógójì nínú rẹ̀ jẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì, sọ pé: “Bẹ́tẹ́lì kò dà bí ilé àwọn ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé, gẹ́gẹ́ bí àwọn kan ṣe máa ń rò. Ọ̀nà tí a gbà ṣètò ìgbésí ayé wa ló ń jẹ́ ká máa ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan láṣeyọrí. . . . Kò tíì sí ọjọ́ kan tí mo wá síbi iṣẹ́ tí mi ò gbádùn iṣẹ́ tí mo ṣe. Kí nìdí? Nítorí pé tá a bá lo ara wa tọkàntọkàn nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, inú wa yóò máa dùn pé ‘ohun tó yẹ ká ṣe la ti ṣe.’”—Lúùkù 17:10.

9 Arákùnrin mìíràn, ẹni tó ti lo ọdún méjìlélọ́gọ́ta nínú iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì, sọ pé: “Ó dá mi lójú gidigidi pé Bẹ́tẹ́lì ni ibi tó dára jù lọ láti máa gbé ní èyí tó kù díẹ̀ kí Párádísè orí ilẹ̀ ayé wọlé dé yìí. Mi ò kábàámọ̀ rí láé pé mo fi iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún ṣe iṣẹ́ ìgbésí ayé mi. Ayọ̀ ńláǹlà ló jẹ́ fún mi láti fojú ara mi rí bí ètò àjọ Jèhófà orí ilẹ̀ ayé ṣe ń gbèrú sí i lọ́nà kíkàmàmà, tí mo sì ń nípìn-ín nínú ìtẹ̀síwájú yìí! Ìpinnu mi ni pé, pẹ̀lú agbára Jèhófà, màá máa bá a nìṣó láti fi Bẹ́tẹ́lì ṣe ibùgbé mi, màá sì máa lo ara mi tọkàntọkàn láti mú ire Ìjọba náà tẹ̀ síwájú.”

10 Kìkì ìwọ̀nba díẹ̀ lára ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbùkún tó o lè gbádùn bó o bá yọ̀ǹda ara rẹ fún iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì làwọn tó jẹ́ ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì wọ̀nyí mẹ́nu kàn. Àmọ́, bó ṣe jẹ́ pé èèyàn gbọ́dọ̀ kúnjú ìwọ̀n kó tó ní àǹfààní iṣẹ́ ìsìn èyíkéyìí, bẹ́ẹ̀ náà ló pọn dandan kó o dójú ìlà ohun tá à ń béèrè. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ohun tí à ń béèrè lọ́wọ́ ẹni tó bá fẹ́ wá sìn ní Bẹ́tẹ́lì?

11 Àwọn Ohun Tí À Ń Béèrè fún Iṣẹ́ Ìsìn Bẹ́tẹ́lì: Àwọn nǹkan pàtàkì tí à ń béèrè lọ́wọ́ àwọn tó bá ń kọ̀wé béèrè fún iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì wà nínú àpótí tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí. Bákan náà, ó ṣe pàtàkì pé kí wọ́n múra tán láti ṣiṣẹ́ kára, kí wọ́n má ṣe jẹ́ “olùfẹ́ adùn.” (2 Tím. 3:4; 1 Kọ́r. 13:11) Àwọn tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì gbọ́dọ̀ jẹ́ ọkùnrin àti obìnrin tẹ̀mí, tí wọ́n ti ṣe ètò tó múná dóko fún ṣíṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́, tí wọ́n sì ti kọ́ agbára ìwòye wọn láti “fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.” (Héb. 5:14) Wọ́n ti gbọ́dọ̀ máa fi ìdàgbàdénú Kristẹni hàn kedere nínú gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe ní ìgbésí ayé wọn, títí kan ìwọṣọ, ìmúra, àti irú orin àti eré ìnàjú tí wọ́n ń gbádùn. Àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn tinútinú láti sìn ní Bẹ́tẹ́lì pẹ̀lú ẹ̀mí ìmúratán máa ń sìn níbikíbi tí a bá ti nílò wọn. Àwọn tí kò bá tíì dàgbà púpọ̀ la sábà máa ń fún ní iṣẹ́ agbára ṣe, irú bí ìwé títẹ̀, ṣíṣètò bí a ó ṣe fi ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ ránṣẹ́ sí àwọn ìjọ, bíbójútó àwọn ohun èlò, títọ́jú ilé, bíbójútó ọ̀ràn ìmọ́tótó, aṣọ fífọ̀, àti oúnjẹ sísè. (Òwe 20:29) Àmọ́, láìdàbí àwọn iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ ti ayé, iṣẹ́ kọ̀ọ̀kan máa ń fúnni láyọ̀ gan-an nítorí pé ó jẹ́ iṣẹ́ ìsìn mímọ́ tí ń fògo fún Jèhófà.—Kól. 3:23.

12 A retí pé kí àwọn tá a bá ké sí láti sìn ní Bẹ́tẹ́lì dúró fún ọdún kan, ó kéré tán. Èyí á jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wọn láti gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tó máa sọ wọ́n di òṣìṣẹ́ tó lè ṣiṣẹ́ gan-an. Ìrètí wa ni pé wọ́n á fi Bẹ́tẹ́lì ṣe ibùgbé wọn. Ìfẹ́ fún Jèhófà lohun tó ń sún àwọn tó jẹ́ ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì láti fi iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run ṣáájú àwọn nǹkan tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí fúnra wọn, èyí sì ń mú inú Jèhófà dùn.—Mát. 16:24.

13 Àwọn Tí A Nílò Báyìí: Nítorí irú iṣẹ́ tí à ń ṣe ní Bẹ́tẹ́lì, àwọn tí a nílò ní lọ́wọ́lọ́wọ́ ni àwọn arákùnrin tí kò tíì gbéyàwó. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò pọn dandan kí ẹnì kan jẹ́ aṣáájú ọ̀nà déédéé kó tó kọ̀wé fún iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì, àwọn tí wọ́n bá jẹ́ aṣáájú ọ̀nà déédéé la máa ń kọ́kọ́ gbé ọ̀ràn wọn yẹ̀ wò, níwọ̀n bí wọ́n ti wà nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún tẹ́lẹ̀. Nígbà míì, àyè máa ń ṣí sílẹ̀ fún àwọn arábìnrin tí kò tíì lọ́kọ àtàwọn tọkọtaya tí ọjọ́ orí wọn wà láàárín ọdún mọ́kàndínlógún sí márùndínlógójì, tí wọ́n ní òye àwọn iṣẹ́ pàtó kan tí a nílò ní Bẹ́tẹ́lì. Láfikún sí i, a rọ àwọn arákùnrin àti arábìnrin tí wọ́n fi díẹ̀ lé ní ọmọ ọdún márùndínlógójì, tí wọ́n sì mọ àwọn àkànṣe iṣẹ́ kan tí a lè lò ní Bẹ́tẹ́lì, pé kí wọ́n kọ̀wé fún iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì. Bí àpẹẹrẹ, lára àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ tí a nílò ni àwọn dentist (olùtọ́jú eyín), àwọn dókítà, àwọn accountant (olùṣirò owó), àwọn architect (ayàwòrán ilé), àwọn ẹnjiníà, àwọn nọ́ọ̀sì tó níwèé ẹ̀rí ìjọba, àwọn tó ń tún ọkọ̀ ṣe, àtàwọn electronic technician (onímọ̀ nípa ohun abánáṣiṣẹ́). Àmọ́ o, a kò rọ ẹ̀yin tẹ́ ẹ fẹ́ wá pé kí ẹ lọ gba àkànṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú èrò pé ìyẹn á jẹ́ ká tètè pè yín sí Bẹ́tẹ́lì. Àwọn tó ti gba àkànṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tẹ́lẹ̀, bóyá ṣáájú kí wọ́n tó wá sínú òtítọ́, lè kọ gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ ìsọfúnni nípa àwọn iṣẹ́ tí wọ́n mọ̀ sínú ìwé, kí wọ́n sì fi ránṣẹ́ pẹ̀lú fọ́ọ̀mù iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì.

14 Bó o bá fi fọ́ọ̀mù ránṣẹ́, àmọ́ tí a kò ké sí ọ láti wá sìn ní Bẹ́tẹ́lì, má ṣe jẹ́ kí ìyẹn mú ọ rẹ̀wẹ̀sì. O lè máa kọ̀wé béèrè fún iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì lẹ́ẹ̀kan lọ́dọọdún. Àwọn arákùnrin kan ti yọ̀ǹda ara wọn fún iṣẹ́ ìsìn onígbà kúkúrú. Wọ́n lè kọ̀wé láti wá bá wa ṣiṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì fún oṣù kan, oṣù méjì, tàbí oṣù mẹ́ta.

15 Sísin Jèhófà ní ìbákẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn arákùnrin Kristi jẹ́ àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ fún àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì. Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso mọrírì ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ gbogbo àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn, tí wọ́n sì ń lo ara wọn láti pèsè àwọn ohun tí ẹgbẹ́ ará wa jákèjádò ayé nílò.—Fíl. 2:20-22; 2 Tím. 4:11.

16 Ẹ̀yin Ọ̀dọ́—Ẹ Múra Sílẹ̀ Nísinsìnyí fún Iṣẹ́ Ìsìn Bẹ́tẹ́lì: Tipẹ́tipẹ́ ṣáájú kéèyàn tó di ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún tó jẹ́ ọjọ́ orí tó kéré jù tá a béèrè lọ́wọ́ àwọn tó bá fẹ́ wá sìn ní Bẹ́tẹ́lì ni ìmúrasílẹ̀ ti ní láti bẹ̀rẹ̀. Kí làwọn ọ̀dọ́ lè ṣe láti múra ara wọn sílẹ̀ fún iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì? Jésù sọ pé: “Ta ni nínú yín tí ó fẹ́ kọ́ ilé gogoro kan tí kò ní kọ́kọ́ jókòó, kí ó sì gbéṣirò lé ìnáwó náà?” (Lúùkù 14:28) Níwọ̀n bí ìmúrasílẹ̀ àti ìwéwèé ti ṣe pàtàkì fún iṣẹ́ ilé kíkọ́ èyíkéyìí, ó mà ṣe pàtàkì o pé kí àwọn ọ̀dọ́ fara balẹ̀ ronú nípa bí wọ́n ṣe ń fi ìpìlẹ̀ lélẹ̀ fún ọjọ́ ọ̀la wọn nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà! Wọ́n ní láti fi ìpìlẹ̀ tó dúró sán-ún lélẹ̀ ní kùtùkùtù ìgbésí ayé wọn kí ọwọ́ wọn bàa lè tẹ àwọn góńgó tẹ̀mí. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́, báwo ni ìpìlẹ̀ tó ò ń fi lélẹ̀ ti dára tó? Bó o bá fẹ́ láti sìn ní Bẹ́tẹ́lì, wàá jàǹfààní nípa fífarabalẹ̀ gbé àwọn ìsọfúnni tó wà nísàlẹ̀ yìí yẹ̀ wò.

17 “Wá Àyè” fún Àǹfààní Iṣẹ́ Ìsìn Àkànṣe Yìí: A rọ àwọn arákùnrin wa tí wọ́n ṣì jẹ́ ọ̀dọ́ láti lo okun wọn nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún nígbà tí wọn kò tíì ní ẹrù iṣẹ́ bíbójútó ìdílé. Bí wọ́n bá wá pinnu láti ṣègbéyàwó lẹ́yìn náà, wọ́n á túbọ̀ ṣe ojúṣe wọn dáradára gẹ́gẹ́ bí ọkọ nítorí pé wọ́n á ti ní ọ̀pọ̀ ìrírí nínú ìgbésí ayé àti nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni. Lẹ́yìn tí àwọn kan ti sìn fún bí ọdún mélòó kan ní Bẹ́tẹ́lì, wọ́n ṣègbéyàwó, ó sì ti ṣeé ṣe fún wọn láti máa bá iṣẹ́ ìsìn wọn lọ níbẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi tọkọtaya. Bí wọ́n bá wá ní àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn mìíràn lẹ́yìn náà, irú bí iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà àkànṣe tàbí iṣẹ́ alábòójútó arìnrìn-àjò, ó dájú pé wọn kò ní kábàámọ̀ àkókò tí wọ́n yà sọ́tọ̀ láti fi ṣiṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì.

18 Má Ṣe Jẹ́ Kí Ìlépa Ọrọ̀ Àlùmọ́ọ́nì Pín Ọkàn Rẹ Níyà: Ó yẹ kí ọ̀dọ́ kọ̀ọ̀kan bi ara rẹ̀ léèrè pé: ‘Ṣé góńgó tí mò ń lépa lẹ́yìn tí mo bá ti parí ilé ẹ̀kọ́ mi ni láti máa ṣe iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ tí yóò máa gba gbogbo àkókò mi tàbí ó jẹ́ láti máa sin Jèhófà ní àkókò kíkún?’ Ká sòótọ́, sísin Jèhófà ní àkókò kíkún yóò béèrè fífi àwọn nǹkan kan du ara rẹ. Ṣùgbọ́n lílépa iṣẹ́ ńláńlá inú ayé náà yóò béèrè pé kó o fi àwọn nǹkan kan du ara rẹ! Níkẹyìn, ìgbòkègbodò wo ló máa mú àbájáde pípẹ́títí tó sì ṣàǹfààní wá ní ti tòótọ́? Jésù dáhùn ìbéèrè yìí lọ́nà tó ṣe kedere. (Mátíù 6:19-21) Ǹjẹ́ kí ọkàn wa má ṣe sún wa láti máa lépa àwọn iṣẹ́ ńláńlá inú ayé tàbí ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì, kàkà bẹ́ẹ̀ kó sún wá láti máa ṣe iṣẹ́ ìsìn àtọkànwá fún Jèhófà.

19 Àwọn Tó Ń Sìn ní Bẹ́tẹ́lì Gbọ́dọ̀ Jẹ́ Oníwà Mímọ́: Onísáàmù béèrè pé: “Báwo ni ọ̀dọ́kùnrin ṣe lè mú ipa ọ̀nà rẹ̀ mọ́?” Ó dáhùn pé: “Nípa ṣíṣọ́ra ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ [Jèhófà].” (Sm. 119:9) Láti ṣe èyí, wọ́n ní láti yẹra fún ṣíṣe ohunkóhun tó bá ń gbé ìwà ìbàjẹ́ ètò àwọn nǹkan Sátánì lárugẹ. Díẹ̀ lára àwọn ìdẹkùn tí Sátánì ń lò láti fi ṣèdíwọ́ fún àwọn ọ̀dọ́ wa kí ọwọ́ wọn má bàa tẹ àwọn góńgó tẹ̀mí ni àwọn nǹkan bí, àwọn ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, híhùwà tí kò bójú mu sí ẹ̀yà òdìkejì, àwọn orin tí kò bójú mu, àwọn eré ìnàjú tí kò dára fún ọmọlúwàbí, àti kéèyàn máa mutí láti kékeré. A ní láti dúró gbọn-in láìyẹsẹ̀ tá a bá fẹ́ yẹra fún àwọn ọgbọ́n àrékérekè wọ̀nyí. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́, bó o bá rí i pé ò ń lọ́wọ́ sí èyíkéyìí lára àwọn nǹkan wọ̀nyí, jíròrò àwọn ọ̀ràn wọ̀nyí pẹ̀lú àwọn alàgbà ìjọ rẹ, kẹ́ ẹ sì yanjú wọn ṣáájú kó o tó kọ̀wé béèrè fún iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì. Níní ẹ̀rí ọkàn mímọ́ ṣe pàtàkì láti sin Jèhófà ní kíkún.—1 Tím. 1:5.

20 Mọ Béèyàn Ṣe Ń Gbé Nírẹ̀ẹ́pọ̀ Pẹ̀lú Àwọn Ẹlòmíràn: Ohun pàtàkì kan tó máa jẹ́ kó o gbádùn iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì ni mímọ bó o ṣe lè gbé nírẹ̀ẹ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Àwọn arákùnrin àti arábìnrin tí ipò àtilẹ̀wá wọn yàtọ̀ lónírúurú ọ̀nà ló para pọ̀ di ìdílé Bẹ́tẹ́lì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ní onírúurú àkópọ̀ ìwà tó ń mú kí ẹwà tẹ̀mí Bẹ́tẹ́lì pọ̀ sí i, síbẹ̀ ó tún lè fa ìṣòro lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Bó o bá ń ronú nípa iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì, ó dára kó o bi ara rẹ léèrè pé: ‘Ǹjẹ́ mo máa ń tètè bínú nígbà tí àwọn ẹlòmíràn ò bá fara mọ́ èrò mi? Ǹjẹ́ ó rọrùn fún àwọn ẹlòmíràn láti bá mi da nǹkan pọ̀?’ Bó o bá ní láti ṣe àtúnṣe lórí àwọn nǹkan wọ̀nyí, bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ lórí wọn láti ìsinsìnyí lọ. Bó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, á rọrùn fún ọ láti máa bá àwọn ẹlòmíràn nínú ìdílé Bẹ́tẹ́lì gbé àti láti máa bá wọn ṣiṣẹ́ nírẹ̀ẹ́pọ̀.

21 Ẹ̀yin Òbí, Ẹ Dá Àwọn Ọmọ Yín Lẹ́kọ̀ọ́: Kí lẹ̀yin òbí lè ṣe láti fún àwọn ọmọ yín níṣìírí kí wọ́n lè ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún? Jésù sọ pé: “Gbogbo ẹni tí a fún ní ìtọ́ni lọ́nà pípé yóò dà bí olùkọ́ rẹ̀.” (Lúùkù 6:40) Kò sí àní-àní pé ńṣe ni akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n bá ti dá lẹ́kọ̀ọ́ dáadáa yóò máa fi àwọn ànímọ́ dáradára tí olùkọ́ rẹ̀ ní hàn. Ó yẹ kí àwọn Kristẹni òbí máa fi ìlànà yìí sọ́kàn bí wọ́n ṣe ń ṣiṣẹ́ kára láti tọ́ àwọn ọmọ wọn “pẹ̀lú fífọkànsin Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ìfojúsùn [wọn].” (1 Tím. 4:7) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ojú tí àwọn òbí bá fi ń wo nǹkan tẹ̀mí náà làwọn ọmọ sábà máa ń fi wò ó, ó yẹ kí àwọn òbí béèrè lọ́wọ́ ara wọn pé: ‘Ǹjẹ́ àwa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan mọyì iṣẹ́ tí àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni ń ṣe ní Bẹ́tẹ́lì láti mú kí ire ìjọsìn tòótọ́ Jèhófà tẹ̀ síwájú? Ǹjẹ́ a gbà pé ìbùkún Jèhófà wà lórí ìṣètò Bẹ́tẹ́lì? Ǹjẹ́ a gbà pé lílo ìgbésí ayé ẹni fún iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ni ohun tó dára jù lọ tí àwọn ọmọ wa lè fi ìgbésí ayé wọn ṣe?’ Ìmọrírì àtọkànwá tí àwa fúnra wa bá ní fún iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì àti iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe níbẹ̀ yóò jẹ́ ká lè ran àwọn ọmọ wa lọ́wọ́ kí àwọn náà lè ní irú ìmọrírì kan náà.

22 Ẹlikénà àti Hánà ní ìmọrírì àtọkànwá fún ìjọsìn tòótọ́. (Ẹkís. 23:17; 1 Sám. 1:3, 4, 9, 19; 2:19) Hánà nífẹ̀ẹ́ jíjinlẹ̀ sí ìjọsìn tòótọ́ bíi ti ọkọ rẹ̀. Ó mọ̀ látọkànwá pé ojúṣe òun ni láti ṣètìlẹyìn fún ìjọsìn tòótọ́ ní àgọ́ ìjọsìn. Hánà wá jẹ́jẹ̀ẹ́ pé bí Jèhófà bá fún òun lọ́mọ ọkùnrin kan, òun yóò yọ̀ǹda rẹ̀ fún iṣẹ́ ìsìn ní àgọ́ ìjọsìn. (1 Sám. 1:11) Òfin Mósè fàyè gba àwọn ọkọ láti fagi lé ẹ̀jẹ́ tí àwọn aya wọ́n bá jẹ́, bí ẹ̀jẹ́ náà kò bá wu ọkọ wọn. (Núm. 30:6-8) Àmọ́, ó ṣe kedere pé Ẹlikénà fọwọ́ sí ẹ̀jẹ́ tí Hánà jẹ́, ìyẹn fi hàn pé òun náà gbárùkù ti ìtìlẹyìn tí aya rẹ̀ ń ṣe fún ìjọsìn tòótọ́!—1 Sám. 1:22, 23.

23 Ǹjẹ́ ìmọrírì àti ẹ̀mí rere tí àwọn òbí Sámúẹ́lì fi hàn ní ipa rere lórí ọmọ wọn? Dájúdájú, bẹ́ẹ̀ ni. Nígbà tí Sámúẹ́lì wà lọ́mọdé, ó fi ẹ̀mí ìmúratán àti ìṣòtítọ́ bójú tó àwọn iṣẹ́ tí wọ́n yàn fún un, ó sì gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn àkànṣe mìíràn nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. Ìfẹ́ tí Ẹlikénà àti Hánà fi hàn sí iṣẹ́ ìsìn tí Sámúẹ́lì ń ṣe ní àgọ́ ìjọsìn kò wá sópin lẹ́yìn tó ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ níbẹ̀. Wọ́n máa ń bẹ̀ ẹ́ wò déédéé láti fún un ní ìṣírí àti ìtìlẹyìn bó ṣe ń ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún.—1 Sám. 2:18, 19.

24 Àpẹẹrẹ títayọ mà ni Ẹlikénà àti Hánà fi lélẹ̀ fún àwọn Kristẹni òbí lónìí o! Bí àwọn ọmọ wa bá ń gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ ìmọrírì àtọkànwá tá à ń sọ nípa àǹfààní iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì, tí wọ́n sì ń rí ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ tá à ń fi hàn nínú mímú kí ire Ìjọba Ọlọ́run tẹ̀ síwájú, ìfẹ́ láti sin àwọn ẹlòmíràn yóò máa jinlẹ̀ nínú àwọn náà. Ọ̀pọ̀ òbí ló ń ṣàṣeyọrí nínú ríran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti ní irú ẹ̀mí dáradára yìí.

25 Ẹ̀yin ọ̀dọ́, ẹ rántí pé “ayé ń kọjá lọ, bẹ́ẹ̀ sì ni ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò dúró títí láé.” (1 Jòh. 2:17) Ẹ máa bá a lọ láti lépa àwọn góńgó tẹ̀mí, títí kan àǹfààní àkànṣe ti iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì. Ẹ̀yin òbí, ẹ fara wé àpẹẹrẹ àwọn olóòótọ́ ayé ọjọ́un, tí wọ́n rọ àwọn ọmọ wọn láti ní ìfọkànsin Ọlọ́run. (2 Pét. 3:11) Síwájú sí i, ẹ jẹ́ kí gbogbo wa ṣe ipa tiwa láti ran àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin ọ̀dọ́ wa lọ́wọ́ láti sin Ẹlẹ́dàá wa Atóbilọ́lá dé ibi tó bá ṣeé ṣe fún wọn dé, níwọ̀n bí èyí ti ní “ìlérí ìyè ti ìsinsìnyí àti ti èyí tí ń bọ̀.”—1 Tím. 4:8; Oníw. 12:1.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 4]

Àwọn Nǹkan Tó Ṣe Kókó Tí À Ń Béèrè fún Iṣẹ́ Ìsìn Bẹ́tẹ́lì

● Ẹni tó ti ṣèrìbọmi fún ó kéré tán ọdún kan

● Tó jẹ́ ẹni tẹ̀mí tó sì ní ìfẹ́ àtọkànwá fún Jèhófà àti ètò àjọ rẹ̀

● Tó dúró sán-ún nípa tẹ̀mí, tí kò ní ìṣòro ọpọlọ, tí kò ní ìdààmú ọkàn, tí ìlera rẹ̀ sì jí pépé

● Tó lè ka èdè Gẹ̀ẹ́sì, tó lè kọ ọ́ sílẹ̀, tó sì lè sọ ọ́ dáradára

● Tí ọjọ́ orí rẹ̀ wà láàárín ọdún mọ́kàndínlógún sí márùndínlógójì

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́