Fífi Ìmọrírì Wo “Ilé Ọlọrun”
“OHUN kan ni èmi ń tọrọ ní ọ̀dọ̀ Oluwa, ohun náà ni èmi ó máa wá kiri: kí èmi kí ó lè máa gbé inú ilé Oluwa ní ọjọ́ ayé mi gbogbo, kí èmi kí ó lè máa wo ẹwà Oluwa, kí èmi kí ó sì máa fi inúdídùn wo tẹ́ḿpìlì rẹ̀.”—Orin Dafidi 27:4.
Ọba Dafidi tí ó ní ìmọrírì fi pẹ̀lú ayọ̀, tàbí inúdídùn wo tẹ́ḿpìlì Jehofa. Ìwọ ha ní ìmọ̀lára kan náà nípa àwọn ọ̀gangan ibi ìkóríjọ fún ìjọsìn tòótọ́ lónìí bí? Àwọn ilé Beteli tí wọ́n ju 95 tí ń bẹ ní ẹ̀ka Watch Tower Society wà lára àwọn ilé-lílò tí ó níí ṣe pẹ̀lú ìjọsìn Jehofa ní àkókò wa.
Helga, tí ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní ilé náà ní Germany ní ọdún 1948 ṣàlàyé pé, “Bíbojúwẹ̀yìn wo ọ̀pọ̀ ọdún iṣẹ́-ìsìn Beteli mi mú mi kún fún ìmoore jíjinlẹ̀ àti ìmọrírì ńlá, èyí tí ó ti ń ga síi láti ọdún dé ọdún.” Helga jẹ́ ọ̀kan lára 13,828 àwọn aláyọ̀ òṣìṣẹ́ Beteli kárí ayé ní Beteli tí wọ́n ‘wo ẹwà Jehofa’ ní ọdún iṣẹ́-ìsìn 1993. Kí ni ohun náà gan-an tí orúkọ náà Beteli túmọ̀sí? Báwo ní ọ̀kọ̀ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ṣe lè fi ìmọrírì wo ìṣètò yìí, yálà ó ń ṣiṣẹ́sin Ọlọrun ní Beteli tàbí ní ìta?
Orúkọ kan tí Ó Béèrè fún Ìfọkànsìn
“Beteli” jẹ́ orúkọ kan tí ó bá a mu wẹ́kú jùlọ, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Heberu náà Behth-ʼElʹ ti túmọ̀sí “Ilé Ọlọrun.” (Genesisi 28:19, àkíyèsí ẹsẹ̀-ìwé) Bẹ́ẹ̀ni, Beteli jọ ilé kan tí a ṣètò rẹ̀ dáradára, tàbí ‘agboolé kan tí a fi ọgbọ́n kọ́,’ níbi tí Ọlọrun àti ìfẹ́-inú rẹ̀ ti jẹ́ ohun tí a kó àfiyèsí jọ lé lórí. (Owe 24:3) Herta fi ìmọrírì sọ pé, “Ó dàbí gbígbé nínú ìdílé kan. A ní ọ̀nà ìgbàṣiṣẹ́ ojoojúmọ́ kan tí a ṣètò rẹ̀ dáradára.” Ó ti ń ṣiṣẹ́sìn ní Beteli kan náà gẹ́gẹ́ bíi ti Helga fún ohun tí ó ju ọdún 45 lọ. Mẹ́ḿbà kọ̀ọ̀kan lára ìdílé ńlá yìí ní iṣẹ́ àti àyè tirẹ̀, tí ń mú kí ó nímọ̀lára ayọ̀ àti àìléwu. Lọ́nà tí ó ṣedéédéé pẹ̀lú orúkọ náà Beteli, ìṣètò àti ọnà ìgbàṣàbójútó tí ó dára ni ó jẹ́ àmì ànímọ́ ẹ̀ka-iṣẹ́ kọ̀ọ̀kan. Èyí ń gbé àlàáfíà lárugẹ, ó ń mú kí ìwàásù gbígbéṣẹ́ nípa ìhìnrere náà ṣeéṣe, ó sì ń fún àwọn ìjọ ní ìdí yíyèkooro láti fọwọ́ mú “Ilé Ọlọrun” pẹ̀lú ọ̀wọ̀ gíga jùlọ.—1 Korinti 14:33, 40.
Èéṣe tí irú àwọn ilé-lílò bẹ́ẹ̀ fi jẹ́ ohun yíyẹ? Fún àpẹẹrẹ, ìwé ìròyìn yìí ni a mújáde nínú ibi-ìtẹ̀wé kan ní Beteli. Ìwàásù ìhìn-iṣẹ́ Ìjọba náà àti ìpínkiri oúnjẹ tẹ̀mí, àwọn ohun méjì tí Jesu Kristi ti rí tẹ́lẹ̀, mú kí àwọn ìṣètò ti ètò-àjọ bíi ti Beteli jẹ́ aláìṣeéyẹ̀sílẹ̀—a ń ṣètìlẹ́yìn fún un nípasẹ̀ àwọn òṣìṣẹ́ tí wọ́n múratán tí gbogbo àwọn olùjọ́sìn Jehofa sì ní ọ̀wọ̀ gíga fún un.—Matteu 24:14, 45.
Ìwọ yóò ha fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ púpọ̀ síi nípa ọ̀nà ìgbàṣiṣẹ́ déédéé wa ojoojúmọ́ níhìn-ín bí? Níbi tí Helga àti Herta ń gbé, ìró ohùn gbígbádùnmọ́ni máa ń dún ní gbogbo ilé ibùgbé ní agogo 6:30 òwúrọ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé púpọ̀ nínú àwọn 800 òṣìṣẹ́ déédéé náà ti máa ń jí ṣáájú ìgbà náà láti múrasílẹ̀ fún ọjọ́ náà. Ní agogo 7:00 òwúrọ̀, ní Monday títí di Saturday, ìdílé máa ń pàdépọ̀ ní àwọn gbọ̀ngàn ìjẹun fún ìjíròrò ẹsẹ̀ ìwé mímọ́ ojoojúmọ́, tàbí ìjọsìn òwúrọ̀. Oúnjẹ òwúrọ̀ tí ń fáralókun yóò tẹ̀lé e. Ọjọ́ iṣẹ́ kọ̀ọ̀kan máa ń bẹ̀rẹ̀ ní agogo 8:00 òwúrọ̀ ó sì máa ń gba wákàtí mẹ́jọ, ìsinmi fún oúnjẹ ọ̀sán nìkan ni ó máa ń là á láàárín. (Ìdílé náà sábà máa ń ṣiṣẹ́ fún ìdajì ọjọ́ ní Saturday.) Ìbáà jẹ́ ní ilé ìgbọ́únjẹ, ibi ìtẹ̀wé, ibi ìfọṣọ, ní àwọn ọ́fíìsì, ìsọ̀ iṣẹ́, ibi ìdìwépọ̀, tàbí ní ẹ̀ka iṣẹ́ èyíkéyìí mìíràn, púpọ̀ wà láti ṣe.
Ní àwọn ọwọ́ ìrọ̀lẹ́ àti ní òpin ọ̀sẹ̀, àwọn mẹ́ḿbà ìdílé ń darapọ̀ pẹ̀lú àwọn ìjọ àdúgbò ní àwọn ìpàdé àti nínú ìwàásù fún gbogbo ènìyàn. Ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin ní Beteli jẹ́ alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́-òjíṣẹ́ nínú àwọn ìjọ wọ̀nyí. Àwọn Ẹlẹ́rìí àdúgbò mọrírì ìfọwọ́sọwọ́pọ̀ wọn nítòótọ́, àwùjọ méjèèjì ń ṣiṣẹ́ papọ̀ ní ìṣọ̀kan gẹ́gẹ́ bí ara kan, pẹ̀lú ọ̀wọ̀ àti ìgbọ́ra-ẹni-yé fún tọ̀tún-tòsì. (Kolosse 2:19) Òṣìṣẹ́ Beteli kọ̀ọ̀kan mọ̀ pé iṣẹ́ àyànfúnni òun nínú “Ilé Ọlọrun” wà ní ipò kìn-ín-ní sí àwọn ìgbòkègbodò mìíràn. Bí ó ti wù kí ó rí, ìtara-ọkàn fún wíwàásù àti ṣíṣàjọpín pẹ̀lú ìjọ, papọ̀ pẹ̀lú ìṣesí wíwàdéédéé, ń fún òṣìṣẹ́ Beteli lókun, ó ń mú ayọ̀ rẹ̀ pọ̀ síi, ó sì ń sọ ọ́ di mẹ́ḿbà kan tí ó túbọ̀ ń sèso nínú ìdílé náà. Ẹ sì wo bí àwọn ànímọ́ wọ̀nyí ti ṣekókó tó nígbà tí ẹnìkan bá ń ṣiṣẹ́ nínú “ilé” kan tí orúkọ rẹ̀ sopọ̀ mọ́ ìfọkànsìn tọkàntọkàn!
Ṣíṣe Iṣẹ́-Ìsìn Beteli ní Àṣeyọrísírere
Kí ni ó ti ran àìníye ènìyàn lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́-ìsìn Beteli ní àṣeyọrísírere? Àwọn mẹ́ḿbà ìdílé Beteli ní France tí wọ́n ti ní ìrírí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́yìn ṣàlàyé gẹ́gẹ́ bí ó ti tẹ̀lé e yìí: “Ìfẹ́ fún Jehofa. Níní ìpinnu náà láti máa forítì í nìṣó níbikíbi tí ó bá fi wá sí; ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn, ìtẹríba, àti ìṣègbọràn sí ìtọ́sọ́nà tí Society bá fún wa.” (Denise) “Mo ti ṣàkíyèsí bí ó ti ṣe pàtàkì tó láti bọ̀wọ̀ fún ìlànà tí Paulu mẹ́nukàn ní Romu 12:10: ‘Níti ọlá, ẹ máa fi ẹnìkejì yín ṣáájú.’ Ẹsẹ̀ ìwé mímọ́ yìí fi ìjẹ́pàtàkì ṣíṣàì fi dandan lé e pé èrò tiwa ṣáá ni a gbọ́dọ̀ tẹ́wọ́gbà hàn wá ṣùgbọ́n, kàkà bẹ́ẹ̀, kí a máa gba èrò àwọn ẹlòmíràn yẹ̀wò. Ní èdè mìíràn, kí a má máa wá ìlọ́lá jù.” (Jean-Jacques) Barbara sọ pé, “Ọ̀wọ̀ wa fún iṣẹ́-ìsìn Beteli ni a lè bàjẹ́ bí a bá ń fi ojú-ìwòye tí ẹ̀ran-ara, ti ẹ̀dá wo àwọn nǹkan, nítorí pé èyí lè sún wa débi tí a ó fi gbàgbé òtítọ́ náà pé Jehofa ni ó ń darí ètò-àjọ rẹ̀. A lè pàdánù irú ọ̀wọ̀ bẹ́ẹ̀ bí a bá kọsẹ̀ nítorí àìpé àwọn ẹlòmíràn.”
Olúkúlùkù ènìyàn tí ń bẹ ní Beteli jẹ́ aláìpé, nítorí náà ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ béèrè fún ìfarabalẹ̀ ronú. Àwọn ọ̀dọ́ tàbí àwọn tí kò tíì pẹ́ tí wọ́n dé yóò ṣe dáradára láti máṣe fi ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ wọn mọ sí àárín àwọn ojúgbà wọn nìkanṣoṣo. Àwọn tí wọ́n lè fi ìtẹ̀sí láti ráhùn tàbí láti ronú lọ́nà òdì hàn kìí ṣe alábàákẹ́gbẹ́ tí ń gbéniró ní Beteli tàbí nínú ìjọ. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ṣíṣàfarawé “ọgbọ́n tí ó ti òkè wá,” tí a ṣàpèjúwe ní Jakọbu 3:17, ń mú ìbùkún wá. Èyí ni “a kọ mọ́, a sì ní àlàáfíà, a ní ìpamọ́ra, kìí sìí ṣòro láti bẹ̀, a kún fún àánú àti fún èso rere, ní àìsí ègbè, àti láìsí àgàbàgebè.” Irú àwọn ànímọ́ bẹ́ẹ̀, papọ̀ pẹ̀lú ìpamọ́ra àti inúrere, ṣeérí ní “Ilé Ọlọrun,” ní mímú kí ìdúró ẹnìkan níbẹ̀ gbádùn kí ó sì runisókè. Àní àwọn olùṣèbẹ̀wò tí wọn kìí ṣe Ẹlẹ́rìí pàápàá sábà máa ń sọ bí ìwà dídára, ìwà-bí-ọ̀rẹ́, àti ẹ̀mí ayọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ náà tí jọ wọ́n lójú tó.
Anny, tí ó ti lé ní 70 ọdún tí ó sì ti jẹ́ mẹ́ḿbà ìdílé Beteli ní Germany láti ọdún 1956, ṣàlàyé bí ó ṣe pa ìmúratán rẹ̀ láti ṣiṣẹ́sìn mọ́: “Fún ire-aásìkí mi tẹ̀mí, mo ṣe ìsapá ńláǹlà láti mọ àwọn ìsọfúnni tí ó dé kẹ́yìn nínú àwọn ìtẹ̀jáde Society, láti lọ sí àwọn ìpàdé déédéé, àti láti ní ìpín déédéé nínú wíwàásù. Mo tún gbìyànjú láti pa ìlera dídára mọ́ nípa ṣíṣeré ìmárale ní òròòwúrọ̀, nípa yíyẹra fún lílo ẹ̀rọ agbéniròkè ní ọ̀pọ̀ ìgbà jùlọ, àti nípa fífẹsẹ̀ rìn bí ó bá ti lè ṣeéṣe tó, ní pàtàkì nínú iṣẹ́-ìsìn pápá.”
Ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n ti ní ìrírí nínú ìgbésí-ayé Beteli yóò gbà pẹ̀lú Anny. Wọn kò dẹ́kun rí láti máa kẹ́kọ̀ọ́, wọn kò dáwọ́ iṣẹ́ ṣíṣe dúró. Ìlera tí ara béèrè pé kí wọ́n sun oorun tí ó pọ̀ tó kí wọ́n ṣe eré ìmárale díẹ̀, kí wọ́n sì fi ìwọ̀ntunwọ̀nsì nínú jíjẹ àti mímu hàn. Èyí tí ó ṣe pàtàkì ju gbogbo rẹ̀ lọ, wọn kò pa àdúrà ti ara-ẹni àti ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli tì.
Ọ̀wọ̀ Gíga fún Iṣẹ́-Ìsìn Mímọ́-Ọlọ́wọ̀ ní Beteli
Ìbéèrè náà tí a sábà máa ń béèrè lọ́wọ́ àwọn mẹ́ḿbà Beteli ni pé, “Níbo ni o ti ń ṣiṣẹ́?” Àwọn iṣẹ́-àyànfúnni pín sí onírúurú, ṣùgbọ́n ọ̀kọ̀ọ̀kan ni ó yẹ kí olúkúlùkù ní ọ̀wọ̀ gíga fún. Èéṣe? Nítorí pé iṣẹ́-àyànfúnni kọ̀ọ̀kan—yálà ó jẹ́ ṣíṣiṣẹ́ nídìí ẹ̀rọ tí ń tẹ oúnjẹ tẹ̀mí, fífọ àwọn aṣọ, gbígbọ́únjẹ àti ṣíṣe iṣẹ́ ìmọ́tótó fún ìdílé, tàbí ṣíṣe iṣẹ́ ọ́fíìsì—ni gbogbo wọn parapọ̀ jẹ́ iṣẹ́-ìsìn mímọ́-ọlọ́wọ̀. Gẹ́gẹ́ bí a ti mẹ́nukàn án lókè, àwọn Kristian kìí ṣe ìyàsọ́tọ̀ olójúṣàájú. Rántí pé gbogbo iṣẹ́ tí ó yẹ ní ṣíṣe tí àwọn àlùfáà àti àwọn Lefi ń ṣe ní tẹ́ḿpìlì, nínú àgbàlá àti àwọn gbọ̀ngàn ìjẹun rẹ̀, ni a ka gbogbo wọn sí iṣẹ́-ìsìn mímọ́-ọlọ́wọ̀ fún Jehofa. Ìyẹn ní nínú dídúḿbú àti kíkun àwọn ẹran fún ìrúbọ, fífi òróró sínú àwọn àtùpà, àti iṣẹ́ ìmọ́tótó àti ṣíṣe àwọn iṣẹ́ ẹ̀ṣọ́ pàápàá. Lọ́nà kan náà, iṣẹ́ àyànfúnni kọ̀ọ̀kan ní Beteli jẹ́ ìgbòkègbodò tí ń tẹ́nilọ́rùn tí ó sì níláárí “nínú iṣẹ́ Oluwa,” fún ìdí yìí ó jẹ́ àǹfààní àrà-ọ̀tọ̀.—1 Korinti 15:58.
Ní ṣókí gbé ìwà ànímọ́ kan tí ó lè ṣèdíwọ́ fún wa láti máṣe fi ìmọrírí wo “Ilé Ọlọrun” yẹ̀wò. Àwọn Kristian tí wọ́n wà ní Beteli àti níta gbọ́dọ̀ ṣọ́ra fún ìlara àti owú, tí wọ́n jẹ́ “ìbàjẹ́ egungun.” (Owe 14:30) Kò sí ìdí fún ẹnikẹ́ni láti ṣe ìlara nítorí àwọn àǹfààní iṣẹ́-ìsìn àwọn òṣìṣẹ́ Beteli. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, kò sí àyè fún ìlara, tí ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn iṣẹ́ ti ara láàárín ìdílé Beteli. Fi tìrẹ̀lẹ̀ tìrẹ̀lẹ̀ dúró—ìyẹn ni ìmọ̀ràn yíyèkooro fún ẹnìkan tí ó lè dàbí ẹni pé a ti gbójúfòdá nígbà tí a ń fún àwọn ẹlòmíràn ní àwọn àǹfààní tí ó túbọ̀ pọ̀. Ó ṣetán, àwọn ènìyàn tí ipò àtilẹ̀wá wọn yàtọ̀síra púpọ̀ púpọ̀ níti ìṣúnná-owó ń gbé papọ̀ tímọ́tímọ́ ní Beteli. Ẹ sì wo bí ó ti ń jánikulẹ̀ tó bí ẹnìkan bá wo àwọn ipò rẹ̀ “ní ìfiwéra pẹ̀lú ẹlòmíràn”! Jíjẹ́ kí “oúnjẹ àti aṣọ” tẹ́ni lọ́rùn ti ran ọ̀pọ̀ lọ́wọ́ láti máa fi pẹ̀lú ìṣòtítọ́ bá a nìṣó fún ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún nínú “Ilé Ọlọrun.”—Galatia 5:20, 26; 6:4, NW; 1 Timoteu 6:8.
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa àti àràádọ́ta-ọ̀kẹ́ mìíràn ń jàǹfààní ńláǹlà láti inú iṣẹ́-ìsìn tí a kìí sanwó fún èyí tí a ń ṣe ní Beteli—iṣẹ́ tí a ń fi àìro-tara-ẹni-nìkan ṣe láti inú ìfẹ́ fún Ọlọrun àti aládùúgbò. Àwọn ilé Beteli àti àwọn ilé-iṣẹ́ ìtẹ̀wé Watch Tower Society, ni a ń fi àwọn ọrẹ àfínnúfíndọ̀ṣe bójútó ọ̀ràn ìnáwó rẹ̀, bí a ti ń ṣe pẹ̀lú àwọn ilé-lílò mìíràn tí ó jẹ́ ti ìṣàkóso Ọlọrun. (2 Korinti 9:7) Bíi ti Ọba Dafidi àti àwọn olórí àti àwọn ìjòyè Israeli, a lè fi ọ̀wọ̀ àti ìmọrírì wa fún “Ilé Ọlọrun” hàn nípa ṣíṣètìlẹ́yìn fún Society níti ìwàhíhù àti ọ̀ràn-ìnáwó. (1 Kronika 29:3-7) Nísinsìnyí ẹ jẹ́ kí a wo bí ó ti ṣeéṣe láti “wo ẹwà Oluwa” ní Beteli.
Àwọn Ìbùkún ní “Ilé Ọlọrun”
Nígbà tí o bá lọ sí àpéjọ kan, ìwọ ha nímọ̀lára pé o ní ìtẹ́lọ́rùn jíjinlẹ̀, bí àwọn olùjọ́sìn Jehofa tí wọ́n jẹ́ aláyọ̀ ti yí ọ ká bí? Wulẹ̀ rò ó wò ná, òṣìṣẹ́ Beteli kan ní àǹfààní ṣíṣiṣẹ́sin Jehofa láàárín àwùjọ àwọn arákùnrin lójoojúmọ́! (Orin Dafidi 26:12) Ẹ wo ìrètí títayọlọ́lá fún ìdàgbàsókè tẹ̀mí tí ìyẹn nawọ́ rẹ̀ síni! Arákùnrin kan sọ̀rọ̀ àkíyèsí pé òun kẹ́kọ̀ọ́ púpọ̀ síi láti ran òun lọ́wọ́ láti tún àkópọ̀ ànímọ́ òun ṣe láàárín ọdún kan ní Beteli ju bí òun ti ṣe ní ọdún mẹ́ta níbòmíràn. Èéṣe? Nítorí pé kò sí ibòmíràn tí ó ti ní àǹfààní láti ṣàkíyèsí kí ó sì ṣàfarawé ìgbàgbọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Kristian adàgbàdénú.—Owe 13:20.
Kí a sọ ọ́ lọ́nà àpẹẹrẹ, àwọn olùgbaninímọ̀ràn onírìírí ni wọ́n yí ẹnìkan ka ní Beteli. Ní àfikún, a tún ní àǹfààní ti gbígbọ́ àwọn àlàyé tí a múrasílẹ̀ dáradára èyí tí a ṣe nígbà ìjọsìn òwúrọ̀ àti Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé-Ìṣọ́nà ti ìdílé Beteli àti nígbà tí a bá ń fetísílẹ̀ sí àsọyé ní àwọn ìrọ̀lẹ́ Monday. Àwọn tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé ń rí ìtọ́ni gbà ní Ilé-Ẹ̀kọ́ fún Àwọn tí Ó Ṣẹ̀ṣẹ̀ Wọ Beteli a sì ń yanṣẹ́ fún wọn láti ka gbogbo Bibeli tán láàárín oṣù 12 àkọ́kọ́.
Àwọn ìròyìn àti ìrírí láti ọ̀dọ̀ àwọn olùṣèbẹ̀wò láti àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn pèsè ìṣírí síwájú síi fúnni. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, àwọn mẹ́ḿbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso tàbí àwọn aṣojú wọn ń ṣèbẹ̀wò sí àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì. Helga níran pé, “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ní púpọ̀ láti ṣe, àwọn ará náà sábà máa ń wá àkókò fún ọ̀rọ̀ tàbí ẹ̀rín músẹ́ oníwà-bí-ọ̀rẹ́.” Ẹ sì wo bí ó ti fúnni ní ìṣírí tó láti fojú ara-ẹni rí ìhùwàsí títunilára àti oníwọ̀ntunwọ̀nsì ti irú àwọn adúróṣinṣin bẹ́ẹ̀!
Ní Beteli ní pàtàkì ni ẹnìkan ti lè ṣàkíyèsí dáradára nípa bí ètò-àjọ Ọlọrun ti ń ṣiṣẹ́ àti bí ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ti ń ru àwọn ọkàn-àyà àti ọwọ́ tí ó múratán sókè láti ṣiṣẹ́. Arákùnrin kan tí ó ti ń ṣiṣẹ́sìn ní Beteli ní France láti ọdún 1949 ṣàlàyé pé, “Ní Beteli ẹnìkan máa ń nímọ̀lára pé òun túbọ̀ súnmọ́ ‘àárín gbùngbùn ìgbòkègbodò.’” Ó ń bá ọ̀rọ̀ nìṣó pé: “Mo lè sọ nítòótọ́ pé ní tèmi Beteli jẹ́ irú iṣẹ́-ìsìn alákòókò kíkún kan tí ó gbà mí láyè láti yọ̀ọ̀da ìwọ̀n àkókò àti okun tí ó pọ̀ jùlọ fún iṣẹ́-ìsìn Jehofa àti láti ṣiṣẹ́sin iye àwọn ará tí ó pọ̀ jùlọ.” Ìyẹn ha sì kọ́ ní ète gidi tí a ní nínú ìgbésí-ayé—láti ṣe ìfẹ́-inú Ọlọrun? Ní Beteli ẹnìkan lè “kọrin ìyìn ní ọjọ́ gbogbo.” Ẹ wo bí èyí ti jẹ́ ìbùkún tó!—Orin Dafidi 44:8.
Gẹ́gẹ́ bí a ti rí i, ẹnìkan tí ń ṣiṣẹ́ ní ilé Beteli lè wo ẹwà Jehofa kí ó sì rí ọ̀pọ̀ jaburata ìbùkún. (Heberu 6:10) Iṣẹ́-ìsìn nínú “Ilé Ọlọrun” ha jẹ́ ohun kan tí ó níláárí fún ọ bí? Àwọn wọnnì tí wọ́n wà lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa tí wọ́n ti pé ẹni ọdún 19 ó kérétán, tí wọ́n ń gbádùn ìlera dídára nípa ti ara àti tẹ̀mí, tí a sì ‘ròyìn wọn ní rere lọ́dọ̀ àwọn arákùnrin’ bíi tí Timoteu, lè kọ̀wé béèrè fún àtiṣiṣẹ́sìn ní Beteli. (Iṣe 16:2) Ọ̀pọ̀ ti sọ iṣẹ́-ìsìn Beteli di iṣẹ́ ìgbésí-ayé wọn, gẹ́gẹ́ bíi ti àwọn tí a fa ọ̀rọ̀ wọn yọ lókè yìí. Níti wọn ìyánhànhàn jíjinlẹ̀ ti onípsalmu náà—láti ‘gbé nínú ilé Jehofa ní ọjọ́ ayé rẹ̀ gbogbo’—ti di òtítọ́ gidi.
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní ọ̀wọ̀ ńláǹlà fún ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ tí àwọn arákùnrin àti arábìnrin wọn ní Beteli fihàn, àwọn ẹni tí wọ́n ń bójútó àwọn iṣẹ́-àyànfúnni pẹ̀lú ẹ̀mí ìmúratán àti pẹ̀lú ayọ̀. Yálà a ń ṣiṣẹ́sin Jehofa ní Beteli tàbí ní ibòmíràn, gbogbo wa lẹ́nìkọ̀ọ̀kan ní ìdí rere láti nímọ̀lára gẹ́gẹ́ bíi ti Ọba Dafidi—láti fi ìmọrírì, tàbí inúdídùn, wo “Ilé Ọlọrun.”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Àwọn Kristian wọ̀nyí ti rí inúdídùn nínú iṣẹ́-ìsìn mímọ́-ọlọ́wọ̀ ní Beteli tí ó wà ní Germany fún ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún