ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w01 3/15 ojú ìwé 20-24
  • Èyí Ha Lè Jẹ́ Iṣẹ́ Tó Dára Jù Lọ fún Ọ Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Èyí Ha Lè Jẹ́ Iṣẹ́ Tó Dára Jù Lọ fún Ọ Bí?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé Ọlọ́run Ló Máa Ń Peni?
  • Ìgbésí Ayé Tó Lérè
  • Ìgbésí Ayé ní Bẹ́tẹ́lì
  • Kí Lo Lè Ṣe Láti Di Ẹni Tí Ó Tóótun?
  • Gbogbo Wa La Ní Ipa Tí À Ń Kó
  • Ǹjẹ́ O Lè Yọ̀ǹda Ara Rẹ?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
  • Fífi Ìmọrírì Wo “Ilé Ọlọrun”
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Gbogbo Èèyàn La Pè!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Àwọn Iṣẹ́ Rere Tá Ò Ní Gbàgbé
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2019
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
w01 3/15 ojú ìwé 20-24

Èyí Ha Lè Jẹ́ Iṣẹ́ Tó Dára Jù Lọ fún Ọ Bí?

BÍ O bá jẹ́ Kristẹni tó ti ṣe batisí, ó dájú pé ìfẹ́ tóo ní fún Ọlọ́run yóò sún ọ láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Ó sì dájú pé iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà yóò jẹ́ ohun tóo fi ń ṣiṣẹ́ ṣe. Ó ṣe tán, Jésù Kristi pàṣẹ fún gbogbo àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti máa sọni di ọmọ ẹ̀yìn. (Mátíù 28:19, 20) Láìsí àní-àní, o lè máa ṣiṣẹ́ báyìí láti gbọ́ bùkátà ara rẹ. Àmọ́, gẹ́gẹ́ bí ọmọlẹ́yìn Jésù, tí o sì tún jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ ni pé Kristẹni òjíṣẹ́ ni ọ́—ìyẹn ni pé iṣẹ́ wíwàásù Ìjọba náà ló gbawájú nínú ìgbésí ayé rẹ.—Mátíù 24:14.

Bóyá o ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pé ọmọ ogún ọdún tàbí o ti lé díẹ̀ lógún ọdún. Ó ṣeé ṣe kóo ti ronú gan-an lórí iṣẹ́ tóo fẹ́ fi ìgbésí ayé rẹ ṣe. Nígbà tóo bá ń gbé àwọn àǹfààní tóo ní yẹ̀ wò, bí ọkàn rẹ ṣe máa balẹ̀ lè jẹ́ kókó pàtàkì láti ronú lé lórí.

Nítorí náà, ronú nípa ohun tí Jørgen, tó wà ní Denmark sọ nípa iṣẹ́ tó yàn. Jørgen ṣàpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “ọ̀nà ìgbésí ayé tó dára gan-an, èyí tó lè jẹ́ kóo pọkàn pọ̀ sórí iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ.” Eva, obìnrin kan tó jẹ́ ẹni ọdún mọ́kànlélọ́gbọ̀n ní ilẹ̀ Gíríìsì, sọ pé: “Bí mo bá fi ìgbésí ayé mi wéra pẹ̀lú ti àwọn ojúgbà mi, mó sábà máa ń rí i pé ó nítumọ̀, ó láṣeyọrí, ó sì wúni lórí ju tiwọn lọ.” Iṣẹ́ wo ló ń fúnni nírú ìtẹ́lọ́rùn bẹ́ẹ̀? Báwo lo ṣe lè ṣe irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀?

Ṣé Ọlọ́run Ló Máa Ń Peni?

Ó lè ṣòro láti yan iṣẹ́ kan. Àní, àwọn kan tiẹ̀ lè fẹ́ kí Ọlọ́run fúnra rẹ̀ sọ ohun tó fẹ́ káwọn ṣe.

Nígbà tí Mósè wà ní Mídíánì, Jèhófà sọ pé kó padà sí Íjíbítì, kí ó lọ kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò lóko ẹrú. (Ẹ́kísódù 3:1-10) Áńgẹ́lì Ọlọ́run fara han Gídíónì, ẹni tí Ọlọ́run yàn pé kí ó gba Ísírẹ́lì lọ́wọ́ ìnilára. (Àwọn Onídàájọ́ 6:11-14) Àgùntàn ni Dáfídì ń dà nígbà tí Ọlọ́run sọ fún Sámúẹ́lì pé kí ó fi òróró yàn án gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ọba kàn ní Ísírẹ́lì. (1 Sámúẹ́lì 16:1-13) Ọ̀ràn kò rí bẹ́ẹ̀ lónìí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe la ní láti gbé àwọn ọ̀ràn yẹ̀ wò, tí a ó sì pinnu bí a ó ṣe lo àwọn ànímọ́ tí Ọlọ́run fún wa.

Jèhófà ti ṣí “ilẹ̀kùn ńlá tí ń ṣamọ̀nà sí ìgbòkègbodò” sílẹ̀ fún àwọn ọ̀dọ́ Kristẹni lóde òní. (1 Kọ́ríńtì 16:9) Lọ́nà wo? Ní ẹ̀wádún tó kọjá, iye àwọn olùpòkìkí Ìjọba ti lọ sókè láti mílíọ̀nù méjì, ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́fà ó lé márùn-ún [2,125,000], sí ohun tó lé ní mílíọ̀nù mẹ́fà [6,000,000] kárí ayé. Àwọn wo ló ń ṣèrànwọ́ láti pèsè àràádọ́ta ọ̀kẹ́ Bíbélì, àwọn ìwé, ìwé pẹlẹbẹ, ìwé ìròyìn, àti àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú tí ń gbéni ró nípa tẹ̀mí, tí a sì ń lò fún iṣẹ́ wíwàásù ìhìn rere náà kárí ayé? Àǹfààní oníbùkún yìí ni àwọn mẹ́ńbà ìdílé Bẹ́tẹ́lì jákèjádò ayé ń gbádùn.

Ìgbésí Ayé Tó Lérè

Bẹ́tẹ́lì túmọ̀ sí “Ilé Ọlọ́run,” Bẹ́tẹ́lì sì ni ibùgbé àwọn Kristẹni tó yọ̀ǹda ara wọn, tí wọ́n ń sìn ní orílé iṣẹ́ àti ní àwọn ẹ̀ka iléeṣẹ́ Watch Tower Society. (Jẹ́nẹ́sísì 28:19, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW) Àwọn ìdílé Bẹ́tẹ́lì òde òní la lè fi wé ‘agbo ilé tí a fi ọgbọ́n gbé ró,’ tí a ṣètò rẹ̀ dáadáa, tí a sì fìdí rẹ̀ múlẹ̀ sórí ìfẹ́ Jèhófà.—Òwe 24:3.

Kí la lè sọ nípa ipò tó jọ ti inú ìdílé tó wà ní Bẹ́tẹ́lì? Ọ̀kan lára mẹ́ńbà ìdílé Bẹ́tẹ́lì ní Estonia, tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n sọ pé: “Mò ń gbádùn bí mo ṣe wà láàárín àwọn ọ̀rẹ́ Jèhófà ní gbogbo ìgbà. Èyí ṣì ni ohun tó jọ mí lójú jù lọ ní Bẹ́tẹ́lì.”—Sáàmù 15:1, 2.

Jákèjádò ayé, nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta dín ní ẹgbàáwàá [19,500] èèyàn ló ń gbádùn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì. (Sáàmù 110:3) Ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, ìpín mẹ́rìndínláàádọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tó wà ní Bẹ́tẹ́lì ló jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún sí mọ́kàndínlọ́gbọ̀n. Bíi ti Aísáyà, wọ́n ti sọ pé: “Èmi nìyí! Rán mi.” (Aísáyà 6:8) Aísáyà—tó ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà—yọ̀ǹda ara rẹ̀ fún àfikún àǹfààní iṣẹ́ ìsìn. Ó ṣe kedere pé èyí túmọ̀ sí fífi àwọn àǹfààní kan du ara ẹni. Àwọn tó wà ní Bẹ́tẹ́lì fi ilé àti àwọn àyíká tó ti mọ́ wọn lára sílẹ̀, wọ́n tún fi ìyá, baba, ẹ̀gbọ́n, àbúrò, àtàwọn ọ̀rẹ́ sílẹ̀. Wọ́n ń fi àwọn nǹkan wọ̀nyí du ara wọn tinútinú “nítorí ìhìn rere.”—Máàkù 10:29, 30.

Ṣùgbọ́n, àwọn ìbùkún tẹ̀mí tó wà ní Bẹ́tẹ́lì bùáyà! Ọ̀dọ́ kan tó jẹ́ ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì ní Rọ́ṣíà ṣàlàyé pé: “Nípa fífi ara wa rúbọ, a lè kọ́ ọ̀pọ̀ nǹkan tí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti gbé nínú ayé tuntun. Ní tèmi o, mo lè sọ pé àwọn ìbùkún Jèhófà pọ̀ gan-an ju ìrúbọ tí mo ṣe lọ.”—Málákì 3:10.

Ìgbésí Ayé ní Bẹ́tẹ́lì

Báwo ni ìgbésí ayé ṣe rí ní Bẹ́tẹ́lì? Àwọn mẹ́ńbà ìdílé Bẹ́tẹ́lì gbà pé ó gbámúṣé, ó tẹ́ni lọ́rùn, ó tiẹ̀ ń wúni lórí pàápàá. Jens, tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́tàlélógójì, ń gbádùn iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì. Kí nìdí? Ó ní: “Nítorí pé a nímọ̀lára pé a wà lára àwọn tí ń sapá lọ́nà kíkọyọyọ láti ṣe iṣẹ́ pàtàkì kan. Mo lè fojú inú wo bí iṣẹ́ Jèhófà ṣe pọ̀ tó, àti bó ṣe ṣe pàtàkì tó.”

Ìjọsìn òwúrọ̀ ni wọ́n fi máa ń bẹ̀rẹ̀ ọjọ́ Monday sí Saturday ní Bẹ́tẹ́lì. Èyí ni ìjíròrò Bíbélì, tí alàgbà kan tó nírìírí máa ń darí. Wọ́n tún ya wákàtí kan sọ́tọ̀ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ìdílé, èyí tí wọ́n ń fi Ilé Ìṣọ́ ṣe ní alaalẹ́ Monday, ìgbà mìíràn sì wà tí àsọyé kan tí a gbé ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ̀ ka Ìwé Mímọ́, tó ṣe pàtàkì fún ìdílé Bẹ́tẹ́lì, máa ń wáyé.

Kí ló máa ń ṣẹlẹ̀ nígbà téèyàn bá kọ́kọ́ dé Bẹ́tẹ́lì? Kí àwọn tó jẹ́ mẹ́ńbà tuntun lè mọ bí ìgbésí ayé ní Bẹ́tẹ́lì ṣe rí, àwọn arákùnrin tó dàgbà dénú nínú ìdílé náà yóò sọ àwọn àwíyé tó ní í ṣe pẹ̀lú onírúurú apá tí iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì ní. Fún àwọn ọ̀sẹ̀ bíi mélòó kan láàárín ọdún àkọ́kọ́, mẹ́ńbà tuntun kan nínú ìdílé Bẹ́tẹ́lì yóò lọ sí ilé ẹ̀kọ́ gbígbámúṣé tí wọ́n ń ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, èyí tí a ṣètò láti mú kí òye rẹ̀ nínú Ìwé Mímọ́ túbọ̀ gbòòrò sí i. Àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé tún máa ń gbádùn àkànṣe ìtòlẹ́sẹẹsẹ Bíbélì kíkà. Láàárín ọdún wọn àkọ́kọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì, mẹ́ńbà tuntun nínu ìdílé náà máa ń ka odindi Bíbélì látìbẹ̀rẹ̀ dópin.

Kí ni gbogbo ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yìí wà fún? Joshua, ẹni ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n tó jẹ́ mẹ́ńbà ìdílé Bẹ́tẹ́lì ní Hong Kong dáhùn pé: “Bẹ́tẹ́lì ti jẹ́ kí n túbọ̀ mọyì Jèhófà sí i. Mo lè bá ọ̀pọ̀ ará tó nírìírí, tí wọ́n ti fi èyí tó pọ̀ jù lọ nínú ìgbésí ayé wọn sin Jèhófà, kẹ́gbẹ́. Mo tiẹ̀ dìídì ń gbádùn àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ tẹ̀mí, bí ìjọsìn òwúrọ̀ àti Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ tí ìdílé ń ṣe. Síwájú sí i, mo fẹ́ràn bí wọn ò ṣe walé ayé máyà, tí ọ̀nà ìgbésí ayé wọn sì wà létòlétò níbẹ̀. Èyí jẹ́ kí n bọ́ lọ́wọ́ gbígbé ẹ̀mí ara mi gbóná. Mo tún kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí mo ṣe máa bójú tó àwọn nǹkan lọ́nà ti Kristẹni, èyí sì ti ṣàǹfààní gan-an.”

Àwọn mẹ́ńbà ìdílé Bẹ́tẹ́lì máa ń lo èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àkókó àti akitiyan wọn lórí ṣíṣe ohun tí wọ́n yọ̀ǹda ara wọn láti ṣe. Ìyẹn ni pé, iṣẹ́ táa yàn fún wọn láti bójú tó ní Bẹ́tẹ́lì ni olórí ohun tí wọ́n ń fi okun àti ọpọlọ wọn ṣe. Ọ̀pọ̀ nǹkan ló sì wà láti ṣe. Àwọn kan ń ṣiṣẹ́ lórí ẹ̀rọ ìtẹ̀wé, tàbí kí wọ́n máa di ìwé, ìyẹn ni pé wọ́n ń ṣe ìwé tí wọ́n máa kó lọ sí ọ̀pọ̀ ìjọ. Àwọn mìíràn ń ṣiṣẹ́ ní ilé ìdáná, yàrá ìjẹun, tàbí ibi ìfọṣọ. Lára àwọn iṣẹ́ wọn ni, iṣẹ́ ìmọ́tótó, oko dídá, ilé kíkọ́, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Iṣẹ́ àwọn kan ni pé kí wọ́n máa bójú tó àwọn ohun èlò tí wọ́n fi ń ṣiṣẹ́ láwọn ibi iṣẹ́ wọ̀nyí. Àwọn mìíràn ń bójú tó ìlera tàbí kí wọ́n máa ṣiṣẹ́ ní ọ́fíìsì. Gbogbo iṣẹ́ Bẹ́tẹ́lì ló ní àwọn ìpèníjà tó gbádùn mọ́ni àti àgbàyanu èrè. Iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe ní Bẹ́tẹ́lì jẹ́ iṣẹ́ tó ń fúnni láyọ̀ gan-an nítorí pé ó ń gbé ire Ìjọba náà lárugẹ, ìfẹ́ fún Ọlọ́run ló sì ń súnni ṣe é.

Wọ́n máa ń yan àwọn mẹ́ńbà ìdílé Bẹ́tẹ́lì sí àwọn ìjọ, níbi tí wọ́n ti ń gbádùn àwọn àǹfààní iṣẹ́ ọwọ́ wọn ní tààrà. Wọ́n máa ń gbádùn lílọ sí àwọn ìpàdé ìjọ àti kíkópa nínú iṣẹ́ ìwàásù. Nítorí ìdí èyí, àwọn mẹ́ńbà ìdílé Bẹ́tẹ́lì ti mú àjọṣe tímọ́tímọ́ dàgbà pẹ̀lú àwọn arákùnrin àti arábìnrin wọn tó wà láwọn ìjọ àdúgbò.—Máàkù 10:29, 30.

Rita, tó jẹ́ mẹ́ńbà ìdílé Bẹ́tẹ́lì ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, sọ pé: “Mo mà dúpẹ́ lọ́wọ́ ìjọ tí mo wà o! Ìgbàgbọ́ mi máa ń lágbára sí i nígbà tí mo bá wà láwọn ìpàdé àti nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, tí mo rí àwọn arákùnrin, àwọn arábìnrin, àwọn ọmọdé, àtàwọn arúgbó tí wọ́n jẹ́ ẹni ọ̀wọ́n níbẹ̀! Bó ti wù kí nǹkan rí, wọ́n á wà níbẹ̀ ṣáá ni. Ìyẹn ràn mí lọ́wọ́ láti túbọ̀ máa fi ìtara ṣe iṣẹ́ ìsìn mi ní Bẹ́tẹ́lì.”

Gbogbo ìgbésí ayé Bẹ́tẹ́lì kì í ṣe kìkì ìpàdé lílọ, ṣíṣe iṣẹ́ ìsìn pápá, àti kíkẹ́kọ̀ọ́ nìkan. Ìdílé náà tún ní àkókò fàájì. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ tó máa ń dáni lára yá, tó sì lérè nípa tẹ̀mí máa ń wáyé ní “Alẹ́ Fàájì fún Ìdílé Bẹ́tẹ́lì [Family Night],” èyí tó máa ń fúnni láǹfààní láti gbádùn àwọn ẹ̀bùn tí ọ̀pọ̀ èèyàn ní, àti láti gbọ́ àwọn nǹkan tí ń fúnni níṣìírí nípa ìgbésí ayé àwọn ẹlòmíràn tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì. Nǹkan mìíràn tí wọ́n tún máa ń gbádùn ni ìbẹ̀wò ọlọ́rẹ̀ẹ́ sọ́rẹ̀ẹ́ tó gbámúṣé, tó sì ń gbéni ró tí wọ́n máa ń ṣe láàárín ara wọn. Wọ́n tún ní àwọn nǹkan mìíràn tí wọ́n lè fi dára yá, àti ibi ìkówèésí tí kálukú ti lè lọ kàwé, kó sì ṣe ìwádìí. Ohun táa ò tún ní gbàgbé ni àwọn ìjíròrò alárinrin tí wọ́n máa ń ní lákòókò oúnjẹ.

Tom, tó jẹ́ mẹ́ńbà ìdílé Bẹ́tẹ́lì ní Estonia sọ pé: “Nǹkan bí òpó iná kan ni ibi tí Bẹ́tẹ́lì wà sí òkun, igbó kan sì wà nítòsí ibẹ̀, níbi tí èmi àti aya mi ti máa ń najú. Èmi àtàwọn ọ̀rẹ́ mi nínú ìjọ àti ní Bẹ́tẹ́lì sì máa ń gbá bọ́ọ̀lù àfọ̀págbá, bọ́ọ̀lù hockey, àti bọ́ọ̀lù tẹ́níìsì lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. A sì máa ń gun kẹ̀kẹ́ wa káàkiri nígbà tójú ọjọ́ bá dára.”

Kí Lo Lè Ṣe Láti Di Ẹni Tí Ó Tóótun?

Ṣùgbọ́n ní pàtàkì, Bẹ́tẹ́lì jẹ́ ibi tí àwọn Kristẹni tó dàgbà dénú ti máa ń ṣe iṣẹ́ ìsìn sí Jèhófà, tí wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ fún ire àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn jákèjádò ayé. Àwọn tó ń di mẹ́ńbà ìdílé Bẹ́tẹ́lì gbọ́dọ̀ kúnjú àwọn ohun kan. Kí lo lè ṣe láti tóótun fún iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì?

Bíi ti Tímótì, tó bá àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣiṣẹ́, àwọn táa bá tẹ́wọ́ gbà fún iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì gbọ́dọ̀ ní ìdúró rere nínú ìjọ wọn. (1 Tímótì 1:1) “Àwọn ará ní Lísírà àti Íkóníónì . . . ròyìn” Tímótì “dáadáa.” (Ìṣe 16:2) Bí Tímótì tilẹ̀ jẹ́ ọ̀dọ́mọdé, síbẹ̀ ó mọ Ìwé Mímọ́, ó sì lóye òtítọ́ dáadáa. (2 Tímótì 3:14, 15) Bákan náà la ṣe fẹ́ káwọn táa tẹ́wọ́ gbà fún iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì ní ìmọ̀ Bíbélì.

Àwọn mẹ́ńbà ìdílé Bẹ́tẹ́lì gbọ́dọ̀ ní ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ. Ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ tí Tímótì ní àti bó ṣe múra tán láti fi ire Ìjọba náà ṣáájú ire ara rẹ̀ hàn kedere débi tí Pọ́ọ̀lù fi lè sọ nípa rẹ̀ pé: “Èmi kò ní ẹlòmíràn tí ó ní ìtẹ̀sí-ọkàn bí tirẹ̀ tí yóò fi òótọ́ inú bójú tó àwọn ohun tí ó jẹmọ́ yín. Nítorí gbogbo àwọn yòókù ń wá ire ara wọn, kì í ṣe ti Kristi Jésù. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin mọ ẹ̀rí tí ó fúnni nípa ara rẹ̀, pé bí ọmọ lọ́dọ̀ baba ni ó sìnrú pẹ̀lú mi fún ìtẹ̀síwájú ìhìn rere.”—Fílípì 2:20-22.

Àwọn ọkùnrin àtàwọn obìnrin tẹ̀mí ni iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì wà fún. Àwọn ètò tó wà fún àwọn mẹ́ńbà ìdílé Bẹ́tẹ́lì mú kó ṣeé ṣe fún wọn láti dàgbà nípa tẹ̀mí nípasẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, lílọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá déédéé, àti bíbá àwọn Kristẹni tó dàgbà dénú kẹ́gbẹ́. A ń tipa báyìí ran àwọn tó wà ní Bẹ́tẹ́lì lọ́wọ́ láti tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù pé: “Ẹ máa bá a lọ ní rírìn ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú [Kristi Jésù], kí ẹ ta gbòǹgbò, kí a sì máa gbé yín ró nínú rẹ̀, kí ẹ sì fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́, gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti kọ́ yín, kí ẹ máa kún fún ìgbàgbọ́ ní àkúnwọ́sílẹ̀ nínú ìdúpẹ́.”—Kólósè 2:6, 7.

Nítorí irú iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe ní Bẹ́tẹ́lì, àwọn tí wọ́n fún ní àǹfààní iṣẹ́ ìsìn yìí gbọ́dọ̀ jẹ́ àwọn tí ara wọn le. Bí o bá kúnjú ìwọ̀n àwọn ohun tí a mẹ́nu kàn yìí, tí o jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, tí ó sì ti tó, ó kéré tán ọdún kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ tóo ti ṣe batisí, a gbà ọ́ níyànjú láti gbé iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì yẹ̀ wò.

Gbogbo Wa La Ní Ipa Tí À Ń Kó

Gẹ́gẹ́ bí Kristẹni, ó dájú pé gbogbo wa ló fẹ́ láti fi ire Ìjọba náà sí ipò kìíní nínú ìgbésí ayé wa, kí a sì máa fi tọkàntọkàn ṣe iṣẹ́ ìsìn wa sí Jèhófà. (Mátíù 6:33; Kólósè 3:23) A sì tún lè gba àwọn tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì níyànjú láti máa bá iṣẹ́ ìsìn mímọ́ wọn níbẹ̀ nìṣó. Ó tún ṣe pàtàkì láti gba àwọn ará tó jẹ́ ọ̀dọ́ tó tóótun fún iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì níyànjú láti nàgà fún àǹfààní oníbùkún yìí.

Iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì jẹ́ ọ̀nà ìgbésí ayé tẹ̀mí tí ń fini lọ́kàn balẹ̀—èyí tó lè jẹ́ iṣẹ́ tó dára jù lọ fún ọ. Bó ṣe rí fún Nick nìyẹn, ẹni tó bẹ̀rẹ̀ sí sìn ní Bẹ́tẹ́lì nígbà tó wà lọ́mọ ogún ọdún. Lẹ́yìn tó ti sìn ní Bẹ́tẹ́lì fún ọdún mẹ́wàá, ó sọ pé: “Mo máa ń gbàdúrà sí Jèhófà nígbà gbogbo, láti dúpẹ́ fún inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀. Kí ni ǹ bá tún béèrè? Àwọn Kristẹni olóòótọ́ tí wọ́n ń sa gbogbo ipá wọn láti sin Jèhófà ló yí wa ká níhìn-ín.”

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]

KÍ LÀWỌN ALÀGBÀ ÀTÀWỌN ÒBÍ LÈ ṢE?

Àwọn alàgbà àtàwọn alábòójútó arìnrìn-àjò ní pàtàkì gbọ́dọ̀ máa gba àwọn ọ̀dọ́ níyànjú láti gba fọ́ọ̀mù Bẹ́tẹ́lì. Ìwádìí kan táa ṣe lọ́dọ̀ àwọn ọ̀dọ́ tó jẹ́ mẹ́ńbà ìdílé Bẹ́tẹ́lì lẹ́nu àìpẹ́ yìí fi hàn pé ìpín mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n nínú ọgọ́rùn-ún lára wọn ló jẹ́ pé àwọn Kristẹni alábòójútó ló gbà wọ́n níyànjú láti fi iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì ṣe góńgó wọn. Òótọ́ ni pé, ipa tí wọ́n ń kó lè mú kí àárò sọ ìjọ tí wọ́n ń dara pọ̀ mọ́ ládùúgbò wọn. Àmọ́, ó dára láti rántí pé bó ti wù kí Tímótì ti ní ipa rere lórí àwọn ọ̀dọ́ mìíràn tó wà ní Lísírà àti Íkóníónì tó, àwọn alàgbà ibẹ̀ ò sọ pé kó máà bá Pọ́ọ̀lù ṣiṣẹ́. Wọn ò parí èrò sí pé àdánù ńlá ló máa jẹ́ fún ìjọ wọn bí Tímótì bá lọ ń bá àpọ́sítélì náà ṣiṣẹ́.—1 Tímótì 4:14.

Ó tún ṣe pàtàkì pé káwọn Kristẹni òbí rí i dájú pé wọ́n ní ipa rere lórí àwọn ọmọ wọn nínú ọ̀ràn yìí. Nínú ìwádìí táa mẹ́nu kàn yẹn, ìpín ogójì nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò ló sọ pé òbí àwọn ló jẹ́ olórí orísun ìṣírí fún àwọn láti wọnú iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì. Arábìnrin kan tó ti ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì fún ọdún bíi mélòó kan sọ pé: “Ìgbésí ayé àwọn òbí mi nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ni ohun tó fún mi lágbára gan-an láti wọnú iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì. Nípa rírí àpẹẹrẹ wọn nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún, mo mọ̀ pé èyí yóò jẹ́ ọ̀nà ìgbésí ayé tó dára jù lọ, tó sì fini lọ́kàn balẹ̀ jù lọ láti yàn.”

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 24]

WỌ́N MỌYÌ IṢẸ́ ÌSÌN BẸ́TẸ́LÌ

“Mo mọyì iṣẹ́ ìsìn mi ní Bẹ́tẹ́lì. Ó ń fún mi láyọ̀ láti mọ pé mo ti sin Jèhófà láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀, àti pé mo tún máa ṣe ohun kán náà lọ́la, lọ́tùn-ún-la, àti títí lọ. Èyí jẹ́ kí n ní ẹ̀rí ọkàn rere, ó sì mú kí ọkàn mi kún fún èrò tó dára.”

“Bẹ́tẹ́lì ni ibi tóo ti lè lo gbogbo àkókò rẹ àti gbogbo agbára rẹ nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà láìsí ìpínyà ọkàn. Èyí ń fúnni láyọ̀. O sì tún lè rí ètò-àjọ Jèhófà lọ́nà mìíràn. Wàá rí i pé o túbọ̀ sún mọ́ ibi tó jẹ́ orísun ìgbòkègbodò ètò àjọ náà, èyí sì ń mórí ẹni yá gágá.”

“Wíwá tí mo wá sí Bẹ́tẹ́lì ni ohun tó tíì ṣe mí láǹfààní jù lọ. Ẹ̀kọ́ kíkọ́ kì í tán níhìn-ín. Ẹ̀kọ́ tí mo sì ń kọ́ níhìn-ín, kì í ṣe kí n lè gbé ògo ara mi yọ, bí kò ṣe fún ògo Jèhófà. Iṣẹ́ tí mò ń ṣe níbí kò lè já sí asán láé.”

“Lílo àwọn ẹ̀bùn àbínibí mi ní Bẹ́tẹ́lì ti jẹ́ kí n ní ìtẹ́lọ́rùn àti ìbàlẹ̀ ọkàn nítorí pé mò ń lò wọ́n fún Jèhófà àti fún àwọn arákùnrin mi.”

“Mi ò ní ojúlówó ìtẹ́lọ́rùn àti ayọ̀ nínú iṣẹ́ tí mò ń ṣe tẹ́lẹ̀. Fún ọ̀pọ̀ ọdún ni mo ti ń ronú nípa bíbá àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin mi ṣiṣẹ́ pa pọ̀, kí n sì máa ṣiṣẹ́ sìn wọ́n. Ìdí tí mo fi wá sí Bẹ́tẹ́lì nìyẹn. Mo ní ojúlówó ìtẹ́lọ́rùn ní mímọ̀ pé gbogbo ìsapá mi yóò ṣàǹfààní fún àwọn ẹlòmíràn nípa tẹ̀mí, yóò sì mú ìyìn bá Jèhófà.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́