MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Àwọn Iṣẹ́ Rere Tá Ò Ní Gbàgbé
Gbogbo àwa tá à ń sin Jèhófà la lè gbé nǹkan ńlá ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, nǹkan tá à ò ní gbàgbé láé. Àwọn òbí tó nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ wọn kì í gbàgbé àwọn nǹkan rere tí àwọn ọmọ wọn ń ṣe, Jèhófà náà kì í gbàgbé àwọn iṣẹ́ rere wa àti ìfẹ́ tá a ní fún orúkọ rẹ̀. (Mt 6:20; Heb 6:10) Òótọ́ kan ni pé ohun tá a mọ̀ ọ́ ṣe àti ipò wa yàtọ̀ síra, àmọ́ tá a bá ṣe gbogbo nǹkan tá a lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, a máa láyọ̀. (Ga 6:4; Kol 3:23) Láti ọ̀pọ̀ ọdún wá, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ará lọ́kùnrin lóbìnrin ló ti ṣiṣẹ́ sìn ní Bẹ́tẹ́lì. Ṣé ìwọ náà lè yọ̀ǹda ara rẹ láti ṣiṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì? Tó ò bá lè ṣe bẹ́ẹ̀, ṣé o lè gba ẹlòmíì níyànjú láti ṣe bẹ́ẹ̀, àbí o lè ran ẹnì kan tó ń ṣiṣẹ́ sìn ní Bẹ́tẹ́lì lọ́wọ́ kó lè máa bá a lọ lẹ́nu àkànṣe iṣẹ́ ìsìn náà?
WO FÍDÍÒ NÁÀ OHUN TÓ O LÈ ṢE LÁTI ṢIṢẸ́ SÌN NÍ BẸ́TẸ́LÌ, KÓ O SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
Kí ló yẹ kó sún wa láti fẹ́ sìn ní Bẹ́tẹ́lì?
Kí ni àwọn kan ti sọ nípa àwọn ìbùkún tá a máa rí tá a bá ṣiṣẹ́ sìn ní Bẹ́tẹ́lì?
Kí làwọn nǹkan tá à ń retí lọ́wọ́ ẹni tó bá fẹ́ sìn ní Bẹ́tẹ́lì?
Kí lo lè ṣe láti yọ̀ǹda ara rẹ fún iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì?