ORÍ 10
Àwọn Ọ̀nà Tó O Lè Gbà Mú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Gbòòrò Sí I
NÍGBÀ tí àkókò tó lójú Jésù láti rán àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ jáde lọ wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, ó sọ fún wọn pé: “Ìkórè pọ̀, àmọ́ àwọn òṣìṣẹ́ ò tó nǹkan.” Torí pé iṣẹ́ náà máa pọ̀ fún wọn, ó ní kí wọ́n “bẹ Ọ̀gá ìkórè pé kó rán àwọn òṣìṣẹ́ jáde láti bá a kórè.” (Mát. 9:37, 38) Ó tún sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ bó ṣe yẹ kí wọ́n ṣe iṣẹ́ ìwàásù náà. Ọ̀rọ̀ tó sọ fi hàn pé kò yẹ kí wọ́n fi iṣẹ́ náà falẹ̀, ó ní: “Ó dájú pé ẹ ò lè lọ yí ká àwọn ìlú Ísírẹ́lì tán títí Ọmọ èèyàn fi máa dé.”—Mát. 10:23.
2 Lónìí, àwa náà ní púpọ̀ láti ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. A sì gbọ́dọ̀ wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run kí òpin tó dé, bẹ́ẹ̀ sì rèé, àkókò tó kù ò tó nǹkan. (Máàkù 13:10) Jésù pe ayé yìí ní pápá tá a ti máa wàásù, torí náà bí nǹkan ṣe rí nígbà tí Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wà láyé náà ló rí fáwa náà lónìí, tiwa kàn pọ̀ ju tiwọn lọ ni. Iye àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò tó nǹkan tá a bá fi wé gbogbo èèyàn tó wà láyé, síbẹ̀ ó dá wa lójú pé Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi dá wa lójú pé a máa wàásù ìhìn rere Ìjọba yìí ní gbogbo ayé àti pé òpin máa dé tó bá tó àsìkò lójú Jèhófà. Ṣé a máa fi Ìjọba Ọlọ́run sí ipò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé wa ká lè ṣe iṣẹ́ ìwàásù náà láṣeyọrí? Àwọn nǹkan wo la lè fi ṣe àfojúsùn táá mú ká ṣe iṣẹ́ náà láṣeyọrí?
3 Jésù sọ pé gbogbo àwọn tó ti ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà gbọ́dọ̀ ṣe nǹkan kan, ó ní: “Kí o sì fi gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo ara rẹ àti gbogbo èrò rẹ àti gbogbo okun rẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ.” (Máàkù 12:30) Ọlọ́run fẹ́ ká máa sin òun tọkàntọkàn. Ìyẹn gba pé ká máa ṣe gbogbo ohun tágbára wa gbé nínú ìjọsìn Jèhófà, èyí ló máa fi hàn pé à ń fọkàn sin Jèhófà àti pé ojúlówó ni ìyàsímímọ́ wa sí i. (2 Tím. 2:15) Ipò ẹnì kọ̀ọ̀kan wa yàtọ̀ síra, bẹ́ẹ̀ sì ni ohun tágbára wa gbé ò dọ́gba, àmọ́ àǹfààní wà fún ẹnì kọ̀ọ̀kan wa láti ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa àwọn àǹfààní yìí ná, kó o wá pinnu èyí tí wàá fi ṣe àfojúsùn rẹ kó o lè ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ láṣeyọrí.
AKÉDE ÌJỌ
4 Gbogbo ẹni tó bá ti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ ló láǹfààní láti máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Èyí ni olórí iṣẹ́ tí Jésù ní káwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ máa ṣe. (Mát. 24:14; 28:19, 20) Lọ́pọ̀ ìgbà, kété tí ẹni tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù Kristi bá ti gbọ́ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ni á ti máa sọ ọ́ fún àwọn èèyàn. Ohun tí Áńdérù, Fílípì, Kọ̀nílíù, àtàwọn míì ṣe nìyẹn. (Jòh. 1:40, 41, 43-45; Ìṣe 10:1, 2, 24; 16:14, 15, 25-34) Ṣé ohun tí èyí túmọ̀ sí ni pé ẹnì kan lè máa wàásù ìhìn rere kó tó ṣe ìrìbọmi? Bẹ́ẹ̀ ni o! Gbàrà tí ẹnì kan bá ti di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi nínú ìjọ lòun náà ti láǹfààní àtimáa wàásù láti ilé dé ilé. Ó tún lè máa wàásù láwọn ọ̀nà míì, bí ipò rẹ̀ bá gbà á láyè tí agbára rẹ̀ sì gbé e.
5 Lẹ́yìn tí akéde kan bá ti ṣèrìbọmi, ó dájú pé ó máa fẹ́ ṣe gbogbo ohun tó bá lè ṣe kó lè ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Tọkùnrin tobìnrin ló láǹfààní láti máa wàásù. Ṣe ló yẹ ká máa dúpẹ́ pé a tiẹ̀ láǹfààní láti mú kí ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run máa tẹ̀ síwájú. Ó dájú pé èèyàn máa láyọ̀ tó bá tún lè mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ gbòòrò débi táá fi lè lọ́wọ́ nínú àwọn apá iṣẹ́ ìsìn míì.
LÍLỌ SÍBI TÍ WỌ́N TI NÍLÒ ONÍWÀÁSÙ PÚPỌ̀ SÍ I
6 Ó ṣeé ṣe kó o wà ní ìjọ tẹ́ ẹ ti ń kárí ìpínlẹ̀ ìwàásù yín déédéé tẹ́ ẹ sì ń wàásù dáadáa fún àwọn èèyàn tó wà níbẹ̀. Torí èyí, o lè fẹ́ lọ sí agbègbè míì tá a ti nílò oníwàásù púpọ̀ sí i kó o lè mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ gbòòrò sí i. (Ìṣe 16:9) Tó o bá jẹ́ alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, ìjọ míì lè wà tó máa nílò ìrànlọ́wọ́ rẹ. Alábòójútó àyíká tó ń bẹ ìjọ yín wò lè dábàá ọ̀nà tó o lè gbà ran ìjọ míì lọ́wọ́ ní àyíká yín. Tó o bá fẹ́ lọ síbòmíì ní orílẹ̀-èdè tó o wà, kọ̀wé sí ẹ̀ka ọ́fíìsì, wọ́n á tọ́ ẹ sọ́nà.
7 Ṣé wàá fẹ́ lọ sìn ní orílẹ̀-èdè míì? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, fara balẹ̀ ronú lórí ọ̀rọ̀ náà kó o tó lọ. O ò ṣe jíròrò ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú àwọn alàgbà ìjọ rẹ? Ìdí ni pé lílọ sí orílẹ̀-èdè míì máa gba pé kí ìwọ àtàwọn tẹ́ ẹ jọ fẹ́ lọ ṣe àwọn àyípadà kan. (Lúùkù 14:28) Àmọ́, tí o kò bá ní in lọ́kàn láti pẹ́ níbẹ̀, ó máa dáa kó o lọ sí agbègbè kan lórílẹ̀-èdè rẹ.
8 Láwọn ilẹ̀ kan, àwọn arákùnrin tí kò tíì pẹ́ tí wọ́n di Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ń bójú tó ìjọ. Inú àwọn arákùnrin onírẹ̀lẹ̀ yìí máa ń dùn tí àwọn alàgbà tó ní ìrírí bá wá sí ìjọ wọn, wọ́n sì máa ń gbà kí wọ́n múpò iwájú. Torí náà, tó o bá jẹ́ alàgbà, tó o sì ń gbèrò láti lọ sí irú orílẹ̀-èdè bẹ́ẹ̀, fi sọ́kàn pé kì í ṣe torí kó o lè gba iṣẹ́ lọ́wọ́ àwọn arákùnrin tó wà nínú ìjọ náà lo ṣe ń lọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni kẹ́ ẹ jọ máa ṣiṣẹ́. Máa fún wọn níṣìírí pé kí wọ́n tẹ̀ síwájú, kí wọ́n sì máa ṣe àwọn iṣẹ́ tí wọ́n bá fún wọn nínú ìjọ. (1 Tím. 3:1) Máa mú sùúrù fún wọn bí ọ̀nà tí wọ́n gbà ń ṣe nǹkan bá yàtọ̀ sí bẹ́ ẹ ṣe ń ṣe é ní orílẹ̀-èdè tó o ti wá. Lo ìrírí tó o ní lẹ́nu iṣẹ́ alàgbà láti ran àwọn ará lọ́wọ́. Tó bá sì wá ṣẹlẹ̀ pé o fẹ́ pa dà sí orílẹ̀-èdè tó o ti wá, àwọn alàgbà ìjọ náà á ti túbọ̀ mọ bí wọ́n ṣe lè máa bójú tó ìjọ.
9 Kí ẹ̀ka ọ́fíìsì tó lè fún ẹ ní orúkọ àwọn ìjọ tó máa nílò ìrànlọ́wọ́ rẹ, Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn Ìjọ rẹ gbọ́dọ̀ fi lẹ́tà tí wọ́n fi dámọ̀ràn rẹ ránṣẹ́. Lẹ́tà yìí ṣe pàtàkì yálà o jẹ́ alàgbà, ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, aṣáájú-ọ̀nà tàbí akéde. Ìgbìmọ̀ iṣẹ́ ìsìn á fi lẹ́tà tí wọ́n fi dámọ̀ràn rẹ pẹ̀lú lẹ́tà tó o kọ láti béèrè ibi tó o ti lè sìn ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì tó ń bójú tó orílẹ̀-èdè tó o ti fẹ́ lọ sìn.
KỌ́ ÈDÈ MÍÌ TÍ WÀÁ FI MÁA WÀÁSÙ
10 Tó o bá fẹ́ mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ gbòòrò sí i, o tún lè ronú nípa kíkọ́ èdè míì, títí kan èdè àwọn adití. Tó o bá ní in lọ́kàn láti kọ́ bó o ṣe lè máa fi èdè míì wàásù, o ò ṣe sọ ọ́ létí àwọn alàgbà ìjọ rẹ àti alábòójútó àyíká yín? Wọ́n á gbà ẹ́ nímọ̀ràn wọ́n á sì fún ẹ níṣìírí. Ẹ̀ka ọ́fíìsì ti fọwọ́ sí i pé kí àwọn àyíká kan ṣètò àwọn kíláàsì fún àwọn akéde àtàwọn aṣáájú-ọ̀nà tí wọ́n kúnjú ìwọ̀n, tí wọ́n sì fẹ́ kọ́ èdè míì tí wọ́n á fi máa wàásù.
IṢẸ́ AṢÁÁJÚ-Ọ̀NÀ
11 Ó ṣe pàtàkì pé kí gbogbo akéde mọ ohun tó yẹ kí ẹnì kan ṣe tó bá fẹ́ di aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́, aṣáájú-ọ̀nà déédéé àti aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe tàbí tí wọ́n bá fẹ́ sìn ní àwọn apá míì nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Aṣáájú-ọ̀nà gbọ́dọ̀ jẹ́ Kristẹni àwòfiṣàpẹẹrẹ tó ti ṣèrìbọmi tí ipò rẹ̀ sì yọ̀ǹda fún un láti máa wàásù ìhìn rere fún iye wákàtí kan pàtó. Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn Ìjọ ló ń fọwọ́ sí ìwé ìwọṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ àti ti aṣáájú-ọ̀nà déédéé, nígbà tó jẹ́ pé ẹ̀ka ọ́fíìsì ló ń yan àwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe.
12 Àwọn alàgbà lè fọwọ́ sí i pé kí akéde kan ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lóṣù kan ó kéré tán tàbí fún iye oṣù tí ẹni náà bá fẹ́ fi ṣe é, tàbí kẹ̀, tó bá fẹ́ máa ṣe é lọ bí ipò rẹ̀ bá ṣe gbà. Ọ̀pọ̀ akéde Ìjọba Ọlọ́run ló ń gbádùn iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ láwọn àkókò pàtàkì, bí àkókò Ìrántí Ikú Kristi tàbí lóṣù tí ìbẹ̀wò alábòójútó àyíká wọn bá bọ́ sí. Àwọn míì máa ń ṣe é nígbà tí wọ́n bá gba ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́. Àwọn ọmọ ilé ìwé tí wọ́n ti ṣèrìbọmi lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lásìkò ọlidé. Akéde kan lè lo wákàtí tí a dín kù lẹ́nu iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lóṣù March àti April, àti lóṣù tí ìbẹ̀wò alábòójútó àyíká wọn bọ́ sí. Ipò yòówù kó o wà, inú àwọn alàgbà máa dùn láti fọwọ́ sí fọ́ọ̀mù rẹ, tó o bá jẹ́ oníwà mímọ́, tó o lè ṣètò láti ní iye wákàtí tá a retí, tó sì dájú pé wàá lè ṣe é fún oṣù kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ.
13 Kó o tó lè di aṣáájú-ọ̀nà déédéé, o ní láti wà nípò tí wàá fi lè máa ní iye wákàtí tá a retí pé káwọn aṣáájú-ọ̀nà déédéé máa ní lọ́dún. Tó o bá di aṣáájú-ọ̀nà déédéé, á dáa kó o máa ṣiṣẹ́ ní ìfọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ìjọ tó o bá wà. Ìbùkún ńlá làwọn aṣáájú-ọ̀nà onítara jẹ́ nínú ìjọ. Wọ́n máa ń jẹ́ kí ìtara àwọn ará nínú ìjọ pọ̀ sí i fún iṣẹ́ ìwàásù, wọ́n sì tún máa ń gba àwọn ẹlòmíràn níyànjú láti gba iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Àmọ́ ṣá o, káwọn alàgbà tó fọwọ́ sí i pé kó o di aṣáájú-ọ̀nà déédéé, á ti pé oṣù mẹ́fà, ó kéré tán, tó o ti ṣèrìbọmi, wàá sì jẹ́ àpẹẹrẹ rere.
14 Lára àwọn aṣáájú-ọ̀nà déédéé tí wọ́n já fáfá lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ni ẹ̀ka ọ́fíìsì ti máa ń yan àwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe. Wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe tán láti sìn níbikíbi tí ẹ̀ka ọ́fíìsì bá rán wọn lọ. A sábà máa ń rán wọn lọ sáwọn ìpínlẹ̀ ìwàásù tó wà ní àdádó, kí wọ́n lè wá àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́, kí wọ́n sì dá ìjọ sílẹ̀. Nígbà míì, a máa ń rán wọn lọ sáwọn ìjọ tó nílò ìrànlọ́wọ́ láti kárí ìpínlẹ̀ ìwàásù wọn. A sì lè rán àwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe tó jẹ́ alàgbà sí àwọn ìjọ kéékèèké, kódà bí ìjọ náà kò bá tiẹ̀ ní ìṣòro láti kárí ìpínlẹ̀ ìwàásù wọn. Ètò Ọlọ́run máa ń fún àwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe lówó táṣẹ́rẹ́ tí wọ́n lè fi bójú tó àwọn ìnáwó pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́. A máa ń yan àwọn aṣáájú-ọnà àkànṣe kan pé kí wọ́n ṣiṣẹ́ sìn fún ìgbà díẹ̀.
MÍṢỌ́NNÁRÌ TÓ Ń SÌN NÍ PÁPÁ
15 Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn ti Ìgbìmọ̀ Olùdarí ló máa ń yan àwọn míṣọ́nnárì tó wà ní pápá. Lẹ́yìn èyí, Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka máa ní kí wọ́n lọ sìn láwọn agbègbè tí èèyàn pọ̀ sí gan-an. Iṣẹ́ kékeré kọ́ ni wọ́n ń ṣe láti mú kí iṣẹ́ ìwàásù máa gbòòrò sí i, kí ìjọ sì máa tẹ̀ síwájú. Lọ́pọ̀ ìgbà, wọ́n á ti gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere Ìjọba Ọlọ́run. A máa ń ṣètò ilé tí wọ́n á máa gbé fún wọn, a sì máa ń fún wọn lówó táṣẹ́rẹ́ láti bójú tó àwọn ìnáwó pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́.
IṢẸ́ ALÁBÒÓJÚTÓ ÀYÍKÁ
16 Ìgbìmọ̀ Olùdarí ló máa ń yan àwọn alábòójútó àyíká, àmọ́ wọ́n á ti kọ́kọ́ ṣe adelé alábòójútó àyíká kí wọ́n lè gba ìdálẹ́kọ̀ọ́, kí wọ́n sì ní ìrírí. Àwọn arákùnrin yìí nífẹ̀ẹ́ iṣẹ́ ìwàásù, wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ àwọn ará. Wọ́n jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà tó nítara, wọ́n máa ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì dáadáa, sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ ni wọ́n, wọ́n tún jẹ́ olùkọ́ tó mọ̀ọ̀yàn kọ́ dáadáa. Àpẹẹrẹ gidi ni wọ́n tó bá di pé kéèyàn máa fi èso tẹ̀mí ṣèwàhù, wọn kì í ṣàṣejù, wọ́n máa ń fòye báni lò, wọ́n sì jẹ́ aláròjinlẹ̀. Tí irú arákùnrin bẹ́ẹ̀ bá ti níyàwó, ìyàwó rẹ̀ tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà máa ń jẹ́ àpẹẹrẹ rere nínú ìwà, ó sì máa ń fọgbọ́n bá àwọn èèyàn lò. Ó máa ń fọwọ́ gidi mú iṣẹ́ ìwàásù. Ó mọ ohun tó túmọ̀ sí pé kí aya fi ara rẹ̀ sábẹ́ ọkọ rẹ̀, ó mọ̀wọ̀n ara rẹ̀ nínú ètò Ọlọ́run, kì í fi ara rẹ̀ sípò ọkọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kì í sọ̀rọ̀ jù. Ọwọ́ àwọn alábòójútó àyíká àti ìyàwó wọn máa ń dí gan-an, torí náà àwọn tó bá fẹ́ ṣiṣẹ́ yìí gbọ́dọ̀ ní ìlera tó dáa. Àwọn aṣáájú-ọ̀nà kì í kọ̀wé pé àwọn fẹ́ di alábòójútó àyíká, kàkà bẹ́ẹ̀ ṣe ni wọ́n máa ń sọ fún alábòójútó àyíká wọn pé iṣẹ́ náà wu àwọn. Alábòójútó àyíká á wa sọ ohun tí wọ́n lè ṣe láti kúnjú ìwọ̀n.
ÀWỌN ILÉ Ẹ̀KỌ́ ÈTÒ ỌLỌ́RUN
17 Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere Ìjọba Ọlọ́run: A ṣì nílò àwọn ajíhìnrere Ìjọba Ọlọ́run tó máa ṣiṣẹ́ láwọn ìpínlẹ̀ ìwàásù tí a kì í ṣe déédéé tí wọ́n á sì mú káwọn ìjọ túbọ̀ fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìjọsìn Ọlọ́run. Torí náà, àwọn tí kò ní aya, àwọn tí kò ní ọkọ àtàwọn tọkọtaya lè kọ̀rọ̀ sí fọ́ọ̀mù pé àwọn fẹ́ láti gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ àkànṣe ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ajíhìnrere Ìjọba Ọlọ́run. Lẹ́yìn tí wọ́n bá kẹ́kọ̀ọ́ jáde, a máa ń rán wọn lọ gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà déédéé sí àwọn ibi tá a ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i lórílẹ̀-èdè wọn. Àmọ́, a tún lè fún àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn ní iṣẹ́ míì lórílẹ̀-èdè wọn tàbí lórílẹ̀-èdè míì. A lè ní kí àwọn díẹ̀ lára wọn ṣe aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe fúngbà díẹ̀ tàbí kí wọ́n máa ṣe aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe títí lọ. Àwọn aṣáájú-ọ̀nà tó nífẹ̀ẹ́ sí ilé ẹ̀kọ́ yìí lè mọ púpọ̀ sí i nípa ohun tí wọ́n á ṣe tí wọ́n bá lọ sí ìpàdé tá a ṣètò fún wọn, èyí tó máa ń wáyé nígbà àpéjọ agbègbè.
18 Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì: Àwọn tí kò ní aya tàbí àwọn tí kò lọ́kọ àtàwọn tọkọtaya tí wọ́n gbọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì la máa ń pè sílé ẹ̀kọ́ yìí, wọ́n sì ní láti wà lẹ́nu àkànṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Wọ́n mọ béèyàn ṣe lè mú kí iṣẹ́ ìwàásù gbòòrò sí i àti bí wọ́n ṣe lè jẹ́ kí nǹkan máa lọ bó ṣe yẹ ní ẹ̀ka ọ́fíìsì. Ẹ̀rí wà pé inú wọn máa ń dùn láti ṣiṣẹ́ sin àwọn arákùnrin wọn àti pé wọ́n lè fìfẹ́ ran àwọn míì lọ́wọ́ láti máa tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì àti ìtọ́ni ètò Ọlọ́run. Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka ló máa ń sọ pé kí àwọn tó kúnjú ìwọ̀n kọ̀wé sí fọ́ọ̀mù tó wà fún ilé ẹ̀kọ́ náà. A máa ń yanṣẹ́ fún àwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ jáde nílé ẹ̀kọ́ yìí láti máa sìn ní pápá tàbí ní ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà lórílẹ̀-èdè wọn tàbí nílẹ̀ òkèèrè.
IṢẸ́ ÌSÌN BẸ́TẸ́LÌ
19 Àǹfààní ńlá ni kéèyàn máa sìn ní Bẹ́tẹ́lì. “Ilé Ọlọ́run” ni Bẹ́tẹ́lì túmọ̀ sí, orúkọ yìí sì bá a mu torí pé ibẹ̀ la ti ń darí onírúurú iṣẹ́ tá à ń ṣe nínú ètò Ọlọ́run. Iṣẹ́ ńlá táwọn arákùnrin àti arábìnrin tó wà ní Bẹ́tẹ́lì ń ṣe ló ń mú ká lè máa tẹ àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa, ká máa túmọ̀ wọn sí àwọn èdè míì ká sì máa fi wọ́n ránṣẹ́ sáwọn ìjọ. Ìgbìmọ̀ Olùdarí mọyì iṣẹ́ táwọn tó wà ní Bẹ́tẹ́lì ń ṣe gidigidi. Ìgbìmọ̀ yìí ló ń bójú tó gbogbo ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà kárí ayé. Ọ̀pọ̀ àwọn tó jẹ́ atúmọ̀ èdè lára ìdílé Bẹ́tẹ́lì ń gbé ní agbègbè tí wọ́n ti ń sọ èdè tí wọ́n ń túmọ̀, ibẹ̀ sì ni wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ wọn. Èyí mú kí wọ́n lè máa gbọ́ báwọn èèyàn ṣe ń lo èdè náà lójoojúmọ́. Ó sì tún ń mú kí àwọn fúnra wọn mọ̀ bóyá àwọn èèyàn lóye bí àwọn ṣe lo èdè náà nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa.
20 Ọ̀pọ̀ iṣẹ́ tá à ń ṣe ní Bẹ́tẹ́lì ló jẹ́ iṣẹ́ àṣekára. Ìdí nìyí tó fi jẹ́ pé àwọn ọ̀dọ́kùnrin tó ti ya ara wọn sí mímọ́ tí wọ́n sì ti ṣèrìbọmi la sábà máa ń pè sí Bẹ́tẹ́lì. Bákàn náà, ara wọn ní láti dá ṣáṣá kí wọ́n sì lè ṣiṣẹ́ agbára. Bí wọ́n bá ń fẹ́ àwọn tó máa yọ̀ǹda ara wọn ní ẹ̀ka ọ́fíìsì tó ń bójú tó iṣẹ́ wa lórílẹ̀-èdè rẹ, tíwọ náà sì fẹ́ láti sìn ní Bẹ́tẹ́lì, o lè mọ púpọ̀ sí i nípa ohun tí wàá ṣe tó o bá béèrè lọ́wọ́ àwọn alàgbà ìjọ rẹ.
IṢẸ́ ÌKỌ́LÉ
21 Iṣẹ́ ìsìn mímọ́ ni iṣẹ́ kíkọ́ àwọn ibi tá à ń lò fún ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run, irú iṣẹ́ yìí sì làwọn tó kọ́ tẹ́ńpìlì nígbà ayé Sólómọ́nì ṣe. (1 Ọba 8:13-18) Ọ̀pọ̀ àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin ń fi hàn pé àwọn ní ìtara gan-an bí wọ́n ṣe ń yọ̀ǹda ara wọn àti ohun ìní wọn fún iṣẹ́ yìí.
22 Kí ni wàá ṣe kó o lè ṣe nínú iṣẹ́ yìí? Tó o bá ti ṣèrìbọmi, tó sì wù ẹ́ láti lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ náà, inú àwọn arákùnrin tó ń bójú tó iṣẹ́ ìkọ́lé ní agbègbè rẹ máa dùn tó o bá lọ ràn wọ́n lọ́wọ́, wọ́n á sì dá ẹ lẹ́kọ̀ọ́ tí o ò bá tiẹ̀ fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ nípa iṣẹ́ ìkọ́lé. Á dáa kó o sọ fún àwọn alàgbà ìjọ rẹ pé o fẹ́ yọ̀ǹda ara rẹ. Kódà àwọn akéde kan tó ti ṣèrìbọmi tí wọ́n sì kúnjú ìwọ̀n ti yọ̀ǹda ara wọn láti máa kọ́ àwọn ibi tá à ń lò fún ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run láwọn orílẹ̀-èdè míì.
23 Ọ̀pọ̀ ọ̀nà la lè gbà lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìkọ́lé. Àwọn akéde tó ti ṣèrìbọmi tí wọ́n jẹ́ àpẹẹrẹ rere, tí wọ́n sì lóye díẹ̀ nípa iṣẹ́ ìkọ́lé lè lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ náà. Wọ́n lè dara pọ̀ mọ́ àwọn tó ń kọ́ ibi ìjọsìn wa ládùúgbò wọn, wọ́n á sì tipa bẹ́ẹ̀ di ọ̀kan lára àwọn olùyọ̀ǹda tó ń yàwòrán ilé tí wọ́n sì ń kọ́ ọ, ìyẹn Local Design/Construction volunteers. Àwọn míì máa ń lọ síbi tó jìn sí àdúgbò wọn láti kọ́wọ́ ti iṣẹ́ ìkọ́lé fúngbà díẹ̀, bóyá fún bí ọ̀sẹ̀ méjì sí oṣù mẹ́ta. Ẹ̀ka ọ́fíìsì máa ń yan irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ pè kí wọ́n di olùyọ̀ǹda lẹ́nu iṣẹ́ ìkọ́lé, ìyẹn construction volunteers. Àwọn tí ẹ̀ka ọ́fíìsì yàn láti máa ṣiṣẹ́ ìkọ́lé lọ fún ìgbà pípẹ́ là ń pé ní ìránṣẹ́ ìkọ́lé, ìyẹn construction servants. Ìránṣẹ́ ìkọ́lé tá a rán lọ sílẹ̀ òkèèrè láti lọ ṣiṣẹ́ ìkọ́lé là ń pè ní ìránṣẹ́ ìkọ́lé nílẹ̀ òkèèrè, ìyẹn expatriate construction servant. Àwọn ìránṣẹ́ ìkọ́lé àtàwọ̀n olùyọ̀ǹda lẹ́nu iṣẹ́ ìkọ́lé ló wà nínú Ẹgbẹ́ Àwọn Tí Ń Kọ́lé, ìyẹn Construction Group. Ẹgbẹ́ yìí ló máa ń múpò iwájú nígbà tá a bá ń kọ́lé, àwọn tá a pè ní Local Design/Construction volunteers àtàwọn ará látinú ìjọ sì máa ń kún wọn lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ náà. Ńṣe ni Ẹgbẹ́ Àwọn Tí Ń Kọ́lé máa ń ti ibi ilé kíkọ́ kan bọ́ sí ibòmíì ní àwọn ilẹ̀ tí ẹ̀ka ọ́fíìsì wọn ń bójú tó.
KÍ LÀWỌN ÀFOJÚSÙN RẸ?
24 Tó o bá ti ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà, ó dájú pé ohun tó wù ẹ́ ni pé kó o máa sin Jèhófà títí láé. Àmọ́ ní báyìí ná, kí làwọn ohun tó o fẹ́ ṣe nínú ìjọsìn Ọlọ́run? Tó o bá ní àwọn nǹkan tó ò ń fojú sùn, wàá lè máa lo okun rẹ àtàwọn nǹkan míì tó o ní lọ́nà tó dára. (1 Kọ́r. 9:26) Tó o bá ní àwọn àfojúsùn bẹ́ẹ̀, wàá túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, á sì jẹ́ kó o pọkàn pọ̀ sórí àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù bó o ṣe ń sapá láti ní àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn míì.—Fílí. 1:10; 1 Tím. 4:15, 16.
25 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi àpẹẹrẹ tó dára lélẹ̀ fún wa, èyí tá a lè tẹ̀ lé nínú iṣẹ́ ìsìn wa sí Ọlọ́run. (1 Kọ́r. 11:1) Pọ́ọ̀lù fi gbogbo okun tó ní sin Jèhófà. Ó mọ̀ pé Jèhófà ló fún òun ní ọ̀pọ̀ àǹfààní tóun ní. Ìyẹn ló fi kọ lẹ́tà sáwọn ará ní Kọ́ríńtì pé: “Ilẹ̀kùn ńlá ti ṣí sílẹ̀ fún mi láti ṣe iṣẹ́ púpọ̀.” Ó ṣe kedere pé bọ́rọ̀ tiwa náà ṣe rí nìyẹn. Àwa náà ní ọ̀pọ̀ àǹfààní láti máa sin Jèhófà pẹ̀lú àwọn ará nínú ìjọ. Ọ̀kan pàtàkì lára àǹfààní yìí ni pé a jọ ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Àmọ́ bíi ti Pọ́ọ̀lù a gbọ́dọ̀ máa rántí pé a máa kojú ‘ọ̀pọ̀ àtakò’ tá a bá fẹ́ gba ẹnu “ilẹ̀kùn ńlá” yẹn. (1 Kọ́r. 16:9) Pọ́ọ̀lù ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti kó ara rẹ̀ níjàánu. Kíyè sí ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ, ó ní: “Mò ń lu ara mi kíkankíkan, mo sì ń darí rẹ̀ bí ẹrú.” (1 Kọ́r. 9:24-27) Ṣé àwa náà ṣe tán láti ṣe bẹ́ẹ̀?
Tó o bá ní àwọn nǹkan tó ò ń fojú sùn, wàá lè máa lo okun rẹ àtàwọn nǹkan míì tó o ní lọ́nà tó dára
26 A rọ gbogbo wa pé ká ní àwọn àfojúsùn kan nínú ìjọsìn wa sí Jèhófà bí agbára wa ba ṣe gbé e tó. Ọ̀pọ̀ àwọn tó wà nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún lónìí ló jẹ́ pé tipẹ́tipẹ́ ni wọ́n ti fi iṣẹ́ ìsìn náà ṣe àfojúsùn wọn. Láti kékeré làwọn òbí wọn àtàwọn míì ti ń gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Torí náà, wọ́n ń gbádùn iṣẹ́ ìsìn wọn sí Jèhófà, wọn ò sì kábàámọ̀. (Òwe 10:22) Àwọn àfojúsùn míì tá a lè ní ni pé àá máa kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, àá bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tàbí pé àá fi kún àkókò tá a fi ń múra àwọn ìpàdé sílẹ̀. Ohun tó ṣe pàtàkì ni pé ká jẹ́ adúróṣinṣin ká sì ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa láṣeyọrí. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, àá bọlá fún Jèhófà, ọwọ́ wa á sì tẹ àfojúsùn tó dáa jù lọ, ìyẹn láti máa sin Jèhófà títí ayé.—Lúùkù 13:24; 1 Tím. 4:7b, 8.