ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w12 9/15 ojú ìwé 13-17
  • Àwọn Ilé Ẹ̀kọ́ Ètò Ọlọ́run—Ẹ̀rí Pé Jèhófà Nífẹ̀ẹ́ Wa

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ilé Ẹ̀kọ́ Ètò Ọlọ́run—Ẹ̀rí Pé Jèhófà Nífẹ̀ẹ́ Wa
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • JÀǸFÀÀNÍ LÁTINÚ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ÈTÒ ỌLỌ́RUN
  • Bí A Ṣe Ń Dá Àwọn Òjíṣẹ́ Ìjọba Náà Lẹ́kọ̀ọ́
    Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!
  • Ǹjẹ́ Ò Ń Kọ́ Gbogbo Ohun Tó O Lè Kọ́ Lọ́dọ̀ Jèhófà?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
  • Àwọn Ìdálẹ́kọ̀ọ́ Wo Ló Ń Mú Káwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Já Fáfá Lẹ́nu Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Wa?
    Àwọn Ìbéèrè Táwọn Èèyàn Sábà Máa Ń Béèrè Nípa Ẹlẹ́rìí Jèhófà
  • Àwọn Ọ̀nà Tó O Lè Gbà Mú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Gbòòrò Sí I
    A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
w12 9/15 ojú ìwé 13-17

Àwọn Ilé Ẹ̀kọ́ Ètò Ọlọ́run​—Ẹ̀rí Pé Jèhófà Nífẹ̀ẹ́ Wa

JÈHÓFÀ ni ‘Olùkọ́ni Atóbilọ́lá’ wa. (Aísá. 30:20) Ìfẹ́ ló ń mú kó máa kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́. Bí àpẹẹrẹ, torí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ Jésù gan-an, ó fi “gbogbo ohun tí òun fúnra rẹ̀ ń ṣe” hàn án. (Jòh. 5:20) Torí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí rẹ̀, ó fún wa ní “ahọ́n àwọn tí a kọ́,” bá a ṣe ń sa gbogbo ipá wa láti bọlá fún un tá a sì ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́.—Aísá. 50:4.

Ìgbìmọ̀ Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ ti Ìgbìmọ̀ Olùdarí náà ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìfẹ́ Jèhófà. Wọ́n ń lo ilé ẹ̀kọ́ mẹ́wàá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó jẹ́ ti ètò Ọlọ́run láti fún àwọn tí wọ́n bá fẹ́ bẹ́ẹ̀ tí ipò wọn sì yọ̀ǹda ní ìdálẹ́kọ̀ọ́. Ǹjẹ́ o gbà pé àwọn ilé ẹ̀kọ́ yìí jẹ́ ẹ̀rí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa?

Ẹ jẹ́ ká jíròrò àwọn ilé ẹ̀kọ́ ètò Ọlọ́run tó wà báyìí ká sì gbọ́ ohun tí àwọn kan tí wọ́n ti lọ sí ilé ẹ̀kọ́ náà sọ. Lẹ́yìn náà, kó o wá bi ara rẹ pé, ‘Báwo ni mo ṣe lè jàǹfààní látinú ẹ̀kọ́ tí Ọlọ́run ń kọ́ wa yìí?’

JÀǸFÀÀNÍ LÁTINÚ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ÈTÒ ỌLỌ́RUN

Nítorí pé Jèhófà jẹ́ “Ọlọ́run ìfẹ́,” àwọn ẹ̀kọ́ tó ń kọ́ wa ń mú kí ìgbé ayé wa dára sí i, wọ́n ń jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè borí ìṣòro, wọ́n sì ń mú ká ní ayọ̀ púpọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. (2 Kọ́r. 13:11) Bíi ti àwọn ọmọ ẹ̀yìn ní ọ̀rúndún kìíní, a ti gbára dì dáadáa láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, a fẹ́ “máa kọ́ wọn láti máa pa gbogbo ohun” tá a ti pa láṣẹ fún wa mọ́.—Mát. 28:20.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé, ó lè má ṣeé ṣe fún wa láti lọ sí gbogbo ilé ẹ̀kọ́ yìí, a lè jàǹfààní látinú ọ̀kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ nínú wọn. A sì lè máa fi àwọn ìtọ́ni Bíbélì tá a bá kọ́ níbẹ̀ sílò. A tún lè jáfáfá sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù nípa bíbá àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tí wọ́n ti gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ dáadáa ṣiṣẹ́.

O lè bi ara rẹ pé: ‘Ǹjẹ́ ipò mi yọ̀ǹda fún mi láti lọ sí èyíkéyìí lára àwọn ilé ẹ̀kọ́ yìí?’

Àǹfààní ńlá ni àwọn olùjọ́sìn Jèhófà kà á sí láti máa ṣètìlẹ́yìn fún àwọn ilé ẹ̀kọ́ tó ṣeyebíye yìí kí wọ́n sì máa kẹ́kọ̀ọ́ níbẹ̀. Àdúrà wa ni pé kí ẹ̀kọ́ tí wàá gbà mú kó o túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run, kó o lè gbára dì láti ṣe ojúṣe tó gbé lé ẹ lọ́wọ́, pàápàá jù lọ iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere tó jẹ́ kánjúkánjú.

ÀLÀYÉ ṢÓKÍ NÍPA ÀWỌN ILÉ Ẹ̀KỌ́ ÈTÒ ỌLỌ́RUN

Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run

Ohun Tó Wà Fún: Láti dá àwọn akéde lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè jẹ́ oníwàásù ìhìn rere àti olùkọ́ tó dáńgájíá.

Àkókò: Títí gbére.

Ibi Tí A Ti Ń Ṣe É: Gbọ̀ngàn Ìjọba.

Ohun Téèyàn Gbọ́dọ̀ Dójú Ìlà Rẹ̀: Gbogbo àwọn tó ń dara pọ̀ mọ́ ìjọ déédéé, tí wọ́n fara mọ́ àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì, tí ìgbé ayé wọn sì bá àwọn ìlànà Kristẹni mu.

Béèyàn Ṣe Lè Gba Ìdálẹ́kọ̀ọ́: Sọ fún alábòójútó Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run.

Sharon, tí àrùn tí wọ́n ń pè ní ALS mú kó yarọ látòkè délẹ̀, sọ pé: “Ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, mo ti kọ́ béèyàn ṣe ń ṣe ìwádìí àti béèyàn ṣe ń gbé ọ̀rọ̀ kalẹ̀ lọ́nà tó mọ́gbọ́n dání. Mo tún ti kẹ́kọ̀ọ́ bí mo ṣe lè ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Ọlọ́run, kí n sì tún ran àwọn èèyàn míì lọ́wọ́.”

Arnie, tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ alábòójútó arìnrìn-àjò ṣàlàyé pé: “Mo máa ń kólòlò, ó sì máa ń ṣòro fún mi láti wo ojú àwọn èèyàn nígbà tí mo bá ń bá wọn sọ̀rọ̀. Ohun tí mo kọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ yìí ti mú kí n ní ìgboyà kí n má sì máa fojú kéré ara mi. Jèhófà ń ràn mí lọ́wọ́ bí mo ṣe ń gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ náà, mo sì ti wá kọ́ ọ̀nà tí mo lè gbà máa mí sínú, mí síta kí n sì máa pọkàn pọ̀. Mo dúpẹ́ gan-an pé ó ti ṣeé ṣe fún mi láti máa yin Ọlọ́run nínú ìjọ àti nígbà tí mo bá ń wàásù.”

Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Tó Ṣẹ̀ṣẹ̀ Wọ Bẹ́tẹ́lì

Ohun Tó Wà Fún: Láti ran àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé Bẹ́tẹ́lì lọ́wọ́ kí wọ́n lè kẹ́sẹ járí lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wọn níbẹ̀.

Àkókò: Ìṣẹ́jú márùnlélógójì [45] lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, fún ọ̀sẹ̀ mẹ́rìndínlógún [16].

Ibi Tí A Ti Ń Ṣe É: Bẹ́tẹ́lì.

Ohun Téèyàn Gbọ́dọ̀ Dójú Ìlà Rẹ̀: Ó gbọ́dọ̀ jẹ́ ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì tàbí ẹni tó yọ̀ǹda ara rẹ̀ fún ìgbà díẹ̀ àmọ́ tí wọ́n ti fọwọ́ sí i pé kó sìn fún ọdún kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ní Bẹ́tẹ́lì.

Béèyàn Ṣe Lè Gba Ìdálẹ́kọ̀ọ́: Gbogbo àwọn tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ di ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì ni wọ́n máa ń fi sílé ẹ̀kọ́ yìí.

Láàárín ọdún 1980 sí ọdún 1989 ni Demetrius lọ sí ilé ẹ̀kọ́ yìí. Ó sọ ohun tó kọ́ ní ọdún tó lọ síbẹ̀, ó ní: “Ohun tí mo kọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ náà mú kí ọ̀nà tí mo gbà ń kẹ́kọ̀ọ́ sunwọ̀n sí i, ó sì jẹ́ kí n mọ bí mo ṣe lè sìn fún ìgbà pípẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì. Ọ̀nà tí àwọn olùkọ́ wa ń gbà kọ́ni, àwọn ohun tí à ń kọ́ àti àwọn ìmọ̀ràn tó wúlò tí wọ́n ń fún wa mú kó dá mi lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ mi àti pé ó wù ú láti ràn mí lọ́wọ́ kí n lè ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn mi ní Bẹ́tẹ́lì.”

Kaitlyn sọ pé: “Ilé Ẹ̀kọ́ náà ràn mí lọ́wọ́ láti pọkàn pọ̀ sórí ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ, ìyẹn ni pé kí n jẹ́ ẹni tó ń ṣe nǹkan lọ́nà tí Jèhófà fẹ́. Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Tó Ṣẹ̀ṣẹ̀ Wọ Bẹ́tẹ́lì ti mú kí ìmọrírì tí mo ní fún Jèhófà, ilé rẹ̀ àti ètò rẹ̀ pọ̀ sí i.”

Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Alàgbà Àtàwọn Ìránṣẹ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́

Ohun Tó Wà Fún: Láti dá àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò, àwọn alàgbà àti nígbà míì àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ lẹ́kọ̀ọ́ nípa bí wọ́n ṣe lè máa bójú tó ìjọ àtàwọn ojúṣe míì tí wọ́n ní nínú ètò Ọlọ́run. (Ìṣe 20:28) Ìdálẹ́kọ̀ọ́ náà máa ń dá lórí àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ìjọ àti àwọn ohun tó ń fẹ́ àbójútó ní kíákíá. Ọdún mélòó kan síra wọn ni ilé ẹ̀kọ́ yìí máa ń wáyé, Ìgbìmọ̀ Olùdarí ló sì máa ń pinnu ìgbà tó máa jẹ́.

Àkókò: Láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, ọjọ́ méjì sí ọjọ́ méjì àtààbọ̀ ni àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò lò ní ilé ẹ̀kọ́ yìí, ọjọ́ kan sí ọjọ́ kan àtààbọ̀ làwọn alàgbà lò, àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ sì lo ọjọ́ kan.

Ibi Tí A Ti Ń Ṣe É: Ó sábà máa ń jẹ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí Gbọ̀ngàn Àpéjọ.

Ohun Téèyàn Gbọ́dọ̀ Dójú Ìlà Rẹ̀: Ó gbọ́dọ̀ jẹ́ alábòójútó arìnrìn-àjò, alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́.

Béèyàn Ṣe Lè Gba Ìdálẹ́kọ̀ọ́: Alábòójútó àyíká máa kàn sí àwọn alàgbà àtàwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó bá kúnjú ìwọ̀n. Ẹ̀ka ọ́fíìsì ló máa ń pe àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò.

Quinn, tó fara hàn gbangba nínú àwòrán tó wà lójú ìwé yìí, sọ pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ilé ẹ̀kọ́ náà kò gba àkókò tó pọ̀, ọ̀pọ̀ nǹkan tí àwọn alàgbà ń kọ́ níbẹ̀ máa ń fún wọn lókun ó sì máa ń mú kí wọ́n máa láyọ̀ kí wọ́n sì ‘máa bá’ iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ‘nìṣó bí ọkùnrin.’ Àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di alàgbà àtàwọn tó ti ń sìn látọjọ́ pípẹ́ ti kọ́ bí wọ́n ṣe lè máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo lọ́nà tó múná dóko, kí wọ́n sì wà ní ìṣọ̀kan rẹ́gírẹ́gí ‘nínú ìlà ìrònú kan náà.’”

Michael sọ pé: “Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yìí kò pọ̀n sápá kan. Ó jẹ́ ká ní òye tó tọ́ nípa àwọn ohun tó jẹ mọ́ ìgbàgbọ́ wa, ó kìlọ̀ fún wa nípa àwọn ewu tó yẹ ká sá fún, ó sì fún wa ní àwọn àbá tó wúlò nípa bó ṣe yẹ ká máa bójú tó agbo. Bí Jèhófà ṣe ń kọ́ wa yìí fi hàn pé ó jẹ́ onínúure.”

Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Aṣáájú-Ọ̀nà

Ohun Tó Wà Fún: Láti ran àwọn aṣáájú-ọ̀nà lọ́wọ́ kí wọ́n lè ‘ṣàṣeparí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn ní kíkún.’—2 Tím. 4:5.

Àkókò: Ọ̀sẹ̀ méjì.

Ibi Tí A Ti Ń Ṣe É: Ẹ̀ka ọ́fíìsì ló máa ń pinnu; ó sábà máa ń jẹ́ ní Gbọ̀ngàn Ìjọba.

Ohun Téèyàn Gbọ́dọ̀ Dójú Ìlà Rẹ̀: Ó ti gbọ́dọ̀ wà lẹ́nu iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà fún ọdún kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ.a

Béèyàn Ṣe Lè Gba Ìdálẹ́kọ̀ọ́: Alábòójútó àyíká ló máa ń forúkọ àwọn aṣáájú-ọ̀nà tó bá kúnjú ìwọ̀n sílẹ̀, òun ló sì máa ń sọ ìgbà tí wọ́n máa lọ sí ilé ẹ̀kọ́ náà.

Lily, tí àwòrán rẹ̀ wà lójú ìwé yìí, sọ pé: “Ilé ẹ̀kọ́ yẹn ti ràn mí lọ́wọ́ láti kojú àwọn ìṣòro tí mò ń bá pàdé ní pápá àti nínú ìgbésí ayé mi. Bí mo ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́, bí mo ṣe ń kọ́ni àti bí mo ṣe ń lo Bíbélì ti sunwọ̀n sí i lọ́pọ̀lọpọ̀. Ó ti mú kí n túbọ̀ wà ní sẹpẹ́ láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, kí n kọ́wọ́ ti àwọn alàgbà, kí n sì máa pa kún ìtẹ̀síwájú ìjọ.”

Brenda, tó ti lọ sí ilé ẹ̀kọ́ náà nígbà méjì sọ pé: “Ó mú kí n pa ọkàn pọ̀ sórí àjọṣe mi pẹ̀lú Ọlọ́run, ó fún ẹ̀rí ọkàn mi lókun, ó sì mú kí n gbájú mọ́ ríran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Ó ṣe kedere pé Jèhófà jẹ́ ọ̀làwọ́!”

a Bí àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di aṣáájú-ọ̀nà kò bá pọ̀ tó iye tí wọ́n fi lè jẹ́ kíláàsì kan, a lè pe àwọn aṣáájú-ọ̀nà kan tí wọn kò tíì lọ sí ilé ẹ̀kọ́ yìí ní ọdún márùn-ún sígbà yẹn láti kún wọn.

Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Alàgbà Ìjọ

Ohun Tó Wà Fún: Láti ran àwọn alàgbà lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa ṣe ojúṣe wọn nínú ìjọ kí wọ́n sì lè mọ púpọ̀ sí i nípa bó ṣe yẹ kí wọ́n máa sin Jèhófà.

Àkókò: Ọjọ́ márùn-ún.

Ibi Tí A Ti Ń Ṣe É: Ẹ̀ka ọ́fíìsì ló máa ń pinnu; ó sábà máa ń jẹ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí Gbọ̀ngàn Àpéjọ.

Ohun Téèyàn Gbọ́dọ̀ Dójú Ìlà Rẹ̀: Ó gbọ́dọ̀ jẹ́ alàgbà.

Béèyàn Ṣe Lè Gba Ìdálẹ́kọ̀ọ́: Ẹ̀ka ọ́fíìsì máa pe àwọn alàgbà tó bá kúnjú ìwọ̀n.

Ohun tí àwọn kan tó lọ sí kíláàsì kejìléláàádọ́rùn-ún lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ rèé:

“Mo ti jàǹfààní tó pọ̀ gan-an ní ilé ẹ̀kọ́ náà, ó ti mú kí n máa kíyè sí bí mo ṣe ń ṣe sí kí n sì máa ronú nípa bí mo ṣe lè máa bójú tó àwọn àgùntàn Jèhófà.”

“Mo ti ṣe tán báyìí láti máa fún àwọn èèyàn níṣìírí nípa ṣíṣàlàyé àwọn kókó pàtàkì tó wà nínú Ìwé Mímọ́.”

“Mi ò jẹ́ gbàgbé ìdálẹ́kọ̀ọ́ yìí ní gbogbo ọjọ́ ayé mi.”

Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Alábòójútó Arìnrìn-Àjò Àtàwọn Ìyàwó Wọn

Ohun Tó Wà Fún: Láti mú kí àwọn alábòójútó àyíká àtàwọn alábòójútó àgbègbè máa ṣe ìbẹ̀wò sí ìjọ lọ́nà tó túbọ̀ múná dóko, bí wọ́n ti ń “ṣiṣẹ́ kára nínú ọ̀rọ̀ sísọ àti kíkọ́ni.”—1 Tím. 5:17; 1 Pét. 5:2, 3.

Àkókò: Oṣù méjì.

Ibi Tí A Ti Ń Ṣe É: Ẹ̀ka ọ́fíìsì ló máa ń pinnu rẹ̀.

Ohun Téèyàn Gbọ́dọ̀ Dójú Ìlà Rẹ̀: Ó gbọ́dọ̀ jẹ́ alábòójútó àyíká tàbí alábòójútó àgbègbè.

Béèyàn Ṣe Lè Gba Ìdálẹ́kọ̀ọ́: Ẹ̀ka ọ́fíìsì ló máa ń pe àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò àtàwọn ìyàwó wọn.

Joel tó lọ sí kíláàsì àkọ́kọ́ ní ọdún 1999 sọ pé: “Ó ti mú ká túbọ̀ mọyì bí Jésù ṣe ń darí ètò Ọlọ́run. A rí i pé ó ṣe pàtàkì pé ká máa fún àwọn ará tí à ń bẹ̀ wò ní ìṣírí kí a sì mú kí ìjọ kọ̀ọ̀kan túbọ̀ wà ní ìṣọ̀kan. Ìdálẹ́kọ̀ọ́ yìí gbìn ín sí wa lọ́kàn pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé alábòójútó arìnrìn-àjò máa ń fún àwọn ará nímọ̀ràn tó sì máa ń sọ àwọn nǹkan tó nílò àtúnṣe nígbà míì, ìdí pàtàkì tó fi ń ṣe ìbẹ̀wò sáwọn ìjọ ni pé kó lè mú kó dá àwọn ará lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wọn.”

Ilé Ẹ̀kọ́ Bíbélì fún Àwọn Àpọ́n

Ohun Tó Wà Fún: Láti mú kí àwọn alàgbà àtàwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí kò tíì gbéyàwó wà ní ìmúratán láti ṣe púpọ̀ sí i nínú ètò Jèhófà. Ọ̀pọ̀ lára àwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ yege la máa ń rán lọ sí àwọn ibi tá a ti nílò àwọn oníwáàsù púpọ̀ sí i lórílẹ̀-èdè wọn. Wọ́n lè rán àwọn míì lọ sìn lórílẹ̀-èdè mìíràn bí wọ́n bá sọ fún ẹ̀ka ọ́fíìsì pé àwọn lè ṣe bẹ́ẹ̀. Wọ́n lè ní kí àwọn kan lọ máa sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe fún ìgbà díẹ̀, kí wọ́n lè lọ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù láwọn ibi tó jìnnà àti láwọn ibi àdádó, kí wọ́n sì lè mú iṣẹ́ ìwàásù gbòòrò níbẹ̀.

Àkókò: Oṣù méjì.

Ibi Tí A Ti Ń Ṣe É: Ẹ̀ka ọ́fíìsì ló máa ń pinnu; ó sábà máa ń jẹ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí Gbọ̀ngàn Àpéjọ.

Ohun Téèyàn Gbọ́dọ̀ Dójú Ìlà Rẹ̀: Arákùnrin tí kò níyàwó tí ọjọ́ orí rẹ̀ wà láàárín ọdún mẹ́tàlélógún [23] sí ọdún méjìlélọ́gọ́ta [62], tó ní ìlera tó dáa, tó sì fẹ́ lọ sìn níbikíbi tá a bá ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i. (Máàkù 10:29, 30) Ó kéré tán, ó ti gbọ́dọ̀ máa sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà déédéé fún ọdún méjì, ó sì ti gbọ́dọ̀ máa sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ fún ọdún méjì láìdáwọ́dúró.

Béèyàn Ṣe Lè Gba Ìdálẹ́kọ̀ọ́: A máa ń ṣe ìpàdé kan nígbà àpéjọ àyíká láti pèsè ìsọfúnni fún àwọn tó bá fẹ́ lọ sí ilé ẹ̀kọ́ yìí.

Rick tó lọ sí kíláàsì kẹtàlélógún [23] ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Bí mo ṣe ń gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ yìí ni ẹ̀mí Jèhófà túbọ̀ ń mú kí n ṣe àwọn àtúnṣe kan nínú ìgbésí ayé mi. Bí Jèhófà bá gbé iṣẹ́ lé èèyàn lọ́wọ́, kì í dá onítọ̀hún dá irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀. Mo ti kẹ́kọ̀ọ́ pe Ọlọ́run máa fún mi lókun tí n bá gbájú mọ́ ṣíṣe ìfẹ́ rẹ̀.”

Andreas tó ń sìn ní orílẹ̀-èdè Jámánì sọ pé: “Látàrí ohun tí mo kọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ yìí, iṣẹ́ ìyanu ni ètò tí Ọlọ́run ń lò lóde òní jọ lójú mi. Ìdálẹ́kọ̀ọ́ náà mú kí n gbára dì fún iṣẹ́ tó wà níwájú. Bákan náà, ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ tó wà nínú Bíbélì fi òótọ́ pàtàkì kan kọ́ mi. Ìyẹn ni pé: Tí mo bá ń ṣiṣẹ́ sin Jèhófà tí mo sì ń lo ara mi fún àwọn arákùnrin àti arábìnrin mi, ó dájú pé màá ní ojúlówó ayọ̀.”

Ilé Ẹ̀kọ́ Bíbélì fún Àwọn Tọkọtaya

Ohun Tó Wà Fún: Láti fún àwọn tọkọtaya ní ìdálẹ́kọ̀ọ́ àkànṣe, kí wọ́n lè túbọ̀ wúlò fún Jèhófà àti ètò rẹ̀. Ọ̀pọ̀ lára àwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ yege la máa rán lọ sí àwọn ibi tá a ti nílò àwọn oníwáàsù púpọ̀ sí i lórílẹ̀-èdè wọn. A lè ní kí àwọn kan lọ sìn ní orílẹ̀-èdè mìíràn bí wọ́n bá sọ fún ẹ̀ka ọ́fíìsì pé àwọn lè ṣe bẹ́ẹ̀. Àwọn tó jáde ní ilé ẹ̀kọ́ náà lè lọ máa sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe fún ìgbà díẹ̀, kí wọ́n lè lọ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù láwọn ibi tó jìnnà àti láwọn ibi àdádó, kí wọ́n sì lè mú iṣẹ́ ìwàásù gbòòrò níbẹ̀.

Àkókò: Oṣù méjì.

Ibi Tí A Ti Ń Ṣe É: Ilé ẹ̀kọ́ yìí ti ń lọ lọ́wọ́ ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà báyìí, àmọ́ láti oṣù September, ọdún 2012, ó máa bẹ̀rẹ̀ ní àwọn àgbègbè tó wà lábẹ́ àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì kan kárí ayé. Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí Gbọ̀ngàn Àpéjọ la ti sábà máa ń ṣe é.

Ohun Téèyàn Gbọ́dọ̀ Dójú Ìlà Rẹ̀: Àwọn tọkọtaya tọ́jọ́ orí wọn wà láàárín ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] sí àádọ́ta [50] ọdún, tí wọ́n ní ìlera tó dáa, tí ipò wọn sì yọ̀ǹda fún wọn láti lọ sìn ní ibikíbi tá a ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i, tí wọ́n sì ní irú ẹ̀mí tí wòlíì Aísáyà ní, nígbà tó sọ pé: “Èmi nìyí! Rán mi.” (Aísá. 6:8) Ó kéré tán, wọ́n ti gbọ́dọ̀ ṣègbéyàwó fún ọdún méjì kí wọ́n sì ti máa ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún láìdáwọ́dúró fún ọdún méjì, ó kéré tán. Ọkọ ti gbọ́dọ̀ máa sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ láìdáwọ́dúró fún ọdún méjì, ó kéré tán.

Béèyàn Ṣe Lè Gba Ìdálẹ́kọ̀ọ́: A máa ń ṣe ìpàdé kan nígbà àpéjọ àgbègbè láti pèsè ìsọfúnni fún àwọn tó bá fẹ́ lọ sí ilé ẹ̀kọ́ yìí. Bí wọn kì í bá ṣe irú ìpàdé yìí ní àpéjọ àgbègbè lórílẹ̀-èdè rẹ, tó o sì fẹ́ lọ sí ilé ẹ̀kọ́ náà, o lè kọ̀wé sí ẹ̀ka ọ́fíìsì, kó o lè gba ìsọfúnni síwájú sí i.

“Ńṣe ni ìdálẹ́kọ̀ọ́ ọlọ́sẹ̀-mẹ́jọ yìí ń yí ìgbé ayé ẹni pa dà, àǹfààní ńlá ló sì jẹ́ fún àwọn tọkọtaya tó bá fẹ́ ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà! Ìpinnu wa ni pé a ó máa gbé ìgbé ayé tó wà ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì ká lè máa fi ọgbọ́n lo àkókò wa.”—Eric àti Corina (nínú àwòrán ojú ìwé yìí), kíláàsì àkọ́kọ́, ọdún 2011.

Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì

Ohun Tó Wà Fún: Láti pèsè ìdálẹ́kọ̀ọ́ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè máa sìn ní pápá bíi míṣọ́nnárì láwọn àgbègbè táwọn èèyàn pọ̀ sí gan-an, kí wọ́n lè máa sìn bí alábòójútó arìnrìn-àjò tàbí kí wọ́n lè kúnjú ìwọ̀n fún iṣẹ́ ìsìn ní Bẹ́tẹ́lì. A dìídì ṣètò ilé ẹ̀kọ́ yìí láti mú kí iṣẹ́ ìwàásù gbòòrò sí i, kí àbójútó gidi sì lè wà ní àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì kárí ayé.

Àkókò: Oṣù márùn-ún.

Ibi Tí A Ti Ń Ṣe É: Ibùdó Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ti Watchtower tó wà ní ìlú Patterson, ní ìpínlẹ̀ New York, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.

Ohun Téèyàn Gbọ́dọ̀ Dójú Ìlà Rẹ̀: Àwọn tọkọtaya tí wọ́n ti wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún lọ́nà àkànṣe, bóyá àwọn míṣọ́nnárì tó wà ní pápá tí wọn kò tíì lọ sí ilé ẹ̀kọ́ náà, àwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe, àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò tàbí àwọn tó wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì. Ó kéré tán, wọ́n ti gbọ́dọ̀ jọ wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún lọ́nà àkànṣe fún ọdún mẹ́ta láìdáwọ́dúró. Wọ́n gbọ́dọ̀ lè sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì, kí wọ́n lè kà á, kí wọ́n sì lè kọ ọ́ dáadáa.

Béèyàn Ṣe Lè Gba Ìdálẹ́kọ̀ọ́: Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka tó ń bójú tó orílẹ̀-èdè tí tọkọtaya kan ti ń sìn lè ní kí wọ́n kọ ọ̀rọ̀ kún fọ́ọ̀mù ilé ẹ̀kọ́ yìí.

Lade àti Monique tí wọ́n wá láti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ti ń sìn báyìí ní ilẹ̀ Áfíríkà. Lade sọ pé: “Pẹ̀lú ìdálẹ́kọ̀ọ́ tá a gbà ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì yìí, kò sí ibi tí a kò lè lọ láyé yìí, a ti múra tán láti lọ ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ará wa ọ̀wọ́n.”

Monique náà sọ pé: “Bí mo ṣe ń fi àwọn nǹkan tí mo ti kọ́ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílò, bẹ́ẹ̀ ni mò ń láyọ̀ púpọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ tí wọ́n yàn fún mi. Ayọ̀ tí mo ní yìí ń jẹ́ kó túbọ̀ dá mi lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ mi.”

Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka Àtàwọn Ìyàwó Wọn

Ohun Tó Wà Fún: Láti ran àwọn tó wà lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka lọ́wọ́ kí wọ́n lè túbọ̀ máa ṣe àbójútó àwọn ilé Bẹ́tẹ́lì, kí wọ́n máa fún àwọn ọ̀ràn iṣẹ́ ìsìn tó ní í ṣe pẹ̀lú àwọn ìjọ láfiyèsí, kí wọ́n sì máa bójú tó àwọn àyíká àti àgbègbè tó wà lábẹ́ àbójútó wọn. Wọ́n tún ń fún wọn ní ìsọfúnni nípa iṣẹ́ ìtúmọ̀ èdè, ìwé títẹ̀ àti kíkó ìwé ránṣẹ́ sí àwọn ìjọ.

Àkókò: Oṣù méjì.

Ibi Tí A Ti Ń Ṣe É: Ibùdó Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ti Watchtower tó wà ní ìlú Patterson, ní ìpínlẹ̀ New York, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.

Ohun Téèyàn Gbọ́dọ̀ Dójú Ìlà Rẹ̀: Arákùnrin náà gbọ́dọ̀ jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka tàbí Ìgbìmọ̀ Orílẹ̀-èdè tàbí àwọn tí wọ́n bá yàn láti máa ṣe ojúṣe yìí.

Béèyàn Ṣe Lè Gba Ìdálẹ́kọ̀ọ́: Ìgbìmọ̀ Olùdarí ló máa ń pe àwọn arákùnrin tó bá kúnjú ìwọ̀n àtàwọn ìyàwó wọn.

Lowell àti Cara, tí wọ́n lọ sí kíláàsì kẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] ti ń sìn báyìí ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Lowell sọ pé: “Mo ti kẹ́kọ̀ọ́ pé kò sí bí ọwọ́ mi ṣe lè dí tó tàbí iṣẹ́ yòówù kí wọ́n gbé fún mi, ohun pàtàkì tó lè jẹ́ kí n mú inú Jèhófà dùn ni pé kí n máa ṣe nǹkan lọ́nà tó wù ú. Ìdálẹ́kọ̀ọ́ yẹn tún jẹ́ kí n rí bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká nífẹ̀ẹ́ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ṣe nífẹ̀ẹ́ wọn.”

Cara náà sọ pé: “Ọ̀rọ̀ kan tí mo sábà máa ń ronú lé lórí ni pé, tí mi ò bá ti lè ṣàlàyé kókó ọ̀rọ̀ kan lọ́nà tó rọrùn, àfi kí n fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ dáadáa kí n tó fi kọ́ ẹlòmíì.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́