ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • kr orí 17 ojú ìwé 182-191
  • Bí A Ṣe Ń Dá Àwọn Òjíṣẹ́ Ìjọba Náà Lẹ́kọ̀ọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bí A Ṣe Ń Dá Àwọn Òjíṣẹ́ Ìjọba Náà Lẹ́kọ̀ọ́
  • Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Gẹ́gẹ́ Bí Baba Ti Kọ́ Mi Ni Mo Ń Sọ”
  • Bí A Ṣe Ń Dá Àwọn Òjíṣẹ́ Lẹ́kọ̀ọ́ Láti Di Ajíhìnrere
  • Bí A Ṣe Ń Dá Àwọn Arákùnrin Lẹ́kọ̀ọ́ Láti Bójú Tó Àwọn Ojúṣe Pàtàkì
  • Àwọn Ilé Ẹ̀kọ́ Ètò Ọlọ́run—Ẹ̀rí Pé Jèhófà Nífẹ̀ẹ́ Wa
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Àwọn Ìdálẹ́kọ̀ọ́ Wo Ló Ń Mú Káwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Já Fáfá Lẹ́nu Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Wa?
    Àwọn Ìbéèrè Táwọn Èèyàn Sábà Máa Ń Béèrè Nípa Ẹlẹ́rìí Jèhófà
  • Ǹjẹ́ Ò Ń Kọ́ Gbogbo Ohun Tó O Lè Kọ́ Lọ́dọ̀ Jèhófà?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
  • Àwọn Ilé Ẹ̀kọ́ Tó Wà fún Àwọn Aṣáájú-Ọ̀nà
    Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?
Àwọn Míì
Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!
kr orí 17 ojú ìwé 182-191

ORÍ 17

Bí A Ṣe Ń Dá Àwọn Òjíṣẹ́ Ìjọba Náà Lẹ́kọ̀ọ́

OHUN TÍ ORÍ YÌÍ DÁ LÉ

Bí àwọn ilé ẹ̀kọ́ ètò Ọlọ́run ṣe ń múra àwọn òjíṣẹ́ Ìjọba náà sílẹ̀ kí wọ́n lè ṣe iṣẹ́ tí a yàn fún wọn

1-3. Báwo ni Jésù ṣe mú iṣẹ́ ìwàásù gbòòrò sí i, àwọn ìbéèrè wo ló sì jẹ yọ?

ỌDÚN méjì gbáko ni Jésù fi wàásù jákèjádò ìlú Gálílì. (Ka Mátíù 9:35-38.) Ó lọ sí ọ̀pọ̀ ìlú àtàwọn abúlé, ó ń kọ́ àwọn èèyàn nínú àwọn sínágọ́gù, bẹ́ẹ̀ ló sì ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Ní gbogbo ibi tó ti wàásù, ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Jésù sọ pé, “ìkórè pọ̀” a sì nílò àwọn òṣìṣẹ́ púpọ̀ sí i.

2 Jésù ṣètò láti mú iṣẹ́ ìwàásù gbòòrò sí i. Lọ́nà wo? Nípa rírán àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ méjìlá jáde láti “wàásù Ìjọba Ọlọ́run.” (Lúùkù 9:1, 2) Ó ṣeé ṣe kí àwọn àpọ́sítélì náà ti ní àwọn ìbéèrè nípa ọ̀nà tí wọ́n máa gbà ṣe iṣẹ́ yìí. Kí Jésù tó rán wọn jáde, ó fìfẹ́ fún wọn ní nǹkan tí Baba rẹ̀ ọ̀run ti fún un, ìyẹn ìdálẹ́kọ̀ọ́.

3 Àwọn ìbéèrè kan lè wá síni lọ́kàn. Àwọn ni: Irú ìdálẹ́kọ̀ọ́ wo ni Jésù gbà látọ̀dọ̀ Baba rẹ̀? Báwo ni Jésù ṣe dá àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́? Lóde òní ńkọ́, ṣé Mèsáyà Ọba ti dá àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ nípa bí wọ́n ṣe máa ṣe iṣẹ́ ìwàásù wọn? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, lọ́nà wo?

“Gẹ́gẹ́ Bí Baba Ti Kọ́ Mi Ni Mo Ń Sọ”

4. Ìgbà wo ni Bàbá Jésù ti kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́? Ibo ló sì ti kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́?

4 Jésù gbà pé Baba òun ló kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́. Nígbà tí Jésù ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, ó sọ pé: “Gẹ́gẹ́ bí Baba ti kọ́ mi ni mo ń sọ nǹkan wọ̀nyí.” (Jòhánù 8:28) Ìgbà wo àti ibo ni Jésù ti gba ìdálẹ́kọ̀ọ́? Ó dájú pé ìdálẹ́kọ̀ọ́ àkọ́bí Ọmọ Ọlọ́run yìí bẹ̀rẹ̀ kété lẹ́yìn tí Ọlọ́run dá a. (Kól. 1:15) Ó gbé pẹ̀lú Baba rẹ̀ ní ọ̀run. Ọ̀kẹ́ àìmọye ọdún ló fi ń tẹ́tí sílẹ̀ tó sì ń wo “Olùkọ́ni Atóbilọ́lá náà.” (Aísá. 30:20) Fún ìdí yìí, Ọmọ gba ẹ̀kọ́ tí kò láfiwé látara àwọn ànímọ́ àtàwọn iṣẹ́ Baba rẹ̀ àti nípa àwọn ète Baba rẹ̀.

5. Ìtọ́ni wo ni Bàbá fún Ọmọ rẹ̀ nípa iṣẹ́ ìwàásù tó máa ṣe lórí ilẹ̀ ayé?

5 Nígbà tó yá, Jèhófà kọ́ Ọmọ rẹ̀ nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó máa ṣe lórí ilẹ̀ ayé. Wo àsọtẹ́lẹ̀ kan tó ṣàpèjúwe àjọṣe tó wà láàárín Olùkọ́ni Atóbilọ́lá náà àti Ọmọ rẹ̀ àkọ́bí. (Ka Aísáyà 50:4, 5.) Àsọtẹ́lẹ̀ náà sọ pé, Jèhófà ń jí Ọmọ rẹ̀ ní “òròòwúrọ̀.” Àpèjúwe yìí jẹ́ ká mọ bí olùkọ́ kan ṣe máa ń jí akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ní kùtùkùtù òwúrọ̀ kó bàa lè kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́. Ìwé kan tó ń ṣàlàyé Bíbélì sọ pé: “Ká kúkú sọ pé ńṣe ni Jèhófà . . . ń mú un lọ ilé ẹ̀kọ́ bíi ti akẹ́kọ̀ọ́ kan, ó sì ń kọ́ ọ nípa nǹkan tó máa wàásù àti bó ṣe máa wàásù.” Ní “ilé ẹ̀kọ́” tó wà lọ́run yìí, Jèhófà kọ́ ọmọ rẹ̀ ní ‘ohun tí yóò wí àti ohun tí yóò sọ.’ (Jòh. 12:49) Baba tún fún Ọmọ ní ìtọ́ni nípa bó ṣe máa kọ́ni.a Nígbà tí Jésù wà láyé, ó fi ohun tó kọ́ yìí sílò ní ti pé ó ṣe iṣẹ́ ìwàásù rẹ̀ yanjú, ó sì tún kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ nípa bí wọ́n ṣe máa ṣe iṣẹ́ ìwàásù wọn láṣeyọrí.

6, 7. (a) Ìdálẹ́kọ̀ọ́ wo ni Jésù fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀, kí ni ìdálẹ́kọ̀ọ́ náà mú kí wọ́n gbara dì láti ṣe? (b) Irú ìdálẹ́kọ̀ọ́ wo ni Jésù rí i dájú pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun rí gbà ní ọjọ́ tiwa yìí?

6 Bí a ṣe sọ níṣàájú, báwo ni Jésù ṣe dá àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́? Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Mátíù orí 10 sọ, ó fún wọn ní àwọn ìtọ́ni pàtó nípa iṣẹ́ ìwàásù. Lára wọn ni: ibi tí wọ́n á ti wàásù (ẹsẹ 5 àti 6), ohun tí wọ́n máa wàásù (ẹsẹ 7), ìdí tó fi yẹ kí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà (ẹsẹ 9 àti 10), bí wọ́n ṣe lè bá àwọn èèyàn tó wà nílé kan sọ̀rọ̀ (ẹsẹ  11 sí 13), ohun tó yẹ́ kí wọ́n ṣe tí àwọn èèyàn kò bá fetí sílẹ̀ (ẹsẹ 14 àti 15), ohun tí wọ́n máa ṣe táwọn èèyàn bá ń ṣe inúnibíni sí wọn (ẹsẹ 16 sí  23).b Ìtọ́ni tó ṣe kedere tí Jésù fún àwọn àpọ́sítélì mú kí wọ́n gbara dì láti mú ipò iwájú nínú wíwàásù ìhìn rere náà ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní Sànmánì Kristẹni.

7 Lákòókò tiwa yìí ńkọ́? Jésù tó jẹ́ Ọba Ìjọba Ọlọ́run ti fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ níṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ, ìyẹn wíwàásù “ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.” (Mát. 24:14) Ǹjẹ́ Ọba náà ti kọ́ wa bí a ṣe máa ṣe iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ yìí? Ó dájú pé, ó ti kọ́ wa! Láti ibi tí Ọba náà wà lọ́run, ó ń rí i dájú pé àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ń gbà ìdálẹ́kọ̀ọ́ nípa bí wọ́n ṣe lè wàásù fáwọn tí kì í ṣe onígbàgbọ́ bíi tiwọn àti bí wọ́n ṣe lè bójú tó àwọn ojúṣe pàtàkì nínú ìjọ.

Bí A Ṣe Ń Dá Àwọn Òjíṣẹ́ Lẹ́kọ̀ọ́ Láti Di Ajíhìnrere

8, 9. (a) Kí ni ìdí pàtàkì tá a fi dá Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run sílẹ̀? (b) Báwo ni ìpàdé àárín ọ̀sẹ̀ ṣe túbọ̀ ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti máa ṣe dáadáa nínú iṣẹ́ ìwàásù rẹ?

8 Ọjọ́ ti pẹ́ tí ètò Jèhófà ti ń lo àwọn àpéjọ àyíká, àpéjọ àkànṣe, àpéjọ àgbègbè àti àwọn ìpàdé ìjọ irú bí Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn láti dá àwọn èèyàn Ọlọ́run lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè máa ṣe iṣẹ́ ìwàásù. Láti nǹkan bí ọdún 1940 síwájú ni àwọn arákùnrin tó ń múpò iwájú ní orílé-iṣẹ́ wa ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣètò oríṣiríṣi ilé ẹ̀kọ́ láti máa dáni lẹ́kọ̀ọ́.

9 Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run. Bí a ṣe rí i ní orí tó ṣáájú, ọdún 1943 la bẹ̀rẹ̀ ilé ẹ̀kọ́ náà. Ṣé dídá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n bàa lè máa sọ àwọn àsọyé lọ́nà tó gbéṣẹ́ nìkan ni ilé ẹ̀kọ́ yìí wà fún? Rárá o. Ìdí pàtàkì tá a fi dá ilé ẹ̀kọ́ náà sílẹ̀ ni láti dá àwọn èèyàn Ọlọ́run lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè lo àwọn ẹ̀bùn ọ̀rọ̀ sísọ tí wọ́n ní láti máa fi yin Jèhófà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wọn. (Sm. 150:6) Ilé ẹ̀kọ́ náà mú kí àwọn arákùnrin àti arábìnrin tó forúkọ sílẹ̀ níbẹ̀ túbọ̀ di òjíṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run tó já fáfá. Ìpàdè àárín ọ̀sẹ̀ la ti ń gba irú ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yẹn lóde òni.

10, 11. Àwọn wo ló lè forúkọ sílẹ̀ láti lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì, kí sì ni àwọn ẹ̀kọ́ ibẹ̀ wà fún?

10 Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì. Ilé ẹ̀kọ́ tá a wá mọ̀ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ Monday, February 1, 1943. Níbẹ̀rẹ̀, a dá ilé ẹ̀kọ́ náà sílẹ̀ láti pèsè ìdálẹ́kọ̀ọ́ fáwọn aṣáájú-ọ̀nà àtàwọn ìránṣẹ́ alákòókò-kíkún kí wọ́n lè ṣe iṣẹ́ míṣọ́nárì láwọn ibì kan láyé. Àmọ́, láti October 2011, kìkì àwọn tó ti wà nínú àkànṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún nìkan ló máa ń lọ ilé ẹ̀kọ́ yìí, àwọn bíi, àwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe, àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò àtàwọn ìyàwó wọn, àwọn tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì àtàwọn tó ń sìn ní pápá bíi míṣọ́nnárì àmọ́ tí wọn kò tíì lọ ilé ẹ̀kọ́ náà tẹ́lẹ̀.

11 Kí ni àwọn ẹ̀kọ́ tí wọ́n ń gbà ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì wà fún? Ohun tí Olùkọ́ kan tó ti ń kọ́ni tipẹ́ nílé ẹ̀kọ́ náà sọ rèé: “Láti mú kí ìgbàgbọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lágbára sí i nípasẹ̀ kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lọ́nà tó jinlẹ̀ àti pé kí wọ́n bàa lè ní àwọn ànímọ̀ tẹ̀mí tó máa jẹ́ kí wọ́n ṣàṣeyọrí nínú yíyanjú àwọn ìṣòrò tó lè jẹ yọ lẹ́nu iṣẹ́ wọn. Ohun tó tún ṣe pàtàkì jù tí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ náà wà fún ni gbíngbin ìtara púpọ̀ sí i sọ́kàn àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láti mú kí wọ́n túbọ̀ máa kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù.”—Éfé. 4:11.

12, 13. Ipa wo ni Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì ti ní lórí iṣẹ́ ìwàásù kárí ayé? Sọ àpẹẹrẹ kan.

12 Ipa wo ni Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì ti ní lórí iṣẹ́ ìwàásù tá a ń ṣe kárí ayé? Láti ọdún 1943, ó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [8,500] èèyàn tó ti gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ nílé ẹ̀kọ́ náà.c Àwọn míṣọ́nnárì tó sì ti gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ nílé ẹ̀kọ́ Gílíádì ti sìn láwọn ilẹ̀ tó lé ní àádọ́sàn-án [170] kárí ayé. Àwọn míṣọ́nnárì yìí ń fi àwọn ohun tí wọ́n ti kọ́ sílò dáadáa, wọ́n sì ń tipa báyìí fí àpẹẹrẹ ìtara lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù lélẹ̀, wọ́n sì ń kọ́ àwọn míì láti ṣe bẹ́ẹ̀. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn míṣọ́nnárì yìí ló máa ń múpò iwájú nínú iṣẹ́ ìwàásù láwọn agbègbè tó jẹ́ pé àwọn oníwàásù díẹ̀ ló wà níbẹ̀ tàbí tí kò sí oníwàásù rárá.

13 Bí àpẹẹrẹ, wo nǹkan tó ṣẹlẹ̀ lórílẹ̀-èdè Japan níbi tí iṣẹ́ ìwàásù tí a fètò sí ti dáwọ́ dúró nígbà Ogun Àgbáyé Kejì. Ní August 1949, àwọn akéde tó wà lórílẹ̀-èdè Japan kò tó mẹ́wàá. Àmọ́, ìgbà tó fi máa di ìparí ọdún yẹn, àwọn míṣọ́nnárì mẹ́tàlá [13] tó ti gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ nílé ẹ̀kọ́ Gílíádì tẹra mọ́ iṣẹ́ ìwàásù lórílẹ̀-èdè Japan. Àwọn míṣọ́nnárì púpọ̀ sí i dé lẹ́yìn náà. Níbẹ̀rẹ̀, àwọn ìlú ńlá làwọn míṣọ́nnárì náà gbájú mọ́, àmọ́ nígbà tó yá, wọ́n lọ sí àwọn ìlú míì. Tọkàntọkàn ni àwọn míṣọ́nnárì fi ń rọ àwọn tí wọ́n ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àtàwọn ará nínú ìjọ pé kí wọ́n gba iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Ìtara àwọn míṣọ́nnárì náà so èso rere. Ní báyìí, ó lé ní ọ̀kẹ́ mẹ́wàá àti ẹgbàájọ [216,000] àwọn olùpòkìkí Ìjọba Ọlọ́run tó wà lórílẹ̀-èdè Japan, ìdámẹ́rin nínú mẹ́wàá wọn ló ń ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà!d

14. Àwọn ilé ẹ̀kọ́ ètò Ọlọ́run jẹ́ ẹ̀rí tó lágbára nípa kí ni? (Wo àpótí náà, “Àwọn Ilé Ẹ̀kọ́ Tó Ń Dá Àwọn Òjíṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run Lẹ́kọ̀ọ́,” lójú ìwé 188.)

14 Àwọn ilé ẹ̀kọ́ míì tí ètò Ọlọ́run dá sílẹ̀. Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Aṣáájú-Ọ̀nà, Ilé Ẹ̀kọ́ Bíbélì fún Àwọn Tọkọtaya àti Ilé Ẹ̀kọ́ Bíbélì fún Àwọn Àpọ́n ti ran àwọn tó lọ sílé ẹ̀kọ́ yìí lọ́wọ́ láti sunwọ̀n sí i nípa tẹ̀mí àti láti máa fìtara múpò iwájú lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù.e Gbogbo àwọn ilé ẹ̀kọ́ tí ètò Ọlọ́run ń lò yìí jẹ́ ẹ̀rí tó lágbára pé Ọba wa ti pèsè gbogbo ohun táwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ nílò láti ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn ní àṣeyọrí.—2 Tím. 4:5.

Bí A Ṣe Ń Dá Àwọn Arákùnrin Lẹ́kọ̀ọ́ Láti Bójú Tó Àwọn Ojúṣe Pàtàkì

15. Ọ̀nà wo ni àwọn ọkùnrin tó wà nípò àbójútó ní láti gbà tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù?

15 Rántí àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà tó sọ̀rọ̀ nípa bí Ọlọ́run ṣe dá Jésù lẹ́kọ̀ọ́. Ní “ilé ẹ̀kọ́” ti ọ̀run yìí, Ọmọ náà kọ́ “bí a ti ń fi ọ̀rọ̀ dá ẹni tí ó ti rẹ̀ lóhùn.” (Aísá. 50:4) Jésù fí ìtọ́ni yẹn sílò. Nígbà tó wà láyé, ó tu àwọn “tí ń ṣe làálàá, tí a sì di ẹrù wọ̀ lọ́rùn” lára. (Mát. 11:28-30) Àwọn ọkùnrin tó wà nípò àbójútó ní láti máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, kí wọ́n jẹ́ orísun ìtura fún àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin. Torí náà, a dá oríṣiríṣi ilé ẹ̀kọ́ sílẹ̀ láti ran àwọn arákùnrin tí wọ́n kúnjú ìwọ̀n lọ́wọ́ kí wọ́n lè túbọ̀ já fáfá nínú ṣíṣiṣẹ́ sin àwọn ará.

16, 17. Kí ni Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Alàgbà Àtàwọn Ìránṣẹ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ wà fún? (Tún wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)

16 Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Alàgbà Àtàwọn Ìránṣẹ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́. Kíláàsì àkọ́kọ́ ti ilé ẹ̀kọ́ yìí bẹ̀rẹ̀ ní March 9, 1959, nílùú South Lansing, ìpínlẹ̀ New York. Àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò àtàwọn ìránṣẹ́ ìjọ ni wọ́n máa ń pè fún ìdálẹ́kọ̀ọ́ olóṣù kan. Nígbà tó yá, wọ́n túmọ̀ ìdálẹ́kọ̀ọ́ náà láti èdè Gẹ̀ẹ́sì sí àwọn èdè míì, ilé ẹ̀kọ́ náà sí bẹ̀rẹ̀ sí í dá àwọn arákùnrin lẹ́kọ̀ọ́ kárí ayé.f

Arákùnrin Lloyd Barry ń kọ̀ àwọn tó wá sí Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Alàgbà Àtàwọn Ìránṣẹ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ lórílẹ̀-èdè Japan, lọ́dún 1970

Arákùnrin Lloyd Barry ń kọ̀ àwọn tó wá sí Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Alàgbà Àtàwọn Ìránṣẹ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ lórílẹ̀-èdè Japan, lọ́dún 1970

17 Ìwé ọdọọdún wa 1962 Yearbook of Jehovah’s Witnesses, sọ ohun tí Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Alàgbà Àtàwọn Ìránṣẹ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ wà fún, ó ní: “Nínú ayé tí ọwọ́ àwọn èèyàn ti dí gan-an yìí, alábòójútó nínú ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni tó lè ṣètò ara rẹ̀ kí ó lè fún gbogbo àwọn tó wà nínú ìjọ láfiyèsí tó yẹ kó sì jẹ́ ìbùkún fún wọn. Síbẹ̀, kò gbọ́dọ̀ gbójú fo ìdílé rẹ̀ nítorí ìjọ, ṣùgbọ́n èrò inú rẹ̀ gbọ́dọ̀ yè kooro. Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá ló jẹ́ fáwọn ìránṣẹ́ ìjọ kárí ayé láti kóra jọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Alàgbà Àtàwọn Ìránṣẹ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ kí wọ́n lè gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ tó máa ràn wọ́n lọ́wọ́ láti lè ṣe ohun tí Bíbélì sọ pé alábòójútó gbọ́dọ̀ máa ṣe!”—1 Tím. 3:1-7; Títù 1:5-9.

18. Báwo ni gbogbo àwọn Èèyàn Ọlọ́run ṣe ń jàǹfààní nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Alàgbà Àtàwọn Ìránṣẹ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́?

18 Gbogbo àwọn èèyàn Ọlọ́run ló ti jàǹfààní látinú Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Alàgbà Àtàwọn Ìránṣẹ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Nígbà tí àwọn alàgbà àtàwọn ìránṣẹ́ ìṣẹ́ òjíṣẹ́ bá ń fi àwọn ohun tí wọ́n ti kọ́ nílé ẹ̀kọ́ náà sílò, ńṣe ni àwọn náà fìwà jọ Jésù, wọ́n á jẹ́ orísun ìtura fáwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́. Ǹjẹ́ o máa ń mọrírì ọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́ àwọn alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, bí wọ́n ṣe máa ń fara balẹ̀ tẹ́tí sọ́rọ̀ rẹ àti ìbẹ̀wò tí wọ́n ń ṣe ṣe sọ́dọ̀ rẹ láti fún ẹ níṣìírí? (1 Tẹs. 5:11) Ìbùkún gidi làwọn ọkùnrin tó kúnjú ìwọ̀n yìí jẹ́ fáwọn ìjọ wọn!

19. Àwọn ilé ẹ̀kọ́ yòókù wo ni Ìgbìmọ̀ Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ ń bójú tó, kí sì ni àwọn ilé ẹ̀kọ́ náà wà fún?

19 Àwọn ilé ẹ̀kọ́ míì tí ètò Ọlọ́run dá sílẹ̀. Ìgbìmọ̀ Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ ti Ìgbìmọ̀ Olùdarí ló máa ń bójú tó àwọn ilé ẹ̀kọ́ míì tó ń pèsè ìdálẹ́kọ̀ọ́ fáwọn arákùnrin tó wà nípò àbójútó nínú ètò Ọlọ́run. A dá àwọn ilé ẹ̀kọ́ yìí sílẹ̀ láti ran àwọn arákùnrin tó wà nípò àbójútó lọ́wọ́, ìyẹn àwọn alàgbà ìjọ, àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò àti àwọn tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka, kí wọ́n lè túbọ̀ já fáfá nínú bíbójú tó àwọn ojúṣe wọn. Ìdálẹ́kọ̀ọ́ tá a gbé ka Bíbélì yìí ń fún àwọn arákùnrin yìí níṣìírí nípa bí wọ́n ṣe lè máa jẹ́ ẹni tẹ̀mí àti bí wọ́n ṣe lè máa fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò bí wọ́n ṣe ń bójú tó àwọn àgùntàn ṣíṣeyebíye tí Jèhófà fi sábẹ́ àbójútó wọn.—1 Pét. 5:1-3.

Kíláàsì Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ àkọ́kọ́ tí wọ́n ṣe lórílẹ̀-èdè Màláwì lọ́dún 2007

Kíláàsì Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ àkọ́kọ́ tí wọ́n ṣe lórílẹ̀-èdè Màláwì, lọ́dún 2007

20. Kí nìdí tí Jésù fi lè sọ pé gbogbo wa jẹ́ ẹni tí a “kọ́ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà,” kí sì ni ìwọ pinnu láti ṣe?

20 Ó ṣe kedere pé Mèsáyà Ọba ti rí sí i pé àwọn ọmọlẹ́yìn òun gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ dáadáa. Látọ̀dọ̀ Jèhófà ni gbogbo ìdálẹ́kọ̀ọ́ yìí ti wá, ìyẹn ni pé Jèhófà kọ́ Ọmọ rẹ̀, Ọmọ rẹ̀ sì kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀. Ìdí nìyẹn ti Jésù fi sọ pé gbogbo wa jẹ́ àwọn “tí a kọ́ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà.” (Jòh. 6:45; Aísá. 54:13) Ẹ jẹ́ ká pinnu láti máa jàǹfààní lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ látinú gbogbo ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí Ọba wa ti pèsè fún wa. Ká sì rántí pé ìdí pàtàkì tí gbogbo àwọn ìdálẹ́kọ̀ọ́ yìí wà fún ni láti mú kí àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run dára ká bàa lè ṣàṣeparí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa.

a Báwo la ṣe mọ̀ pé Baba kọ́ Ọmọ rẹ̀ bó ṣe máa kọ́ni? Rò ó wò ná: Ọ̀pọ̀ àwọn àpèjúwe tí Jésù lò nígbà tó ń kọ́ àwọn èèyàn jẹ́ ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ kan tá a ti kọ sílẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún kí wọ́n tó bí i. (Sm. 78:2; Mát. 13:34, 35) Ó ṣe kedere pé tipẹ́tipẹ́ ni Jèhófà tó jẹ́ Orísun àsọtẹ́lẹ̀ náà ti pinnu pé Ọmọ òun máa lo àwọn àpèjúwe tàbí àkàwé láti fi kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́.—2 Tím. 3:16, 17.

b Oṣù mélòó kàn lẹ́yìn ìgbà náà, Jésù “yan àwọn àádọ́rin mìíràn sọ́tọ̀, ó sì rán wọn jáde ní méjìméjì” láti lọ wàásù. Ó tún fún wọn ní ìdálẹ́kọ̀ọ́.—Lúùkù 10:1-16.

c Àwọn míì ti lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì ju ìgbà kan lọ.

d Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa ipa tí àwọn míṣọ́nnárì tó ti gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ nílé ẹ̀kọ́ Gílíádì ti kó nínú iṣẹ́ ìwàásù kárí ayé, wo orí 23 nínú ìwé Jehovah’s Witnesses—Proclaimers of God’s Kingdom.

e Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere Ìjọba Ọlọ́run tí rọ́pò àwọn ilé ẹ̀kọ́ méjì tó kẹ́yìn yẹn.

f Ní bá yìí, gbogbo àwọn alàgbà ló ń jàǹfààní látinú ní Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Alàgbà Àtàwọn Ìránṣẹ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́. Iye ọjọ́ tí wọ́n fi máa ń ṣe é yàtọ̀ síra, ọdún mélòó kan síra wọn ni ilé ẹ̀kọ́ yìí sì máa ń wáyé. Látọdún 1984, àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ti ń gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ nílé ẹ̀kọ́ yìí.

Ṣé O Gbà Lóòótọ́ Pé Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso?

  • Ìdálẹ́kọ̀ọ́ wo ni Jésù gbà lọ́dọ̀ Baba rẹ̀?

  • Ọ̀nà wo ni Ọba náà gbà kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti di ajíhìnrere?

  • Báwo ni àwọn arákùnrin tó kúnjú ìwọ̀n ṣe gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ nípa bí wọ́n á ṣe máa ṣe àwọn ojúṣe wọn?

  • Báwo lo ṣe lè fi hàn pé o mọrírì ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí Ọba náà ti pèsè?

ÀWỌN ILÉ Ẹ̀KỌ́ TÓ Ń DÁ ÀWỌN ÒJÍṢẸ́ ÌJỌBA ỌLỌ́RUN LẸ́KỌ̀Ọ́

ÌPÀDÉ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀTI IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ ÀWA KRISTẸNI

Ohun Tó Wà Fún: Láti dá àwọn akéde lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè jẹ́ oníwàásù ìhìn rere àti olùkọ́ tó pegedé.

Àkókò: Títí gbére.

Ibi Tí A Ti Ń Ṣe É: Gbọ̀ngàn Ìjọba.

Béèyàn Ṣe Lè Forúkọ Sílẹ̀: Gbogbo àwọn tó ń dara pọ̀ mọ́ ìjọ déédéé, tí wọ́n fara mọ́ àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì, tí ìgbé ayé wọn sì bá àwọn ìlànà Kristẹni mu. Sọ fún alábòójútó Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni tó o bá fẹ́ forúkọ sílẹ̀.

Àwọn Àǹfààní Rẹ̀: Ìpàdé àárín ọ̀sẹ̀ máa ń kọ́ wa bá a ṣe ń ṣe ìwádìí àti bá a ṣe ń gbé ọ̀rọ̀ kalẹ̀ lọ́nà tó mọ́gbọ́n dání. A tún ń kọ́ bá a ṣe lè ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Ọlọ́run àti bá a ṣe lè ran àwọn míì lọ́wọ́

Arnie, tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ alábòójútó arìnrìn-àjò ṣàlàyé pé: “Mo máa ń kólòlò, ó sì máa ń ṣòro fún mi láti wo ojú àwọn èèyàn nígbà tí mo bá ń bá wọn sọ̀rọ̀. Ohun tí mo kọ́ ní [ìpàdé] yìí ti mú kí n ní ìgboyà kí n má sì máa fojú kéré ara mi. Jèhófà ń ràn mí lọ́wọ́ bí mo ṣe ń gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ náà, mo sì ti wá kọ́ ọ̀nà tí mo lè gbà máa mí sínú, mí síta, kí n sì máa pọkàn pọ̀. Mo dúpẹ́ gan-an pé ó ti ṣeé ṣe fún mi láti máa yin Ọlọ́run nínú ìjọ àti nígbà tí mo bá ń wàásù.”

Ọ̀dọ́kùnrin kan tó jẹ́ akéde ń ka Bíbélì ní Ilẹ́ Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run

ILÉ Ẹ̀KỌ́ ÀWỌN ALÀGBÀ ÌJỌg

Ohun Tó Wà Fún: Láti ran àwọn alàgbà lọ́wọ́ kí ipò tẹ̀mí wọn lè lágbára sí i àti kí wọ́n lè máa bójú tó ojúṣe wọn nínú ìjọ dáadáa.

Àkókò: Ọjọ́ márùn-ún.

Ibi Tí A Ti Ń Ṣe É: Ẹ̀ka ọ́fíìsì ló máa ń pinnu rẹ̀; ó sábà máa ń jẹ́ ní Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí Gbọ̀ngàn Àpéjọ tó bá wà nítòsí.

Béèyàn Ṣe Lè Forúkọ Sílẹ̀: Ẹ̀ka ọ́fíìsì ló máa pe àwọn alàgbà.

Àwọn Àǹfààní Rẹ̀: Ohun tí àwọn arákùnrin kan tó lọ sí kíláàsì kejìléláàádọ́rùn-ún [92] nílùú Patterson, ìpínlẹ̀ New York lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ rèé:

“Mo ti jàǹfààní tó pọ̀ gan-an ní ilé ẹ̀kọ́ náà. Ó ti mú kí n máa kíyè sí bí mo ṣe ń ṣe sí kí n sì máa ronú nípa bí mo ṣe lè máa bójú tó àwọn àgùntàn Jèhófà.”

“Mi ò jẹ́ gbàgbé ìdálẹ́kọ̀ọ́ yìí ní gbogbo ọjọ́ ayé mi.”

ILÉ Ẹ̀KỌ́ ÀWỌN AṢÁÁJÚ-Ọ̀NÀ

Ohun Tó Wà Fún: Láti ran àwọn aṣáájú-ọ̀nà lọ́wọ́ kí wọ́n lè ‘ṣàṣeparí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn ní kíkún.’—2 Tím. 4:5.

Àkókò: Ọjọ́ mẹ́fà.

Ibi Tí A Ti Ń Ṣe É: Ẹ̀ka ọ́fíìsì ló máa ń pinnu; ó sábà máa ń jẹ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà nítòsí.

Béèyàn Ṣe Lè Forúkọ Sílẹ̀: Àwọn tó ti wà lẹ́nu iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà fún ọdún kan ó kéré tan ní alábòójútó àyíká máa ń forúkọ wọn sílẹ̀, òun ló sì máa ń sọ ìgbà tí wọ́n máa lọ sí ilé ẹ̀kọ́ náà. A lè pe àwọn tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà tí wọn kò tíì lọ sí ilé ẹ̀kọ́ yìí ní ọdún márùn-ún sẹ́yìn láti tún wá sílé ẹ̀kọ́ náà.

Àwọn Àǹfààní Rẹ̀: Lily sọ pé: “Ilé ẹ̀kọ́ yẹn ti ràn mí lọ́wọ́ láti kojú àwọn ìṣòro tí mò ń bá pàdé ní pápá àti nínú ìgbésí ayé mi. Bí mo ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́, bí mo ṣe ń kọ́ni àti bí mo ṣe ń lo Bíbélì ti sunwọ̀n sí i lọ́pọ̀lọpọ̀. Ó ti mú kí n túbọ̀ wà ní sẹpẹ́ láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, kí n kọ́wọ́ ti àwọn alàgbà, kí n sì máa fi kún ìtẹ̀síwájú ìjọ.”

Brenda, tó ti lọ sí ilé ẹ̀kọ́ náà nígbà méjì sọ pé: “Ó mú kí n pa ọkàn pọ̀ sórí àjọṣe mi pẹ̀lú Ọlọ́run, ó fún ẹ̀rí ọkàn mi lókun, ó sì mú kí n gbájú mọ́ ríran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Ó ṣe kedere pé Jèhófà jẹ́ ọ̀làwọ́!”

ILÉ Ẹ̀KỌ́ ÀWỌN TÓ ṢẸ̀ṢẸ̀ WỌ BẸ́TẸ́LÌ

Ohun Tó Wà Fún: Ilé ẹ̀kọ́ yìí wà fún ríran àwọn tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ dé Bẹ́tẹ́lì lọ́wọ́ kí wọ́n lè kẹ́sẹ járí lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wọn ní Bẹ́tẹ́lì.

Àkókò: Ọjọ́ mẹ́rin, wọ́n á sì máa lo wákàtí mẹ́rin lójúmọ́.

Ibi Tí A Ti Ń Ṣe É: Bẹ́tẹ́lì.

Béèyàn Ṣe Lè Forúkọ Sílẹ̀: O gbọ́dọ̀ jẹ́ ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì tàbí olùyọ̀ǹda ara ẹni tó jẹ́ alákòókò kúkúrú àmọ́ tó ṣeé ṣe kó lo ọdún kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ.

Àwọn Àǹfààní Rẹ̀: Ní ọdún kan, láàárín 1980 àti 1989 ni Demetrius lọ sí ilé ẹ̀kọ́ yìí. Ó sọ pé: “Ohun tí mo kọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ náà mú kí ọ̀nà tí mo gbà ń kẹ́kọ̀ọ́ sunwọ̀n sí i, ó sì jẹ́ kí n mọ bí mo ṣe lè sìn fún ìgbà pípẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì. Ọ̀nà tí àwọn olùkọ́ wa ń gbà kọ́ni, àwọn ohun tí à ń kọ́ àti àwọn ìmọ̀ràn tó wúlò tí wọ́n ń fún wa mú kó dá mi lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ mi àti pé ó wù ú láti ràn mí lọ́wọ́ kí n lè ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn mi ní Bẹ́tẹ́lì.”

ILÉ Ẹ̀KỌ́ ÀWỌN AJÍHÌNRERE ÌJỌBA ỌLỌ́RUNh

Ohun Tó Wà Fún: Láti fún àwọn tó wà nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún (àwọn tọkọtaya àti àwọn tí kò ní aya àtàwọn tí kò ní ọkọ) ní ìdálẹ́kọ̀ọ́ àkànṣe kí Jèhófà àti ètò rẹ̀ lè túbọ̀ lò wọ́n. Ọ̀pọ̀ lára àwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ yege la máa rán lọ sí àwọn ibi tá a ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i lórílẹ̀-èdè wọn. A lè rán àwọn tí kò tíì tó àádọ́ta [50] ọdún lọ sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe fún ìgbà díẹ̀ láwọn àdádó, kí wọ́n lè bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù níbẹ̀, kí wọ́n sì lè mú iṣẹ́ ìwàásù gbòòrò níbẹ̀.

Àkókò: Oṣù méjì.

Ibi Tí A Ti Ń Ṣe É: Ẹ̀ka ọ́fíìsì ló máa ń pinnu; ó sábà máa ń jẹ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí Gbọ̀ngàn Àpéjọ.

Arábìnrin kan ń wàásù

Kíláàsì kan ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì ní Patterson, New York

Béèyàn Ṣe Lè Forúkọ Sílẹ̀: Àwọn tí ọjọ́ orí wọn wà ní àárín ọdún mẹ́tàlélógún [23] àti márùnlélọ́gọ́ta [65] tí wọ́n wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún tí wọ́n sì ní ìlera tó dáa, tí ipò wọn sì yọ̀ǹda fún wọn láti lọ sìn ní ibikíbi tá a ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i, tí wọ́n sì ní irú ẹ̀mí tí wòlíì Aísáyà ní, nígbà tó sọ pé: “Èmi nìyí! Rán mi.” (Aísá. 6:8) Gbogbo ẹni tó bá máa wá sí ilé ẹ̀kọ́ yìí, yálà àwọn tí kò lọ́kọ, àwọn tí kò ní aya tàbí tọkọtaya, ti gbọ́dọ̀ máa ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún láìdáwọ́dúró fún ọdún méjì, ó kéré tán. Ó kéré tán, tọkọtaya gbọ́dọ̀ jẹ́ àwọn tó ti tó ọdún méjì tí wọ́n ti ṣègbéyàwó. Àwọn arákùnrin ti gbọ́dọ̀ máa sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ láìdáwọ́dúró fún ọdún méjì, ó kéré tán. Tí ilé ẹ̀kọ́ yìí bá wà lórílẹ̀-èdè rẹ, ìpàdé kan máa wáyé nígbà àpéjọ àgbègbè láti pèsè ìsọfúnni fún àwọn tó bá fẹ́ forúkọ sílẹ̀.

Àwọn Àǹfààní Rẹ̀: Àwọn tó ti lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Bíbélì fún Àwọn Àpọ́n àti Ilé Ẹ̀kọ́ Bíbélì fún Àwọn Tọkọtaya sọ àwọn ọ̀rọ̀ amóríwú nípa àwọn ilé ẹ̀kọ́ náà. Lọ́dún 2013, Ìgbìmọ̀ Olùdarí fọwọ́ sí i pé ká pa ilé ẹ̀kọ́ méjèèjì yìí pọ̀ di ọ̀kan ṣoṣo tí à ń pè ní Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere Ìjọba Ọlọ́run. Ní báyìí, àwọn aṣáájú-ọ̀nà olóòótọ́ púpọ̀ sí i títí kan àwọn arábìnrin tí kò lọ́kọ ni yóò máa jàǹfààní látinú ìdálẹ́kọ̀ọ́ yìí.

ILÉ Ẹ̀KỌ́ GÍLÍÁDÌ

Ohun Tó Wà Fún: Wọ́n lè yan àwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ yege níbẹ̀ láti máa sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó arìnrìn-àjò tàbí bí àwọn míṣọ́nnárì tó wà ní pápá tàbí kí wọ́n sìn ní Bẹ́tẹ́lì. Nípa fífi ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n ti gbà sílò lọ́nà tó dáa, àwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ yege nílé ẹ̀kọ́ náà máa ń mú kí iṣẹ́ ìwàásù gbòòrò sí i, kí àbójútó gidi sì lè wà ní àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa.

Àkókò: Oṣù márùn-ún.

Ibi Tí A Ti Ń Ṣe É: Ibùdó Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ti Watchtower tó wà ní ìlú Patterson, ní ìpínlẹ̀ New York, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.

Àwọn ọmọ Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì ń fetísílẹ̀ sí olùkó wọn

Àwọn arákùnrin àti arábìnrin ń jàǹfààní látinú ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí ètò Ọlọ́run ń pèsè

Béèyàn Ṣe Lè Forúkọ Sílẹ̀: Àwọn tọkọtaya, àwọn tí kò ní aya àti àwọn tí kò ní ọkọ tí wọ́n ti wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún lọ́nà àkànṣe. Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka lè ní kí àwọn míṣọ́nnárì tó wà ní pápá, àwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe, àwọn tó wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì tàbí àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò àtàwọn ìyàwó wọn tí wọn kò tíì lọ sí ilé ẹ̀kọ́ náà forúkọ sílẹ̀. Àwọn tó bá forúkọ sílẹ̀ fún ilé ẹ̀kọ́ náà gbọ́dọ̀ lè sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì, kí wọ́n sì lè kọ ọ́.

Àwọn Àǹfààní Rẹ̀: Lade àti Monique wá láti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, wọ́n sì ti lo ọdún tó pọ̀ díẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wọn nílẹ̀ òkèèrè. Ohun tí wọn sọ rèé:

“Lade sọ pé: “Pẹ̀lú ìdálẹ́kọ̀ọ́ tá a gbà ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì yìí, kò sí ibi tí a kò lè lọ láyé yìí, a ti múra tán láti lọ ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ará wa ọ̀wọ́n.”

Monique náà sọ pé: “Bí mo ṣe ń fi àwọn nǹkan tí mo ti kọ́ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílò, bẹ́ẹ̀ ni mò ń láyọ̀ púpọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ tí wọ́n yàn fún mi. Ayọ̀ tí mo ní yìí ń jẹ́ kó túbọ̀ dá mi lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ mi.”

ILÉ Ẹ̀KỌ́ ÀWỌN ALÀGBÀ ÀTÀWỌN ÌRÁNṢẸ́ IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́

Ohun Tó Wà Fún: Láti dá àwọn alàgbà àtàwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ lẹ́kọ̀ọ́ nípa bí wọ́n ṣe lè máa bójú tó ìjọ àtàwọn ojúṣe míì tí wọ́n ní nínú ètò Ọlọ́run. (Ìṣe 20:28) Ìdálẹ́kọ̀ọ́ náà máa ń dá lórí àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ìjọ àti àwọn ohun tó ń fẹ́ àbójútó ní kíákíá. Ọdún mélòó kan síra wọn ni wọ́n máa ń ṣe ilé ẹ̀kọ́ yìí, Ìgbìmọ̀ Olùdarí ló sì máa ń pinnu ìgbà tí wọ́n máa ṣe é.

Àkókò: Láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, ọjọ́ kan àtààbọ̀ làwọn alàgbà fi máa ń ṣe ilé ẹ̀kọ́ yìí, àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ sì máa ń ṣe tiwọn fún ọjọ́ kan.

Ibi Tí A Ti Ń Ṣe É: Ó sábà máa ń jẹ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí Gbọ̀ngàn Àpéjọ tó bá wà nítòsí.

Béèyàn Ṣe Lè Forúkọ Sílẹ̀: Alábòójútó àyíká máa kàn sí àwọn alàgbà àtàwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó bá kúnjú ìwọ̀n. Ẹ̀ka ọ́fíìsì ló máa ń pe àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò.

Àwọn Àǹfààní Rẹ̀: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ilé ẹ̀kọ́ náà kò gba àkókò tó pọ̀, ọ̀pọ̀ nǹkan tí àwọn alàgbà ń kọ́ níbẹ̀ máa ń fún wọn lágbára ó sì máa ń mú kí wọ́n máa láyọ̀ kí wọ́n sì máa bá iṣẹ́ ìsìn Jèhófà nìṣó bí ọkùnrin. Àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di alàgbà àtàwọn tó ti ń sìn látọjọ́ pípẹ́ ti kọ́ bí wọ́n ṣe lè máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo lọ́nà tó múná dóko, kí wọ́n sì wà ní ìṣọ̀kan rẹ́gírẹ́gí ‘nínú ìlà ìrònú kan náà.”—Quinn.

“Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yìí kò pọ̀n sápá kan. Ó jẹ́ ká ní òye tó tọ́ nípa àwọn ohun tó jẹ mọ́ ìgbàgbọ́ wa, ó kìlọ̀ fún wa nípa àwọn ewu tó yẹ ká sá fún, ó sì fún wa ní àwọn àbá tó wúlò nípa bó ṣe yẹ ká máa bójú tó agbo.”—Michael.

ILÉ Ẹ̀KỌ́ ÀWỌN ALÁBÒÓJÚTÓ ARÌNRÌN-ÀJÒ ÀTÀWỌN ÌYÀWÓ WỌNi

Ohun Tó Wà Fún: Láti mú kí àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò máa ṣe ìbẹ̀wò sí ìjọ lọ́nà tó gbẹ́ṣẹ́, kí wọ́n máa “ṣiṣẹ́ kára nínú ọ̀rọ̀ sísọ àti kíkọ́ni,” kí wọ́n sì máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo tó wà lábẹ́ àbójútó wọn.—1 Tím. 5:17; 1 Pét. 5:2, 3.

Àkókò: Oṣù méjì.

Ibi Tí A Ti Ń Ṣe É: Ẹ̀ka ọ́fíìsì ló máa ń pinnu rẹ̀.

Béèyàn Ṣe Lè Forúkọ Sílẹ̀: Ẹ̀ka ọ́fíìsì ló máa ń pe àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò pẹ̀lú ìyàwó wọn.

Àwọn Àǹfààní Rẹ̀: “Ó ti mú ká túbọ̀ mọyì bí Jésù ṣe ń darí ètò Ọlọ́run. A rí i pé ó ṣe pàtàkì pé ká máa fún àwọn ará tí à ń bẹ̀ wò ní ìṣírí kí a sì mú kí ìjọ kọ̀ọ̀kan túbọ̀ wà ní ìṣọ̀kan. Ìdálẹ́kọ̀ọ́ yìí gbìn ín sí wa lọ́kàn pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé alábòójútó arìnrìn-àjò máa ń fún àwọn ará nímọ̀ràn tó sì máa ń sọ àwọn nǹkan tó nílò àtúnṣe nígbà míì, ìdí pàtàkì tó fi ń ṣe ìbẹ̀wò sáwọn ìjọ ni pé kó lè mú kó dá àwọn ará lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wọn.”—Joel àti Connie, kíláàsì àkọ́kọ́ lọ́dún 1999.

ILÉ Ẹ̀KỌ́ ÀWỌN ÌGBÌMỌ̀ Ẹ̀KA ÀTÀWỌN ÌYÀWÓ WỌN

Ohun Tó Wà Fún: Láti ran àwọn tó wà lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka lọ́wọ́ kí wọ́n lè túbọ̀ máa ṣe àbójútó àwọn Bẹ́tẹ́lì, kí wọ́n máa fún àwọn ọ̀ràn iṣẹ́ ìsìn tó ní í ṣe pẹ̀lú àwọn ìjọ láfiyèsí, kí wọ́n sì máa bójú tó àwọn àyíká tó wà láwọn ìpínlẹ̀ ìwàásù wọn kọ̀ọ̀kan.—Lúùkù 12:48b.

Àkókò: Oṣù méjì.

Ibi Tí A Ti Ń Ṣe É: Ibùdó Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ti Watchtower tó wà ní ìlú Patterson, ní ìpínlẹ̀ New York, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.

Béèyàn Ṣe Lè Forúkọ Sílẹ̀: Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn ti Ìgbìmọ̀ Olùdarí ló máa ń pe àwọn tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka tàbí orílẹ̀-èdè àtàwọn ìyàwó wọn wá sí ilé ẹ̀kọ́ yìí.

Àwọn Àǹfààní Rẹ̀: Lowell àti Cara, tí wọ́n lọ sí kíláàsì kẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] ti ń sìn báyìí ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Lowell sọ pé: “Mo ti kẹ́kọ̀ọ́ pé kò sí bí ọwọ́ mi ṣe lè dí tó tàbí iṣẹ́ yòówù kí wọ́n gbé fún mi, ohun pàtàkì tó lè jẹ́ kí n mú inú Jèhófà dùn ni pé kí n máa ṣe nǹkan lọ́nà tó wù ú.”

Cara náà sọ ohun tóun náà rí kọ́ nílè ẹ̀kọ́ yìí. Ó sọ pé: “Ọ̀rọ̀ kan tí mo sábà máa ń ronú lé lórí ni pé, tí mi ò bá ti lè ṣàlàyé kókó ọ̀rọ̀ kan lọ́nà tó rọrùn, àfi kí n fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ dáadáa kí n tó fi kọ́ ẹlòmíì.”

g Kì í ṣe gbogbo orílẹ̀-èdè ni ilé ẹ̀kọ́ yìí wà ní báyìí.

h Kì í ṣe gbogbo orílẹ̀-èdè ni ilé ẹ̀kọ́ yìí wà ní báyìí.

i Kì í ṣe gbogbo orílẹ̀-èdè ni ilé ẹ̀kọ́ yìí wà ní báyìí.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́