ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 10/11 ojú ìwé 3-6
  • Ǹjẹ́ Ò Ń Kọ́ Gbogbo Ohun Tó O Lè Kọ́ Lọ́dọ̀ Jèhófà?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ Ò Ń Kọ́ Gbogbo Ohun Tó O Lè Kọ́ Lọ́dọ̀ Jèhófà?
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Ilé Ẹ̀kọ́ Ètò Ọlọ́run—Ẹ̀rí Pé Jèhófà Nífẹ̀ẹ́ Wa
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Bí A Ṣe Ń Dá Àwọn Òjíṣẹ́ Ìjọba Náà Lẹ́kọ̀ọ́
    Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!
  • Àwọn Ìdálẹ́kọ̀ọ́ Wo Ló Ń Mú Káwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Já Fáfá Lẹ́nu Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Wa?
    Àwọn Ìbéèrè Táwọn Èèyàn Sábà Máa Ń Béèrè Nípa Ẹlẹ́rìí Jèhófà
  • Àwọn Ọ̀nà Tó O Lè Gbà Mú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Gbòòrò Sí I
    A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
km 10/11 ojú ìwé 3-6

Ǹjẹ́ Ò Ń Kọ́ Gbogbo Ohun Tó O Lè Kọ́ Lọ́dọ̀ Jèhófà?

1. Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo ẹ̀kọ́?

1 Jèhófà ‘Olùkọ́ni wa Atóbilọ́lá’ fẹ́ ká gba ẹ̀kọ́. (Aísá. 30:20) Látìgbà tó ti dá àkọ́bí ọmọ rẹ̀ ló ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́. (Jòh. 8:28) Lẹ́yìn tí Ádámù ṣọ̀tẹ̀, Jèhófà kò ṣíwọ́ kíkọ́ni lẹ́kọ̀ọ́, àmọ́ tìfẹ́tìfẹ́ ló fi ń fún àwa èèyàn aláìpé ní ìtọ́ni.—Aísá. 48:17, 18; 2 Tím. 3:14, 15.

2. Iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ wo ló ń lọ lọ́wọ́ báyìí?

2 Lóde òní, Jèhófà ń darí ètò ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ kan tó pabanbarì jù lọ, èyí tí irú rẹ̀ kò tíì wáyé rí. Gẹ́gẹ́ bí Aísáyà ṣe sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀, ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn kárí ayé ló ń rọ́ lọ sí “òkè ńlá ilé Jèhófà.” (Aísá. 2:2) Kí nìdí tí wọ́n fi ń rọ́ lọ síbẹ̀? Kí wọ́n lè gba ìtọ́ni ní àwọn ọ̀nà Ọlọ́run, kí Jèhófà lè kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́! (Aísá. 2:3) Láàárín ọdún iṣẹ́ ìsìn 2010, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lo ohun tó lé ní bílíọ̀nù kan àbọ̀ wákàtí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù àti kíkọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bákan náà, àwọn ìjọ tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún ó lé márùn-ún [105,000] kárí ayé ló ń gba ìtọ́ni nípa tẹ̀mí lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, ẹrú olóòótọ́ àti olóye sì tún ń ṣe àwọn ìtẹ̀jáde tó ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ ní èdè tó lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500].

3. Àǹfààní wo ni ìwọ fúnra rẹ ti jẹ látinú ẹ̀kọ́ tí Jèhófà ń kọ́ wa?

3 Jàǹfààní Lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́: A ti jàǹfààní tó pọ̀ gan-an látinú ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí Jèhófà ń fún wa. A ti kẹ́kọ̀ọ́ pé Ọlọ́run ní orúkọ àti pé ó bìkítà fún wa. (Sm. 83:18; 1 Pét. 5:6, 7) A ti rí ìdáhùn sí àwọn kan lára àwọn ìbéèrè tó ṣe pàtàkì nípa ìgbésí ayé. Àwọn ìbéèrè bíi: Kí nìdí tí àwa èèyàn fi ń jìyà tá a sì ń kú? Báwo ni mo ṣe lè rí ojúlówó ayọ̀? Kí nìdí tá a fi wà láyé? Jèhófà tún ti fún wa ní àwọn ìlànà ìwà rere, èyí tó jẹ́ ká lè ‘mú kí ọ̀nà wa yọrí sí rere.’—Jóṣ. 1:8.

4. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lè jàǹfààní rẹ̀, kí sì nìdí tó fi yẹ ká kọ́ gbogbo ohun tá a bá lè kọ́ lọ́dọ̀ Jèhófà?

4 Láfikún sí i, Jèhófà ti mú kí àwọn ìdálẹ́kọ̀ọ́ àkànṣe kan wà, èyí tó máa ran àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ kí wọ́n lè mú iṣẹ́ ìsìn wọn gbòòrò sí i. Ní ojú ìwé 4 sí 6, a máa rí àwọn àǹfààní tó ṣí sílẹ̀ fún àwọn kan. Kódà bí ipò wa kò bá gbà wá láyè láti gba àwọn ìdálẹ́kọ̀ọ́ tá a tò sí àwọn ojú ìwé yẹn, ǹjẹ́ à ń gba àwọn ìdálẹ́kọ̀ọ́ mìíràn tí ipò wa gbà wá láyè lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́? Ǹjẹ́ à ń fún àwọn ọ̀dọ́ ní ìṣírí láti ní àfojúsùn tẹ̀mí, kí wọ́n sì máa lépa ẹ̀kọ́ tó ga jù lọ, ìyẹn ẹ̀kọ́ tí Ọlọ́run ń kọ́ wa, dípò tí wọ́n á fi máa lépa ẹ̀kọ́ gíga nínú ayé, bí àwọn olùkọ́ wọn àtàwọn ẹlòmíì ṣe máa ń rọ̀ wọ́n? Tá a bá ń kọ́ gbogbo ohun tá a lè kọ́ lọ́dọ̀ Jèhófà, a máa láyọ̀ nísinsìnyí, a sì tún máa gbádùn ìyè ayérayé lọ́jọ́ iwájú.—Sm. 119:105; Jòh. 17:3.

Díẹ̀ Lára Àwọn Ìdálẹ́kọ̀ọ́ Tá A Lè Rí Gbà Nípasẹ̀ Ètò Jèhófà

Ilé Ẹ̀kọ́ Mọ̀ọ́kọ-Mọ̀ọ́kà

  • Ohun Tó Wà Fún: Láti kọ́ àwọn èèyàn kí wọ́n lè mọ ìwé kọ, kí wọ́n sì mọ̀ ọ́n kà, kí wọ́n bàa lè máa dá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fúnra wọn, kí wọ́n sì lè kọ́ àwọn ẹlòmíì lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́.

  • Àkókò: Èyí sinmi lórí ohun tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ nílò.

  • Ibi Tí A Ti Ń Ṣe É: Gbọ̀ngàn Ìjọba.

  • Àwọn Tó Lè Lọ: Gbogbo akéde àtàwọn olùfìfẹ́hàn.

  • Béèyàn Ṣe Lè Forúkọ Sílẹ̀: Àwọn alàgbà ìjọ máa ń ṣètò ilé ẹ̀kọ́ mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà níbàámu pẹ̀lú ohun tí wọ́n nílò nínú ìjọ wọn, wọ́n sì máa ń gba gbogbo àwọn tó bá lè jàǹfààní nínú rẹ̀ níyànjú pé kí wọ́n wá.

Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run

  • Ohun Tó Wà Fún: Láti dá àwọn akéde lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè jẹ́ oníwàásù ìhìn rere àti olùkọ́ tó dáńgájíá.

  • Àkókò: Títí gbére.

  • Ibi Tí A Ti Ń Ṣe É: Gbọ̀ngàn Ìjọba.

  • Àwọn Tó Lè Forúkọ Sílẹ̀: Gbogbo akéde. Àwọn tó tún lè forúkọ sílẹ̀ ni àwọn tó ń dara pọ̀ mọ́ ìjọ déédéé, tí wọ́n fara mọ́ àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì, tí ìgbé ayé wọn sì bá àwọn ìlànà Kristẹni mu.

  • Béèyàn Ṣe Lè Forúkọ Sílẹ̀: Sọ fún alábòójútó Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run.

Ilé Ẹ̀kọ́ Èdè Ilẹ̀ Òkèèrè

  • Ohun Tó Wà Fún: Láti kọ́ àwọn akéde bí wọ́n ṣe lè fi èdè tó yàtọ̀ sí ti wọn wàásù.

  • Àkókò: Oṣù mẹ́rin tàbí oṣù márùn-ún. Òwúrọ̀ Saturday ni wọ́n sábà máa ń ṣe é, wákàtí kan tàbí méjì ni wọ́n sì máa ń lò ní kíláàsì.

  • Ibi Tí A Ti Ń Ṣe É: Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà nítòsí ló sábà máa ń jẹ́.

  • Àwọn Tó Lè Forúkọ Sílẹ̀: Àwọn akéde tó ń ṣe dáadáa nínú ìjọ, tí wọ́n sì fẹ́ máa fi èdè ilẹ̀ òkèèrè wàásù.

  • Béèyàn Ṣe Lè Forúkọ Sílẹ̀: Ẹ̀ka ọ́fíìsì ló máa ń ṣètò ilé ẹ̀kọ́ yìí nígbà tí àwọn èèyàn bá nílò rẹ̀.

Ètò Kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba

  • Ohun Tó Wà Fún: Láti kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun àti láti ṣàtúnṣe àwọn tó ti gbó. Èyí kì í ṣe ilé ẹ̀kọ́ o, àmọ́ a máa ń kọ́ àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn lẹ́kọ̀ọ́ nípa iṣẹ́ ìkọ́lé, kí wọ́n bàa lè ṣèrànwọ́ nínú iṣẹ́ ilé kíkọ́.

  • Àkókò: Bí ipò ẹni tó yọ̀ǹda ara rẹ̀ bá ṣe gbà á láyè sí.

  • Ibi Tí A Ti Ń Ṣe É: Àdúgbò èyíkéyìí tí wọ́n bá yan Ẹgbẹ́ Àwọn Tó Ń Kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba sí. A lè pe àwọn kan lára àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn pé kí wọ́n wá ṣèrànwọ́ nígbà tí àjálù bá ṣẹlẹ̀, ibẹ̀ sì lè jìnnà.

  • Àwọn Ohun Téèyàn Gbọ́dọ̀ Dójú Ìlà Rẹ̀: Arákùnrin tàbí arábìnrin náà gbọ́dọ̀ ti ṣe ìrìbọmi, ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà ìjọ rẹ̀ sì gbọ́dọ̀ fọwọ́ sí i. Wọ́n lè jẹ́ akọ́ṣẹ́mọṣẹ́, wọ́n sì lè má mọ̀ nípa iṣẹ́ ilé kíkọ́.

  • Béèyàn Ṣe Lè Forúkọ Sílẹ̀: Gba fọ́ọ̀mù Application for Kingdom Hall Construction Volunteer Program (A-25) lọ́wọ́ àwọn alàgbà ìjọ rẹ, kó o sì kọ ọ̀rọ̀ tó yẹ sí i.

Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Aṣáájú-Ọ̀nà

  • Ohun Tó Wà Fún: Láti ran àwọn aṣáájú-ọ̀nà lọ́wọ́ kí wọ́n lè ‘ṣàṣeparí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn ní kíkún.’—2 Tím. 4:5.

  • Àkókò: Ọ̀sẹ̀ Méjì.

  • Ibi Tí A Ti Ń Ṣe É: Ẹ̀ka ọ́fíìsì ló máa ń pinnu; ó sábà máa ń jẹ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà nítòsí.

  • Ohun Téèyàn Gbọ́dọ̀ Dójú Ìlà Rẹ̀: Ó ti gbọ́dọ̀ wà lẹ́nu iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà fún ọdún kan, ó kéré tán.

  • Béèyàn Ṣe Lè Forúkọ Sílẹ̀: Ẹ̀ka ọ́fíìsì máa pe àwọn aṣáájú-ọ̀nà tó bá tóótun, nípasẹ̀ alábòójútó àyíká wọn.

Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Tó Ṣẹ̀ṣẹ̀ Wọ Bẹ́tẹ́lì

  • Ohun Tó Wà Fún: Ilé ẹ̀kọ́ yìí wà fún ríran àwọn tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ dé Bẹ́tẹ́lì lọ́wọ́ kí wọ́n lè kẹ́sẹ járí lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wọn ní Bẹ́tẹ́lì.

  • Àkókò: Wákàtí kan lẹ́ẹ̀kan lọ́sẹ̀ fún ọ̀sẹ̀ mẹ́rìndínlógún.

  • Ibi Tí A Ti Ń Ṣe É: Bẹ́tẹ́lì.

  • Àwọn Ohun Téèyàn Gbọ́dọ̀ Dójú Ìlà Rẹ̀: Ó gbọ́dọ̀ jẹ́ ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì tàbí olùyọ̀ǹda ara ẹni tó jẹ́ alákòókò kúkúrú àmọ́ tó ṣeé ṣe kó lo ọdún kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ.

  • Béèyàn Ṣe Lè Forúkọ Sílẹ̀: Wọ́n máa pe àwọn tó jẹ́ ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì tó bá kúnjú ìwọ̀n sílé ẹ̀kọ́ yìí.

Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Alàgbà Àtàwọn Ìránṣẹ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́

  • Ohun Tó Wà Fún: Láti dá àwọn alàgbà àtàwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ lẹ́kọ̀ọ́ nípa bí wọ́n ṣe lè máa bójú tó ìjọ àtàwọn ojúṣe míì tí wọ́n ní nínú ètò Ọlọ́run. (Ìṣe 20:28) Ọdún mélòó kan síra wọn ni wọ́n máa ń ṣe ilé ẹ̀kọ́ yìí, Ìgbìmọ̀ Olùdarí ló sì máa ń pinnu ìgbà tí wọ́n máa ṣe é.

  • Àkókò: Láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, ọjọ́ kan àtààbọ̀ làwọn alàgbà fi máa ń ṣe ilé ẹ̀kọ́ yìí, àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ sì máa ń ṣe tiwọn fún ọjọ́ kan.

  • Ibi Tí A Ti Ń Ṣe É: Ó sábà máa ń jẹ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí Gbọ̀ngàn Àpéjọ tó bá wà nítòsí.

  • Ohun Téèyàn Gbọ́dọ̀ Dójú Ìlà Rẹ̀: Ó gbọ́dọ̀ jẹ́ alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́.

  • Béèyàn Ṣe Lè Forúkọ Sílẹ̀: Alábòójútó àyíká máa kàn sí àwọn alàgbà àtàwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó bá kúnjú ìwọ̀n.

Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Alàgbà Ìjọa

  • Ohun Tó Wà Fún: Láti ran àwọn alàgbà lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa bójú tó ojúṣé wọn nínú ìjọ dáadáa.

  • Àkókò: Ọjọ́ márùn-ún.

  • Ibi Tí A Ti Ń Ṣe É: Ẹ̀ka ọ́fíìsì ló máa ń pinnu; ó sábà máa ń jẹ́ ní Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí Gbọ̀ngàn Àpéjọ tó bá wà nítòsí.

  • Àwọn Ohun Téèyàn Gbọ́dọ̀ Dójú Ìlà Rẹ̀: Ó gbọ́dọ̀ jẹ́ alàgbà.

  • Béèyàn Ṣe Lè Forúkọ Sílẹ̀: Ẹ̀ka ọ́fíìsì máa pe àwọn alàgbà tó bá kúnjú ìwọ̀n.

Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Alábòójútó Arìnrìn-Àjò Àtàwọn Ìyàwó Wọnb

  • Ohun Tó Wà Fún: Láti mú kí àwọn alábòójútó àyíká àtàwọn alábòójútó àgbègbè máa ṣe ìbẹ̀wò sí ìjọ lọ́nà tó gbẹ́ṣẹ́, kí wọ́n máa “ṣiṣẹ́ kára nínú ọ̀rọ̀ sísọ àti kíkọ́ni,” kí wọ́n sì máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo tó wà lábẹ́ àbójútó wọn.—1 Tím. 5:17; 1 Pét. 5:2, 3.

  • Àkókò: Oṣù méjì.

  • Ibi Tí A Ti Ń Ṣe É: Ẹ̀ka ọ́fíìsì ló máa ń pinnu rẹ̀.

  • Àwọn Ohun Téèyàn Gbọ́dọ̀ Dójú Ìlà Rẹ̀: Ó gbọ́dọ̀ jẹ́ alábòójútó àyíká tàbí alábòójútó àgbègbè.

  • Béèyàn Ṣe Lè Forúkọ Sílẹ̀: Ẹ̀ka ọ́fíìsì ló máa ń pe àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò tó bá kúnjú ìwọ̀n àtàwọn ìyàwó wọn.

Ilé Ẹ̀kọ́ Bíbélì fún Àwọn Àpọ́nc

  • Ohun Tó Wà Fún: Láti múra àwọn alàgbà àtàwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí kò tíì gbéyàwó sílẹ̀ fún àfikún iṣẹ́ ìsìn. Èyí tó pọ̀ jù lára àwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ yege la máa ń rán lọ sí àwọn ibi tá a ti nílò àwọn oníwáàsù púpọ̀ sí i lórílẹ̀-èdè wọn. Àwọn díẹ̀ lè láǹfààní láti lọ sìn lórílẹ̀-èdè mìíràn bí wọ́n bá sọ fún ẹ̀ka ọ́fíìsì pé àwọn lè ṣe bẹ́ẹ̀.

  • Àkókò: Oṣù méjì.

  • Ibi Tí A Ti Ń Ṣe É: Ẹ̀ka ọ́fíìsì ló máa ń pinnu; àmọ́ ó sábà máa ń jẹ́ ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ, Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí ní ẹ̀ka ọ́fíìsì.

  • Àwọn Ohun Téèyàn Gbọ́dọ̀ Dójú Ìlà Rẹ̀: Arákùnrin tí kò níyàwó tó wà láàárín ẹni ọdún mẹ́tàlélógún [23] sí méjìlélọ́gọ́ta [62], tó ní ìlera tó dáa, tó fẹ́ ṣiṣẹ́ sin àwọn ará, tó sì fẹ́ láti kópa nínú mímú kí ire Ìjọba Ọlọ́run tẹ̀ síwájú níbikíbi tá a bá ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i. (Máàkù 10:29, 30) Wọ́n ti gbọ́dọ̀ máa sìn gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tàbí alàgbà fún ọdún méjì, ó kéré tán.

  • Béèyàn Ṣe Lè Forúkọ Sílẹ̀: Bí ilé ẹ̀kọ́ yìí bá wà ní orílẹ̀-èdè tó o wà, wọ́n máa ń ṣe ìpàdé pẹ̀lú àwọn tó fẹ́ forúkọ sílẹ̀ nígbà àpéjọ àyíká. Wọ́n máa ń fúnni ní ìsọfúnni síwájú sí i ní ìpàdé yìí.

Ilé Ẹ̀kọ́ Bíbélì fún Àwọn Tọkọtayad

  • Ohun Tó Wà Fún: Láti fún àwọn tọkọtaya ní ìdálẹ́kọ̀ọ́ àkànṣe, kí wọ́n lè túbọ̀ wúlò fún Jèhófà àti ètò rẹ̀. Èyí tó pọ̀ jù lára àwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ yege la máa ń rán lọ sí àwọn ibi tá a ti nílò àwọn oníwáàsù púpọ̀ sí i lórílẹ̀-èdè wọn. Àwọn díẹ̀ lè láǹfààní láti lọ sìn lórílẹ̀-èdè mìíràn bí wọ́n bá sọ fún ẹ̀ka ọ́fíìsì pé àwọn lè ṣe bẹ́ẹ̀.

  • Àkókò: Oṣù méjì.

  • Ibi Tí A Ti Ń Ṣe É: Ibùdó Ìdánílẹ́kọ̀ọ́ ti Watchtower tó wà ní ìlú Patterson, ìpínlẹ̀ New York, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ni wọ́n ti ṣe mélòó kan lára ilé ẹ̀kọ́ yìí tí wọ́n kọ́kọ́ ṣe. Lẹ́yìn náà, wọ́n á máa ṣe ilé ẹ̀kọ́ yìí ní àwọn ibi tí ẹ̀ka ọ́fíìsì bá ti sọ pé kí wọ́n ṣe é, ó lè jẹ́ ní àwọn Gbọ̀ngàn Àpéjọ tàbí Gbọ̀ngàn Ìjọba.

  • Àwọn Ohun Téèyàn Gbọ́dọ̀ Dójú Ìlà Rẹ̀: Àwọn tọkọtaya tọ́jọ́ orí wọn wà láàárín ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] sí àádọ́ta [50] ọdún, tí wọ́n ní ìlera tó dáa, tí ipò wọn sì lè gbà wọ́n láyè láti lọ sìn ní ibikíbi tá a ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i, tí wọ́n sì ní irú ẹ̀mí tí wòlíì Aísáyà ní, nígbà tó sọ pé: “Èmi nìyí! Rán mi.” (Aísá. 6:8) Láfikún sí i, wọ́n ti gbọ́dọ̀ ṣègbéyàwó fún ọdún méjì ó kéré tán, kí wọ́n sì ti wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún ó kéré tán, fún ọdún méjì láìdáwọ́dúró.

  • Béèyàn Ṣe Lè Forúkọ Sílẹ̀: Bí ilé ẹ̀kọ́ yìí bá wà ní orílẹ̀-èdè tó o wà, wọ́n máa ń ṣe ìpàdé pẹ̀lú àwọn tó fẹ́ forúkọ sílẹ̀ nígbà àpéjọ àkànṣe. Wọ́n sì máa ń fúnni ní ìsọfúnni síwájú sí i ní ìpàdé yìí.

Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì

  • Ohun Tó Wà Fún: Láti dá àwọn aṣáájú-ọ̀nà àtàwọn míì tó wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún lẹ́kọ̀ọ́ fún iṣẹ́ ìsìn míṣọ́nnárì.

  • Àkókò: Oṣù márùn-ún.

  • Ibi Tí A Ti Ń Ṣe É: Ibùdó Ìdánílẹ́kọ̀ọ́ ti Watchtower tó wà ní ìlú Patterson, ní ìpínlẹ̀ New York, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.

  • Àwọn Ohun Téèyàn Gbọ́dọ̀ Dójú Ìlà Rẹ̀: Àwọn tọkọtaya tí wọ́n ti ṣèrìbọmi fún ọdún mẹ́ta, tí ọjọ́ orí wọn sì wà láàárín ọdún mọ́kànlélógún [21] sí ọdún méjìdínlógójì [38] nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ forúkọ sílẹ̀ fún ilé ẹ̀kọ́ náà. Wọ́n gbọ́dọ̀ lè sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì, kí wọ́n ti ṣègbéyàwó fún ọdún méjì ó kéré tán, kí wọ́n sì ti wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún fún ọdún méjì láìdáwọ́dúró. Wọ́n gbọ́dọ̀ ní ìlera tó dáa. Àwọn tó tún lè forúkọ sílẹ̀ bí wọ́n bá dójú ìlà ohun tá a béèrè ni, àwọn aṣáájú-ọ̀nà tó ń sìn nílẹ̀ òkèèrè (àti àwọn míṣọ́nnárì); àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò; ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì; àti àwọn tí wọ́n ti kẹ́kọ̀ọ́ yege ní Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́, Ilé Ẹ̀kọ́ Bíbélì fún Àwọn Àpọ́n, àti Ilé Ẹ̀kọ́ Bíbélì fún Àwọn Tọkọtaya.

  • Béèyàn Ṣe Lè Forúkọ Sílẹ̀: Ní àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì kan tá a yàn, a ti ṣètò ìpàdé kan fún àwọn tó bá fẹ́ lọ sílé ẹ̀kọ́ yìí nígbà àpéjọ àgbègbè. Wọ́n sì máa ń fúnni ní ìsọfúnni síwájú sí i ní ìpàdé yìí. Bí kò bá sí irú ìpàdé bẹ́ẹ̀ ní àwọn àpéjọ àgbègbè lórílẹ̀-èdè tó o wà, tó o sì fẹ́ forúkọ sílẹ̀, o lè kọ̀wé sí ẹ̀ka ọ́fíìsì fún ìsọfúnni síwájú sí i.

Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka Àtàwọn Ìyàwó Wọn

  • Ohun Tó Wà Fún: Láti ran àwọn tó wà lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka lọ́wọ́ kí wọ́n lè túbọ̀ máa ṣàbójú tó àwọn ilé Bẹ́tẹ́lì, kí wọ́n máa fún àwọn ọ̀ràn iṣẹ́ ìsìn tó ní ín ṣe pẹ̀lú àwọn ìjọ láfiyèsí, kí wọ́n sì máa bójú tó àwọn àyíká àti àgbègbè tó wà ní àwọn ìpínlẹ̀ tí wọ́n ń bójú tó, iṣẹ́ ìtúmọ̀ èdè, ìwé títẹ̀, kíkó ìwé ránṣẹ́ sí àwọn ìjọ àti bíbójú tó ọ̀kan-ò-jọ̀kan ẹ̀ka iṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì.—Lúùkù 12:48b.

  • Àkókò: Oṣù méjì.

  • Ibi Tí A Ti Ń Ṣe É: Ibùdó Ìdánílẹ́kọ̀ọ́ ti Watchtower tó wà ní ìlú Patterson, ní ìpínlẹ̀ New York, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.

  • Àwọn Ohun Téèyàn Gbọ́dọ̀ Dójú Ìlà Rẹ̀: Àwọn tó wà lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka tàbí Ìgbìmọ̀ Orílẹ̀-èdè tàbí àwọn tí wọ́n bá yàn láti máa ṣe ojúṣe yìí.

  • Béèyàn Ṣe Lè Forúkọ Sílẹ̀: Ìgbìmọ̀ Olùdarí ló máa ń pe àwọn arákùnrin tó bá kúnjú ìwọ̀n àtàwọn ìyàwó wọn.

a Kì í ṣe gbogbo orílẹ̀-èdè ni àwọn ilé ẹ̀kọ́ yìí wà ní báyìí.

b Kì í ṣe gbogbo orílẹ̀-èdè ni àwọn ilé ẹ̀kọ́ yìí wà ní báyìí.

c Kì í ṣe gbogbo orílẹ̀-èdè ni àwọn ilé ẹ̀kọ́ yìí wà ní báyìí.

d Kì í ṣe gbogbo orílẹ̀-èdè ni àwọn ilé ẹ̀kọ́ yìí wà ní báyìí.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́