Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ October 24
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ OCTOBER 24
Orin 75 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
bt orí 11 ìpínrọ̀ 13 sí 19 (25 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Òwe 17-21 (10 min.)
No. 1: Òwe 17:21–18:13 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Ìjọba Ọlọ́run Ni Ọlọ́run Máa Lò Láti Mú Ìwòsàn ti Ara Tó Wà Pẹ́ Títí Wá—td 32B (5 min.)
No. 3: Irú Ẹni Wo Ni Àwọn Tó Ń Yin Ìṣẹ̀dá Àmọ́ Tí Wọn Kò Yin Ẹlẹ́dàá Fi Hàn Pé Àwọn Jẹ́?—Róòmù 1:20 (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
10 min: Àwọn Ìfilọ̀. Sọ ìwé tá a máa lò lóṣù November, kó o sì ṣe àṣefihàn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ kan tàbí méjì.
25 min: “Ǹjẹ́ Ò Ń Kọ́ Gbogbo Ohun Tó O Lè Kọ́ Lọ́dọ̀ Jèhófà?” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Ní ṣókí, fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu ẹnì kan tó gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ àkànṣe nípasẹ̀ ètò Jèhófà.
Orin 105 àti Àdúrà