Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ October 31
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ OCTOBER 31
Orin 104 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
bt orí 12 ìpínrọ̀ 1 sí 8, àti àpótí tó wà lójú ìwé 96 (25 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Òwe 22-26 (10 min.)
Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run (20 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
10 min: Àwọn Ìfilọ̀. “Báwo Ló Ṣe Rí?” Àsọyé. Lẹ́yìn àsọyé náà, lo àbá tó wà lójú ìwé 8 láti ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní Saturday àkọ́kọ́ lóṣù November.
15 min: Ìdí Tó Fi Ṣe Pàtàkì Pé Kí Ìrísí Wa Dára Nígbà Tá A Bá Wà Lóde Ẹ̀rí. Ìjíròrò. Alàgbà ni kó ṣe iṣẹ́ yìí, a gbé e ka ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 131 sí 134.
10 min: Múra Sílẹ̀ Láti Lo Àwọn Ìwé Ìròyìn Lóṣù November. Ìjíròrò. Fi ìṣẹ́jú kan tàbí méjì sọ àwọn àpilẹ̀kọ tó ṣeé ṣe kó fa àwọn èèyàn mọ́ra ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín. Lẹ́yìn náà, lo àwọn àpilẹ̀kọ tó dá lórí àkòrí tó wà níwájú Ilé Ìṣọ́, kó o sì ní kí àwọn ará sọ àwọn ìbéèrè tó lè múni nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ tí wọ́n lè lò, kí wọ́n sì sọ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n lè kà láti fi ti ọ̀rọ̀ wọn lẹ́yìn. Ṣe ohun kan náà nípa àwọn àpilẹ̀kọ tó dá lórí àkòrí tó wà níwájú ìwé ìròyìn Jí!, bí àyè bá sì wá, fi àpilẹ̀kọ míì kún un. Ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo ìwé ìròyìn kọ̀ọ̀kan.
Orin 90 àti Àdúrà