Ẹ̀yin Ọ̀dọ́—Kí Lẹ Máa Fi Ìgbésí Ayé Yín Ṣe?
ỌMỌBÌNRIN kan tí kò tíì pé ogún ọdún sọ pé: “Mo fẹ́ gbádùn ayé mi lọ́nà tó dára jù lọ.” Kò sí àní-àní pé ohun tí ìwọ náà ń fẹ́ nìyẹn. Àmọ́, báwo lo ṣe lè gbádùn ayé rẹ “lọ́nà tó dára jù lọ”? Àwọn ilé iṣẹ́ agbéròyìnjáde, àwọn ojúgbà rẹ, tàbí àwọn olùkọ́ rẹ pàápàá, lè sọ pé bí owó bá ti ń ya wọlé, tíṣẹ́ tó dáa sì wà lọ́wọ́ ẹ, ayé ẹ ti dáa nìyẹn!
Àmọ́ ṣá o, Bíbélì kìlọ̀ fún àwọn ọ̀dọ́ pé lílépa àtikó ọrọ̀ jọ kò yàtọ̀ sí “lílépa ẹ̀fúùfù.” (Oníwàásù 4:4) Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ìwọ̀nba làwọn ọ̀dọ́ tí ọwọ́ wọn ń tẹ ọrọ̀ àti òkìkí tí wọ́n ń lépa. Àwọn tó bá jàjà lówó ọ̀hún sì rèé, ìjákulẹ̀ tí kò ṣeé fẹnu sọ ló sábà máa ń bá wọn. Ọ̀dọ́ kan tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, ẹni tó kàwé dé ipò ọlá, sọ pé: “Ṣe ni kíkó ọrọ̀ jọ dà bíi kíkówó sínú ajádìí àpò, bó o bá wo ohun tó o ti ń kó jọ, wà á rí i pé òfìfo gbáà ni.” Òótọ́ ni pé iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ lè mówó wọlé, ó sì lè sọni di gbajúmọ̀, àmọ́ kò lè kájú àwọn “àìní [rẹ] nípa ti ẹ̀mí.” (Mátíù 5:3) Yàtọ̀ sí ìyẹn, 1 Jòhánù 2:17 kìlọ̀ pé: “Ayé ń kọjá lọ.” Kódà, bó o bá rí ọrọ̀ ọ̀hún kó jọ nínú ayé yìí, kì í ṣe ohun tó máa wà pẹ́ títí.
Nípa báyìí, Oníwàásù 12:1 rọ àwọn ọ̀dọ́ pé: “Rántí Ẹlẹ́dàá rẹ nígbà tí o ṣì wà ní ọ̀dọ́.” (Today’s English Version) Dájúdájú, ọ̀nà tó dára jù lọ láti gbà lo ìgbésí ayé rẹ jẹ́ nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà Ọlọ́run. Àmọ́ o, wàá kọ́kọ́ tóótun ná kó o tó lè ṣe iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. Báwo lo ṣe lè tóótun? Kí ló sì wé mọ́ lílo ìgbésí ayé ẹni nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run?
Bó O Ṣe Lè Tóótun Láti Di Ẹlẹ́rìí fún Jèhófà
Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ìfẹ́ láti sin Ọlọ́run gbọ́dọ̀ tinú ọkàn rẹ wá. Irú ìfẹ́ àtọkànwá yìí kì í sì í dédé wá kódà báwọn òbí rẹ bá tiẹ̀ jẹ́ Kristẹni. Ìwọ fúnra rẹ gbọ́dọ̀ ní àjọṣe tìẹ pẹ̀lú Jèhófà. Ọmọbìnrin kan tí kò tíì pé ogún ọdún sọ pé: “Àdúrà gbígbà máa ń jẹ́ kéèyàn lè ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú Jèhófà.”—Sáàmù 62:8; Jákọ́bù 4:8.
Róòmù 12:2 tún sọ ìgbésẹ̀ mìíràn tó o gbọ́dọ̀ gbé. Ó kà pé: “Ẹ . . . ṣàwárí fúnra yín ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó dára, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, tí ó sì pé.” Ǹjẹ́ ó tíì ṣẹlẹ̀ sí ọ rí pé o kàn bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiyèméjì nípa àwọn ohun kan tó o ti kọ́, pé ǹjẹ́ wọ́n tiẹ̀ jóòótọ́? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, ńṣe ni kó o ṣe ohun tí Bíbélì gbà wá níyànjú láti ṣe, ìyẹn ni pé kó o ‘ṣàwárí fúnra rẹ’ láti lè rí i pé òótọ́ pọ́ńbélé ni gbogbo rẹ̀! Ṣe ìwádìí fúnra rẹ. Ka Bíbélì àti àwọn ìwé tí a gbé karí Bíbélì. Àmọ́ o, kíkẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run kì í ṣe ọ̀ràn pé kó o kàn ti kàwé rẹpẹtẹ, láìfọkàn sí ohun tó ò ń kà. Rí i pé ò ń ṣàṣàrò lórí ohun tó o kà kí ó lè wọnú ọkàn rẹ lọ jinlẹ̀jinlẹ̀. Èyí yóò mú kí ìfẹ́ tó o ní fún Ọlọ́run pọ̀ sí i.—Sáàmù 1:2, 3.
Lẹ́yìn èyí, gbìyànjú láti máa fúnra rẹ wá àyè láti sọ ohun tó ò ń kọ́ fún àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ àti àwọn ẹlòmíràn tó o mọ̀. Ìgbésẹ̀ tó kàn lẹ́yìn èyí ni wíwàásù láti ilé dé ilé. O ṣeé ṣe kó o máa pàdé àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan nígbà tó o bá ń wàásù, èyí sì lè kó ìtìjú bá ọ lákọ̀ọ́kọ́. Ṣùgbọ́n Bíbélì rọ̀ wá pé kí a má ṣe “tijú ìhìn rere.” (Róòmù 1:16) Ṣebí ọ̀rọ̀ tó ń fúnni ní ìrètí àti ìyè lò ń wàásù! Kí ló wá dé tí wàá fi máa tijú?
Báwọn òbí rẹ bá jẹ́ Kristẹni, o lè ti máa bá wọn lọ sóde ẹ̀rí. Ṣùgbọ́n, ǹjẹ́ o máa ń wàásù, àbí ńṣe lo kàn máa ń dákẹ́ jẹ́ẹ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹnu ilẹ̀kùn onílé, tàbí kó o kàn fi ìwé ìròyìn tàbí ìwé àṣàrò kúkúrú lọ̀ wọ́n lásán? Ǹjẹ́ ìwọ fúnra rẹ máa ń lè wàásù, kó o sì fi Bíbélì kọ́ onílé lẹ́kọ̀ọ́? Bí kò bá rí bẹ́ẹ̀, sọ pé kí àwọn òbí rẹ tàbí ẹnì kan tó dàgbà dénú nínú ìjọ ràn ọ́ lọ́wọ́. Fi ṣe ìpinnu rẹ pé o fẹ́ tóótun láti di akéde ìhìn rere tí kò tíì ṣèrìbọmi!
Bí àkókò ti ń lọ, wàá dẹni tó ń fẹ́ láti ṣe ìyàsímímọ́, ìyẹn ni pé wàá jẹ́jẹ̀ẹ́ fún Ọlọ́run pé òun ni wàá máa sìn láti ìsinsìnyí lọ. (Róòmù 12:1) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀ràn ìdákọ́ńkọ́ ni ìyàsímímọ́ jẹ́, kò tán síbẹ̀. Ọlọ́run ń béèrè pé kí gbogbo wa ṣe “ìpolongo ní gbangba fún ìgbàlà.” (Róòmù 10:10) Ní kété kó o tóó ṣe ìrìbọmi, wàá kọ́kọ́ fi ẹnu polongo ìgbàgbọ́ rẹ. Lẹ́yìn èyí lo máa wá ṣe batisí nínú omi. (Mátíù 28:19, 20) Lóòótọ́, ìrìbọmi jẹ́ ìgbésẹ̀ tó gba ìrònújinlẹ̀. Àmọ́ má torí wí pé kó o má bàa ṣàṣìṣe kankan, kó o wá máa fà sẹ́yìn. Bó o bá gbára lé Ọlọ́run fún okun, yóò fún ọ ní “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá” kó o bàa lè dúró ṣinṣin.—2 Kọ́ríńtì 4:7; 1 Pétérù 5:10.
Nígbà tó o ṣèrìbọmi, o di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. (Aísáyà 43:10) Ó yẹ kí èyí ní ipa tó lágbára lórí bó o ṣe máa lo ìgbésí ayé rẹ, nítorí pé ìyàsímímọ́ wé mọ́ ‘sísẹ́ ara ẹni.’ (Mátíù 16:24) Ó ṣeé ṣe kó o mójú kúrò nínú àwọn ìlépa ti ara kan tàbí àwọn ohun mìíràn tó o nífẹ̀ẹ́ sí kí o bàa lè ‘wá ìjọba Ọlọ́run lákọ̀ọ́kọ́.’ (Mátíù 6:33) Ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi tó o ti ṣe sì mú kí onírúurú àǹfààní ṣí sílẹ̀ láti ṣe èyí. Jẹ́ ká gbé díẹ̀ lára wọn yẹ̀ wò.
Àwọn Àǹfààní Tó O Lè Lò Láti Fi Sin Ọlọ́run Ní Àkókò Kíkún
● Iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà jẹ́ ọ̀kan lára irú àwọn àǹfààní bẹ́ẹ̀. Akéde tó jẹ́ aṣáájú ọ̀nà jẹ́ Kristẹni àwòfiṣàpẹẹrẹ tó ti ṣèrìbọmi, tó sì ti ṣètò láti máa lo, ó kéré tán, àádọ́rin wákàtí lóṣooṣù fún wíwàásù ìhìn rere. Lílo àkókò púpọ̀ sí i lóde ẹ̀rí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti túbọ̀ di ọ̀jáfáfá nínú bó o ṣe ń wàásù àti bó o ṣe ń kọ́ni. Ọ̀pọ̀ àwọn aṣáájú ọ̀nà ló ti nírìírí ayọ̀ ríran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wọn lọ́wọ́ láti di Ẹlẹ́rìí tó ti ṣe batisí. Iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ wo ló lè fúnni ní irú ayọ̀ àti ìbàlẹ̀ ọkàn bẹ́ẹ̀ yẹn?
Èyí tó pọ̀ jù lára àwọn aṣáájú ọ̀nà ló ń ṣiṣẹ́ aláàbọ̀ àkókò láti fi gbọ́ bùkátà ara wọn. Ọ̀pọ̀ sì ń kọ́ṣẹ́ ọwọ́ kan níléèwé tàbí látọ̀dọ̀ àwọn òbí wọn láti fi múra sílẹ̀ fún ẹrù iṣẹ́ yìí. Bí ìwọ àti àwọn òbí rẹ bá rò pé ohun tó máa ṣe ọ́ láǹfààní jù ni pé kó o gba àfikún ìdánilẹ́kọ̀ọ́ lẹ́yìn tó o bá jáde nílé ẹ̀kọ́ gíga, kò burú. Ṣùgbọ́n o, rí i dájú pé ète tó o fi ń lọ kẹ́kọ̀ọ́ sí i kì í ṣe láti lè lówó rẹpẹtẹ bí kò ṣe láti lè gbọ́ bùkátà ara rẹ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, pàápàá gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ alákòókò kíkún.
Bó ti wù kí ó rí, kì í ṣe iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ làwọn aṣáájú ọ̀nà kúkú ń fi ìgbésí ayé wọn lépa, bí kò ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn, ìyẹn ni ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti jèrè ìyè! Èé ṣe tó ò fi fi iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà ṣe ìlépa tìẹ? Iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà sábà máa ń ṣamọ̀nà sí àwọn àǹfààní mìíràn. Bí àpẹẹrẹ, àwọn aṣáájú ọ̀nà kan ti ṣí lọ sí àwọn àgbègbè tí wọ́n ti nílò àwọn akéde Ìjọba púpọ̀. Àwọn mìíràn ti kọ́ èdè àjèjì, tí wọ́n sì ń sìn nínú ìjọ kan ládùúgbò tí wọ́n ti ń sọ èdè àjèjì tàbí kí wọ́n lọ sìn ní ilẹ̀ òkèèrè pàápàá. Láìsí tàbí ṣùgbọ́n, iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà jẹ́ iṣẹ́ ìgbésí ayé kan tó lérè nínú!
● Iṣẹ́ míṣọ́nnárì jẹ́ ilẹ̀kùn àǹfààní mìíràn tó ṣí sílẹ̀. Láti ọdún 1943 ni ilé ẹ̀kọ́ Watchtower Bible School of Gilead ti ń pèsè ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tó yè kooro fáwọn aṣáájú ọ̀nà tó bá tóótun, kí wọ́n lè lọ sìn gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì. Àwọn tó bá ti kẹ́kọ̀ọ́ yege máa ń lọ sìn gẹ́gẹ́ bí oníwàásù alákòókò kíkún nílẹ̀ òkèèrè. Níwọ̀n bí ipò nǹkan ò ti fararọ ní ọ̀pọ̀ lára àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí, ó ṣe pàtàkì pé kí ara àwọn tó ń sìn gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì le dáadáa. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwọn míṣọ́nnárì ń gbádùn ìgbésí ayé alárinrin, tó sì ń fọkàn ẹni balẹ̀.
● Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ ni a dá sílẹ̀ láti dá àwọn alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó jẹ́ àpọ́n, tó sì tóótun lẹ́kọ̀ọ́. Ìdálẹ́kọ̀ọ́ olóṣù méjì tó kún fún iṣẹ́ àṣekára yìí, máa ń kárí àwọn kókó ẹ̀kọ́ lónírúurú. Irú bí ẹrù iṣẹ́ àwọn alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, ọ̀ràn nípa ìṣètò àti sísọ̀rọ̀ níwájú àwùjọ. A máa ń yan àwọn kan láti sìn ní orílẹ̀-èdè wọn. A sì máa ń rán àwọn mìíràn lọ sí ilẹ̀ òkèèrè.
● Iṣẹ́ ìsìn ní Bẹ́tẹ́lì wé mọ́ sísìn gẹ́gẹ́ bí olùyọ̀ǹda ara ẹni ní ọ̀kan lára àwọn ẹ̀ka ilé iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Iṣẹ́ àwọn kan lára ìdílé Bẹ́tẹ́lì ni pé kí wọ́n máa tẹ àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Iṣẹ́ àwọn mìíràn sì ń ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ ìwé títẹ̀. Lára irú àwọn iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ ni bíbójútó àwọn ilé ní Bẹ́tẹ́lì àti àwọn ohun èlò tá a fi ń ṣiṣẹ́ tàbí bíbójútó ọ̀ràn oúnjẹ, ìmọ́tótó àti ìlera ìdílé Bẹ́tẹ́lì. Gbogbo iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe ni Jèhófà kà sí àǹfààní tí olúkúlùkù wọn ní láti fi ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ sí òun. Láfikún sí i, àwọn tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì máa ń láyọ̀ pé iṣẹ́ yòówù kí àwọn máa ṣe, yóò ṣàǹfààní fún púpọ̀ nínú àwọn arákùnrin wọn kárí ayé.
Nígbà míì, a máa ń ké sí àwọn arákùnrin tó mọ àwọn iṣẹ́ pàtàkì kan láti wá sìn ní Bẹ́tẹ́lì. Ṣùgbọ́n, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tó wà ní Bẹ́tẹ́lì ló jẹ́ pé ẹ̀yìn tí wọ́n dé Bẹ́tẹ́lì tán ni wọ́n gba ìdálẹ́kọ̀ọ́. Àwọn tó wà ní Bẹ́tẹ́lì ò ṣiṣẹ́ nítorí àtilè kó ọrọ̀ jọ, kàkà bẹ́ẹ̀ wọ́n nítẹ̀ẹ́lọ́rùn pẹ̀lú ètò tí a ṣe fún wọn ní ti oúnjẹ, ilé gbígbé àti owó táṣẹ́rẹ́ fún ìnáwó ti ara wọn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. Ọ̀dọ́ kan tó jẹ́ ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì ṣàpèjúwe iṣẹ́ ìsìn tó ń ṣe lọ́nà yìí: “Ó lárinrin! Lóòótọ́ o, ìgbòkègbodò wa ojoojúmọ́ gba iṣẹ́ àṣekára, àmọ́ ìbùkún tí mò ń rí gbà bí mo ṣe ń sìn níbí kò lóǹkà.”
● Iṣẹ́ kárí ayé jẹ́ iṣẹ́ ìsìn kan tó ń fúnni láǹfààní láti kópa nínú kíkọ́ àwọn ẹ̀ka ilé iṣẹ́ àti Gbọ̀ngàn Ìjọba. Àwọn òṣìṣẹ́ káyé là ń pe àwọn tó ń sìn lọ́nà yìí, torí wọ́n máa ń lọ sí ilẹ̀ òkèèrè láti lọ ṣèrànwọ́ níbi irú iṣẹ́ ìkọ́lé bẹ́ẹ̀. Èyí jẹ́ irú iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ kan tó fara jọ iṣẹ́ tí àwọn tó kọ́ tẹ́ńpìlì Sólómọ́nì ṣe. (1 Àwọn Ọba 8:13-18) Irú àwọn ètò tá a ṣe láti bójú tó ìdílé Bẹ́tẹ́lì náà la ṣe fún àwọn òṣìṣẹ́ káyé wọ̀nyí. Àǹfààní àgbàyanu mà làwọn arákùnrin àti arábìnrin wọ̀nyí ní o, bí wọ́n ti ń ṣe iṣẹ́ ìsìn tiwọn lọ́nà yìí láti fi yin Jèhófà!
Sin Jèhófà Tọkàntọkàn
Sísin Jèhófà ni ọ̀nà tó dára jù lọ láti gbà lo ìgbésí ayé rẹ. Èé ṣe tó ò fi gbé fífi àkókò kíkún sin Ọlọ́run yẹ̀ wò gẹ́gẹ́ bí ìlépa tìẹ? Jíròrò iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún pẹ̀lú àwọn òbí rẹ, àwọn alàgbà ìjọ rẹ, àti alábòójútó àyíká yín. Bó o bá nífẹ̀ẹ́ sí iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì, ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì, tàbí Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́, pésẹ̀ sí ìpàdé tá a máa ń ṣe pẹ̀lú àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí àwọn iṣẹ́ ìsìn wọ̀nyí nígbà àpéjọ àyíká tàbí àpéjọ àgbègbè.
Ká sòótọ́, kì í ṣe gbogbo wa la lè tóótun tàbí ká láǹfààní láti ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Nígbà míì, nítorí àìsàn, ọ̀ràn àtijẹ àtimu, tàbí ojúṣe ìdílé, ó lè jẹ́ pé ìwọ̀nba lohun tá a máa lè ṣe. Bó ti wù kó rí, gbogbo Kristẹni tó ti ṣèyàsímímọ́ ló gbọ́dọ̀ pa àṣẹ Bíbélì yìí mọ́, pé: “Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò inú rẹ.” (Mátíù 22:37) Jèhófà ń béèrè pé kó o ṣe gbogbo ohun tí ipá rẹ bá ká láti ṣe. Nítorí náà, ipòkípò tó o bá wà, jẹ́ kí ṣíṣe iṣẹ́ ìsìn Jèhófà jẹ́ ohun àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé rẹ. Fi àwọn ohun kan tí ọwọ́ rẹ lè tẹ̀ nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ sí Ọlọ́run síwájú ara rẹ láti máa lépa. Ó dájú pé tó o bá “rántí Ẹlẹ́dàá rẹ nígbà tí o ṣì wà ní ọ̀dọ́,” títí ayé ni ìbùkún yàbùgà-yabuga yóò máa jẹ́ tìrẹ!
Bí a kò bá fi hàn pé ó yàtọ̀, gbogbo ẹsẹ Bíbélì wá láti inú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.