ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • yp2 ojú ìwé 50
  • Àwòkọ́ṣe—Jósẹ́fù

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwòkọ́ṣe—Jósẹ́fù
  • Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ‘Èmi Kò Lè Hùwà Búburú Ńlá Yìí’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • Ó Dáàbò Bo Ìdílé Rẹ̀, Ó Pèsè fún Wọn, Ó sì Ní Ìfaradà
    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
  • Ẹrú Tó Ṣègbọràn sí Ọlọ́run
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
  • “Èmi Ha Wà ní Ipò Ọlọ́run Bí?”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
Àwọn Míì
Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
yp2 ojú ìwé 50

Àwòkọ́ṣe—Jósẹ́fù

Wàhálà rèé o! Ìyàwó ọ̀gá Jósẹ́fù ń pè é léraléra pé kó wá bá òun sùn. Ó tún ti bẹ̀rẹ̀ o! Àmọ́ Jósẹ́fù ò wojú ẹ̀. Ńṣe ló kọ̀ jálẹ̀. Ó sọ fún obìnrin yẹn pé: “Báwo ni èmi ṣe lè hu ìwà búburú ńlá yìí, kí n sì dẹ́ṣẹ̀ sí Ọlọ́run ní ti gidi?” Nígbà tíyàwó ọ̀gá Jósẹ́fù fẹ́ fipá mú un balẹ̀, ojú ò tì í láti fẹsẹ̀ fẹ. Àní sẹ́, eré ló sá jáde kúrò nínú ilé yẹn! Jósẹ́fù fi hàn pé òun ò gbàgbàkugbà.—Jẹ́nẹ́sísì 39:7-12.

Ẹnì kan lè fi ìṣekúṣe lọ ìwọ náà. Yàtọ̀ sí pé o gbọ́dọ̀ pinnu lọ́kàn ẹ pé o ò ní ṣe é, ó yẹ kó máa wù ẹ́ láti tẹ́ Ẹlẹ́dàá rẹ lọ́rùn, ìyẹn Jèhófà Ọlọ́run. Ṣó o rí i, bó ti ń wù ẹ́ láti ní ìbálòpọ̀ náà ló ń wu Jósẹ́fù. Àmọ́, Jósẹ́fù ò rídìí tó fi yẹ kóun tẹ́ra òun lọ́rùn lọ́nà tínú Ẹlẹ́dàá ò dùn sí. Ó yẹ kíwọ náà mọ̀ dájú pé inú Ọlọ́run ò dùn sí ìṣekúṣe àtàwọn àṣàkaṣà wọ̀nyẹn, àti pé ńṣe lo máa kábàámọ̀ gbẹ̀yìn. Torí náà, kọ́ ara ẹ bíi ti Jósẹ́fù, kó o sì rí i dájú pé o ò gbàgbàkugbà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́