ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JẸ́NẸ́SÍSÌ 40-41
Jèhófà Gba Jósẹ́fù Sílẹ̀
Nǹkan bí ọdún mẹ́tàlá (13) ni Jósẹ́fù fi jìyà bí ẹrú àti ẹlẹ́wọ̀n kó tó di pé Jèhófà gbà á sílẹ̀. Dípò kí Jósẹ́fù máa bínú, ṣe ló kẹ́kọ̀ọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i. (Sm 105:17-19) Ó mọ̀ pé Jèhófà ò fi òun sílẹ̀. Báwo ni Jósẹ́fù ṣe ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe nínú ipò tó wà?
Ó máa ń ṣiṣẹ́ kára, ó sì jẹ́ olóòótọ́ nínú gbogbo ohun tó ń ṣe, èyí mú kí Jèhófà bù kún un.—Jẹ 39:21, 22
Ó fi ìfẹ́ han sí àwọn míì dípò kó máa wá bó ṣe máa gbẹ̀san lára àwọn tó hùwà ìkà sí i.—Jẹ 40:5-7
Báwo ni ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jósẹ́fù ṣe lè ràn mí lọ́wọ́ láti fara da àwọn ìṣòro mi?
Títí Jèhófà á fi gbà mí là ní Amágẹ́dọ́nì, báwo ni mo ṣe lè ṣe gbogbo ohun tí agbára mi gbé nínú ipò tí mo wà?