ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwbq àpilẹ̀kọ 157
  • Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Àwọn Àjálù Tó Ń Ṣẹlẹ̀?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Àwọn Àjálù Tó Ń Ṣẹlẹ̀?
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun tí Bíbélì sọ
  • Kí ló jẹ́ kó dá wa lójú pé Ọlọ́run kọ́ ló ń fi àwọn àjálù jẹ wá níyà?
  • Ṣé àwọn àjálù wà lára àmì ọjọ́ ìkẹyìn?
  • Báwo ni Ọlọ́run ṣe ń ran àwọn tí àjálù ń ṣẹlẹ̀ sí lọ́wọ́?
  • Ṣé Bíbélì lè ràn wá lọ́wọ́ láti múra sílẹ̀ de àjálù?
  • Àjálù—Kí Nìdí Tó Fi Pọ̀ Tó Bẹ́ẹ̀?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Ṣé Ọlọ́run Ló Ń Fa Àwọn Ìjábá Láti Máa Fi Jẹ Àwa Èèyàn Níyà?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Àwọn Ìjábá ti Ẹ̀dá—Ọlọrun Ni Ó Ha Ń Fà Á Bí?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Ṣé Ọlọ́run Ló Ń Fìyà Jẹ Wá?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
Àwọn Míì
Ohun Tí Bíbélì Sọ
ijwbq àpilẹ̀kọ 157
Ìdílé kan ń wo àdúgbò kan tí àjálù ba gbogbo ibẹ̀ jẹ́

Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Àwọn Àjálù Tó Ń Ṣẹlẹ̀?

Ohun tí Bíbélì sọ

Ọlọ́run kọ́ ló ń fa àwọn àjálù tó ń ṣẹlẹ̀ lóde òní, àmọ́ ọ̀rọ̀ àwọn tó ń ṣẹlẹ̀ sí máa ń ká Ọlọ́run lára. Àjálù wà lára àwọn ohun tó ń fìyà jẹ àwa èèyàn, tí Ìjọba Ọlọ́run máa mú kúrò. Àmọ́ ní báyìí ná, Ọlọ́run ń tu àwọn tí àjálù ń ṣẹlẹ̀ sí nínú.​—2 Kọ́ríńtì 1:3.

  • Kí ló jẹ́ kó dá wa lójú pé Ọlọ́run kọ́ ló ń fi àwọn àjálù jẹ wá níyà?

  • Ṣé àwọn àjálù wà lára àmì ọjọ́ ìkẹyìn?

  • Báwo ni Ọlọ́run ṣe ń ran àwọn tí àjálù dé bá lọ́wọ́?

  • Ṣé Bíbélì lè ràn wá lọ́wọ́ láti múra sílẹ̀ de àjálù?

  • Àwọn ẹsẹ Bíbélì tó lè tu àwọn tí àjálù ṣẹlẹ̀ sí nínú

Kí ló jẹ́ kó dá wa lójú pé Ọlọ́run kọ́ ló ń fi àwọn àjálù jẹ wá níyà?

Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé láyé àtijọ́, Ọlọ́run ti lo àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àdáyébá láti ṣèdájọ́ àwọn olubi, àmọ́ ìyẹn yàtọ̀ sí àwọn àjálù tó ń ṣẹlẹ̀ lóde òní.

  • Ẹnikẹ́ni làwọn àjálù lè pa tàbí kó sọ di aláàbọ̀ ara. Nígbà àtijọ́ tí Ọlọ́run lo ìṣẹ̀lẹ̀ àdáyébá láti ṣèdájọ́, Bíbélì sọ pé àwọn ẹni burúkú nìkan ló pa run. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Ọlọ́run pa ìlú Sódómù àti Gòmórà àtijọ́ run, ó dá Lọ́ọ̀tì tó jẹ́ ẹni rere sí àtàwọn ọmọbìnrin rẹ̀ méjèèjì. (Jẹ́nẹ́sísì 19:29, 30) Ọlọ́run rí ọkàn àwọn tó ń gbé láyé nígbà yẹn, torí ẹ̀ ló ṣe jẹ́ pé àwọn èèyàn burúkú nìkan ló pa run.​—Jẹ́nẹ́sísì 18:23-​32; 1 Sámúẹ́lì 16:7.

  • Tí àjálù bá fẹ́ ṣẹlẹ̀, kì í sábà fu àwọn èèyàn lára. Nígbà tí Ọlọ́run fi ìṣẹ̀lẹ̀ àdáyébá ṣèdájọ́, ó kọ́kọ́ kìlọ̀ fáwọn ẹni burúkú kó tó pa wọ́n run. Àwọn tó gbọ́ ìkìlọ̀ nínú wọn ráyè mórí bọ́.​—Jẹ́nẹ́sísì 7:1-5; Mátíù 24:38, 39.

  • Déwọ̀n àyè kan, àfọwọ́fà àwọn èèyàn ló máa ń fa àjálù. Lọ́nà wo? Àwọn èèyàn ń ba àyíká jẹ́, wọ́n ń kọ́lé síbi tí ilẹ̀ ti lè mì tìtì, wọ́n ń kọ́lé sétí omi àtàwọn ibòmíì tí ojú ọjọ́ ibẹ̀ ò dáa. (Ìfihàn 11:18) Ọlọ́run kọ́ la máa dá lẹ́bi tí ohun táwọn èèyàn yàn bá bẹ́yìn yọ, tó sì fa àjálù.​—Òwe 19:3.

Ṣé àwọn àjálù wà lára àmì ọjọ́ ìkẹyìn?

Bẹ́ẹ̀ ni, Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn àjálù á máa ṣẹlẹ̀ ní “ìparí ètò àwọn nǹkan,” tàbí “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.” (Mátíù 24:3; 2 Tímótì 3:1) Bí àpẹẹrẹ, Jésù sọ nípa àkókò wa yìí pé: “Àìtó oúnjẹ àti ìmìtìtì ilẹ̀ sì máa wà láti ibì kan dé ibòmíì.” (Mátíù 24:7) Láìpẹ́, Ọlọ́run máa fòpin sí gbogbo ohun tó ń fa ìrora àti ìyà láyé, títí kan àwọn àjálù tó ń ṣẹlẹ̀.​—Ìfihàn 21:3, 4.

Báwo ni Ọlọ́run ṣe ń ran àwọn tí àjálù ń ṣẹlẹ̀ sí lọ́wọ́?

  • Ọlọ́run ń fi Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ràn wọ́n lọ́wọ́. Bíbélì fi dá wa lójú pé ọ̀rọ̀ wa ṣe pàtàkì sí Ọlọ́run, inú ẹ̀ kì í sì í dùn tá a bá ń jìyà. (Àìsáyà 63:9; 1 Pétérù 5:6, 7) Bíbélì tún jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run ṣèlérí ìgbà kan tí àjálù ò ní wáyé mọ́.​—Wo “Àwọn ẹsẹ Bíbélì tó lè tu àwọn tí àjálù ṣẹlẹ̀ sí nínú.”

  • Ọlọ́run máa ń lo àwọn olùjọ́sìn rẹ̀ láti ran àwọn tí àjálù ṣẹlẹ̀ sí lọ́wọ́. Ọlọ́run máa ń mú kí àwọn olùjọ́sìn rẹ̀ tó wà láyé tẹ̀ lé àpẹẹrẹ tí Jésù fi lélẹ̀. Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé Jésù máa tu “àwọn tó ní ọgbẹ́ ọkàn” nínú pẹ̀lú “gbogbo àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀.” (Àìsáyà 61:1, 2) Àwọn tó ń jọ́sìn Ọlọ́run náà máa ń sapá láti ṣe bẹ́ẹ̀.​—Jòhánù 13:15.

    Ọlọ́run tún máa ń lo àwọn olùjọ́sìn rẹ̀ láti pèsè oúnjẹ àtàwọn nǹkan míì fáwọn tí àjálù ṣẹlẹ̀ sí.​—Ìṣe 11:28-30; Gálátíà 6:10.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń tún ilé kan ṣe ní Puerto Rico

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣèrànwọ́ fún àwọn tí ìjì líle ṣèpalára fún ní Puerto Rico

Ṣé Bíbélì lè ràn wá lọ́wọ́ láti múra sílẹ̀ de àjálù?

Bẹ́ẹ̀ ni. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe torí àtilè múra wa sílẹ̀ de àjálù ni Bíbélì ṣe wà, síbẹ̀, àwọn ìlànà tó wà nínú ẹ̀ lè ràn wá lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ:

  • Múra ohun tó o máa ṣe sílẹ̀ ká sọ pé àjálù ṣẹlẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Ọlọ́gbọ́n rí ewu, ó sì fara pa mọ́.” (Òwe 22:3) Ìwà ọgbọ́n la hù tá a bá ti múra ohun tá a máa ṣe sílẹ̀ ṣáájú kí àjálù tó dé. Irú ìmúra bẹ́ẹ̀ lè gba pé ká ti di báàgì kan tó ní oríṣiríṣi ohun ìgbẹ̀mílà sílẹ̀, tá a kàn máa gbé tí ọ̀rọ̀ pàjáwìrì bá ṣẹlẹ̀, tàbí kí àwa àti ìdílé wa ti jọ sọ ọ́ pé ibi báyìí báyìí la ti máa pàdé tí àjálù bá ṣẹlẹ̀.

  • Gbà pé ẹ̀mí ṣe pàtàkì ju ohun ìní lọ. Bíbélì sọ pé: “A ò mú nǹkan kan wá sí ayé, a ò sì lè mú ohunkóhun jáde.” (1 Tímótì 6:7, 8) Tí àjálù bá ṣẹlẹ̀, ó yẹ ká múra tán láti filé fọ̀nà wa sílẹ̀ ká lè sá fún ẹ̀mí wa. Ẹ jẹ́ ká máa rántí pé ẹ̀mí wa ṣe pàtàkì ju ohun ìní èyíkéyìí lọ.​—Mátíù 6:25.

Àwọn ẹsẹ Bíbélì tó lè tu àwọn tí àjálù ṣẹlẹ̀ sí nínú

Jẹ́nẹ́sísì 18:25: “Ó dájú pé [ìwọ Ọlọ́run] ò ní hùwà báyìí, pé kí o pa olódodo pẹ̀lú ẹni burúkú, . . . Ṣé Onídàájọ́ gbogbo ayé kò ní ṣe ohun tó tọ́ ni?”

Ohun tó túmọ̀ sí: Ohun tó tọ́ ni Ọlọ́run máa ń ṣe ní gbogbo ìgbà; tí àjálù bá ṣẹlẹ̀, tó sì pa àwọn èèyàn rere, Ọlọ́run kọ́ ló fà á.

Sáàmù 46:1, 2: “Ọlọ́run ni ibi ààbò wa àti okun wa, ìrànlọ́wọ́ tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó ní àkókò wàhálà. Ìdí nìyẹn tí a kò fi ní bẹ̀rù, bí ayé tilẹ̀ ń mì tìtì.”

Ohun tó túmọ̀ sí: Ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀ láyìíká wa, a lè gbára lé Ọlọ́run pé kó fún wa lókun.

Àìsáyà 63:9: “Nínú gbogbo ìdààmú wọn, ìdààmú bá òun náà.”

Ohun tó túmọ̀ sí: Ọlọ́run mọ bí nǹkan ṣe ń rí lára wa, ó máa ń dùn ún tá a bá ń jìyà.

Jòhánù 5:28, 29: “Wákàtí náà ń bọ̀, tí gbogbo àwọn tó wà nínú ibojì ìrántí máa gbọ́ ohùn [Jésù], tí wọ́n á sì jáde wá.”

Ohun tó túmọ̀ sí: Tí àwọn tá a nífẹ̀ẹ́ bá kú, ká nírètí pé a ṣì máa pa dà rí wọn torí Ọlọ́run máa fún Jésù lágbára láti jí wọn dìde.

1 Pétérù 5:6, 7: “Ẹ rẹ ara yín sílẹ̀ lábẹ́ ọwọ́ agbára Ọlọ́run, . . . ẹ máa kó gbogbo àníyàn yín lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, torí ó ń bójú tó yín.”

Ohun tó túmọ̀ sí: Ọ̀rọ̀ wa jẹ Ọlọ́run lógún gan-an, ó sì fẹ́ ká máa gbàdúrà sí òun nípa àwọn ohun tó ń jẹ wá lọ́kàn.

Ìfihàn 21:4: “[Ọlọ́run] máa nu gbogbo omijé kúrò ní ojú wọn, ikú ò ní sí mọ́, kò ní sí ọ̀fọ̀ tàbí ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn nǹkan àtijọ́ ti kọjá lọ.”

Ohun tó túmọ̀ sí: Ọlọ́run máa fòpin sí gbogbo ohun tó ń fìyà jẹ wá, títí kan àwọn àjálù tó ń ṣẹlẹ̀.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́