Àwọn Ìjábá ti Ẹ̀dá—Ọlọrun Ni Ó Ha Ń Fà Á Bí?
“ỌLỌRUN, èyí tí o fi ṣe wá yìí ti jẹ́?”
Ohun tí a ròyìn pé ó jẹ́ ìdáhùnpadà olùlàájá kan tí ó ṣèwádìí nípa ìparun tí ìrujáde òkè Nevado del Ruiz tí òjò-dídì mọdi yíká mú wá ní Colombia ní November 13, 1985 nìyẹn. Ìṣànwálẹ̀ pẹ̀tẹ̀pẹ́tẹ̀ tí ó jẹ́ àbájáde rẹ̀ bo gbogbo ìlú-ńlá Armero mọ́lẹ̀ ó sì ṣekúpa ènìyàn tí ó ju 20,000 ní alẹ́ ọjọ́ kanṣoṣo.
Ó ṣeélóye pé olùlàájá náà lè hùwàpadà lọ́nà yẹn. Bí ó bá di pé wọn kò lè gbèjà araawọn mọ́ lójú àwọn ipá ẹ̀dá tí ń múni bẹ̀rù jìnnìjìnnì, àwọn ènìyàn láti ìgbà ìjímìjí ti ka irú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ oníjàábá bẹ́ẹ̀ sí ti Ọlọrun. Àwọn ará àtijọ́ rú àwọn ẹbọ, àní àwọn ẹbọ tí a fi ènìyàn rú pàápàá, láti tu àwọn ọlọrun wọn ti òkun, òfuurufú, ilẹ̀-ayé, òkè-ńlá, òkè ayọná-yèéfín, àti àwọn orísun ewu mìíràn lójú. Àní lónìí pàápàá, àwọn kan wulẹ̀ ń gba àbájáde àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ti ẹ̀dá tí ó jẹ́ alájàálù gẹ́gẹ́ bí àyànmọ́ tàbi àmúwá Ọlọrun.
Ǹjẹ́ Ọlọrun ni ó ń fa àwọn ìjábá tí ń mú ìjìyà àti àdánù tí ó pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ wá fún ènìyàn káàkiri ayé níti gidi bí? Òun ni ó ha yẹ kí a dẹ́bi fún bí? Láti rí àwọn ìdáhùn náà, ó yẹ kí a túbọ̀ wo ohun tí ó wémọ́ irúfẹ́ àwọn ìjábá bẹ́ẹ̀ kínníkínní síi. Nítòótọ́, o yẹ́ kí a tún àwọn òtítọ́-ìṣẹ̀lẹ̀ kan tí a mọ̀ yẹ̀wò.
Kí ni “Ìjábá ti Ẹ̀dá” Jẹ́?
Nígbà tí ìsẹ̀lẹ̀ kan sẹ̀ ní Tangshan, China, tí ó sì pa 242,000 ènìyàn gẹ́gẹ́ bí àwọn ìròyìn tí a fàṣẹ sí ti sọ ní China, àti nígbà tí Ìjì-Líle Andrew bìlu Gúúsù Florida àti Louisiana ní United States tí ó sì ba nǹkan ọ̀pọ̀ billion owó dọ́là jẹ́, irú àwọn ìjábá ti ẹ̀dá bẹ́ẹ̀ ni àwọn àjọ-akọ̀ròyìn jákèjádò àwọn orílẹ̀-èdè fún ní ìgbéjáde apàfíyèsí. Síbẹ̀, kání isẹ̀lẹ̀ yẹn ti sẹ̀ ní Aṣálẹ̀ Gobi tí a kìí gbé, ní 1,100 kìlómítà sí àríwá ìwọ̀-oòrùn Tangshan ń kọ́, tàbí kí a sọ pé Ìjì-Líle Andrew ti fẹ́ gba ọ̀nà kan tí ó yàtọ̀ lọ tí ó sì wọlẹ̀ sínú òkun, ní títàsé orí ilẹ̀ pátápátá ńkọ́? Agbára káká ni a ó fi rántí wọn nísinsìnyí.
Ní kedere, nígbà náà, bí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìjábá ti ẹ̀dá, kìí ṣe pé a wulẹ̀ ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìfihànsóde amúnijígìrì nípa àwọn ipá ti ẹ̀dá. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìsẹ̀lẹ̀ ni ń sẹ̀ lọ́dọọdún, ńlá àti kékeré, àti ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ẹ̀fúùfù líle, àfẹ́yípo-ìjì, ìjì-líle, ìjì-ńlá, ìrujáde òkè ayọná-yèéfín, àti àwọn àrà mérìíyìírí lílégbákan mìíràn tí wọ́n kò ṣe ohunkóhun ju kí wọ́n di àkọsílẹ̀ oníṣirò nínú àwọn ìwé àkọsílẹ̀ kan. Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà tí irú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ bá fa ìparun ìwàláàyè àti dúkìá ńláǹlà àti rúdurùdu ọ̀nà ìgbésí-ayé ojoojúmọ́, wọ́n di ìjábá.
A níláti ṣàkíyèsí pé ìbàjẹ́ àti àdánù tí ó máa ń yọrísí kìí fìgbà gbogbo bá àwọn ipá ti ẹ̀dá tí ó wémọ́ ọn dọ́gba. Ìjábá títóbi jùlọ ni kò fi dandan jẹ́ èyí tí ìfihànsóde àwọn ipá ti ẹ̀dá lílágbara jùlọ jẹ́ okùnfà fún. Fún àpẹẹrẹ, ní 1971 ìsẹ̀lẹ̀ kan tí ó wọn 6.6 lórí ìwọ̀n Richter sẹ̀ ní San Fernando, California, United States, ó sì ṣekúpa ènìyàn 65. Ní ọdún kan lẹ́yìn náà, ìsẹ̀lẹ̀ kan tí ó wọn 6.2 ní Managua, Nicaragua, pa 5,000 ènìyàn!
Nípa báyìí, nígbà tí ó bá di ti ìṣèparun àwọn ìjábá ti ẹ̀dá tí ń ga síi, a gbọ́dọ̀ béèrè pé, Àwọn ipá ìṣẹ̀dá ha ti túbọ̀ di èyí tí ó légbákan síi bí? Tàbí àwọn kókó-ọ̀ràn tí ó jẹ́ ti ènìyàn ha ti dákún ìṣòro náà bí?
Ta ni Ń Fà Á?
Bibeli fi Jehofa Ọlọrun hàn gẹ́gẹ́ bí Atóbilọ́lá Ẹlẹ́dàá gbogbo àwọn nǹkan, títíkan àwọn ipá ti ẹ̀dá orí ilẹ̀-ayé yìí. (Genesisi 1:1; Nehemiah 9:6; Heberu 3:4; Ìfihàn 4:11) Èyí kò túmọ̀sí pé ó ń mú kí gbogbo fífẹ́ ẹ̀fúùfù tàbí rírọ̀ òjò wáyé. Kàkà bẹ́ẹ̀, òun ti gbé ìlànà àwọn òfin kan kalẹ̀ tí ń ṣàkóso ilẹ̀-ayé àti àyíká rẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, ní Oniwasu 1:5-7, a kà nípa mẹ́ta lára àwọn ọ̀nà ìṣiṣẹ́ pàtàkì tí ó mú kí ìwàláàyè lórí ilẹ̀-ayé ṣeéṣe—yíyọ àti wíwọ̀ oòrùn lójoojúmọ́, ọ̀nà tí ẹ̀fúùfù gbà ń fẹ́ tí kìí yípadà, àti ètò àyípoyípo omi. Yálà aráyé mọ̀ nípa wọn tàbí wọ́n ṣaláìmọ̀, fún ọ̀pọ̀ ẹgbẹ̀rún ọdún ni àwọn ètò ti ẹ̀dá wọ̀nyí, àti àwọn mìíràn tí ó dàbí wọn, tí ó ní nínú ipò-ojú-ọjọ́, ìpele ilẹ̀, òkúta àti ẹ̀dá ilẹ̀-ayé, àti ibùgbé àwọn ohun alààyè orí ilẹ̀-ayé ti wà lẹ́nu iṣẹ́. Nítòótọ́, òǹkọ̀wé Oniwasu ń pe àfiyèsí sí ìyàtọ̀ ńláǹlà tí ó wà láàárín àwọn ọ̀nà ìṣẹ̀dá tí kìí yípadà tí kò sì lópin àti bí ìgbésí-ayé ẹ̀dá ènìyàn ti wà fún ìgbà díẹ̀ tí ó sì ń yára rékọjá lọ.
Kìí ṣe pé Jehofa jẹ́ Ẹlẹ́dàá àwọn ipá ti ẹ̀dá nìkan ni ṣùgbọ́n ó tún ní agbára láti ṣàkóso wọn. Jálẹ̀ Bibeli ni a rí àwọn àkọsílẹ̀ nípa bí Jehofa ti ń ṣàkóso tàbí dọ́gbọ́n-darí irú àwọn ipá bẹ́ẹ̀ láti ṣe àṣepé ète rẹ̀. Èyí ní nínú pípín Òkun Pupa níyà ní ọjọ́ Mose àti dídá oòrùn àti òṣùpá dúró ní ipa-ọ̀nà wọn la àwọn ọ̀rùn já ní ìgbà Joṣua. (Eksodu 14:21-28; Joṣua 10:12, 13) Jesu Kristi, Ọmọkùnrin Ọlọrun àti Messia tí a ṣèlérí náà, tún ṣàṣefihàn agbára rẹ̀ lórí àwọn ipá ti ẹ̀dá bíi, fún àpẹẹrẹ, nígbà tí ó mú kí ìjì kan parọ́rọ́ ní Òkun Galili. (Marku 4:37-39) Àwọn àkọsílẹ̀ bí irú èyí kò fi iyèméjì kankan sílẹ̀ pé Jehofa Ọlọrun àti Ọmọkùnrin rẹ̀, Jesu Kristi, lè ṣàkóso gbogbo ohun tí ń nípa lórí ìwàláàyè níhìn-ín lórí ilẹ̀-ayé lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́.—2 Kronika 20:6; Jeremiah 32:17; Matteu 19:26.
Bí ọ̀ràn ti rí báyìí, a ha lè sọ pé Ọlọrun ni ó ń fa òfò àti ìparun tí ń pọ̀ síi tí àwọn ìjábá ti ẹ̀dá ti múwá ní àwọn àkókò ẹnu àìpẹ́ yìí bí? Láti dáhùn ìbéèrè yìí, a gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ gbé e yẹ̀wò ná bí ẹ̀rí bá wà pé àwọn ipá ti ẹ̀dá ṣẹ̀ṣẹ̀ di èyí tí ó légbákan síi lọ́nà tí ó múnijígìrì lẹ́nu àìpẹ́ yìí, bóyá tí apá kò tilẹ̀ ká wọn mọ́.
Ní ìsopọ̀ pẹ̀lú èyí, ṣàkíyèsí ohun tí ìwé náà Natural Disasters—Acts of God or Acts of Man? ní láti sọ: “Kò sí ẹ̀rí pé àwọn ètò-ìṣiṣẹ́ ipò-ojú-ọjọ́ tí ó níí ṣe pẹ̀lú ọ̀dá, ìkún-omi, àti àfẹ́yípo-ìjì ń yípadà. Kò sì sí onímọ̀ nípa ìtàn ìpele ilẹ̀, òkúta àti ẹ̀dá inú ilẹ̀-ayé kan tí ń jẹ́wọ́ pé ìyẹ̀gẹ̀ẹ̀rẹ̀ ilẹ̀ tí ó níí ṣe pẹ̀lú àwọn ìsẹ̀lẹ̀, òkè ayọná-yèéfín àti tsunami (ìjì ìsẹ̀lẹ̀) túbọ̀ ń légbákan síi. Bákan-náà, ìwé Earthshock ṣàlàyé pé: “Àpáta gbogbo àgbáálá-ilẹ̀ ní àkọsílẹ̀ àìlóǹkà àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ nípa ìtàn ìpele ilẹ̀, òkúta àti ẹ̀dá alààyè èyí tí ó léwu jọjọ àti èyí tí kò tó nǹkan nínú, ọ̀kọ̀ọ̀kan èyí tí yóò jẹ́ ìjábá alájàálù-ibi fún aráyé bí wọ́n bá ṣẹlẹ̀ lónìí—ó sì dájú lọ́nà ti ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ pé irú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ yóò tún wáyé léraléra síi ní ọjọ́-iwájú.” Ní èdè mìíràn, ilẹ̀-ayé àti àwọn ipá alágbára-iṣẹ́ rẹ̀ ni ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ wà bákan-náà jálẹ̀ ọ̀pọ̀ sànmánì. Fún ìdí yìí, yálà àwọn ìsọfúnni oníṣirò kan fi ìbísí hàn nínú irú-oríṣi ìtàn ìpele ilẹ̀, òkúta àti ẹ̀dá alààyè kan tàbí ìgbòkègbodò mìíràn tàbí bẹ́ẹ̀kọ̀, ilẹ̀-ayé kò tíì di èyí tí ó lágbára lọ́nà tí kò ṣeé ṣàkóso ní àwọn àkókò ẹnu àìpẹ́ yìí.
Nígbà náà, kí ni ó lè ṣàlàyé ìdí fún ìpeléke tí a rí nínú ìṣelemọ́lemọ́ àti ìṣèparun àwọn ìjábá ti ẹ̀dá tí a ń kà nípa wọn? Bí a kò bá ní dẹ́bi fún àwọn ipá ẹ̀dá, ó jọ pé àwọn ènìyàn ni a ó nàka ẹ̀bi sí. Àwọn aláṣẹ sì ti mọ̀, nítòótọ́, pé ìgbòkègbodò àwọn ènìyàn ti mú kí sàkáání-àyíká wa túbọ̀ nítẹ̀sí síhà ìjábá ti ẹ̀dá kí ó sì tún jẹ́ èyí tí wọ́n lè tètè ṣèpalára fún. Ní àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, àìní tí ń ga síi fún oúnjẹ ń fípa mú àwọn àgbẹ̀ láti fi ilẹ̀ tí wọ́n ní dáko àdárégèé tàbí láti tún ilẹ̀ ṣe fún ọ̀gbìn nípa gígé àwọn igbó ṣíṣe pàtàkì tí wọ́n jẹ́ ìbòrí fún ilẹ̀ kúrò. Èyí ń yọrísí ìṣànlọ líléwu ti erùpẹ̀-ilẹ̀. Ìye àwọn ènìyàn tí ń di púpọ̀ síi tún ń mú kí àwọn i̇̀lé akúṣẹ̀ẹ́ àti àdúgbò onílé ẹgẹrẹmìtì tí a kọ́ gátagàta sí àwọn agbègbè tí ó léwu máa yárakánkán pọ̀ síi. Àní ní àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti túbọ̀ gòkè àgbà pàápàá, àwọn ènìyàn, bíi àràádọ́ta-ọ̀kẹ́ tí ń gbé lẹ́gbẹ̀ẹ́ San Andreas Fault ní California, ti ṣí ara wọn sílẹ̀ fún ewu láìka àwọn ìkìlọ̀ tí ó ṣe kedere sí. Nínú àwọn àyíká-ipò bẹ́ẹ̀, nígbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ àràmàǹdà kan—ìjì, ìkún-omi, tàbí ìsẹ̀lẹ̀—bá wáyé, a ha lè pe ìyọrísí oníjàábá náà ní “ti ẹ̀dá” bí?
Àpẹẹrẹ irú èyí kan ni ti ọ̀dá ní Sahel ti Africa. A sábà máa ń ro pé ọ̀dá jẹ́ àìsí òjò tàbí omi, tí ń yọrísí ìyàn, ìjìyà nítorí àìtó oúnjẹ, àti ikú. Ṣùgbọ́n ìyàn àti ìjìyà nítorí àìtó oúnjẹ ńláǹlà tí ó wà ní agbègbè yẹn ha wulẹ̀ jẹ́ kìkì nítorí àìsí omi bí? Ìwé náà Nature on the Rampage sọ pé: “Ẹ̀rí tí àwọn ẹgbẹ́-aṣojú ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ àti olùpèsè-ìrànlọ́wọ́ kójọ fihàn pé ìyàn ti òde-ìwòyí ń báa lọ láìdáwọ́dúró kìí ṣe nítorí ọ̀dá tí ó wà fún ìgbà pípẹ́ bíkòṣe nítorí àṣìlò àwọn ohun-àmúṣọrọ̀ inú ilẹ̀ àti omi tí ó wà fún ìgbà pípẹ́. . . . Dídi aṣálẹ̀ nìṣó Sahel lọ́nà tí ó pọ̀ jùlọ jẹ́ nítorí àwọn àrà-mérìíyìírí tí ènìyàn fọwọ́fà.” Ìwé-akéde-ìròyìn South Africa kan, The Natal Witness, ṣàlàyé pé: “Ìyàn kò jẹmọ́ àìsí oúnjẹ; ó jẹmọ́ àìrọ́nà débi tí oúnjẹ wà. Ní èdè mìíràn, ó jẹmọ́ òṣì.”
Ohun kan-náà ni a lè sọ nípa púpọ̀ lára iparun tí ń jẹyọ láti inú àwọn àjálù mìíràn. Àwọn ìwádìí ti fihàn pé àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n tòṣì jù ń jìyà ìwọ̀n ikú tí ó ga jù láti ọwọ́ àwọn ìjábá ti ẹ̀dá lọ́nà tí kò báradọ́gba ju bí ó ti rí pẹ̀lú àwọn orílẹ̀-èdè ayé tí wọ́n lọ́rọ̀ jù wọ́n lọ. Fún àpẹẹrẹ, láti 1960 sí 1981, gẹ́gẹ́ bí ìwádìí kan ti fihàn, Japan ṣẹlẹ́rìí ìsẹ̀lẹ̀ 43 àti àwọn ìjábá mìíràn ó sì pàdánù 2,700 ẹ̀mí, tí ó jẹ́ ikú 63 nínú ìjábá kọ̀ọ̀kan ní ìpíndọ́gba. Ní sáà-àkókò kan-náà, Peru ṣẹlẹ́rìí ìjábá 31 pẹ̀lú ikú 91,000, tàbí 2,900 nínú ìjábá kọ̀ọ̀kan. Kí ni ó fa ìyàtọ̀ náà? Àwọn ipá ti ẹ̀dá ti lè fa sábàbí náà, ṣùgbọ́n ìgbòkègbodò ènìyàn—ti ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà, ọrọ̀-ajé, ìṣèlú—ní ó gbọ́dọ̀ dáhùn fún ìyàtọ̀ títóbi náà tí ó wà nínú ìpàdánù ìwàláàyè àti ìparun ohun-ìní tí ó ti jẹ́ ìyọrísí rẹ̀.
Kí ni Àwọn Ojútùú Náà?
Àwọn onímọ̀-ìjìnlẹ̀ àti àwọn ògbógi ti gbìyànjú fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún láti hùmọ̀ àwọn ọ̀nà tí wọ́n lè gbà kojú àwọn ìjábá ti ẹ̀dá. Wọ́n fìtọpinpin wádìí jinlẹ̀ wọnú ilẹ̀-ayé láti ṣàwárí òye nípa ọ̀nà tí ìsẹ̀lẹ̀ àti àwọn ìrujáde òkè ayọná-yèéfín ń gbà ṣiṣẹ́. Pẹ̀lú àwọn sátẹ́láìtì ojú òfuurufú wọ́n fìṣọ́ra kíyèsí ipa-ìrìn ojú-ọjọ́ láti lè tọsẹ̀ àwọn ipa-ọ̀nà àfẹ́yípo-ìjì àti ìjì-líle tàbí sọ àsọtẹ́lẹ̀ ìkún-omi àti ọ̀dá. Gbogbo ìwádìí-jinlẹ̀ yìí ti fún wọn ní ìsọfúnni tí wọ́n nírètí pé yóò ràn wọ́n lọ́wọ́ láti dín ipa-ìyọrísí àwọn ipá ti ẹ̀dá wọ̀nyí kù.
Irú àwọn ìsapá bẹ́ẹ̀ ha ti mú àwọn ìyọrísí rere wá bí? Nípa irú ìgbésẹ̀ gbígbówólórí, ọlọ́gbọ́n-iṣẹ́-ẹ̀rọ-gíga yìí, àjọ kan tí ń ṣàbójútó sàkáání-àyíká ti ẹ̀dá ṣàlàyé pé: “Ìwọ̀nyí ní ààyè tiwọn. Ṣùgbọ́n bí wọ́n bá jẹ iye owó àti agbára tí kò báradọ́gba—bí wọ́n bá ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí àwáwí láti ṣàìkọbiara sí ewu jàm̀bá tí ó ti di apákan ẹgbẹ́-àwùjọ àwọn òjìyà ìpalára náà èyí tí ń mú kí àwọn ewu ìjábá túbọ̀ burú síi—nígbà náà wọ́n lè ṣe ìpalára púpọ̀ ju rere lọ.” Fún àpẹẹrẹ, nígbà tí ó wúlò láti mọ̀ pé bèbè etíkun níbi ti odò ti pínyà wọnú òkun ní Bangladesh ni ìkún-omi àti ìjì ìgbì òkun ń wuléwu nígbà gbogbo, ìmọ̀ yẹn kò ṣèdíwọ́ fún àràádọ́ta-ọ̀kẹ́ àwọn olùgbé Bangladesh láti máṣe di ẹni tí a fipá mú láti gbé níbẹ̀. Ìyọrísí náà ti jẹ́ ìjábá léraléra pẹ̀lú àdánù ikú tí iye rẹ̀ ń lọ sí ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún.
Lọ́nà tí ó ṣe kedere, ìsọfúnni oníkúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé lè wúlò dé kìkì ìwọ̀n-ààyè kan. Ohun mìíràn tí a nílò ni agbára láti mú àwọn ìkìmọ́lẹ̀ tí kò fún àwọn ènìyàn ní yíyàn tí ó pọ̀ bíkòṣe kí wọ́n gbé ní àwọn agbègbè tí ó ṣí sílẹ̀ ní pàtàkì sí ewu tàbí láti gbé ní àwọn ọ̀nà tí ń ba sàkáání-àyíká jẹ́ dínkù. Ní èdè mìíràn, láti mú kí ìpalára tí àwọn ohun náà ń ṣe fúyẹ́, yóò béèrè fún ṣíṣe àtúntò ètò-ìgbékalẹ̀ ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà, ètò-ọrọ̀-ajé, àti ìṣèlú lábẹ́ èyí tí a ń gbé pátápátá. Ta ní lè ṣàṣeparí irú iṣẹ́ kan bẹ́ẹ̀? Kìkì Ẹni náà tí ó lè ṣàkóso àní àwọn ipá tí ń ṣokùnfà àwọn ìjábá ti ẹ̀dá ni.
Àwọn Àmúwá Ọlọrun tí Ń Bẹ Níwájú
Jehofa Ọlọrun kì yóò wulẹ̀ wá ojútùú sí àwọn àmì náà nìkan, ṣùgbọ́n yóò wá gbòǹgbò orísun ìbànújẹ́ ènìyàn. Òun yóò fòpin sí ètò-ìgbékalẹ̀ oníwọra àti atẹnilóríba ti ìṣèlú, ìṣòwò, àti ìsìn tí ó ti “ṣe olórí ẹnìkejì fún ìfarapa rẹ̀.” (Oniwasu 8:9) Ẹnikẹ́ni tí ó bá mọ Bibeli dáradára kì yóò kùnà láti kíyèsi pé jálẹ̀ àwọn ojú-ewé rẹ̀ ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ wà tí ń tọ́kasí àkókò náà tí Ọlọrun yóò gbé ìgbésẹ̀ láti mú kí ayé dòmìnira kúrò lọ́wọ́ ìwà-burúkú àti ìjìyà àti láti mú paradise orí ilẹ̀-ayé kan ti àlàáfíà àti òdodo padàbọ̀sípò.—Orin Dafidi 37:9-11, 29; Isaiah 13:9; 65:17, 20-25; Jeremiah 25:31-33; 2 Peteru 3:7; Ìfihàn 11:18.
Ìyẹn, nítòótọ́, ni ohun tí Jesu Kristi kọ́ gbogbo àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti gbàdúrà fún, pé, “Kí ìjọba rẹ dé; ìfẹ́ tìrẹ ni kí a ṣe, bíi ti ọ̀run, bẹ́ẹ̀ ni ní ayé.” (Matteu 6:10) Ìjọba Messia náà yóò mú gbogbo àkóso ènìyàn aláìpé kúrò tí yóò sì fi òmíràn rọ́pò rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí wòlíì Danieli ti sọtẹ́lẹ̀: “Ní ọjọ́ àwọn ọba wọ̀nyí ni Ọlọrun ọ̀run yóò gbé ìjọba kan kalẹ̀, èyí tí a kì yóò lè parun títí láé: a kì yóò sì fi ìjọba náà lé orílẹ̀-èdè mìíràn lọ́wọ́, yóò sì fọ́ túútúú, yóò sì pa gbogbo ìjọba wọ̀nyí run, ṣùgbọ́n òun ó dúró títí láéláé.”—Danieli 2:44.
Kí ni Ìjọba Ọlọrun yóò ṣe àṣeparí rẹ̀ tí àwọn orílẹ̀-èdè lónìí kò lè ṣe? Bibeli mú kí a rí àrítẹ́lẹ̀ fífanimọ́ra nípa ohun tí ń bọ̀. Dípò àwọn ipò tí a fàwòrán ṣàpèjúwe ní àwọn ojú-ewé wọ̀nyí, irú bíi ìyàn àti òṣì, “ìkúnwọ́ ọkà ni yóò máa wà lórí ilẹ̀, lórí àwọn òkè ńlá ni èso rẹ̀ yóò máa mì,” “igi ìgbẹ́ yóò sì so èso rẹ̀, ilẹ̀ yóò sì máa mú àsunkún rẹ̀ wá, wọn ó sì wà ní àlááfíà ní ilẹ̀ wọn.” (Orin Dafidi 72:16; Esekieli 34:27) Nípa ti sàkáání-àyíká ti ẹ̀dá, Bibeli sọ fún wa pé: “Aginjù àti ilẹ̀ gbígbẹ yóò yọ̀ fún wọn; ijù yóò yọ̀, yóò sì tanná bíi lílì. . . . Nítorí omi yóò tú jáde ní aginjù, àti iṣàn omi ní ijù. Ilẹ̀ yíyan yóò sì di àbàtà, àti ilẹ̀ òùngbẹ yóò di ìsun omi.” (Isaiah 35:1, 6, 7) Ogun kì yóò sì sí mọ́.—Orin Dafidi 46:9.
Bí Jehofa Ọlọrun yóò ṣe ṣàṣeparí gbogbo ìyẹn, àti bí òun yóò ṣe bójútó gbogbo àwọn ipá ti ẹ̀dá kí wọ́n má baà fa ìpalára èyíkéyìí mọ́, ni Bibeli ko sọ. Bí ó ti wù kí ó rí, ohun tí ó dájú ni pé gbogbo àwọn tí ń gbé lábẹ́ àkóso òdodo yẹn “kì yóò ṣiṣẹ́ lásán, wọn kì yóò bímọ fún wàhálà: nítorí àwọn ni irú alábùkún Oluwa àti irú-ọmọ wọn pẹ̀lú wọn.”—Isaiah 65:23.
Nínú àwọn ojú-ewé ìwé-ìròyìn yìí, àti nínú àwọn ìtẹ̀jáde Watch Tower Society mìíràn pẹlu, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti ṣàlàyé léraléra pé Ìjọba Ọlọrun ní a fìdìí rẹ̀ múlẹ̀ ní ọ̀run ní ọdún 1914. Lábẹ́ ìdarí Ìjọba yẹn, ìjẹ́rìí yíká ilẹ̀-ayé ni a ti fi fúnni fún ohun tí ó súnmọ́ 80 ọdún, àti pé lónìí a ti wà lẹ́nu ọ̀nà àbáwọlé sínú “àwọn ọ̀run titun àti ayé titun.” Aráyé yóò dòmìnira kìí ṣe kúrò lọ́wọ́ àwọn ìrunbàjẹ́ ìjábá ti ẹ̀dá nìkan ni ṣùgbọ́n kúrò lọ́wọ́ gbogbo ìrora àti ìjìyà tí ó ti ń dààmú ìran ènìyàn fún ẹgbẹ̀rún ọdún mẹ́fà tí ó ti kọjá. Nípa àkókò yẹn a lè sọ nítòótọ́ pé, “ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.”—2 Peteru 3:13; Ìfihàn 21:4.
Ṣùgbọ́n, kí ni nípa ìsinsìnyí? Ọlọrun ha ti ń gbégbèésẹ̀ nítìtorí àwọn wọnnì tí ń bẹ nínú ìdààmú nítorí àwọn àyíká-ipò ti ẹ̀dá tàbí lọ́nà mìíràn bí? Lọ́nà tí ó dájú jùlọ òun ti ṣe bẹ́ẹ̀ ṣùgbọ́n ko fi dandan jẹ́ lọ́nà tí ọ̀pọ̀ ènìyàn lè retí.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]
Àwọn ìgbòkègbodò ènìyàn ti mú kí sàkáání-àyíká wa túbọ̀ nítẹ̀sí síhà ìjábá ti ẹ̀dá
[Àwọn Credit Line]
Laif/Sipa Press
Chamussy/Sipa Press
Wesley Bocxe/Sipa Press
Jose Nicolas/Sipa Press