ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w96 12/1 ojú ìwé 2-4
  • Nígbà Tí Ìjábá Ti Ìṣẹ̀dá Bá Ṣẹlẹ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Nígbà Tí Ìjábá Ti Ìṣẹ̀dá Bá Ṣẹlẹ̀
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Àwọn Àjálù Tó Ń Ṣẹlẹ̀?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Àjálù—Kí Nìdí Tó Fi Pọ̀ Tó Bẹ́ẹ̀?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Àwọn Ìjábá ti Ẹ̀dá—Ọlọrun Ni Ó Ha Ń Fà Á Bí?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Àwọn Ìjábá ti Ẹ̀dá—Àmì Àwọn Àkókò Ha Ni Bí?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
w96 12/1 ojú ìwé 2-4

Nígbà Tí Ìjábá Ti Ìṣẹ̀dá Bá Ṣẹlẹ̀

Accra, Gánà, July 4, 1995: Àrọ̀ọ̀rọ̀dá òjò tí ó tí ì pọ̀ jù lọ ní nǹkan bí 60 ọdún fa omíyalé ńláǹlà. Nǹkan bí 200,000 ènìyàn pàdánù gbogbo ohun tí wọ́n ní, 500,000 ènìyàn kò lè wọnú ilé wọn, ènìyàn 22 sì pàdánù ẹ̀mí wọn.

San Angelo, Texas, U.S.A., May 28, 1995: Ìjì líle àti yìnyín fọ́ ìlú yìí tí ó ní 90,000 olùgbé túútúú, ó sì ba ohun tí iye owó rẹ̀ tó 120 mílíọ̀nù dọ́là (U.S.) jẹ́.

Kobe, Japan, January 17, 1995: Ìsẹ̀lẹ̀ tí ó wáyé fún nǹkan bí 20 ìṣẹ́jú àáyá péré gbẹ̀mí ẹgbẹẹgbẹ̀rún ènìyàn, ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà mẹ́wàá mẹ́wàá fara pa, ọgọ́rọ̀ọ̀rún lọ́nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún sì di aláìnílé.

SÀNMÁNÌ kan tí a lè pè ní ti ìjábá ni a ń gbé. Ìròyìn kan láti ọ̀dọ̀ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ṣí i payá pé, ní sáà 30 ọdún láti 1963 sí 1992, iye ènìyàn tí ìjábá pa, tí ó fa ìpalára fún, tàbí tí ó yí nípò padà pọ̀ sí i ní ìpíndọ́gba ti ìpín 6 nínú ọgọ́rùn-ún lọ́dọọdún. Ipò pípòkúdu náà ti mú kí àjọ UN pe àwọn ọdún 1990 ní “Ẹ̀wádún fún Dídín Ìjábá Ti Ìṣẹ̀dá Kù Jákèjádò Ayé.”

Àmọ́ ṣáá o, ipá ìṣẹ̀dá—irú bí ìjì, ìyọnáyèéfín òkè, tàbí ìsẹ̀lẹ̀—kì í fìgbà gbogbo mú ìjábá wá. Ọgọ́rọ̀ọ̀rún ń ṣẹlẹ̀ lọ́dọọdún láìpa ẹ̀dá ènìyàn lára. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó bá mú ẹ̀mí àti dúkíà lọ́wọ́, ó tọ́ láti pè é ní ìjábá.

Ìlọsókè nínú ìjábá ti ìṣẹ̀dá dà bí ohun tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀. Ìwé náà, Natural Disasters—Acts of God or Acts of Man?, sọ pé: “Àwọn ènìyàn ń yí àyíká wọn padà láti mú kí ó fàyè gba àwọn ìjábá kan, wọ́n sì ń hùwà lọ́nà tí yóò jẹ́ kí àwọn ìjábá wọ̀nyẹn túbọ̀ ṣe ìpalára fún wọn.” Ìwé náà gbé àpẹẹrẹ àbá ìpìlẹ̀ kan kalẹ̀ pé: “Ìsẹ̀lẹ̀ níwọ̀nba nínú ìlú kan tí ó kún fún àwọn ẹgẹrẹmìtì ilé alábàrá tí wọ́n wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ àfonífojì, lè jẹ́ ìjábá, ní ti ikú ẹ̀dá ènìyàn àti ìjìyà. Ṣùgbọ́n ìjábá náà ha jẹ́ ìyọrísí ìmìtìtì ilẹ̀ tàbí nítorí pé àwọn ènìyàn ń gbé nínú irú àwọn ilé eléwu bẹ́ẹ̀ tí a kọ sórí àwọn ilẹ̀ eléwu bí?”

Lójú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìdí mìíràn wà tí ìlọsókè nínú ìjábá kò fi yani lẹ́nu. Ní nǹkan bí 2,000 ọdún sẹ́yìn, Jésù Kristi sọ tẹ́lẹ̀ pé “àìtó oúnjẹ àti [ìsẹ̀lẹ̀] . . . láti ibì kan dé ibòmíràn” wà lára àwọn ohun tí yóò sàmì sí “ìparí ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan.” (Mátíù 24:3, 6-8) Bíbélì pẹ̀lú sọ tẹ́lẹ̀ pé nígbà “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn,” àwọn ènìyàn yóò jẹ́ olùfẹ́ ara wọn, olùfẹ́ owó, aláìní ìfẹ́ni àdánidá, àti aláìní ìfẹ́ ohun rere.a (Tímótì Kejì 3:1-5) Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn ànímọ́ wọ̀nyí ń mú kí ènìyàn ṣe ohun tí ó lòdì sí àyíká rẹ̀, ní mímú kí ẹ̀dá ènìyàn di ẹni tí ipá ìṣẹ̀dá ṣe ìpalára fún. Àwọn ìjábá tí ó jẹ́ àfọwọ́fà ènìyàn tún jẹ́ ohun tí ó jẹ yọ láti inú àwùjọ aláìnífẹ̀ẹ́, nínú èyí tí àwọn tí ó pọ̀ jù lọ ń gbé.

Bí pílánẹ́ẹ̀tì wa ṣe túbọ̀ ń kún fọ́fọ́ fún olùgbé, bí ìhùwàsí ẹ̀dá ènìyàn ṣe túbọ̀ ń wu ènìyàn léwu, àti bí a ṣe túbọ̀ ń ṣi ọrọ̀ àlùmọ́nì ilẹ̀ ayé lò, ìjábá yóò túbọ̀ máa pọ́n ènìyàn lójú. Pípèsè ìrànwọ́ ń gbé ìpèníjà kalẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀ lé e yóò ti fi hàn.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Fún ìsọfúnni síwájú sí i lórí àmì àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, wo ìwé náà, Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun, ojú ìwé 98 sí 107, tí a tẹ̀ jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]

Òkè: Information Services Department, Gánà; ọwọ́ ọ̀tún: San Angelo Standard-Times

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 2]

Ẹ̀YÌN ÌWÉ: Maxie Roberts/Nípasẹ̀ ìyọ̀ọ̀da onínúure THE STATE

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́