ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w93 12/1 ojú ìwé 2-4
  • Àwọn Ìjábá ti Ẹ̀dá—Àmì Àwọn Àkókò Ha Ni Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìjábá ti Ẹ̀dá—Àmì Àwọn Àkókò Ha Ni Bí?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Àwọn Àjálù Tó Ń Ṣẹlẹ̀?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Àjálù—Kí Nìdí Tó Fi Pọ̀ Tó Bẹ́ẹ̀?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Àwọn Ìjábá ti Ẹ̀dá—Ọlọrun Ni Ó Ha Ń Fà Á Bí?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Nígbà Tí Ìjábá Ti Ìṣẹ̀dá Bá Ṣẹlẹ̀
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
w93 12/1 ojú ìwé 2-4

Àwọn Ìjábá ti Ẹ̀dá—Àmì Àwọn Àkókò Ha Ni Bí?

“ORÍLẸ̀-ÈDÈ yóò dìde sí orílẹ̀-èdè àti ìjọba sí ìjọba, àìtó oúnjẹ yóò sì wà àti àwọn ìsẹ̀lẹ̀ ní ibìkan tẹ̀lé òmíràn. Gbogbo nǹkan wọ̀nyí jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ìroragógó ìdààmú.” Pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, Jesu Kristi ṣàlàyé fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ní ọ̀rúndún 19 sẹ́yìn pé irúfẹ́ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó kún fún ìjábá bẹ́ẹ̀, papọ̀ pẹ̀lú ìbísí nínú ìwà-àìlófin, àti ìwàásù ìhìnrere Ìjọba Ọlọrun kárí-ayé, yóò bẹ̀rẹ̀ àmì alápá-púpọ̀ kan tí ń sàmìsí “ìparí ètò-ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan.”—Matteu 24:3-14, NW.

Lójú-ìwòye ìyẹn, a gbọ́dọ̀ béèrè pé, Àwa ha ń rí àwọn ìsẹ̀lẹ̀ alájàálù, ìjì-líle, ìkún-omi, ọ̀dá, àti ìyàn púpọ̀ síi ju ti àwọn ìran-ènìyàn àtijọ́ bí? Àti pé láìka ìtẹ̀síwájú nínú ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ àti ọgbọ́n-iṣẹ́-ẹ̀rọ sí, àwọn ènìyàn púpọ̀ síi ní ìbádọ́gba ha ń jìyà gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí rẹ̀ bí?

Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀, ìdáhùn náà jẹ́ bẹ́ẹ̀ni. Fún àpẹẹrẹ, ìwé-ìròyìn náà New Scientist kìlọ̀ pé “ayé lè retí àwọn ìjábá púpọ̀ síi nínú àwọn ọdún 1990 ju bí ó ti rí ní àwọn ẹ̀wádún tí ó kọjá.” Bákan náà, nínú ìwé-ìròyìn UN Chronicle ti June 1991, olùdarí Ètò-Àjọ Ipò-Ojú-Ọjọ́ Lágbàáyé sọ pé: “Ìtẹ̀sí náà ṣe kedere gan-an. Láti àwọn ọdún 1960 títí dé àwọn ọdún 1980 . . . , ìbísí ìlọ́po márùn-ún ti wà nínú ìṣelemọ́lemọ́ àwọn ìjábá ti ẹ̀dá ńláǹlà, àti ìbísí ìlọ́po mẹ́ta nínú àpapọ̀ àdánù ọrọ̀-ajé.” Ní pípèsè ọgbọ́n-ìwòye kékeré kan lórí kókó-ọ̀rọ̀ náà, World Health, ìwé-ìròyìn Ètò-Àjọ Ìlera Àgbáyé ti UN, ṣàlàyé pé: “A lè rí àpẹẹrẹ àwọn ìjábá ti ẹ̀dá àti ìyọrísí ìṣèparun wọn jálẹ̀ ọ̀rọ̀-ìtàn. Bí ó ti wù kí ó rí, bí ọ̀rúndún kọkànlélógún ti ń súnmọ́lé, a dojúkọ ìlúpọ̀mọ́ra àwọn ipò níti ìlọsókè-lọsódò iye ènìyàn, ibùgbé àwọn ohun alààyè, àti ti ọgbọ́n-iṣẹ́-ẹ̀rọ tí kò dúró sójúkan tí ó mú kí ọ̀pọ̀ iye ènìyàn jẹ́ ẹni tí ipa ìyọrísí àjálù ti ẹ̀dá àti èyí tí ènìyàn fọwọ́fà lè tètè ṣèpalára fún.”

Irú àwọn gbólóhùn bẹ́ẹ̀ kò ní jẹ́ ìyàlẹ́nu fún ẹnikẹ́ni tí ó bá ń fiyèsí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́. Àwọn àjọ-akọ̀ròyìn kò ṣàìfìgbà kan ní àwọn ìtàn tí kò finilọ́kànbalẹ̀ ní ànító, ìbáà jẹ́ ti ìrujáde òkè ayọná-yèéfín ní Philippines, ìsẹ̀lẹ̀ ní California, ìkún-omi ní Bangladesh, ìyàn ní Somalia, ìjì-líle ní Hawaii, tàbí ìjì ìgbì òkun ní Nicaragua. Agbára káká ní oṣù kan yóò fi kọjá lọ láìsí ìròyìn nípa ìjábá kan ní apá ibìkan tàbí òmíràn nínú ayé.

Àwọn ènìyàn kan ka èyí sí aláìjámọ́pàtàkì. Wọ́n ṣàròyé pé ìbísí tí ó farahàn kedere nínú àwọn ìjábá ní àkókò wa wulẹ̀ jẹ́ nítorí ríròyìn lọ́nà tí ó túbọ̀ dára tàbí nítorí pípa àkọsílẹ̀ tí ó túbọ̀ dára mọ́. Wọ́n ṣàròyé síwájú síi pé ènìyàn púpọ̀ síi ń jìyà lọ́wọ́ ìjábá kìkì nítorí pé ènìyàn púpọ̀ síi wà lónìí. Àwọn àròyé wọ̀nyí ha ni gbogbo ohun tí ń bẹ nínú ìròyìn náà bí?

Kíyèsí ohun tí a sọ nínú ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ ìwé ìròyìn New Scientist tí a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ lókè yìí. “A ròyìn àwọn ìjábá 523 ní àwọn ọdún 1960 àti 767 ní àwọn ọdún 1970. Nígbà tí ó di àwọn ọdún 1980, iye náà ti dé 1387.” Ó ń báa lọ láti ṣàlàyé pé “ríròyìn àwọn ìjábá lọ́nà tí ó túbọ̀ ṣe kedere síi ní China àti Soviet Union lè ṣàlàyé ìdí fún apákan lára ìlọsókè híhàn kedere náà ní àwọn ẹ̀wádún tí ó ti kọjá.” Ó wá fi kún un pé: “Àní bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, iye náà ń ga síi.” A kò lè fi ríròyìn lọ́nà tí ó túbọ̀ dára tàbí pípa àkọsílẹ̀ tí ó túbọ̀ dára mọ́ nìkanṣoṣo ṣàlàyé ìdí fún ìlọsókè lemọ́lemọ́ nínú iye àwọn ìjábá.

Síwájú síi, ìwé-ìròyìn UN Chronicle ti March 1992 ròyìn pé: “Ní àwọn ẹ̀wádún méjì tí ó ti kọjá, àwọn ènìyàn bíi million mẹ́ta ti pàdánù ìwàláàyè wọn tí ‘òfò, ìnira àti ìjìyà’ tí ìjábá ti ẹ̀dá mú wá sì ti nípa lórí 800 million síi.” Èyí túmọ̀sí pé nǹkan bíi ẹnìkan nínú ènìyàn méje tí ń gbé lórí ilẹ̀-ayé ni irú ìjábá tàbí ọ̀ràn ìbìnújẹ́ kan ti ṣẹlẹ̀ sí rí. Ìyẹn lè kódààmú báni nítòótọ́ ó sì fi ààyè tí kò tó nǹkan sílẹ̀ fún ìyèméjì pé tiwa ni sànmánì rúkèrúdò àti àìrójúráyè.

Níwọ̀n bí Bibeli ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ irú àkókò ìdààmú ńlá kan bẹ́ẹ̀, ó ha túmọ̀sí pé Ọlọrun ni ó ń fa àwọn ìjábá àti ìjìyà tí ń ti inú wọn jẹyọ bí? Ọ̀pọ̀ ènìyàn rò bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n kí ni àwọn òtítọ́ fihàn? Àti ní pàtàkì jù, kí ni Bibeli fihàn?

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 2]

Cover: W. Faidley/​Weatherstock

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]

Fọ́tò àárín: Mark Peters/Sipa Press

WHO/League of Red Cross

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́